‘Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn’
1. Kí ni a láǹfààní láti ṣàjọpín?
1 Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn máa ń fi ògo fún Jèhófà Ọlọ́run. Síbẹ̀, irú ìmọ́lẹ̀ kan tó yàtọ̀ sí èyí ni Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní, ìyẹn ni “ìmọ́lẹ̀ ìyè.” (Jòh. 8:12) Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ fún wa láti ní irú òye tẹ̀mí yìí, ó sì tún gbé àwọn ojúṣe pàtàkì lé wa lọ́wọ́. Jésù fún wa ní ìtọ́ni pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn,” ká lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn ẹlòmíì láǹfààní. (Mát. 5:16) Bí òkùnkùn tẹ̀mí ti ṣú bo àwọn èèyàn yìí, a gbọ́dọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí yìí fún àwọn èèyàn, èyí sì ṣe pàtàkì gan-an lákòókò yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Bíi ti Kristi, báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn?
2. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí fún àwọn èèyàn?
2 Nípa Wíwàásù: Jésù lo àkókò rẹ̀, okun rẹ̀, àti ohun ìní rẹ̀ láti jẹ́ kí àwọn èèyàn rí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ nínú ilé wọn, ní ibi tí àwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí, lórí àwọn òkè, àti ní ibikíbi tó bá ti lè rí àwọn èèyàn. Ó mọ àǹfààní wíwà pẹ́ títí tí pípèsè ìlàlóye tẹ̀mí máa ṣe fún àwọn èèyàn. (Jòh. 12:46) Kí Jésù lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́, ó múra àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ láti jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Mát. 5:14) Wọ́n jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn nípa ṣíṣe ohun rere fún àwọn aládùúgbò wọn, tí wọ́n sì ń sọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.
3. Báwo la ṣe lè fi hàn látọkàn wá pé a mọrírì ìmọ́lẹ̀ òtítọ́?
3 Àwọn èèyàn Ọlọ́run fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wọn láti “máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀,” wọ́n sì máa ń wàásù níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí àwọn èèyàn. (Éfé. 5:8) Téèyàn bá kàn ń ka Bíbélì tàbí ìtẹ̀jáde ètò Ọlọrun míì níbi tí àwọn èèyàn wà, bóyá níbi iṣẹ́ tàbí ní àkókò oúnjẹ níléèwé, ó lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún wa láti jíròrò Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ohun tí ọ̀dọ́bìnrin kan ṣe nìyí tó fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, tí méjìlá lára àwọn ọmọ kíláàsì sì gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa.
4. Kí nìdí tí ‘jíjẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn’ fi kan híhu ìwà rere?
4 Nípa Ìwà Rere: Jíjẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn tún kan ìwà tá à ń hù lójoojúmọ́. (Éfé. 5:9) Níbi iṣẹ́, níléèwé àti níbòmíì tí àwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí, àwọn èèyàn máa ń kíyè sí ìwà Kristẹni tá a bá hù, ó sì máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti sọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn. (1 Pét. 2:12) Bí àpẹẹrẹ, ìwà rere tí ọmọkùnrin ọmọ ọdún márùn-ún kan hù mú kí olùkọ́ rẹ̀ pe àwọn òbí rẹ̀. Ó sọ pé: “Mi ò tíì rí ọmọ tó mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ bí èyí rí!” Bẹ́ẹ̀ ni o, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti ìwà rere wa máa ń mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí “ìmọ́lẹ̀ ìyè,” ó sì máa ń mú ìyìn wá fún Ọlọ́run.