Ìdáǹdè Sínú Ayé Tuntun Òdodo
“Wọn óò . . . máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—ORIN DÁFÍDÌ 37:11.
1, 2. (a) Báwo ni ìdáǹdè Jèhófà ní àkókò tiwa yóò ṣe yàtọ̀ sí àwọn ìdáǹdè ti ìgbàanì? (b) Irú ayé wo ni Jèhófà yóò mú àwọn ènìyàn rẹ̀ wọ̀?
JÈHÓFÀ jẹ́ Ọlọ́run ìdáǹdè. Ní ìgbà láéláé, ó dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Àwọn ìdáǹdè wọ̀nyẹn jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, nítorí kò sí ìgbà kankan nínú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyẹn, tí Jèhófà mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ayé Sátánì látòkè délẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ títí. Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ wa, kò ní pẹ́ tí Jèhófà yóò fi mú ìdáǹdè kíkọyọyọ jù lọ tí ó tí ì ṣẹlẹ̀ rí wá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yí, òun yóò pa gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì kárí ayé run, yóò sì mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá sínú ayé tuntun òdodo, tí yóò wà pẹ́ títí.—Pétérù Kejì 2:9; 3:10-13.
2 Jèhófà ṣèlérí pé: “Nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí: . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” (Orin Dáfídì 37:10, 11) Títí dìgbà wo? “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” (Orin Dáfídì 37:29; Mátíù 5:5) Ṣùgbọ́n, kí ìyẹn tó ṣẹlẹ̀, ayé yìí yóò nírìírí àkókò onídààmú tí ó kàmàmà jù lọ, tí a tí ì gbọ́ nípa rẹ̀ rí.
“Ìpọ́njú Ńlá”
3. Báwo ni Jésù ṣe ṣàpèjúwe “ìpọ́njú ńlá”?
3 Ní 1914, ayé yìí wọnú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” rẹ̀. (Tímótì Kejì 3:1-5, 13) Ọdún 83 nínú sáà yẹn ni a wà yí, a sì ti ń sún mọ́ òpin rẹ̀ nígbà tí ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí yóò ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà irúfẹ́ èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21) Bẹ́ẹ̀ ni, yóò burú ju Ogun Àgbáyé Kejì pàápàá, nígbà tí a gbẹ̀mí nǹkan bí 50 mílíọ̀nù ènìyàn. Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ àkókò tí yóò mi ayé jìgìjìgì, tí ń yára sún mọ́lé!
4. Èé ṣe tí ìdájọ́ Ọlọ́run ṣe wá sórí “Bábílónì Ńlá”?
4 “Ìpọ́njú ńlá” yóò dé lójijì, lọ́nà tí ń múni ṣe háà, “ní wákàtí kan.” (Ìṣípayá 18:10) Mímú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí gbogbo ìsìn èké, tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pè ní “Bábílónì Ńlá,” ni yóò sàmì sí ìbẹ́sílẹ̀ rẹ̀. (Ìṣípayá 17:1-6, 15) Ìsìn èké ni ohun àkọ́kọ́ tí a fi dá Bábílónì ìgbàanì mọ̀. Bábílónì òde òní dà bí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti ìgbàanì, ó sì dúró fún ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Ó ti hùwà aṣẹ́wó nípa lílẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ètò ìṣèlú. Ó ti kọ́wọ́ ti àwọn ogun wọn lẹ́yìn, ó sì ti gbàdúrà fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn ní ìhà ìhín àti ìhà ọ̀hún, ní yíyọrí sí kí àwọn ènìyàn tí ń ṣe ìsìn kan náà máa pa ara wọn lẹ́nì kíní kejì. (Mátíù 26:51, 52; Jòhánù Kíní 4:20, 21) Ó ti dijú sí ìwà ìbàjẹ́ àwọn tí ń tẹ̀ lé e, ó sì ti ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni tòótọ́.—Ìṣípayá 18:5, 24.
5. Báwo ni “ìpọ́njú ńlá” yóò ṣe bẹ̀rẹ̀?
5 “Ìpọ́njú ńlá” yóò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ètò ìṣèlú bá gbéjà ko “Bábílónì Ńlá” lójijì. Wọn “yóò kórìíra aṣẹ́wó náà wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.” (Ìṣípayá 17:16) Lẹ́yìn náà, àwọn tí wọ́n jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún un tẹ́lẹ̀ “yóò sunkún wọn yóò sì lu ara wọn nínú ẹ̀dùn ọkàn lórí rẹ̀.” (Ìṣípayá 18:9-19) Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń retí èyí tipẹ́tipẹ́, wọn yóò sì kókìkí pé: “Ẹ yin Jáà, . . . nítorí pé ó ti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí aṣẹ́wó ńlá náà tí ó fi àgbèrè rẹ̀ sọ ilẹ̀ ayé di ìbàjẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹrú rẹ̀ lára rẹ̀.”—Ìṣípayá 19:1, 2.
A Kọ Lu Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run
6, 7. Èé ṣe tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi lè ní ìgbọ́kànlé nígbà tí a bá kọlù wọ́n nígbà “ìpọ́njú ńlá”?
6 Lẹ́yìn pípa ìsìn èké run, ètò ìṣèlú yóò kọjú sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Sátánì, “Gọ́ọ̀gù, ilẹ̀ Mágọ́gù” nínú àsọtẹ́lẹ̀, yóò sọ pé: “Èmi óò tọ àwọn tí ó wà ní ìsinmi lọ, tí wọ́n ń gbé láìbẹ̀rù.” Ní rírò pé wọ́n rọrùn láti pa jẹ, yóò fi “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun alágbára . . . , bí àwọ sánmà láti bo ilẹ̀” kọ lù wọ́n. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:2, 10-16) Àwọn ènìyàn Jèhófà mọ̀ pé ìkọlù yí yóò forí ṣánpọ́n, nítorí pé, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
7 Nígbà tí Fáráò àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ rò pé ọwọ́ àwọn ti tẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní Òkun Pupa, lọ́nà ìyanu, Jèhófà dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè, ó sì pa ẹgbẹ́ ọmọ ogun Íjíbítì run. (Ẹ́kísódù 14:26-28) Nígbà “ìpọ́njú ńlá,” nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá rò pé ọwọ́ àwọn ti tẹ àwọn ènìyàn Jèhófà, lọ́nà ìyanu, òun yóò gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní ìṣáájú: “Nígbà kan náà . . . ìrunú mi yóò yọ ní ojú mi. Nítorí ní ìjowú mi àti ni iná ìbínú mi, ni mo ti sọ̀rọ̀.” (Ìṣíkẹ́ẹ̀lì 38:18, 19) Nígbà náà, òtéńté “ìpọ́njú ńlá” yóò ti sún mọ́lé!
8. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ajẹ̀dálọ wo ni yóò ṣẹlẹ̀ kí Jèhófà tó pa àwọn ẹni búburú run, ipa wo ni yóò sì ní?
8 Ní àkókò kan, lẹ́yìn tí “ìpọ́njú ńlá” bá ti bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n kí Jèhófà tó mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ìyókù ayé yìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ajẹ̀dálọ yóò ṣẹlẹ̀. Ṣàkíyèsí ipa tí wọn yóò ní. “Nígbà náà . . . ni àmì Ọmọkùnrin ènìyàn [Kristi] yóò fara hàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọ sánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.” (Mátíù 24:29, 30) “Àwọn àmì yóò wà nínú oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, . . . nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa kú sára láti inú ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—Lúùkù 21:25, 26.
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”
9. Èé ṣe tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi lè ‘gbé orí wọn sókè’ nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ajẹ̀dálọ bá ṣẹlẹ̀?
9 Ní àkókò yẹn gan-an, àsọtẹ́lẹ̀ inú Lúùkù 21:28 yóò ṣeé mú lò. Jésù wí pé: “Bí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nàró ṣánṣán kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” Ìbẹ̀rù yóò mú kí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run gbọ̀n jìnnìjìnnì, nítorí pé wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ Jèhófà ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ajẹ̀dálọ tí ń ṣẹlẹ̀ ti wá. Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò hó fún ayọ̀, nítorí wọ́n yóò mọ̀ pé, ìdáǹdè àwọn ń sún mọ́lé.
10. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣàpèjúwe òtéńté “ìpọ́njú ńlá”?
10 Nígbà náà, Jèhófà yóò mú ìparun pátápátá dé bá ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì: “Èmi óò sì fi àjàkálẹ̀ àrùn àti ẹ̀jẹ̀ bá a [Gọ́ọ̀gù] wíjọ́; èmi óò sì rọ òjò púpọ̀, àti yìnyín ńlá, iná àti [imí ọjọ́, NW] sí i lórí, àti sórí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ . . . Wọn óò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:22, 23) A óò pa gbogbo ìràlẹ̀rálẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì run. Gbogbo àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí ó pa Ọlọ́run tì, yóò parẹ́ ráúráú. Ìyẹn ni Amágẹ́dọ́nì tí yóò kágbá “ìpọ́njú ńlá” nílẹ̀.—Jeremáyà 25:31-33; Tẹsalóníkà Kejì 1:6-8; Ìṣípayá 16:14, 16; 19:11-21.
11. Èé ṣe tí a óò fi dá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nídè nínú “ìpọ́njú ńlá”?
11 A óò dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùjọsìn Jèhófà kárí ayé nídè la “ìpọ́njú ńlá” já. Àwọn wọ̀nyí para pọ̀ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Èé ṣe tí a fi dá wọn nídè lọ́nà tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé, wọ́n ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀” fún Jèhófà “tọ̀sán tòru.” Nítorí náà, wọ́n la òpin ayé yìí já, a sì mú wọn wọnú ayé tuntun òdodo. (Ìṣípayá 7:9-15) Nípa báyìí, wọ́n fojú rí ìmúṣẹ ìlérí Jèhófà pé: “Dúró de Olúwa, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ayé: nígbà tí a bá ké àwọn ènìyàn búburú kúrò, ìwọ óò rí i.”—Orin Dáfídì 37:34.
Ayé Tuntun Náà
12. Kí ni àwọn tí wọ́n la Amágẹ́dọ́nì já lè máa fojú sọ́nà fún?
12 Ẹ wo irú àkókò amọ́kànyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ tí ìyẹn yóò jẹ́—kíkásẹ̀ ìwà búburú nílẹ̀ àti lílà ọ̀yẹ̀ sànmánì ológo jù lọ nínú gbogbo ìtàn ẹ̀dá ènìyàn! (Ìṣípayá 20:1-4) Ẹ wo bí àwọn tí wọ́n la Amágẹ́dọ́nì já yóò ṣe kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà tó pé àwọn wọnú ọ̀làjú ringindin, aláìlẹ́gbin, tí ó ti ọwọ́ Ọlọ́run wá, ayé tuntun kan, lórí ilẹ̀ ayé tí a óò sọ di párádísè kan! (Lúùkù 23:43) Kì yóò sì sí ìdí kankan fún wọn mọ́ láti kú! (Jòhánù 11:26) Ní tòótọ́, láti àkókò yẹn lọ, wọn yóò ní àgbàyanu ìfojúsọ́nà kíkọyọyọ, ti wíwà láàyè níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà bá ṣì wà láàyè!
13. Báwo ni Jésù yóò ṣe máa bá iṣẹ́ ìwòsàn tí ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé nìṣó?
13 Jésù, ẹni tí Jèhófà ti yàn sípò gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run, yóò bójú tó àwọn ìbùkún àgbàyanu tí àwọn tí a dá nídè yóò gbádùn. Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó la ojú tí ó fọ́, ó la etí tí ó di, ó sì wo “gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara” sàn. (Mátíù 9:35; 15:30, 31) Nínú ayé tuntun, òun yóò tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìmúláradá ńláǹlà yẹn, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kárí gbogbo àgbáyé. Gẹ́gẹ́ bí Aṣojú Ọlọ́run, òun yóò mú ìlérí náà ṣẹ pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) A kò tún ní nílò àwọn dókítà tàbí àwọn abánitọ́jú-òkú mọ́!—Aísáyà 25:8; 33:24.
14. Ìdáǹdè wo ni yóò dé fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti kú?
14 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, tí wọ́n ti kú ní ìgbà àtijọ́ yóò wà lára àwọn tí a óò dá nídè pẹ̀lú. Nínú ayé tuntun, a óò gbà wọ́n lọ́wọ́ ẹ̀mú sàréè, Jèhófà mú un dáni lójú pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé “àwọn olódodo” ni a óò kọ́kọ́ jí dìde, tí wọn yóò sì kópa nínú mímú Párádísè gbòòrò. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tó fún àwọn tí wọ́n la Amágẹ́dọ́nì já, láti gbọ́ ìrírí àwọn olùṣòtítọ́ wọnnì tí wọ́n ti kú tipẹ́tipẹ́, tí wọ́n wá pa dà di alààyè nísinsìnyí!—Jòhánù 5:28, 29.
15. Ṣàpèjúwe díẹ̀ nínú àwọn ipò tí a óò nírìírí rẹ̀ nínú ayé tuntun.
15 Gbogbo àwọn tí wọ́n bá wà láàyè, yóò nírìírí ohun tí onísáàmù náà wí nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Orin Dáfídì 145:16) Kò ní sí ebi mọ́: A óò mú ilẹ̀ ayé pa dà bọ̀ sí ipò tí ó wà déédéé ní ti ibùgbé àwọn ohun alààyè, yóò sì méso jáde lọ́pọ̀ yanturu. (Orin Dáfídì 72:16) Kò ní sí àwọn aláìrílégbé mọ́: “Wọn óò . . . kọ́ ilé, wọn óò sì gbé inú wọn,” olúkúlùkù yóò sì jókòó “lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀: ẹnì kan kì yóò sì dáyà fò wọ́n.” (Aísáyà 65:21, 22; Míkà 4:4) Kò ní sí ìfòyà mọ́: Kò ní sí ogun, ìwà ipa, tàbí ìwà ọ̀daràn. (Orin Dáfídì 46:8, 9; Òwe 2:22) “Gbogbo ayé sinmi, wọ́n sì gbé jẹ́ẹ́: wọ́n bú jáde nínú orin kíkọ.”—Aísáyà 14:7.
16. Èé ṣe tí òdodo yóò fi kún inú ayé tuntun?
16 Nínú ayé tuntun, a óò ti mú ọ̀nà ìgbékèéyíde tí Sátánì ń lò kúrò. Dípò èyí, “àwọn tí ń bẹ ní ayé yóò kọ́ òdodo.” (Aísáyà 26:9; 54:13) Pẹ̀lú ìtọ́ni tẹ̀mí gbígbámúṣé bí ọdún ti ń gorí ọdún, “ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Èrò àti ìgbésẹ̀ tí ń gbéni ró yóò gbilẹ̀ láàárín aráyé. (Fílípì 4:8) Rò ó wò ná, àwùjọ àgbáyé ti àwọn ènìyàn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn, ìgbéra-ẹni-lárugẹ, owú—ẹgbẹ́ ará kárí ayé, níbi tí gbogbogbòò ti ń mú èso ẹ̀mí ti Ọlọ́run jáde. Ní tòótọ́, àní nísinsìnyí pàápàá, ogunlọ́gọ̀ ńlá ń mú irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà.—Gálátíà 5:22, 23.
Èé Ṣe Tí Ó Fi Pẹ́ Tó Bẹ́ẹ̀?
17. Èé ṣe tí Jèhófà fi dúró fún ìgbà pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀ kí ó tó mú ìwà búburú wá sí òpin?
17 Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Jèhófà fi dúró fún ìgbà pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀ láti mú ìwà búburú kúrò, kí ó sì dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè sínú ayé tuntun? Gbé ohun tí a ní láti ṣàṣeparí yẹ̀ wò. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni, ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jèhófà, ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ṣàkóso. Nípa yíyọ̀ǹda kí àkókò tí ó tó kọjá, ó ti fi hàn lọ́nà tí kò ṣeé já ní koro, ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn tí kò sí lábẹ́ ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, ti yọrí sí ìjákulẹ̀ ńláǹlà. (Jeremáyà 10:23) Nítorí náà, nísinsìnyí, Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ ní kíkún láti fi ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run, lábẹ́ Kristi, rọ́pò ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.
18. Ìgbà wo ni àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù tó jogún ilẹ̀ Kénáánì?
18 Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ọ̀rúndún wọ̀nyí fara jọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò Ábúráhámù. Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ Kénáánì—ṣùgbọ́n ìyẹn jẹ́ lẹ́yìn irínwó ọdún “nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Ámórì kò tí ì kún.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-5; 15:13-16) Níhìn-ín èdè ọ̀rọ̀ náà, “àwọn ará Ámórì” (ẹ̀yà kan tí ń jẹ gàba) ṣeé ṣe kí ó dúró fún àwọn ará Kénáánì lápapọ̀. Nítorí náà, nǹkan bí ọ̀rúndún mẹ́rin yóò kọjá, kí Jèhófà tó lè mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti gba ilẹ̀ Kénáánì. Láàárín àkókò náà, Jèhófà jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ní Kénáánì mú àwùjọ wọn gbèrú. Kí ni àbárèbábọ̀ rẹ̀?
19, 20. Irú àwùjọ wo ni àwọn ará Kénáánì mú gbèrú?
19 Ìwé náà, Bible Handbook, láti ọwọ́ Henry H. Halley, sọ pé, ní Mẹ́gídò, àwọn awalẹ̀pìtàn rí òkìtì àlàpà tẹ́ńpìlì Áṣítórétì, abo ọlọ́run, aya Báálì. Ó kọ̀wé pé: “Ní ìṣísẹ̀ díẹ̀ sí tẹ́ńpìlì yí, a rí itẹ́ òkú kan, níbi tí a ti rí ọ̀pọ̀ ìṣà, tí egungun òkú àwọn ọmọdé tí a fi rúbọ ní tẹ́ńpìlì yí wà nínú rẹ̀ . . . Àwọn wòlíì Báálì àti Áṣítórétì ni wọ́n láṣẹ láti pa àwọn ọmọ kéékèèké.” “Àṣà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ míràn ni [ohun] tí wọ́n pè ní ‘ìrúbọ ìpìlẹ̀.’ Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kọ́ ilé, wọn yóò fi ọmọ kan rúbọ, wọn yóò sì mọ ara rẹ̀ mọ́ ògiri.”
20 Halley sọ pé: “Ìjọsìn Báálì, Áṣítórétì, àti àwọn ọlọ́run àwọn ará Kénáánì míràn, ní àwọn ààtò bòńkẹ́lẹ́ aláṣerégèé jù lọ nínú; àwọn tẹ́ńpìlì wọn jẹ́ ojúkò ìwà abèṣe. . . . Àwọn ará Kénáánì jọ́sìn, nípa fífi ìwà pálapàla kẹ́ra, . . . lẹ́yìn náà, nípa pípa àwọn àkọ́bí ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ohun ìrúbọ sí àwọn ọlọ́run kan náà wọ̀nyí. Ó dà bíi pé, dé ìwọ̀n gíga, ilẹ̀ Kénáánì dà bíi Sódómù àti Gòmórà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. . . . Ó ha tọ́ kí àṣà irú ìwà ìbàjẹ́ burúkú àti ìwà òkú òǹrorò bẹ́ẹ̀ máa bá a nìṣó bí? . . . Àwọn awalẹ̀pìtàn tí wọ́n walẹ̀ níbi òkìtì àlàpà ìlú àwọn ará Kénáánì ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run kò fi tètè pa wọ́n run ṣáájú àkókò tí Ó fi pa wọ́n run.”—Fi wé Àwọn Ọba Kìíní 21:25, 26.
21. Ìjọra wo ni ó wà nínú ipò àwọn ará Kénáánì àti ipò ti ọjọ́ wa?
21 Ìwà búburú àwọn ará Ámórì ti “kún.” Nítorí náà, Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ ní kíkún nísinsìnyí láti pa wọ́n run pátápátá. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn rí lónìí. Ayé yìí kún fún ìwà ipá, ìwà pálapàla, àti àìka òfin Ọlọ́run sí. Níwọ̀n bí fífi àwọn ọmọdé rúbọ ní ilẹ̀ Kénáánì ìgbàanì lọ́nà mímúni gbọ̀n rìrì ti kó jìnnìjìnnì bá wa lọ́nà tí ó tọ́, mélòómélòó ni ti ẹgbẹẹgbàarùn-ún àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn tí a ti fi rúbọ nínú àwọn ogun ayé yìí, tí ó burú jáì ju ohunkóhun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì? Dájúdájú, Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ ní kíkún nísinsìnyí láti mú ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí wá sí òpin.
Ṣíṣàṣeparí Ohun Mìíràn
22. Kí ni sùúrù Jèhófà ní àkókò wa ṣàṣeparí rẹ̀?
22 Sùúrù Jèhófà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ń ṣàṣeparí ohun mìíràn. Ó ń yọ̀ǹda àkókò láti kó ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ, kí a sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, àwọn tí wọ́n ti lé ní mílíọ̀nù márùn-ún nísinsìnyí. Lábẹ́ ìdarí Jèhófà, wọ́n ti di ètò àjọ onítẹ̀síwájú. A ń dá àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bíbélì. Nípasẹ̀ àwọn ìpàdé àti ìtẹ̀jáde Bíbélì wọn, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run. (Jòhánù 13:34, 35; Kólósè 3:14; Hébérù 10:24, 25) Ní àfikún sí i, wọ́n ń mú òye dàgbà nínú iṣẹ́ ìkọ́lé, ìṣètò ohun abánáṣiṣẹ́, ìtẹ̀wé, àti àwọn iṣẹ́ mìíràn láti lè ti wíwàásù “ìhìn rere” náà lẹ́yìn. (Mátíù 24:14) Ó ṣeé ṣe kí irú òye ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti ìkọ́lé bẹ́ẹ̀ ṣeé lò lọ́nà gbígbòòrò nínú ayé tuntun.
23. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ àǹfààní láti wà láàyè ní àkókò yí?
23 Bẹ́ẹ̀ ni, lónìí, Jèhófà ń múra àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ láti lè la “ìpọ́njú ńlá” já, sínú ayé tuntun òdodo. Nígbà náà, kì yóò sí Sátánì àti ayé búburú rẹ̀ mọ́ láti bá wọ̀jà, kì yóò sí àìsàn, ìbànújẹ́, àti ikú mọ́. Pẹ̀lú ìtara àti ìdùnnú ńláǹlà, àwọn ènìyàn Ọlọ́run yóò máa bá iṣẹ́ aláyọ̀ ti kíkọ́ párádísè kan nìṣó, níbi tí ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan yóò ti jẹ́ “inú dídùn.” Ẹ wo irú àǹfààní ńláǹlà tí a ní láti wà láàyè ní òtéńté àwọn sànmánì yí, láti mọ Jèhófà, kí a sì ṣiṣẹ́ sìn ín, àti láti mọ̀ pé, láìpẹ́, a óò ‘gbé orí wa sókè, nítorí pé ìdáǹdè wa ń sún mọ́lé’!—Lúùkù 21:28; Orin Dáfídì 146:5.
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Kí ni “ìpọ́njú ńlá,” báwo sì ni yóò ṣe bẹ̀rẹ̀?
◻ Èé ṣe tí kíkọlù tí Gọ́ọ̀gù yóò kọlu àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò fi kùnà?
◻ Báwo ni “ìpọ́njú ńlá” yóò ṣe wá sí òpin?
◻ Àwọn àǹfààní àgbàyanu wo ni ayé tuntun yóò pèsè?
◻ Èé ṣe tí Jèhófà fi dúró fún ìgbà pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀, kí ó tó mú ètò ìgbékalẹ̀ yí wá sí òpin?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
A óò sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di párádísè kan