Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ṣíṣe Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà
1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká ṣọ́ ìwà wa ní àpéjọ àgbègbè?
1 Nígbà tí àwa Ẹlẹ́rìí púpọ̀ bá wà ní àpéjọ àgbègbè, ìwà wa àti ohun tá à ń ṣe sí àwọn ẹlòmíràn máa ń tètè hàn sí àwọn tó ń wò wá. Nítorí náà, ó yẹ kí olúkúlùkù wa kọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì yìí dáadáa, ìyẹn: “Yè kooro ní èrò inú, nínú ohun gbogbo, máa fi ara rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:6, 7) Èyí lè gba pé ká túbọ̀ sapá láti ‘má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ (Fílí. 2:4) Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn apá tá a ti lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò nígbà Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” tí ń bọ̀.
2. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tó bá dọ̀ràn ètò ilé tí a óò dé sí?
2 Ètò Ilé Tí A Óò Dé Sí: Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa kọ́wọ́ ti ìṣètò àpéjọ náà. Èyí sì ṣe kókó, pàápàá nígbà tá a bá ń ṣètò ilé tá a fẹ́ dé sí. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún yàrá la máa ń nílò fún àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ará wa ni kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, tó sì jẹ́ pé yàrá tówó rẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n ni agbára wọ́n ká. A ti sapá gidigidi láti wá àwọn yàrá tówó rẹ̀ mọ níwọ̀n. Ó yẹ ká fi ìfẹ́ gba tàwọn ẹlòmíràn rò, ká ‘má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’—Fílí. 2:4.
3. Báwo la ṣe lè “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn” ní òtẹ́ẹ̀lì?
3 Bó bá jẹ́ pé òtẹ́ẹ̀lì la dé sí, ó yẹ ká fi ire àwọn ẹlòmíràn sọ́kàn bí a ṣe ń lo òtẹ́ẹ̀lì náà. A óò mọrírì rẹ̀ gan-an bí a bá gba tàwọn mìíràn rò nípa pípa àwọn òfin tó rọ̀ mọ́ lílo òtẹ́ẹ̀lì náà mọ́. Ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, à ń “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn,” a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́rìí fáwọn èèyàn lọ́nà tó múná dóko.—Gál. 6:10.
4, 5. Báwo làwọn ọmọ ṣe lè mú káwọn èèyàn yin Jèhófà lógo, kí sì ni ojúṣe àwọn òbí?
4 Àwọn Òbí Àtàwọn Ọmọ: Nínú ayé tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ti yàyàkuyà yìí, ó hàn gbangba sí àwọn èèyàn pé ìwà àwọn ọmọ wa yàtọ̀, èyí sì ń mú kí Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ gba ìyìn. Àmọ́, nígbà mìíràn, ìṣòro máa ń jẹ yọ nígbà tá ò bá mójú tó wọn bó ṣe yẹ. (Òwe 29:15) Kí àwọn òbí má ṣe fi àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ láìsí àbójútó ní òtẹ́ẹ̀lì, ní ibi odò ìlúwẹ̀ẹ́ tàbí ní ilẹ̀ àpéjọ.
5 Àwọn òbí kan máa ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ ṣáájú àpéjọ nípa irú ìwà tó yẹ kí wọ́n hù. (Éfé. 6:4) Wọ́n á jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé ìfẹ́ tòótọ́ tí àwọn Kristẹni ní “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu,” kì í sì í “wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́r. 13:5) A ti ya àkókò àpéjọ àgbègbè sọ́tọ̀ láti gba ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, àtọmọdé àtàgbà sì lè tipa ìwà wọn ní ibi àpéjọ náà àti níbòmíràn bọ̀wọ̀ fún ìṣètò yìí.—Aísá. 54:13.
6. Ipa wo ni ìwà rere wa lè ní lórí àwọn ẹlòmíràn?
6 Ìwà rere wa lè jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé ohun tí àwọn ń rò nípa wa kò rí bí wọ́n ṣe rò, èyí sì lè mú kí wọ́n fẹ́ láti ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. (Mát. 5:16; 1 Pét. 2:12) Ǹjẹ́ kí á tipa ìṣe wa àti ìwà tá a bá hù sáwọn èèyàn jẹ́rìí lọ́nà tó múná dóko fún gbogbo àwọn tá a bá bá pàdé ní àpéjọ àgbègbè wa. Lọ́nà yìí, a ó lè ‘máa fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn iṣẹ́ àtàtà,’ á óò sì máa fi ògo fún Jèhófà.—Títù 2:7.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Gba Tàwọn Ẹlòmíràn Rò
▪ Yàrá tí wàá lò nìkan ni kó o gbà
▪ Ṣe sùúrù nígbà táwọn tó ni òtẹ́ẹ̀lì bá ń ṣètò àtigbà ọ́ wọlé àti nígbà tó o bá ń fi ibẹ̀ sílẹ̀
▪ Má ṣe lo ilé tàbí òtẹ́ẹ̀lì tó o dé sí nílòkulò
▪ Rí i dájú pé o pa àwọn òfin òtẹ́ẹ̀lì mọ́
▪ Mójú tó àwọn ọmọ rẹ dáadáa