“Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”
1 Ayé tó yí wa ká wà nínú òkùnkùn nípa ti ìwà rere àti tẹ̀mí. Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń tú “àwọn iṣẹ́ aláìléso” tó jẹ́ ti òkùnkùn fó, kí a lè máa yẹra fún àwọn òkúta ìkọ̀sẹ̀ tó lè ṣekú pani wọ̀nyí. Nítorí náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.”—Éfé. 5:8, 11.
2 “Èso ìmọ́lẹ̀” yàtọ̀ pátápátá sí òkùnkùn biribiri ayé yìí. (Éfé. 5:9) Láti sèso yìí ń béèrè pé kí á fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ ní ti bí a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ká jẹ́ irú ẹni tí Jésù tẹ́wọ́ gbà. A tún gbọ́dọ̀ máa fi irú àwọn ànímọ́ bíi fífi tọkàntọkàn ṣe nǹkan àti níní ìtara fún òtítọ́ hàn. Àbájáde èso yìí gbọ́dọ̀ máa fara hàn nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
3 Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn Ní Gbogbo Ìgbà tí Àǹfààní Bá Ṣí Sílẹ̀: Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn.” (Mát. 5:16) Ní àfarawé Jésù, a ń gbé ìmọ́lẹ̀ Jèhófà yọ nípa wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run àti nípa àwọn ète rẹ̀. A ń tàn gẹ́gẹ́ bí àwọn atànmọ́lẹ̀ nígbà tí a bá lọ sí ilé àwọn èèyàn, àti nígbà tí a bá tan òtítọ́ kálẹ̀ níbi iṣẹ́, nílé ẹ̀kọ́, láàárín àwọn aládùúgbò wa, tàbí níbikíbi tí a bá ti ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Fílí. 2:15.
4 Jésù sọ pé àwọn kan máa kórìíra ìmọ́lẹ̀. (John 3:20) Nítorí náà, a kì í rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ọ̀pọ̀ kò bá jẹ́ kí “ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi” mọ́lẹ̀ nínú wọn. (2 Kọ́r. 4:4) Jèhófà mọ ọkàn-àyà aráyé, kò sì fẹ́ kí àwọn tó ń ṣe àìṣòdodo wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.
5 Nígbà tí a bá ń tọ ọ̀nà Jèhófà tí a sì ń gbádùn ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí, àwa náà yóò lè tàn án fún àwọn ẹlòmíràn. Bí wọ́n bá rí i nínú ìwà wa pé a “ní ìmọ́lẹ̀ ìyè,” nígbà náà, ìyẹn lè mú kí àwọn pẹ̀lú ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, kí àwọn náà lè máa tan ìmọ́lẹ̀.—Jòh. 8:12.
6 Nípa jíjẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn, a ń mú ìyìn bá Ẹlẹ́dàá wa, a sì ń ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti wá mọ̀ ọ́n kí wọ́n sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Pét. 2:12) Níwọ̀n bí a ti ní ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ọ̀nà jáde kúrò nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀.