“Ẹ Wà Lójúfò”
1 Lẹ́yìn tí Jésù ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí yóò sàmì sí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí, ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti “wà lójúfò.” (Máàkù 13:33) Èé ṣe tí àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ wà lójúfò? Ó jẹ́ nítorí pé àkókò tó léwu jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn la wà yìí. Bí a bá lọ tòògbé pẹ́rẹ́n nípa tẹ̀mí, a gbé nìyẹn o. Ìyẹn ò sì ní jẹ́ ka mọrírì iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ lákòókò òpin yìí. Iṣẹ́ wo nìyẹn ná?
2 Jèhófà ní káwọn èèyàn rẹ̀ máa pòkìkí ìhìn rere nípa Ìjọba rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ayé, ìyẹn sì ni ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé. Ṣíṣiṣẹ́ tí a ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ètò Ọlọ́run ń fi wá hàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó mọ irú àkókò táa wà yìí, àti pé a mọ̀ pé ó yẹ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbọ́ “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:68) Nípa fífi ìtara ṣe nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí, ńṣe la ń fẹ̀rí hàn pé a wà lójúfò nípa tẹ̀mí.
3 A Sún Wa Láti Wàásù: Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, ó yẹ ká ní èrò tó dáa nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún ọmọnìkejì ló ń sún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí. (1 Kọ́r. 9:16, 17) Bí a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò gba ara wa àti àwọn tó ń tẹ́tí sí wa là. (1 Tím. 4:16) Kí ó jẹ́ ìpinnu wa pé a óò máa kópa déédéé bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú wíwàásù nípa ìjọba tó dára jù lọ tí aráyé lè ní, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run, àti pé a óò máa lo àkókò púpọ̀ bí a ti ń ṣe é, a óò sì máa ṣe é tokunratokunra bí ó ti yẹ!
4 Kókó pàtàkì kan ló tẹ bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ti jẹ́ kánjúkánjú tó mọ́ wa lọ́kàn, kókó náà ni pé a ṣì máa wà lẹ́nu iṣẹ́ yìí nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ́ sílẹ̀. Níwọ̀n bí a kò ti mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà, ó ń béèrè pé ká wà lójúfò, ká sì múra sílẹ̀ nígbà gbogbo, ká máa gbára lé Jèhófà tàdúràtàdúrà. (Éfé. 6:18) Iṣẹ́ ìwàásù yìí túbọ̀ ń tàn kálẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n, lọ́jọ́ kan, láìpẹ́, iṣẹ́ ìjẹ́rìí tó tóbi jù lọ nínú ìtàn aráyé yóò dé òtéńté kan.
5 Máa fi ìdúróṣinṣin pa àṣẹ Jésù mọ́ tó sọ pé kí á máa “wà lójúfò.” Ìsinsìnyí gan-an ló ṣe pàtàkì ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé ká máa ṣe ìyẹn. Ǹjẹ́ kí a gbégbèésẹ̀ ní mímọ̀ pé ọ̀ràn ọ̀hún jẹ́ kánjúkánjú. Lónìí, àti lójoojúmọ́, ẹ jẹ́ kí á jẹ́ onírònújinlẹ̀ nípa tẹ̀mí, ká máa wà lójúfò, ká sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà taápọntaápọn. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ jẹ́ kí a “wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.”—1 Tẹs. 5:6.