‘Títàn bí Atànmọ́lẹ̀’
1 Lójú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí tó bolẹ̀ ayé àti ìlànà ìwà rere tó ń jó rẹ̀yìn nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, “ń tàn bí atànmọ́lẹ̀” ní ilẹ̀ tó tó igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] jákèjádò ayé. (Fíl. 2:15) Èyí ló jẹ́ ká dá yàtọ̀ gedegbe. Báwo la ṣe lè fi ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà hàn?—2 Kọ́r. 3:18.
2 Ìwà Wa: Àwọn èèyàn máa ń tètè kíyè sí ìwà tí à ń hù. (1 Pét. 2:12) Obìnrin kan kíyè sí i pé Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ onínúure àti ọmọlúwàbí, kì í sì í sọ ọ̀rọ̀ rírùn tàbí kó máa rẹ́rìn-ín sí àwọn àpárá tí kò bójú mu. Nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá gbìyànjú láti mú Ẹlẹ́rìí náà bínú nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ rírùn níbi tó wà, ńṣe ló máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́, síbẹ̀ á dúró lórí ìpinnu rẹ̀ láti ṣe ohun tó tọ́. Ipa wo ni ìwà rẹ̀ ní lórí obìnrin náà? Ó sọ pé: “Ìwà rẹ̀ wú mi lórí gan-an débi pé mo bẹ̀rẹ̀ sí béèrè àwọn ìbéèrè kan nípa Bíbélì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mo sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn ìgbà náà.” Ó fi kún un pé: “Ìwà rẹ̀ lohun tó sún mi láti ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́.”
3 Ìṣarasíhùwà wa sí àwọn tó wà ní ipò àṣẹ, ojú tí a fi ń wo àwọn àṣà ayé, àti ọ̀rọ̀ tó bójú mu tí à ń sọ, ló ń mú kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá yàtọ̀ gedegbe gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tó ń gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ṣíṣeyebíye tó wà nínú Bíbélì. Irú àwọn iṣẹ́ àtàtà bẹ́ẹ̀ ń fi ògo fún Jèhófà, wọ́n sì lè mú kí àwọn ẹlòmíràn nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn rẹ̀.
4 Ọ̀rọ̀ Tí À Ń Sọ: Ká sòótọ́, àwọn tó ń rí ìwà rere wa lè má mọ ìdí tí a fi yàtọ̀, àyàfi bí a bá sọ fún wọn nípa àwọn ohun tí a gbà gbọ́. Ǹjẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ tàbí àwọn ọmọléèwé rẹ mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́? Ǹjẹ́ o máa ń lo àwọn àǹfààní tó o bá ní láti jẹ́rìí nígbà tó o bá ń ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn? Ǹjẹ́ o ti pinnu láti jẹ́ “kí ìmọ́lẹ̀ [rẹ] máa tàn níwájú àwọn ènìyàn” ní gbogbo ìgbà tó bá ti ṣeé ṣe?—Mát. 5:14-16.
5 Pípa àṣẹ tí a fún wa mọ́ láti jẹ́ atànmọ́lẹ̀ ń béèrè pé ká ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Ìfẹ́ láti ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn yóò sún wa láti yẹra fún àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, ká bàa lè ṣe púpọ̀ sí i dé ibi tí agbára wa bá gbé e dé nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà, ìyẹn wíwàásù àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—2 Kọ́r. 12:15.
6 Nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ láti tàn bí atànmọ́lẹ̀. Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè sún àwọn ẹlòmíràn láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú fífi ògo fún Jèhófà.