ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/04 ojú ìwé 4-5
  • Ẹ Jẹ́ Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • A Máa Gbádùn Ìtura Nípa Tẹ̀mí fún Ọjọ́ Mẹ́ta
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Máa Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ṣíṣe Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 9/04 ojú ìwé 4-5

Ẹ Jẹ́ Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín

1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà wa?

1 Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run mímọ́, a máa ń sapá lójú méjèèjì láti jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà wa. (1 Pét. 1:15, 16) Èyí túmọ̀ sí pé a máa ń làkàkà láti rọ̀ mọ́ ìlànà Jèhófà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe nígbèésí ayé. Àpéjọ àgbègbè ọdún yìí á fún wa ní àǹfààní àkànṣe láti fi hàn pé a jẹ́ oníwà mímọ́.

2. Báwo la ṣe lè hùwà rere ní òtẹ́ẹ̀lì àti ní ilé tá a dé sí?

2 Ní Òtẹ́ẹ̀lì àti Ilé Tá A Dé Sí: Ọ̀gá òtẹ́ẹ̀lì kan táwọn ará wa tó lọ sí àpéjọ àgbègbè lọ́dún tó kọjá lò sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá síbí ṣèèyàn gan-an. . . . Irú èèyàn bíi tiyín là ń fẹ́ máa gbà lálejò ní òtẹ́ẹ̀lì wa.” Bí a bá ń ṣègbọràn sáwọn ìránnilétí tó tẹ̀ lé e yìí, a ò ní ba orúkọ rere tá a ní jẹ́: (1) Bó o bá máa dé sí òtẹ́ẹ̀lì, má ṣe gbà ju iye yàrá tó o máa nílò gan-an lọ, má sì ṣe jẹ́ kí èèyàn tó ju iye tí wọ́n gbà láyè wà pẹ̀lú rẹ nínú yàrá rẹ. (2) Bó bá pọn dandan pé kó o fagi lé ètò tó o ṣe fún gbígba yàrá, sọ fáwọn alábòójútó òtẹ́ẹ̀lì láìjáfara. (3) Má ṣe se oúnjẹ nínú àwọn yàrá tí wọn kò ti gba oúnjẹ sísè láàyè. (4) Máa fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù nígbà tó o bá ń bá àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì lò, pàápàá láwọn ìgbà tí ọwọ́ wọn máa ń dí gan-an, irú bíi táwọn àlejò bá fẹ́ gba yàrá tàbí tí wọ́n fẹ́ kúrò ní òtẹ́ẹ̀lì.—Gál. 5: 22, 23.

3. Báwo ni ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ èwe ṣe lè jẹ́ ohun ìwúrí fún àwọn èèyàn?

3 Ìwà ọmọlúwàbí wa lè jẹ́rìí fún àwọn èèyàn lọ́nà tó máa wọ̀ wọ́ lọ́kàn. Lọ́dún tó kọjá, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí fi ohùn pẹ̀lẹ́ béèrè ohun ìkọ̀wé lọ́wọ́ akọ̀wé òtẹ́ẹ̀lì kan, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wú akọ̀wé náà lórí, ó sì sọ pé: “Ká sòótọ́, irú àwọn ọ̀dọ́ èèyàn tí wọ́n mọ̀wàáhù báyìí ṣọ̀wọ́n lóde òní.” Àmọ́ ṣá o, láwọn ibì kan, àwọn èèyàn kíyè sí i pé ńṣe làwọn ọmọ tí kò sí ẹni tó ń mójú tó wọn ń lúwẹ̀ẹ́, tí wọ́n ń ṣeré lórí àtẹ̀gùn, tí wọ́n ń pariwo gèè, tàbí tí wọ́n ń sáré kiri láàárín ọ̀dẹ̀dẹ̀. Kí àwọn òbí má ṣe gba àwọn ọmọ wọn láyè láti máa káàkiri láìsí àbójútó, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ní láti mójú tó wọn kí wọ́n lè rí i pé ìwà wọn fiyìn fún Jèhófà.—Òwe 29:15.

4. Àwọn wo ló yẹ kó dé sí ilé tá a kọ́ sí ilẹ̀ àpéjọ?

4 Ní ọ̀pọ̀ ibi tí àpéjọ ti máa wáyé, a máa ń ṣètò ilé táwọn ará máa dé sí nílẹ̀ àpéjọ, bóyá kí èyí jẹ́ ibi tá a pèsè fún wọn láti lò fúngbà díẹ̀ tàbí kó jẹ́ ilé tá a dìídì kọ́ fún ìlò àwọn ará. Jọ̀wọ́, rántí pé kò ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ ilé tí gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ máa dé sí. Kìkì àwọn tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí ni kí wọ́n sun ilẹ̀ àpéjọ mọ́jú. Bó bá jẹ́ ibòmíràn ni wọ́n bá ọ wálé sí, rí i pé o fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kó o sì dé síbi tí wọ́n ṣètò fún ọ.

5. Báwo la ṣe lè gba tàwọn ẹlòmíràn rò nígbà tá a bá lọ jẹun nílé oúnjẹ?

5 Nílé Oúnjẹ: Ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ agbáwo nílé oúnjẹ kan nítòsí ibi táwọn ará wa ti ṣe àpéjọ àgbègbè sọ pé: “Ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí yàtọ̀. Àwọn máa ń bọ̀wọ̀ fúnni.” Lára ohun tó ń fi hàn pé à ń hùwà rere ni pé ká yẹra fún ariwo pípa tàbí rírẹ́rìn-ín sókè débi tí èyí á fi dí àwọn mìíràn tí ń jẹun lọ́wọ́. Kódà, nígbà tá a bá ń jẹ tàbí tí à ń mu pàápàá, ó yẹ ká sapá láti máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 10:31.

6, 7. Kí ló yẹ ká ṣe nílẹ̀ àpéjọ tó máa fi hàn pé à ń hùwà rere?

6 Nílẹ̀ Àpéjọ: Ní pàtàkì, ó yẹ kí ìwà rere wa hàn gbangba nílẹ̀ àpéjọ. Jọ̀wọ́, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àwọn olùtọ́jú èrò níbi ìgbọ́kọ̀sí àti ní gbọ̀ngàn àpéjọ. (Héb. 13:17) Kí gbogbo ìdílé jókòó síbì kan náà dípò kí a jẹ́ kí àwọn ọmọ, pàápàá àwọn ọ̀dọ́langba, lọ jókòó pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ mìíràn. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe so ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ èyíkéyìí mọ́ iná mànàmáná tàbí mọ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ àpéjọ, kí a sì rí i pé a lò wọ́n lọ́nà tí wọn kò fi ní dí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Bó o bá fẹ́ ya fọ́tò, má ṣe lo kámẹ́rà abunáyẹ̀rì nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Orí ìjókòó rẹ ni kó o ti ya fọ́tò nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́ kó o má bàa fa ìpínyà ọkàn fún àwọn ẹlòmíràn. Má ṣe pe àwọn onífọ́tò wá sí ilẹ̀ àpéjọ láti wá ya fọ́tò. Kí a yí ẹ̀rọ atanilólobó àti tẹlifóònù alágbèérìn sílẹ̀ kí wọ́n má bàa pín ọkàn àwọn mìíràn níyà. Bó o bá kíyè sí i pé ẹnì kan fara pa nílẹ̀ àpéjọ, jọ̀wọ́ sọ fún olùtọ́jú èrò kan tàbí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìtọ́jú Pàjáwìrì. Àwọn tó lè tọ́jú aláìsàn dáadáa wà nílẹ̀ àpéjọ láti mójú tó ohun tó bá ṣẹlẹ̀.

7 Láwọn àpéjọ tó kọjá, ńṣe làwọn kan máa ń sáré nítorí àtigba ìwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Kò yẹ ká máa sáré, ká máa fara gbúnni tàbí ká máa ti àwọn mìíràn torí pé a fẹ́ gbàwé. Ńṣe ló yẹ ká rọra tò sórí ìlà. A ti sapá gan-an láti rí i dájú pé àwọn tó wá sí àpéjọ rí ìwé tuntun gbà.—1 Kọ́r. 14:40.

8. Báwo ni ìwà wa ṣe ń fògo fún Ọlọ́run?

8 Ìwà wa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a yàtọ̀, ó sì ń fògo fún Ọlọ́run. (1 Pét. 2:12) Ní àpéjọ àgbègbè, kedere làwọn èèyàn máa ń rí ìwà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá hù. Nítorí náà, pinnu pé wàá jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà rẹ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Jẹ́ Oníwà Mímọ́

◼ Pa gbogbo òfin òtẹ́ẹ̀lì mọ́

◼ Mójú tó àwọn ọmọ rẹ dáadáa

◼ Gba ti àwọn ẹlòmíràn rò

◼ Má ṣe dé sí ilé tá a kọ́ sí ilẹ̀ àpéjọ bó bá jẹ́ pé ibòmíràn ni wọ́n ṣètò fún ọ

◼ Ṣe jẹ́jẹ́ nígbà tó o bá fẹ́ gbàwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́