“Ọ̀kan Péré Lára Ọ̀pọ̀ Ìgbésí Ayé tí O Nípa Lé Lórí”
NÍ January 1996, kókó ọlọ́yún inú ọpọlọ yọ Carol lẹ́nu. Ó ti lé ní ẹni 60 ọdún, títí di ìgbà yẹn, ó jẹ́ obìnrin aláyọ̀, tí ó ṣe rùmúrùmú, tí ó sì máa ń sọ ọ̀rọ̀ oníṣìírí fún gbogbo ènìyàn. Ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, àwọn dókítà ń tiraka láti ṣẹ́pá kókó ọlọ́yún tí ń wú sí i, tí ó lè ṣekú pa á. Bí ó ti ń tiraka, Carol gba lẹ́tà tí ó tẹ̀ lé e yìí:
“Carol Ọ̀wọ́n:
“Mo bá ọ kẹ́dùn fún ìlera rẹ tí ń jo àjórẹ̀yìn. A dúpẹ́ pé a ní ojúlówó ìrètí tí Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀, kí a sì nífẹ̀ẹ́. Ìrètí yìí ni pé kí Ìjọba Jèhófà ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé, kí a baà lè gbé nínú ipò párádísè, àkókò kan tí gbogbo wa ń fojú sọ́nà fún.
“Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù tí o ṣe tí gba ọ̀pọ̀ ènìyàn là kúrò nínú ikú àìnípẹ̀kun. Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí. Kò dá mi lójú pé o rántí ìgbà àkọ́kọ́ tí a pàdé. Ọmọ 20 ọdún ni mi nígbà náà. Mo ni irun gígùn, mo ń ta oògùn líle, mo sì ń kẹ́gbẹ́ kiri pẹ̀lú àwọn ọmọkọ́mọ. Gbogbo wa máa ń gbé ìbọn, a kò sì ní ìfẹ́ fún ẹnikẹ́ni àfi ara wa.
“Ìwọ àti Ẹlẹ́rìí kan kan ilẹ̀kùn mi, o sì fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ̀ mí. Mo gbìyànjú láti fún ọ ní dọ́là kan, mo sì sọ pé n kò fẹ́ àwọn ìwé ìròyìn náà. O fi yé mi pé, kì í ṣe nítorí àti gba ọrẹ ní ń mú un yín jáde. O sọ fún mi pé, iṣẹ́ tí ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ka Bíbélì ni ẹ̀ ń ṣe. Kò dá mi lójú pé mo gba ìwé ìròyìn náà tàbí pé mo kà á. Bí ó ti wù kí ó rí, o gbin èso òtítọ́ sínú ìgbésí ayé mi.
“Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí mìíràn, Gary, wá sí ilé ìyá mi, nígbà tí mo wà níbẹ̀. Mo sọ fún un nípa ìbẹ̀wò tí o ṣe sọ́dọ̀ mi ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Gary kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú mi fún àkókò pípẹ́, títí tí mo fi ṣèrìbọmi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ní 1984. Nísinsìnyí, mo ń fi òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ mi.
“Ó dá mi lójú pé mo jẹ́ ọ̀kan péré lára ọ̀pọ̀ ìgbésí ayé tí o nípa lé lórí nínú àwọn ọdún iṣẹ́ ìsìn àfòtítọ́ṣe rẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, nípasẹ̀ inú rere ìfẹ́, o ti mú kí ó ṣeé ṣe fún èmi àti ìdílé mi láti wá mọ Ọlọ́run Ńlá náà, Jèhófà, àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Kristi Jésù. Mo ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ náà, tí yóò ṣeé ṣe fún mi láti rí ọ, nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tuntun, nígbà tí Jèhófà yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wa, tí ikú kì yóò sì sí mọ́.—Ìṣípayá 21:4.
“Ní ti èmi àti ìdílé mi, inú wa dùn pé a ní àǹfààní láti mọ̀ ọ́, kí a sì jẹ́ apá kan iṣẹ́ ìjẹ́rìí rẹ. O ṣeun.
“Pẹ̀lú ìfẹ́ ará,
Peter”
Lẹ́yìn àìsàn oṣù mẹ́fà, Carol kú ní March 1996, lẹ́yìn gbígbin ọ̀pọ̀ irúgbìn òtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ fún ọdún 35, gẹ́gẹ́ bí olùfìtara jíhìn rere. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé, ènìyàn kò lè mọ ìgbà tí irúgbìn kan yóò méso jáde, àní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá.—Mátíù 13:23.