ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/96 ojú ìwé 5-6
  • Jíjẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Wá Máa Tàn Ṣáá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Wá Máa Tàn Ṣáá
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn” Kẹ́ Ẹ Lè Fògo fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ẹ Tẹle Ìmólẹ̀ Ayé Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 7/96 ojú ìwé 5-6

Jíjẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Wá Máa Tàn Ṣáá

1 Kí ni ìmọ́lẹ̀? Ìwé atúmọ̀ èdè túmọ̀ rẹ̀ sí “ohun kan tí ń mú kí ìríran ṣeé ṣe.” Ṣùgbọ́n, ní ti gidi, láìka ìlọsíwájú rẹ̀ nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ sí, ènìyàn kò tí ì mọ ìdáhùn kíkún sí ìbéèrè tí Jèhófà gbé dìde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Jóòbù 38:24. A ha lè wà láìsí ìmọ́lẹ̀ bí? Láìsí ìmọ́lẹ̀, a kò lè wà láàyè. Ìmọ́lẹ̀ ṣe kókó fún ìríran ti ara, Bíbélì sì sọ fún wa pé, léro tẹ̀mí, “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀.” (1 Joh. 1:5) Ìwàláàye wá sinmi pátápátá lórí Ẹni tí ó ‘fún wa ní ìmọ́lẹ̀.’—Sm. 118:27.

2 Èyí jẹ́ òtítọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ jẹ́ òtítọ́ lọ́nà tẹ̀mí. Ìsìn èké ti ṣi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́nà, ní fífi wọ́n sílẹ̀ sínú òkùnkun tẹ̀mí, tí wọ́n “ń wá ògiri kiri bí afọ́jú.” (Aisa. 59:9, 10) Bí ìfẹ́ àti ìyọ́nú rẹ̀ tí ó tayọ ré kọja ohun gbogbó tí sún un, Jèhófà ‘rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ jáde.’ (Sm. 43:3) Ní ti gidi, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùmọrírì ti dáhùn padà, ní jíjáde “kúrò nínú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”—1 Pet. 2:9.

3 Jésù Kristi kó ipa pàtàkì nínú mímú ìmọ́lẹ̀ yìí wá sínú ayé. Ó sọ pé: “Èmí ti wá gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ sínú ayé, kí olúkúlùkù ẹni tí ń lo ìgbàgbọ́ nínú mí má baà wà nínú òkùnkùn.” (Joh. 12:46) Ó darí gbogbo àkókò, agbára, àti ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ sóri mímú kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ di mímọ̀. Ó rin igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìlú rẹ́, ó ń wàásù, ó sì ń kọ́ni ní gbogbo ìlú àti abúlé. Ó fara da inúnibíni tí kò dáwọ́ dúró ní gbogbo ìhà, ṣùgbọ́n ó dúró ṣinṣin nínú iṣẹ́ tí a yàn fún un láti tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ kiri.

4 Jésù pọkàn pọ̀ sórí yíyàn, kíkọ́, àti ṣíṣètò àwọn ọmọ ẹ̀yìn, pẹ̀lú góńgó pàtó kan lọ́kàn. Ní Mátíù 5:14-16, a ka ìtọ́ni rẹ̀ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. . . . Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín kí wọ́n sì lè fi ògo fún Bàbá yín tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run.” Gan-an gẹ́gẹ́ bíi Jésù, wọ́n ní láti jẹ́ “atànmọ́lẹ̀ nínú ayé,” ní títan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ kárí ayé. (Flp. 2:15) Wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ yẹn, ní wíwò ó gẹ́gẹ́ bí ète wọn àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti sọ pé, a ti “wàásù” ìhìn rere náà “nínu gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kol. 1:23) A so gbogbo ìjọ Kristẹni pọ̀ ṣọ̀kan nínú ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ ńlá yẹn.

5 Ó yẹ kí àwa lónìí kún fún ọpẹ́ pé a wà lára àwọn tí wọ́n ti “bọ́ àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn kúrò.” (Rom. 13:12, 13) A lè fi ìmọrírì wa hàn nípa ṣíṣàfarawé àpẹẹrẹ tí Jésù àti àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ní ìjímìjí fi lélẹ̀. Àìní náà fún àwọn ẹlòmíràn láti gbọ́ òtítọ́ jẹ́ kańjúkánjú, ó sì ṣe kókó nísinsìnyí ju ìgbà míràn nínú ìtàn ènìyàn lọ. Kò sí ìgbòkègbodò èyíkéyìí tí a lè fi wé iṣẹ́ yìí nínú ìjẹ́kánjúkánjú rẹ̀ àti àǹfààní ńlá tí ń mú wá.

6 Báwo Ni A Ṣe Lè Tàn bí Atànmọ́lẹ̀? Ọ̀nà àkọ́kọ́ tí a lè gbà jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wá tàn ni láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Gbogbo ìjọ ló ní ètò tí ó wà déédéé fún wíwàásù nínú ìpínlẹ̀ tí a yàn fún un. Ọ̀pọ̀ onírúurú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ni a mú wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ọlọ́kankòjọ̀kan àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. A ń pèsè ẹ̀kọ́ ní yanturu ní àwọn ìpàdé, àwọn tí ó sì nírìírí ń pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àǹfààní láti kópa ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọkùnrin, obìnrin, àgbàlagbà, àti àwọn ọmọdé pàápàá. Gbogbo ènìyàn nínú ìjọ ní a ké sí láti kópa ní ìwọ̀n tí agbára rẹ̀ àti ipò àyíká rẹ̀ yọ̀ǹda. Gbogbo ìgbòkègbodò ìjọ dá lórí iṣẹ́ ìwàásù, pẹ̀lú ìpèsè láti ran gbogbo mẹ́ḿbà ìjọ lọ́wọ́ láti nípìn-ín ní àwọn ọ̀nà kan. Ìkẹ́gbẹ́pọ̀ déédéé, tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìjọ ni ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti rí i dájú pé ìmọ́lẹ̀ wa ń tàn nìṣó.

7 A lè tàn ní àwọn ọ̀nà tí ó lè máà wé mọ́ fífẹnu jẹ́rìí. Kìkì ìwà wa lè fa àfiyèsí àwọn ẹlòmíràn mọ́ra. Ohun tí Pétérù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tí ó rọni pé: “Ẹ tọ́jú ìwa yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, . . . kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà èyí tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí rẹ̀ yin Ọlọ́run lógo.” (1 Pet. 2:12) Ọ̀pọ̀ ń ṣèdájọ́ iṣẹ́ tàbí ètò kan nípa ìwà àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ọn. Nígbà tí àwọn olùṣàkíyèsí bá kíyè sí àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ́ níwà, tí wọ́n jẹ́ aláìlábòsí, onífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, tí wọ́n sì ń pa òfin mọ́, wọ́n ń ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí àrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì máa ń dórí ìpinnu pé, àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n tí ó ga fíofío jù èyí tí ọ̀pọ̀ ń tẹ̀ lé lọ. Nítorí náà, ọkọ ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn nígbà tí ó bá bọlá fún aya rẹ̀ ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́, tí ó sì ń ṣìkẹ́ rẹ̀; aya ń ṣe ohun kàn náà nípa bíbọ̀wọ̀ fún ipò orí ọkọ rẹ̀. Àwọn ọmọ́ máa ń ta yọ gedegbe nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn, tí wọ́n sì ń yẹra fún ìwà pálapàla àti ìlòkulò oògùn. A máa ń mọrírì òṣìṣẹ́ tí ó bá ń ṣiṣẹ́ kára, tí ó jẹ́ aláìlábòsí, tí ó sì ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò. Nípa fífi àwọn ànímọ́ Kristẹni wọ̀nyí hàn, a ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wá tàn, ní dídábàá ọ̀nà ìgbésí ayé wa fún àwọn ẹlòmíràn.

8 Wíwàásù jẹ́ sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ohun tí a ti kọ́ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A ń ṣe èyí láti orí pèpéle tàbí láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, ṣùgbọ́n, kì í ṣe àwọn ìgbà wọ̀nyí nìkan ni a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ ń mú kí a ṣalábàápàdé ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ìgbà mélòó lójúmọ́ ni o ń bá àwọn alámùúlégbè rẹ sọ̀rọ̀ lóòjọ́? Ìgbà mélòó ni àwọn ènìyàn ń kan ilẹ̀kùn rẹ? Onírúurú ènìyàn mélòó ni o ń ṣalábàápàdé nígbà tí o bá lọ ra ọjà, tí o bá wọ ọkọ̀ èrò, tàbí nígbà tí o bá wà níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ? Bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tí ń re ilé ẹ̀kọ́, o ha lè ka iye ènìyàn tí o ń bá sọ̀rọ̀ lójúmọ́ bí? Àǹfààní láti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lọ rẹrẹ. Gbogbo ohun tí o ní láti ṣe kò ju níní èròngbà Ìwé Mímọ́ díẹ̀ lọ́kàn, jẹ́ kí Bíbélì àti ìwé àṣàrò kúkurú díẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kí o sì lo àtinúdá láti sọ̀rọ̀ jáde nígbà tí àǹfààní náà bá ṣí sílẹ̀.

9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣá rọrùn, àwọn kan máa ń lọ́ tìkọ̀ láti gbìyànjú rẹ̀ wò. Wọ́n lè máà fẹ́ sọ̀rọ̀, ní rínrin kinkin mọ́ ọn pé ojú ń ti àwọn tàbí ẹ̀rù ń ba àwọn láti tọ àwọn àjèjì lọ. Ẹ̀rú lè máa bà wọ́n láti pe àfiyèsí sí ara wọn tàbí láti gba ìdáhùn tí kò bára dé. Àwọn tí ó nírìírí nínú ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà lé sọ fún ọ pé kò sí ìdí kankan fún ṣíṣàníyàn. Bí àwa náà ni àwọn yòókù ti rí; àìní kan náà, àníyàn kan náà, ohun kan náà ni wọ́n ń fẹ́ fún ara wọn àti fún ìdílé wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ni yóò finú rere hàn sí ẹ̀rín músẹ́ tàbí ìkíni ọlọ́yàyà wa. Láti bẹ̀rẹ̀, o lè ní láti “máyà le.” (1 Tẹs. 2:2) Ṣùgbọ́n, bí o bá ti bẹ̀rẹ̀, àbájáde náà lè yà ọ́ lẹ́nu, kí ó sì mú inú rẹ dùn.

10 A Ń Bù Kún Wa Nígbà Tí A Bá Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Wá Tàn: Díẹ̀ lára àwọn ìrírí tí ń tuni lára láti inú ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà nìwọ̀nyí: Obìnrin ọlọ́dún 55 kan ń gbìdánwò láti fo ọ̀nà kọjá. Bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan ṣe fẹ́ gbá a, arábìnrin kan gbá ọwọ́ rẹ̀ mú, ó sì fà á kúrò nínú ewu, ní sísọ pé: “Ẹ máa rọra o. Àkókò eléwu ni a ń gbé!” Ó wá ṣàlàyé ìdí tí àkókò wa fi kún fún ewu. Obìnrin náà béèrè pe, “Ṣe ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́?” Nítorí tí ó ti gba ọ̀kan lára ìwé wa lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin, obìnrin náà fẹ́ rí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìbápàdé yìí sì mú kí ó ṣeé ṣe.

11 Arábìnrin kan bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú obìnrin kan tí ń dúró láti rí dókítà nínu ọ́fíìsì rẹ̀. Obìnrin náà tẹ́tí sílẹ̀ kínníkínní, ó sì sọ lẹ́yìn náà pé: “Fún ìgbà díẹ̀, mo ti ń ṣalábàápàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà; ṣùgbọ́n, bí mo bá di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́jọ́ iwájú, yóò jẹ́ nítorí ohun tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ bá mi sọ yìí. Títẹ́tí sílẹ̀ sí ọ dà bíi bíbẹ̀rẹ̀ sí í rí ìmọ́lẹ̀ níbi òkùnkùn kan.”

12 Ìṣe onínúure kan lè jẹ́ òkúta àtẹ̀gùn nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bí wọ́n ti ń darí sílé láti inú iṣẹ́ ìsin pápá, àwọn arábìnrin méjì kan kíyè sí ìyá àgbàlagbà kan tí ó jọ bí ẹni pé ó ń ṣàárẹ̀, bí ó ti sọ̀kalẹ̀ láti inú bọ́ọ̀sì. Wọ́n dúró, wọ́n sì bi ìyá náà bóyá ó nílò ìrànlọ́wọ́. Ó yà á lẹ́nu gidi pé àwọn àjèjì méjì pátápátá lè fi ìfẹ́ hàn nínú òun, débi pé ó rin kinkin mọ́ ọn láti mọ ohun tí ó fa ìṣe àyẹ́sí onínúure bẹ́ẹ̀. Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjẹ́rìí. Ìyá náà kò lọ́ tìkọ̀ kí ó tó fún wọn ní àdírẹ́sì rẹ̀, ó sì fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ké sí wọn láti ṣèbẹ̀wò. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. Kò pẹ́ kò jìnnà, ìyá náà bẹ̀rẹ̀ sí í re ìpàdé, ó sì ti ń ṣàjọpín òtítọ́ náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nísinsìnyí.

13 Arábìnrin àgbàlagbà kán máa ń lo àǹfààní jíjẹ́rìí ní àárọ̀ kùtùkùtù ní etíkun tí ó wà ní àdúgbò wọn. Ó máa ń ṣalábàápàdé àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, àwọn agbọmọtọ́, àwọn akọ̀wé báńkì, àti àwọn mìíràn, tí ń rìnrìn ìgbafẹ́ ní àárọ̀ kùtùkùtù ní bèbè òkun. Ó máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní jíjókòó sórí bẹ́ǹṣì. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí.

14 Ní ibi iṣẹ́ rẹ̀, arábìnrin kan gbọ́ tí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan ń sọ̀rọ̀ nípa ẹgbẹ́ òṣèlú kan tí ó gbà gbọ́ pé ó lè yanjú àwọn ìṣòro ayé. Arábìnrin náà sọ̀rọ̀ jáde, ní ríròyìn àwọn ìlérí nípa àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe. Ìjíròrò lẹ́nu iṣẹ́ yìí yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé déédéé, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀ di Ẹlẹ́rìí.

15 Má Ṣe Gbàgbé Láé Pé Ẹlẹ́rìí Ni Ọ́! Nígbà tí Jésù ṣàpèjúwe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìmọ́lẹ̀ ayé,” ó ronú pé ó yẹ kí wọ́n máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jàǹfààní láti inú ìlàlóye tẹ̀mí inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí a bá fi ìmọ̀ran Jésù sílò, ojú wo ni a óò fi wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

16 Nígbà tí wọ́n bá ń wá iṣẹ́, àwọn kan máa ń yan iṣẹ́ ààbọ̀ọ̀ṣẹ́. Wọ́n ń gbé ìdiwọ̀n karí iye àkókò tí wọn yóò lò àti iye ìsapá tí wọn yóò lò fún un, nítorí tí wọ́n yàn láti lo púpọ̀ jù lọ lára àkókò wọn ní lílépa àwọn ìgbòkègbodò tí wọ́n rí i pé ó túbọ̀ ń mérè wá. Àwá ha ń fojú kan náà wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bí? Bí a tilẹ̀ ronú pé ó di dandan fún wa, kí a sì múra tán pàápàá láti ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó ha yẹ kí ìfẹ́ ọkàn wa wà ní ibòmíràn bí?

17 Ní mímọ̀ pé kò sí ohun tí ń jẹ́ Kristẹni aláàbọ̀ àkókò, a ti ya ara wa sí mímọ́, ní ‘sísẹ́ níní ara wa,’ a sì ti gbà láti tẹ̀ lé Jésù “nígbà gbogbo.” (Mat. 16:24) Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ ‘afitọkàntọkànṣiṣẹ́,’ ní gbígbá gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ mú láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn, kí a baà lè kàn sí àwọn ènìyàn ní ibi yòówù kí wọ́n wà. (Kol. 3:23, 24) A gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ẹ̀mí ìrònú ayé, kí a pa ìtara wa mọ́, bíi ti ìbẹ̀rẹ̀, kí a sì rí i dájú pé ìmọ́lẹ̀ wa ń bá a nìṣó láti tàn kedere. Àwọn kan ti lè yọ̀ǹda fún ìtara wọn láti tutù, kí ìmọ́lẹ̀ wọ́n sì di bàìbàì, kí ó ṣòro láti rí láti ibi tí kò jìnnà. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti jèrè ìtara rẹ̀ tí ó ti pàdánù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

18 Àwọn kan lè nítẹ̀sí láti tàdí mẹ́yìn, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn iṣẹ́ wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé, ìhìn iṣẹ́ nípa Kristi jẹ́ “ìwà òmùgọ̀ lójú àwọn wọnnì tí ń ṣègbé.” (1 Kọr. 1:18) Bí ó ti wù kí ó rí, láìka ohun tí àwọn ẹlòmíràn sọ sí, ó fi tagbáratagbára polongo pé: “Èmi kò tijú ìhìn rere.” (Rom. 1:16) Ẹni tí ń tijú ń ronú pé òun kò tó ẹgbẹ́ tàbí ohun kò yẹ. Báwo ni ojú yóò ṣe tì wá, nígbà tí ó jẹ́ pé nípa Ọba Aláṣẹ Àgbáyé àti àwọn ìpèsè àgbàyanu tí òún ti ṣe fún ayọ̀ wa ayérayé ní a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀? Kò ní ṣeé gbọ́ sétí pé a ń ronú pé à kò tó ẹgbẹ́ tàbí pé a kò yẹ, nígbà tí a bá ń sọ òtítọ́ yìí fún àwọn ẹlòmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a ronú pé ó di dandan fún wa láti ṣe ipa wa, ní fífi ìdánilójú wa hàn pé a kò ní ‘ohun kankan láti tì wá lójú.’—2 Tim. 2:15.

19 Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tí ń tàn nísinsìnyí ní àwọn ilẹ̀ yíká ayé ń fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà nawọ́ ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè ayé tuntun kan síni. Ẹ jẹ́ kí a fi hàn pé a ti fi ìṣílétí náà láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wá tàn nígbà gbogbo sọ́kàn! Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò ní ìdí láti yọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n “ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù,” lójoojúmọ́.—Ìṣe 5:42.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́