‘Ẹ Máa Lépa Ohun Rere Nígbà Gbogbo’
1 Jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni ń béèrè pé ká máa ‘lépa ohun rere sí gbogbo ènìyàn nígbà gbogbo.’ (1 Tẹs. 5:15) Nígbà tá a bá lọ sí àwọn àpéjọ àgbègbè wa, a máa ń ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti ṣe ohun tó dára fún àwọn ẹlòmíràn. Láwọn àkókò yẹn, kedere làwọn èèyàn máa ń rí wa, gbogbo àwọn tá a bá sì bá pàdé ló máa ní àwọn èrò kan pàtó lọ́kàn nípa wa, ó sinmi lórí ọ̀nà tá a bá gbà bá wọn lò. Tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣì máa kan sáárá sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí ìwà rere tí wọ́n mọ̀ wá mọ́, a ní láti máa fi hàn nínú ìwà wa pé à ń “bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.” (1 Pét. 2:17) Èyí ń béèrè pé a ò ní ‘máa mójú tó ire ara wa nínú kìkì àwọn ọ̀ràn tiwa nìkan, ṣùgbọ́n ire ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ (Fílí. 2:4) Wo bí èyí ṣe kan ètò ilé gbígbé ní àpéjọ àgbègbè.
2 Ṣé o ti ṣètò fún ilé tó o máa dé sí? (1) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo yàrá tó bá ti ṣí sílẹ̀ ni Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé fẹ́ láti fi àwọn ará sí, má ṣe béèrè ju iye yàrá tó o máa nílò lọ. (2) Má ṣe retí pé Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé yóò tọ́jú yàrá sílẹ̀ fún ọ, àyàfi bó o bá ti fi fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé ránṣẹ́ ṣáájú àkókò tó o máa dé síbẹ̀. (3) Nígbà tó o bá dé Gbọ̀ngàn Àpéjọ, fi sùúrù àti ọ̀wọ̀ bá àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé lò, bí wọ́n ti ń sapá láti ṣètò ibi tó o máa dé sí. (4) Bó o bá dé sí òtẹ́ẹ̀lì, tẹ̀ lé gbogbo ìlànà tó ní í ṣe pẹ̀lú lílo àyíká òtẹ́ẹ̀lì náà.
3 Kíkọ́ Àwọn Ọmọ Bí Wọ́n Ṣe Lè Ṣe Ohun Tó Dara: Láwọn ìgbà kan, àwọn ọmọ kéékèèké tá a fi sílẹ̀ láìsí ẹnì kan tí yóò máa mójú tó wọn ti dá wàhálà sílẹ̀ níbi tí wọ́n dé sí. (Òwe 29:15) Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ńṣe làwọn òbí gbájú mọ́ nǹkan míì tí wọ́n sì fi àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ nínú yàrá tàbí ibòmíràn láìsí àmójútó kankan. Ìjàngbọ̀n àwọn ọmọ míì pọ̀ débi pé, ńṣe làwọn onílé ká wọn lọ́wọ́ kò láti má ṣe lo àwọn ohun èlò kan tàbí láti má ṣe dé àwọn àgbègbè kan nínú ilé náà. Ìdíwọ́ sì lèyí jẹ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí àtàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ilé náà.
4 Ẹ̀yin òbí, ṣáájú àpéjọ náà, ì bá dára tẹ́ ẹ bá lè lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ yín láti bá wọn jíròrò irú àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni, èyí tẹ́ ẹ retí pé kí wọ́n máa hù nígbà gbogbo àti níbi gbogbo. (Efé. 6:4) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ojúlówó ìfẹ́ Kristẹni “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù.” (1 Kọ́r. 13:5) Àwọn tó jẹ́ àgbàlagbà lè fi ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ yìí hàn nípa fífi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún gbogbo èèyàn láti rí. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ lè ṣe ohun rere nípa ṣíṣègbọràn sáwọn òbí yín, nípa rírí i pé ẹ kò ṣe àwọn nǹkan tó wà nínú ilé tẹ́ ẹ dé sí báṣubàṣu, àti nípa gbígba tàwọn tó wà láyìíká yín rò. (Kól. 3:20) Bí gbogbo wa lápapọ̀ ti ń làkàkà láti ṣe ohun tó dára sí gbogbo èèyàn, ńṣe là ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.
5 Kì í ṣe àwọn tó ń wò wá lókèèrè nìkan ni ìwà rere wa máa ń wú lórí, àmọ́ ó tún máa ń ní ipa rere lórí àwọn tó ti máa ń ṣe lámèyítọ́ wa fún ìdí kan tàbí òmíràn pàápàá. Nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe ní àpéjọ náà àti ní ìlú tí àpéjọ náà ti máa wáyé—bóyá à ń rìn lọ lójú pópó ni o, à ń jẹun nílé àrójẹ ni o, à ń najú ní òtẹ́ẹ̀lì kan ni o, tàbí ńṣe là ń lo àǹfààní èyíkéyìí tó ṣí sílẹ̀ láti wàásù lọ́nà tí kì í ṣe bí àṣà—ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣesí wa tó jẹ́ ti Kristẹni máa fi hàn pé a fẹ́ láti máa ṣe ohun tó dára.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Jọ̀wọ́ Rántí:
■ Fi sùúrù àti ọ̀wọ̀ bá àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé lò.
■ Tẹ̀ lé gbogbo ìlànà òtẹ́ẹ̀lì tó o dé sí, kí ara lè tu àwọn ẹlòmíràn tẹ́ ẹ jọ wà níbẹ̀.
■ Mójú tó ìṣesí àwọn ọmọ rẹ dáadáa.