Ẹ Mọ́kàn Le Bí Ìdáǹdè Ṣe Ń sún Mọ́lé
“Èmi wà pẹ̀lú rẹ, ni Olúwa wí, láti gbà ọ́.”—JEREMÁYÀ 1:19.
1, 2. Èé ṣe tí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn fi nílò ìdáǹdè?
ÌDÁǸDÈ! Ẹ wo irú ọ̀rọ̀ ìtùnú tí ó jẹ́! Láti dáni nídè túmọ̀ sí, láti gbani sílẹ̀, láti dáni sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú ipò búburú, tí ń bani nínú jẹ́. Èyí kan èrò mímúni wá sí ipò tí ó dára, tí ó sì múni láyọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.
2 Ẹ wo bí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn ti nílò irú ìdáǹdè bẹ́ẹ̀ lójú méjèèjì tó ní àkókò yí! Àwọn ìṣòro líle koko—ti ọrọ̀ ajé, ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ti ará, ti ọpọlọ, àti ti ìmọ̀lára—ń pọ́n àwọn ènìyàn níbi gbogbo lójú, ó sì ń mú kí wọ́n rẹ̀ wẹ̀sì. Bí ayé ṣe ń lọ sí kò tẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ lọ́rùn, ó sì mú ìjákulẹ̀ bá wọn, wọn yóò sì fẹ́ kí nǹkan yí pa dà sí rere.—Aísáyà 60:2; Mátíù 9:36.
“Àkókò Líle Koko Tí Ó Nira Láti Bá Lò”
3, 4. Èé ṣe tí àìní fún ìdáǹdè fi túbọ̀ ṣe pàtàkì nísinsìnyí?
3 Níwọ̀n bí ọ̀rúndún ogún yìí ti jìyà tí ó pọ̀ ju ti ọ̀rúndún èyíkéyìí mìíràn lọ, ìdáǹdè ṣe pàtàkì gidigidi nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Lónìí, ènìyàn tí ó lé ní bílíọ̀nù kan dáadáa ń gbé nínú òṣì paraku, iye yẹn sì ń fi nǹkan bíi mílíọ̀nù 25 pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Lọ́dọọdún, nǹkan bíi mílíọ̀nù 13 àwọn ọmọdé ń kú nítorí àìjẹunre-kánú tàbí àwọn ohun mìíràn tí òṣì ń fà—iye tí ó lé ní 35,000 lójúmọ́! Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àgbàlagbà sì ń tètè kú nítorí onírúurú àrùn.—Lúùkù 21:11; Ìṣípayá 6:8.
4 Ogun àti rúgúdù ti fa ìyà tí kò ṣeé fẹnu sọ. Ìwé náà, Death by Government, sọ pé, ogun, gbọ́nmisi-omi-ò-to ti ẹ̀yà ìran àti ti ìsìn, àti ìṣìkàpa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn aráàlú láti ọwọ́ àwọn ìjọba tiwọn fúnra wọn, ti “gbẹ̀mí ènìyàn tí ó lé ní 203 mílíọ̀nù ní ọ̀rúndún yìí.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Iye àwọn tí a pa ní ti gidi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 360 mílíọ̀nù. Ṣe ni ó dà bíi pé Àjàkálẹ̀ Àrùn Runlérùnnà kan ti pa ọ̀wọ́ wa run. Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀ àrùn Agbára ni, kì í ṣe ti kòkòrò àrùn.” Òǹkọ̀wé náà, Richard Harwood, sọ pé: “Àwọn ogun àtijọ́ ti àwọn ọ̀rúndún tí ó ti kọjá, jẹ́ erémọdé lásán ní ìfiwéra pẹ̀lú ti ọ̀rúndún yìí.”—Mátíù 24:6, 7; Ìṣípayá 6:4.
5, 6. Kí ni ó mú kí àkókò wa jẹ́ onídààmú gan-an?
5 Ìwà ọ̀daràn oníwà ipá, ìwà pálapàla, àti ìdílé tí ń forí ṣánpọ́n, tí ń pọ̀ sí i lọ́nà gíga, tún ń fi kún ipò onídààmú ti àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Akọ̀wé Ètò Ẹ̀kọ́ ní United States tẹ́lẹ̀ rí, William Bennett, sọ pé, láàárín 30 ọdún, iye olùgbé United States fi ìpín 41 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè, ṣùgbọ́n ìwà ọ̀daràn oníwà ipá fi ìpín 560 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè, bíbí ọmọ àlè fi ìpín 400 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè, ìkọ̀sílẹ̀ fi ìpín 300 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè, nígbà tí ìpara-ẹni ti àwọn ọ̀dọ́langba sì fi ìpín 200 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè. Ọ̀jọ̀gbọ́n Yunifásítì Princeton, John DiIulio kékeré, kìlọ̀ nípa ìlọsókè nínú iye ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ “ògbógi nínú ìfiniṣèjẹ,” tí wọ́n ń “pànìyàn, tí wọ́n ń kọluni, tí wọ́n ń fipá báni lò pọ̀, tí wọ́n ń jani lólè, tí wọ́n ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń dá rúgúdù ńlá sílẹ̀ láwùjọ. Wọn kò bẹ̀rù ìtìjú tí fífàṣẹ ọba mú wọn yóò mú bá wọn, wọn kò bẹ̀rù ìrora ìfisẹ́wọ̀n, tàbí ìrora gógó ti ẹ̀rí ọkàn.” Ní ilẹ̀ yẹn, ìpànìyàn ni ó wà ní ipò kejì, ní ti ohun tí ń fa ikú láàárín àwọn ọmọ ọdún 15 sí 19. Àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ọmọ ọdún mẹ́rin tí ń kú nítorí ìwà ìkà tí a hù sí wọn, túbọ̀ ń pọ̀ sí i ju àwọn tí àrùn ń pa lọ.
6 Irú ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá bẹ́ẹ̀ kò mọ sí orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo. Ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ń ròyìn irú ìtẹ̀sí kan náà. Ìlọsókè nínú ìlò oògùn líle tí ń sọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dìbàjẹ́ wà nínú ohun tí ń dá kún èyí. Ìwé agbéròyìnjáde ti ilẹ̀ Australia, Sydney Morning Herald, wí pé: “Lẹ́yìn ìṣòwò ohun ìjà ogun, ìṣòwò oògùn líle káàkiri ayé ni òwò kejì tí ń mówó wọlé jù lọ.” Kókó abájọ mìíràn ni ìwà ipá àti ìwà pálapàla tí ó ti gba orí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán kan nísinsìnyí. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, nígbà tí ọmọ kan yóò bá fi tó ẹni ọdún 18, yóò ti wo ẹgbẹẹgbàarùn-ún ìwà ipá lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán àti àìmọye ìwà pálapàla. Ìyẹn jẹ́ agbára ìdarí kan tí ń sọni dìbàjẹ́, tí kò ṣeé gbójú fò dá, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ohun tí a fi ń bọ́ èrò inú wa déédéé ni ó ń darí àkópọ̀ ìwà wa.—Róòmù 12:2; Éfésù 5:3, 4.
7. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ nípa ipò búburú ìsinsìnyí?
7 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ lọ́nà pípéye pé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ onítẹ̀sí amúnifòyà yí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún wa. Ó sọ pé, ogun àjàkáyé, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ, àti ìwà àìlófin tí ń peléke sí i yóò wà. (Mátíù 24:7-12; Lúùkù 21:10, 11) Bí a bá sì gbé àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sínú Tímótì Kejì 3:1-5 yẹ̀ wò, ṣe ni ó dà bíi gbígbọ́ ìròyìn alẹ́. Ó fi sànmánì wa hàn gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó sì ṣàpèjúwe àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ‘àwọn olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.’ Bí ayé ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn lónìí. Gẹ́gẹ́ bí William Bennett ti sọ: “Àmì rẹpẹtẹ ń bẹ tí ó fi hàn pé . . . ọ̀làjú ti bà jẹ́.” A kúkú ti sọ ọ́ pé, ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní ní ọ̀làjú ti dópin.
8. Èé ṣe tí Ọlọ́run fi mú Ìkún Omi wá ní ọjọ́ Nóà, kí sì ni èyí ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ wa?
8 Ipò náà nísinsìnyí tilẹ̀ bà jẹ́ bàlùmọ̀ ju ti àkókò tí ó ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà lọ, nígbà tí “ayé . . . kún fún ìwà agbára.” Nígbà náà lọ́hùn-ún, àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò kọ̀ láti ronú pìwà dà nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run wí pé: “Ayé kún fún ìwà agbára láti ọwọ́ wọn; sì kíyè sí i, èmi óò sì pa wọ́n run.” Àkúnya náà fòpin sí ayé oníwà ipá yẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 6:11, 13; 7:17-24.
Ìdáǹdè Kò Sí Lọ́wọ́ Ẹ̀dá Ènìyàn
9, 10. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a yíjú sí ẹ̀dá ènìyàn láti pèsè ìdáǹdè?
9 Àwọn akitiyan ẹ̀dá ènìyàn ha lè dá wa nídè kúrò nínú àwọn ipò búburú wọ̀nyí bí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáhùn pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.” “Kò sí ní ipá ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Orin Dáfídì 146:3; Jeremáyà 10:23) Ìtàn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ti jẹ́rìí sí àwọn òtítọ́ wọnnì. Ẹ̀dá ènìyàn ti gbìyànjú gbogbo ètò ìṣèlú, ọrọ̀ ajé, àti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí a lè ronú rẹ, ṣùgbọ́n kàkà kéwé àgbọn dẹ̀, líle ló ń le sí i. Ká ní ojútùú kan láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wà ní, ì bá ti hàn gbangba ṣáájú ìsinsìnyí. Dípò ìyẹn, ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an ni pé, “ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9; Òwe 29:2; Jeremáyà 17:5, 6.
10 Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, olùdámọ̀ràn ààbò orílẹ̀-èdè United States tẹ́lẹ̀ rí, Zbigniew Brzezinski, wí pé: “Ìparí èrò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tí àyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ aláìṣègbè nípa ìtẹ̀sí àgbáyé yóò mú wá ni pé, pákáǹleke ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, rògbòdìyàn ìṣèlú, yánpọnyánrin ọrọ̀ ajé, àti gbúngbùngbún àwọn orílẹ̀-èdè lè di ohun tí yóò túbọ̀ tàn kálẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Ewu tí ó dojú kọ aráyé [ni] rúgúdù káàkiri àgbáyé.” Àyẹ̀wò yẹn ní ti ipò ayé tilẹ̀ túbọ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lónìí. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa sànmánì oníwà ipá tí ń peléke sí i yìí, ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé agbéròyìnjáde náà, Register, New Haven, Connecticut, polongo pé: “Ó dà bí ẹni pé a ti lọ jìnnà kọjá àtitún un ṣe.” Rárá o, kò lè sí àtúnṣe sí ìbàjẹ́ ayé yìí, nítorí àsọtẹ́lẹ̀ nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí pẹ̀lú wí pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a óò sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.”—Tímótì Kejì 3:13.
11. Èé ṣe tí àwọn akitiyan ẹ̀dá ènìyàn kò fi lè yí àwọn ipò ti ń burú sí i pa dà?
11 Ẹ̀dá ènìyàn kò lè yí àwọn ìtẹ̀sí wọ̀nyí pa dà, nítorí pé, Sátánì ni “ọlọ́run ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:4) Bẹ́ẹ̀ ni, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù Kíní 5:19; tún wo Jòhánù 14:30.) Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí gan-an, Bíbélì sọ nípa ọjọ́ wa pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Sátánì mọ̀ pé ìṣàkóso òun àti ayé òun ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wá sópin, nítorí náà, ó dà bíi ‘kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.’—Pétérù Kíní 5:8.
Ìdáǹdè Sún Mọ́lé—Fún Àwọn Wo?
12. Àwọn wo ni ìdáǹdè kù sí dẹ̀dẹ̀ fún?
12 Ipò nǹkan tí ó túbọ̀ ń burú sí i lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ẹ̀rí ṣíṣe kedere pé, ìyípadà ńláǹlà kan—ní tòótọ́, ìdáǹdè kíkọyọyọ kan—kù sí dẹ̀dẹ̀! Fún àwọn wo? Ìdáǹdè kù sí dẹ̀dẹ̀ fún àwọn tí wọ́n ń fiyè sí àwọn àmì ìkìlọ̀, tí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ. Jòhánù Kíní 2:17 fi ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe hàn: “Ayé [ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti Sátánì] ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—Tún wo Pétérù Kejì 3:10-13.
13, 14. Báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwà lójúfò?
13 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé, láìpẹ́, a óò gbá àwùjọ òde òní tí ó ti bà jẹ́ kúrò, ní àkókò onídààmú “irúfẹ́ èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni, kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21) Ìdí nìyẹn tí ó fi kìlọ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín kí ọkàn àyà yín má baà di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn wọnnì tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.”—Lúùkù 21:34-36.
14 Àwọn tí wọ́n “kíyè sí ara,” tí wọ́n sì “wà lójúfò” yóò wá ìfẹ́ inú Ọlọ́run, wọn yóò sì ṣe é. (Òwe 2:1-5; Róòmù 12:2) Àwọn wọ̀nyí ni yóò “kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú” ìparun tí yóò dé sórí ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì láìpẹ́. Wọ́n sì lè ní ìgbọ́kànlé pátápátá pé, a óò dá wọn nídè.—Orin Dáfídì 34:15; Òwe 10:28-30.
Olórí Olùdáǹdè
15, 16. Ta ni olórí Olùdáǹdè, èé sì ti ṣe tí a fi ní ìdánilójú pé ìdájọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ òdodo?
15 Kí a tó lè dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nídè, a ní láti kọ́kọ́ mú Sátánì àti gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ ayé rẹ̀ kúrò. Èyí ń béèrè fún orísun ìdáǹdè tí ó lágbára ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ fíìfíì. Jèhófà Ọlọ́run, Ọba Aláṣẹ Gíga Jù Lọ, Olódùmarè Ẹlẹ́dàá àgbáyé amúnikúnfún-ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀, ni orísun yẹn. Òun ni olórí Olùdáǹdè: “Èmi, àní èmi ni Olúwa; àti lẹ́yìn mi, kò sí olùgbàlà kan.”—Aísáyà 43:11; Òwe 18:10.
16 Agbára, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo, àti ìfẹ́ gíga jù lọ ń bẹ nínú Jèhófà. (Orin Dáfídì 147:5; Òwe 2:6; Aísáyà 61:8; Jòhánù Kíní 4:8) Nítorí náà, nígbà tí ó bá mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ, a lè ní ìdánilójú pé, àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ òdodo. Ábúráhámù béèrè pé: “Onídàájọ́ gbogbo ayé kì yóò ha ṣe èyí tí ó tọ́?” (Jẹ́nẹ́sísì 18:24-33) Pọ́ọ̀lù kókìkí pé: “Àìṣèdájọ́ òdodo ha wà pẹ̀lú Ọlọ́run bí? Kí èyíinì má ṣe rí bẹ́ẹ̀ láé!” (Róòmù 9:14) Jòhánù kọ̀wé pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ.”—Ìṣípayá 16:7.
17. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́ ṣe fi ìgbọ́kànlé hàn nínú ìlérí rẹ̀?
17 Bí Jèhófà bá ṣèlérí ìdáǹdè, kò ní ṣàìmú un ṣẹ. Jóṣúà wí pé: “Ohunkóhun kò tàsé nínú ohun rere tí OLÚWA ti sọ.” (Jóṣúà 21:45) Sólómọ́nì sọ pé: “Kò ku ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo ìlérí rẹ̀ tí ó ti ṣe.” (Àwọn Ọba Kìíní 8:56) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, Ábúráhámù “kò mikàn nínú àìnígbàgbọ́, . . . ó . . . gbà gbọ́ dájú ní kíkún pé ohun tí [Ọlọ́run] ti ṣèlérí ni ó lè ṣe pẹ̀lú.” Bákan náà, Sárà “ka [Ọlọ́run] tí ó ṣèlérí sí olùṣòtítọ́.”—Róòmù 4:20, 21; Hébérù 11:11.
18. Èé ṣe tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí fi lè ní ìgbọ́kànlé pé a óò dá wọn nídè?
18 Láìdà bí ẹ̀dá ènìyàn, Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá, ó ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. “Olúwa àwọn ọmọ ogun ti búra, wí pé, Lóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.” (Aísáyà 14:24) Nítorí náà, nígbà tí Bíbélì sọ pé “Jèhófà mọ bí a ti í dá àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìfọkànsin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pamọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò,” a lè ní ìgbọ́kànlé pátápátá pé èyí yóò rí bẹ́ẹ̀. (Pétérù Kejì 2:9) Àní nígbà tí àwọn ọ̀tá tí wọ́n jẹ́ alágbára bá fi ìparun halẹ̀ mọ́ wọn pàápàá, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń nígboyà nítorí ìṣarasíhùwà rẹ̀, tí ó hàn gbangba nínú ìlérí tí ó ṣe fún ọ̀kan lára àwọn wòlíì rẹ̀ pé: “Wọn óò bá ọ jà, wọn kì yóò sì lè borí rẹ; nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, ni Olúwa wí, láti gbà ọ́.”—Jeremáyà 1:19; Orin Dáfídì 33:18, 19; Títù 1:2.
Ìdáǹdè Nígbà Àtijọ́
19. Báwo ni Jèhófà ṣe dá Lọ́ọ̀tì nídè, ìjọra wo ni ó sì ní pẹ̀lú ọjọ́ wa?
19 A lè rí ìṣírí ńláǹlà nínú títún díẹ̀ nínú àwọn ìṣe ìgbàlà tí Jèhófà ti ṣe sẹ́yìn sọ. Fún àpẹẹrẹ, ìwà búburú Sódómù àti Gòmórà “kó wàhálà ọkàn” bá Lọ́ọ̀tì gidigidi. Ṣùgbọ́n, Jèhófà ṣàkíyèsí “òkìkí igbe” tí a ké lòdì sí àwọn ìlú wọnnì. Nígbà tí ó tó àkókò, ó rán àwọn ońṣẹ́ láti rọ Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ láti kúrò ní àgbègbè yẹn lójú ẹsẹ̀. Kí ni ó yọrí sí? Jèhófà “dá Lọ́ọ̀tì olódodo sílẹ̀,” ‘ní sísọ Sódómù àti Gòmórà di eérú.’ (Pétérù Kejì 2:6-8; Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21) Lónìí, pẹ̀lú, Jèhófà ń kíyè sí òkìkí igbe tí a ń ké nípa ìwà búburú lílé kenkà tí ń bẹ nínú ayé yìí. Nígbà tí àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ òde òní bá ti parí iṣẹ́ ìjẹ́rìí wọn tí ó jẹ́ kánjúkánjú, dé àyè tí òun fẹ́, òun yóò gbégbèésẹ̀ lòdì sí ayé yìí, yóò sì dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nídè, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún Lọ́ọ̀tì.—Mátíù 24:14.
20. Ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe dá Ísírẹ́lì ìgbàanì nídè kúrò ní Íjíbítì.
20 Ní Íjíbítì ìgbàanì, a mú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run sìnrú. Jèhófà sọ nípa wọn pé: “Mo . . . gbọ́ igbe wọn . . . mo mọ ìbànújẹ́ wọn. Èmi sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n.” (Ẹ́kísódù 3:7, 8) Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn yíyọ̀ǹda kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run máa lọ, Fáráò yí èrò rẹ̀ pa dà, ó sì fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá rẹ̀ lépa wọn. Ó dà bíi pé a ti ká àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ Òkun Pupa. Síbẹ̀ Mósè wí pé: “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì rí ìgbàlà OLÚWA, tí yóò fi hàn yín ní òní.” (Ẹ́kísódù 14:8-14) Jèhófà pín Òkun Pupa sí méjì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sá àsálà. Àwọn ọmọ ogun Fáráò gbá tọ̀ wọ́n, ṣùgbọ́n Jèhófà lo agbára rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí “ibú bò wọ́n mọ́lẹ̀: wọ́n rì sí ìsàlẹ̀ bí òkúta.” Lẹ́yìn náà, Mósè gbé Jèhófà ga ní kíkọrin pé: “Ta ni ó dà bí ìwọ, OLÚWA, ológo ní mímọ́, ẹlẹ́rù ní ìyìn, tí ń ṣe ìyanu.”—Ẹ́kísódù 15:4-12, 19.
21. Báwo ni a ṣe gba àwọn ènìyàn Jèhófà lọ́wọ́ àwọn ará Ámónì, Móábù, àti Séírì?
21 Ní àkókò míràn, àwọn Ámónì, Móábù, àti Séírì (Édómù), àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá fi ìparun halẹ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Jèhófà. Jèhófà wí pé: “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má sì ṣe fòyà nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn [ọ̀tá] yí, nítorí ogun náà kì í ṣe ti yín bí kò ṣe ti Ọlọ́run. . . . Ẹ̀yin kò ní ìjà ní ọ̀ràn yí; . . . Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa.” Jèhófà dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè, nípa mímú kí ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàárín ẹgbẹ́ àwọn ọ̀tá náà, kí ẹnì kíní baà lè pa ẹnì kejì.—Kíróníkà Kejì 20:15-23.
22. Ìdáǹdè àgbàyanu wo kúrò lọ́wọ́ Ásíríà ni Jèhófà pèsè fún Ísírẹ́lì?
22 Nígbà tí Agbára Ayé Ásíríà dìde sí Jerúsálẹ́mù, Ọba Senakéríbù gan Jèhófà, nípa sísọ fún àwọn ènìyàn tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri pé: “Ta ni nínú gbogbo òrìṣà ilẹ̀ wọ̀nyí [tí mo ti ṣẹ́gun], tí ó ti gba ilẹ̀ wọn kúrò ní ọwọ́ mi, tí Olúwa yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò ní ọwọ́ mi?” Ó wí fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekáyà kí ó mú yín gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa, wí pé, Ní gbígbà Olúwa yóò gbà wá.” Lẹ́yìn náà, Hesekáyà gbàdúrà kíkankíkan fún ìdáǹdè, “kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ìwọ ni Olúwa, àní ìwọ nìkan ṣoṣo.” Jèhófà pa 185,000 ọmọ ogun Ásíríà, a sì dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nídè. Lẹ́yìn náà, bí Senakéríbù ti ń jọ́sìn ọlọ́run èké rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pa á.—Aísáyà, orí 36 àti 37.
23. Àwọn ìbéèrè wo nípa ìdáǹdè lónìí ni ó ń fẹ́ ìdáhùn?
23 Dájúdájú, a lè mọ́kàn le nígbà tí a bá rí bí Jèhófà ṣe dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè lọ́nà ìyanu ní ìgbà àtijọ́. Lónìí ńkọ́? Ipò eléwu wo ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ yóò wà láìpẹ́, tí yóò béèrè pé kí ó dá wọn nídè lọ́nà ìyanu? Èé ṣe tí òun fi dúró títí di ìsinsìnyí láti mú ìdáǹdè wọn wá? Báwo ni a óò ṣe mú ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ pé: “Bí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nàró ṣánṣán kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé”? (Lúùkù 21:28) Báwo sì ni ìdáǹdè yóò ṣe dé fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ti kú? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Èé ṣe tí àìní ńláǹlà fi wà fún ìdáǹdè?
◻ Èé ṣe tí a kò fi ní láti yíjú sí ẹ̀dá ènìyàn fún ìdáǹdè?
◻ Àwọn wo ni ìdáǹdè kù sí dẹ̀dẹ̀ fún?
◻ Èé ṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé nínú ìdáǹdè Jèhófà?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ ìdáǹdè ìgbà àtijọ́ wo ni ó fúnni níṣìírí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ábúráhámù wà lára àwọn tí wọ́n ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà