Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Wọ́n Wà Lójúfò!
“Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè. Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ó wà lójúfò tí ó sì pa àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́.”—ÌṢÍPAYÁ 16:15.
1. Níwọ̀n bí ọjọ́ Jèhófà ti kù sí dẹ̀dẹ̀, kí ni a lè retí?
ỌJỌ́ ńlá Jèhófà kù sí dẹ̀dẹ̀, ìyẹn sì túmọ̀ sí ogun! Nínú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù rí “àwọn àgbéjáde tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí,” tí ó dà bí àkèré, tí ń lọ sọ́dọ̀ “àwọn ọba,” tàbí àwọn olùṣàkóso, ti ilẹ̀ ayé. Láti ṣe kí ni? Họ́wù, “láti kó wọn jọ pa pọ̀ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè”! Jòhánù fi kún un pé: “Wọ́n . . . kó wọn jọ pa pọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—Ìṣípayá 16:13-16.
2. Ta ni Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó bá gbéjà ko àwọn ènìyàn Jèhófà?
2 Láìpẹ́, Jèhófà yóò sún ètò ìṣèlú ti ètò ìgbékalẹ̀ yí láti pa Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, run. (Ìṣípayá 17:1-5, 15-17) Lẹ́yìn náà, Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù, Sátánì Èṣù tí a ti rẹ̀ sílẹ̀ sí sàkáání ilẹ̀ ayé, yóò ṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, yóò sì fi gbogbo agbára gbéjà ko àwọn ènìyàn Jèhófà, àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, tí ó dà bí ẹni pé wọn kò lólùgbèjà. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:1-12) Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀ láti yọ àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú ewu. Ìyẹn ni yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ “ọjọ́ ńlá àti ẹ̀rù Olúwa.”—Jóẹ́lì 2:31; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:18-20.
3. Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ìsíkẹ́ẹ̀lì sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:21-23?
3 Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò yọ àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú ewu, yóò sì pa gbogbo ìyókù ìràlẹ̀rálẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì run, nígbà tí a bá dé ipò ayé tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì, tàbí Amágẹ́dọ́nì. Ka àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ ti Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:21-23, kí o sì fojú inú wo ìran náà. Jèhófà yóò lo agbára rẹ̀ láti mú àrágbáyamúyamù ìkún omi, yìnyín ìsọdahoro, iná ajólala, àjàkálẹ̀ àrùn apanirun, wá. Jìnnìjìnnì yóò bo gbogbo ayé bí ìdàrúdàpọ̀ ti ń bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gọ́ọ̀gù, ní bíbá ara wọn jà. Èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀tá Ọlọ́run Olódùmarè tí ó bá là á já ni a óò pa bí Jèhófà ti ń lo agbára ajẹ̀dálọ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ là. Nígbà tí “ìpọ́njú ńlá” tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà bá parí, kò sí ohun tí yóò ṣẹ́ kù nínú ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì aláìwà-bí-Ọlọ́run. (Mátíù 24:21) Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá ń joró ikú wọn lọ́wọ́ pàápàá, àwọn ẹni búburú náà yóò mọ ẹni tí ó mú àjálù bá wọn. Ọlọ́run wa aṣẹ́gun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Wọn óò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.” Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa, nígbà wíwàníhìn-ín Jésù.
Ó Ń Bọ̀ Bí Olè
4. Ní ọ̀nà wo ni Jésù yóò gbà wá láti pa ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí run?
4 Jésù Kristi Olúwa tí a ṣe lógo wí pé: “Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè.” Lójijì ni olè máa ń dé, ní àìròtẹ́lẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ti sùn. Nígbà tí Jésù bá wá gẹ́gẹ́ bí olè láti pa ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí run, òun yóò pa àwọn tí wọ́n bá wà lójúfò ní tòótọ́ mọ́. Ó sọ fún Jòhánù pé: “Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ó wà lójúfò tí ó sì pa àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́, kí ó má baà rìn ní ìhòòhò kí àwọn ènìyàn sì wo ipò ìtìjú rẹ̀.” (Ìṣípayá 16:15) Kí ni pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Báwo sì ni a ṣe lè wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
5. Ìṣètò wo fún iṣẹ́ ìsìn ní tẹ́ńpìlì ni ó wà nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé?
5 Ní gbogbogbòò, a kì í tú ẹ̀ṣọ́ kan síhòòhò bí ó bá sùn lẹ́nu iṣẹ́. Ṣùgbọ́n, ìyẹn ṣẹlẹ̀ ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, tí ìpín àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sì ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Ní ọ̀rúndún kọkànlá ṣááju Sànmánì Tiwa ni Ọba Dáfídì ṣètò ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àlùfáà ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn sínú ẹgbẹ́ kan tí ó ní ìpín 24. (Kíróníkà Kíní 24:1-18) Ìpín kọ̀ọ̀kan tí ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún, tí a dá lẹ́kọ̀ọ́, ń ṣe ipa tiwọn nínú bíbójútó àwọn apá iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀mejì láàárín ọdún kan fún odindi ọ̀sẹ̀ kan gbáko lẹ́ẹ̀kan. Ṣùgbọ́n, nígbà Àjọ Àgọ́, gbogbo ìpín 24 máa ń pésẹ̀ fún iṣẹ́. A tún nílò àfikún ìrànwọ́ nígbà ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá.
6. Kí ni Jésù lè ti máa tọ́ka sí nígbà tí ó wí pé, “Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ó wà lójúfò tí ó sì pa àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́”?
6 Nígbà tí Jésù wí pé, “Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ó wà lójúfò tí ó sì pa àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́,” ó ti lè máa tọ́ka sí ọ̀nà ìgbàṣe kan tí a ń tẹ̀ lé nígbà náà lọ́hùn-ún, tí ó ní iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ nínú tẹ́ńpìlì nínú. Ìwé Mishnah ti àwọn Júù sọ pé: “Ibi mẹ́ta ni àwọn àlùfáà ti ń ṣọ́nà nínú Tẹ́ńpìlì: ní Ìyẹ̀wù Abtinas, ní Ìyẹ̀wù Ọwọ́ Iná, àti ní Ìyẹ̀wù Ààrò; àwọn ọmọ Léfì sì máa ń wà ní ibi mọ́kànlélógún: àwọn márùn-ún ni ẹnubodè márùn-ún ti Òkè Tẹ́ńpìlì, àwọn mẹ́rin ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin inú rẹ̀, àwọn márùn-ún ní ibi márùn-ún nínú ẹnubodè Àgbàlá Tẹ́ńpìlì, àwọn mẹ́rin ní orígun mẹrẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ tí ń bẹ níta, àti ọ̀kan ní Ìyẹ̀wù Ìrúbọ, àti ọ̀kan ní Ìyẹ̀wù Ìkélé, àti ọ̀kan lẹ́yìn ibi Ìjókòó Àánú [níta ògiri ẹ̀yìn Ibi Mímọ́ Jù Lọ]. Ọ̀gá Òkè Tẹ́ńpìlì máa ń lọ yíká pẹ̀lú òtùfù ní ọwọ́ rẹ̀ láti wo ẹ̀ṣọ́ kọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀ṣọ́ èyíkéyìí kò bá sì dìde dúró, kí ó sì wí pé, ‘Àlàáfíà fún ọ, ọ̀gá Òkè Tẹ́ńpìlì!’ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti sùn, yóò fi ọ̀pá rẹ̀ lù ú, ó sì ní ẹ̀tọ́ láti jó ẹ̀wù rẹ̀.”—The Mishnah, Middoth (“Ìdiwọ̀n”), 1, ìpínrọ̀ 1 àti 2, tí a túmọ̀ láti ọwọ́ Herbert Danby.
7. Èé ṣe tí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tí ń ṣẹ́ṣọ̀ọ́ ní tẹ́ńpìlì fi ní láti wà lójúfò?
7 Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Léfì àti àlùfáà ti ìpín tí ń ṣiṣẹ́ sìn máa ń wà lójúfò ní gbogbo òru láti máa ṣẹ́ṣọ̀ọ́, kí wọ́n má sì ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìmọ́ wọnú àwọn àgbàlá tẹ́ńpìlì. Níwọ̀n bí “ọ̀gá Òkè Tẹ́ńpìlì,” tàbí “olóòtú tẹ́ńpìlì,” ti ń lọ yípo gbogbo ibùdó 24 nígbà ìṣọ́ òru, olùṣọ́ kọ̀ọ̀kan ní láti wà lójúfò ní ibùdó rẹ̀ bí kò bá fẹ́ kí ọwọ́ tẹ òun pé òun kò náání iṣẹ́ òun.—Ìṣe 4:1.
8. Kí ni ẹ̀wù àwọ̀lékè ìṣàpẹẹrẹ ti Kristẹni?
8 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ní láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì jẹ́ kí ẹ̀wù àwọ̀lékè ìṣàpẹẹrẹ wọn wà lára wọn. Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀rí tí ó fara hàn ti yíyàn tí a yàn wá sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà. Ní mímọ èyí, a ní ẹ̀mí mímọ́, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wa àti láti ṣe ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba. Sísùn ní ibùdó wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run yóò fi wá sínú ewu dídi ẹni tí ọwọ́ Jésù Kristi tẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ Olóòtú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí. Bí a bá ti sùn nípa tẹ̀mí lákòókò yẹn, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, a óò bọ́ wa síhòòhò, a óò sì jó ẹ̀wù ìṣàpẹẹrẹ wa. Nítorí náà, báwo ni a ṣe lè wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
Bí A Ṣe Lè Wà Lójúfò
9. Èé ṣe tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni fi ṣe pàtàkì?
9 Ìkẹ́kọ̀ọ́ aláápọn nínú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni jẹ́ ìsúnniṣe fún wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí. Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ yóò mú wa gbára dì fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú yánpọnyánrin, yóò sì fọ̀nà ayọ̀ ayérayé hàn wá. (Òwe 8:34, 35; Jákọ́bù 1:5-8) Ó yẹ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa múná dóko, kí ó sì máa tẹ̀ síwájú. (Hébérù 5:14–6:3) Bí a bá ń jẹ oúnjẹ àtàtà déédéé, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò, kí ara wa sì dá ṣáṣá. Ó lè dènà ṣíṣe sùọ̀sùọ̀, tí ó lè jẹ́ àmì àìjẹunre-kánú. Kò sí ìdí kankan fún wa láti ṣàìjẹunre-kánú nípa tẹ̀mí, kí a sì máa sùn, nítorí Ọlọ́run ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú.” (Mátíù 24:45-47) Jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé jẹ́ ọ̀nà kan láti wà lójúfò, kí a sì jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.”—Títù 1:13.
10. Báwo ni àwọn ìpàdé Kristẹni, àwọn àpéjọ, àti àwọn àpéjọpọ̀ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
10 Àwọn ìpàdé Kristẹni, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Wọ́n ń pèsè ìṣírí àti àǹfààní láti “ru ara wa lọ́kàn sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Ó ṣe pàtàkì pé kí a máa pé jọ déédéé bí a ti ń “rí ọjọ́ náà tí ń sún mọ́lé.” Ọjọ́ náà ti sún mọ́lé gidigidi nísinsìnyí. Ó jẹ́ “ọjọ́ Jèhófà,” nígbà tí yóò dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre. Bí ọjọ́ yẹn bá ṣe pàtàkì sí wa ní tòótọ́—ó sì yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀—a kò ní “ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì.”—Hébérù 10:24, 25; Pétérù Kejì 3:10.
11. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe pàtàkì fún wíwàlójúfò nípa tẹ̀mí?
11 Lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tọkàntọkàn ṣe pàtàkì fún wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí. Nínípìn-ín déédéé nínú wíwàásù ìhìn rere àti fífi ìtara ṣe é ń mú kí a wà lójúfò. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń fún wa ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀, àti àwọn ète rẹ̀. Ó ń tẹ́ni lọ́rùn láti jẹ́rìí láti ilé dé ilé, láti ṣe ìpadàbẹ̀wò, àti láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú àwọn ìtẹ̀jáde bí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àwọn alàgbà ní Éfésù ìgbàanì lè jẹ́rìí sí i pé, Pọ́ọ̀lù ti kọ́ wọn “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 20:20, 21) Àmọ́ ṣáá o, àwọn kan tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ní ìṣòro àìlera líle koko tí ń dí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lọ́wọ́ bákan ṣáá, ṣùgbọ́n, wọ́n ń wá àwọn ọ̀nà láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti ipò ọba rẹ̀, wọ́n sì ń rí ìdùnnú ńlá nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.—Orin Dáfídì 145:10-14.
12, 13. Àwọn ìdí wo ni ó yẹ kí ó mú kí a yẹra fún ìkẹ́rabàjẹ́ nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu?
12 Yíyẹra fún ìkẹ́rabàjẹ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀, Jésù rọ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín kí ọkàn àyà yín má baà di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn wọnnì tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Lúùkù 21:7, 34, 35) Àjẹkì àti ìmutípara kò bá ìlànà Bíbélì mu rárá. (Diutarónómì 21:18-21) Òwe 23:20, 21 sọ pé: “Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí; nínú àwọn tí ń ba ẹran ara àwọn tìkáraawọn jẹ́. Nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ọ̀lẹ ni yóò sì fi àkísà bo ara rẹ̀.”—Òwe 28:7.
13 Ṣùgbọ́n, bí àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri kò bá tilẹ̀ tí ì dé ibẹ̀ yẹn, wọ́n lè mú kí ẹnì kan máa ṣe sùẹ̀sùẹ̀, kí ó yọ̀lẹ, kí ó má sì tara ṣàṣà nípa ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, àníyàn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdílé, ìlera, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ yóò wà. Síbẹ̀, a óò láyọ̀ bí a bá fi ire Ìjọba sí ipò kíní, tí a sì ní ìgbọ́kànlé pé Bàbá wa ọ̀run yóò pèsè fún wa. (Mátíù 6:25-34) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, “ọjọ́ yẹn” yóò dé bá wa bí “ìdẹkùn,” bóyá bíi pàkúté awúrúju tí yóò mú wa láìròtẹ́lẹ̀ tàbí bíi pàkúté tí a fi ìjẹ dẹ, irú èyí tí ń fa àwọn ẹranko tí kò fura mọ́ra, tí ó sì ń mú wọn. Èyí kò ní ṣẹlẹ̀ sí wa bí a bá wà lójúfò, tí a mọ̀ ní tòótọ́ pé, a ń gbé ní “ìgbà ìkẹyìn.”—Dáníẹ́lì 12:4.
14. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a gbàdúrà tọkàntọkàn?
14 Àdúrà àtọkànwá jẹ́ àrànṣe mìíràn fún wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ńlá, Jésù rọ̀ wá síwájú sí i pé: “Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn.” (Lúùkù 21:36) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ jẹ́ kí a gbàdúrà pé kí a lè máa wà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà nígba gbogbo, kí a sì gbádùn ìdúró onítẹ̀ẹ́wọ́gbà nígbà tí Jésù, Ọmọkùnrin ènìyàn, bá wá láti pa ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí run. Fún ire tiwa àti fún ire àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí a ń gbàdúrà fún, a ní láti ‘wà lójúfò nínú àdúrà.’—Kólósè 4:2; Éfésù 6:18-20.
Àkókò Ń Tán Lọ
15. Kí ni iṣẹ́ ìsìn wa gẹ́gẹ́ bí oníwàásù òdodo ń mú kí a ṣàṣeparí rẹ̀?
15 Bí a ti ń dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà, kò sí àníàní pé, a fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bí a bá gbàdúrà sí i tọkàntọkàn nípa èyí, “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” lè ṣí sílẹ̀ fún wa. (Kọ́ríńtì Kíní 16:8, 9) Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yàn bá tó, Jésù yóò ṣèdájọ́, yóò sì ya “àwọn àgùntàn” olódodo tí wọ́n yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun sọ́tọ̀ kúrò lára “àwọn ewúrẹ́” aláìwà-bí-Ọlọ́run tí wọ́n yẹ fún ìparun ayérayé. (Jòhánù 5:22) Kì í ṣe àwa ni a óò ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ ìsìn wa gẹ́gẹ́ bí oníwàásù òdodo nísinsìnyí ń fún àwọn ènìyàn ní àǹfààní láti yan ìgbésí ayé ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọ́run, kí wọ́n sì tipa báyìí ní ìrètí dídi ẹni tí a yà sọ́tọ̀ fún ìyè nígbà tí Jésù “bá dé nínú ògo rẹ̀.” Kíkúrú tí àkókò tí ó ṣẹ́ kù fún ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí kúrú túbọ̀ ń mú kí ìjẹ́pàtàkì ìgbòkègbodò àfitọkàntọkànṣe ga sí i bí a ti ń wá àwọn ‘tí wọ́n ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.’—Mátíù 25:31-46; Ìṣe 13:48.
16. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a jẹ́ olùfìtara-pòkìkí Ìjọba?
16 Àkókò tán fún ayé ọjọ́ Nóà, yóò sì tán fún ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí láìpẹ́. Ẹ jẹ́ kí a jẹ́ olùfìtara-pòkìkí Ìjọba. Iṣẹ́ ìwàásù wa ń tẹ̀ síwájú, nítorí lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ni a ń batisí ní fífi àmì ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọ́run hàn. Wọ́n ń di apá kan ètò àjọ tí Jèhófà bù kún—‘àwọn ènìyàn rẹ̀, àti àgùntàn pápá rẹ̀.’ (Orin Dáfídì 100:3) Ẹ wo irú ìdùnnú tí ó jẹ́ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, tí ń mú ìrètí wá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, kí “ọjọ́ ńlá àti ẹ̀rù Olúwa” tó dé!
17, 18. (a) Bí a ti ń wàásù, ìhùwàpadà wo ni ó yẹ kí a retí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn? (b) Kí ni ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olùyọṣùtì?
17 Gẹ́gẹ́ bíi Nóà, a ní ìtìlẹyìn Ọlọ́run àti ààbò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ènìyàn, àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n para dà, àti àwọn Néfílímù ti gbọ́dọ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu ìhìn iṣẹ́ Nóà, ṣùgbọ́n ìyẹn kò dá a dúró. Lónìí, àwọn kan ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìhìn iṣẹ́ wa, nígbà tí a bá ń tọ́ka sí ẹ̀rí rẹpẹtẹ pé, a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Tímótì Kejì 3:1-5) Irú ìyọṣùtì bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa wíwàníhìn-ín Kristi, nítorí Pétérù kọ̀wé pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn ti ara wọn wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yí tí a ti ṣèlérí náà dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’”—Pétérù Kejì 1:16; 3:3, 4.
18 Àwọn olùyọṣùtì lóde òní lè ronú pé: ‘Kò sí ohun tí ó tí ì yí pa dà láti ìgbà ìṣẹ̀dá. Ìgbésí ayé ń lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ, bí àwọn ènìyàn ti ń jẹ, tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń bímọ. Bí Jésù bá wà níhìn-ín pàápàá, òun kò ní múdàájọ́ ṣẹ ní àkókò tèmi.’ Ẹ wo bí wọ́n ti kùnà tó! Bí àwọn ohun mìíràn tí ń fa ikú kò bá tilẹ̀ pa wọ́n ní àkókò yí, dájúdájú, ọjọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ti Jèhófà yóò mú ìparun wá bá wọn, gẹ́gẹ́ bí ìparun òjijì ti Ìkún Omi ṣe mú òpin dé bá ìran búburú ní ọjọ́ Nóà.—Mátíù 24:34.
Ní Gbogbo Ọ̀nà, Ẹ Wà Lójúfò!
19. Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ìgbòkègbodò wa ní ti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?
19 Bí a bá ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ǹjẹ́ kí a má ṣe jẹ́ kí ìrònú tí kò tọ́ mú kí a sùn láé. Àkókò nìyí láti wà lójúfò, láti lo ìgbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ àtọ̀runwá, àti láti ṣe iṣẹ́ àṣẹ wa láti “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Bí ètò ìgbékalẹ̀ yí ti dojú kọ òpin rẹ̀ ìkẹyìn, a kò lè ní àǹfààní mìíràn tí ó tóbi ju ti ṣíṣiṣẹ́sin Jèhófà Ọlọ́run lọ, lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi, àti nínípìn-ín nínú iṣẹ́ yíká ayé ti wíwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí,” kí òpin tó dé.—Mátíù 24:14; Máàkù 13:10.
20. Àpẹẹrẹ wo ni Kélẹ́ẹ̀bù àti Jóṣúà fi lélẹ̀ fún wa, kí sì ni ìgbésẹ̀ wọn fi hàn wá?
20 Àwọn kan lára àwọn ènìyàn Jèhófà ti ń ṣiṣẹ́ sìn fún ẹ̀wádún, bóyá fún àkókò ìgbésí ayé. Àní bí kò bá sì tilẹ̀ tí ì pẹ́ púpọ̀ tí a tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́, ẹ jẹ́ kí a dà bíi Kélẹ́ẹ̀bù, tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, tí ó “tẹ̀ lé OLÚWA lẹ́yìn pátápátá.” (Diutarónómì 1:34-36) Òun àti Jóṣúà ti múra tán pátápátá láti wọnú Ilẹ̀ Ìlérí kété lẹ́yìn tí a ti dá Ísírẹ́lì nídè kúrò nínú ìgbèkùn àwọn ará Íjíbítì. Ṣùgbọ́n, àwọn àgbàlagbà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbogbòò kò ní ìgbàgbọ́, wọ́n sì ní láti lo ogójì ọdún nínú aginjù, níbi tí wọ́n kú sí. Kélẹ́ẹ̀bù àti Jóṣúà fara da ìnira pẹ̀lú wọn ní gbogbo àkókò yẹn, ṣùgbọ́n, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ àwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyẹn wọnú ilẹ̀ ìlérí náà. (Númérì 14:30-34; Jóṣúà 14:6-15) Bí a bá ‘ń tẹ̀ lé Jèhófà pátápátá,’ tí a sì wà lójúfò nípa tẹ̀mí, a óò ní ìdùnnú wíwọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.
21. Kí ni yóò jẹ́ ìrírí wa bí a bá wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
21 Ẹ̀rí fi hàn ní kedere pé, a ń gbé ní àkókò òpin àti pé ọjọ́ ńlá Jèhófà kù sí dẹ̀dẹ̀. Kì í ṣe àkókò nìyí láti sùn, kí a má sì náání ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run. A óò bù kún wa kìkì bí a bá wà lójúfò nípa tẹ̀mí, tí a sì pa ẹ̀wù ìdánimọ̀ wa mọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni òjíṣẹ́ àti ìránṣẹ́ Jèhófà. Ǹjẹ́ kí ó jẹ́ ìpinnu wa láti ‘wà lójúfò, láti dúró gbọn-ingbọn-in nínú ìgbàgbọ́, láti máa bá a nìṣó bí ọkùnrin, láti di alágbára ńlá.’ (Kọ́ríńtì Kíní 16:13) Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ adúrógbọn-in àti onígboyà. Nígbà náà, a óò wà lára àwọn tí wọ́n wà ní sẹpẹ́ nígbà tí ọjọ́ ńlá Jèhófà bá dé, tí wọ́n ń fi òtítọ́ ṣiṣẹ́ sìn nínú ẹgbẹ́ àwọn aláyọ̀ tí wọ́n wà lójúfò.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni ìwọ yóò ṣe túmọ̀ ẹ̀wù àwọ̀lékè ìṣàpẹẹrẹ wa, báwo sì ni a ṣe lè pa wọ́n mọ́?
◻ Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
◻ Èé ṣe tí a fi ní láti retí àwọn olùyọṣùtì, ojú wo sì ni ó yẹ kí a fi wò wọ́n?
◻ Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí a ń ṣe ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]
Àwọn Kristẹni ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà lójúfò, kí wọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìwọ ha pinnu láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí àti láti pa ẹ̀wù àwọ̀lékè ìṣàpẹẹrẹ rẹ mọ́ bí?