ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 11/1 ojú ìwé 22-26
  • Ọ̀rọ̀ Jèhófà Kì í Kùnà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Jèhófà Kì í Kùnà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Dá Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nídè
  • Jèhófà Ń Dáàbò Bo Àwọn Èèyàn Rẹ̀
  • Jèhófà Ń Pèsè Ohun Táwọn Èèyàn Rẹ̀ Nílò
  • Bí Jèhófà Ṣe Dá Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nídè Lóde Òní
  • Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Lónìí
  • Jèhófà Ń Pèsè Ohun Táwọn Èèyàn Rẹ̀ Nílò Lónìí
  • Ohun Tí Jóṣúà Rántí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ẹni Tó Ń Mú Ìlérí Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Jóṣúà 1:9—“Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóṣúà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 11/1 ojú ìwé 22-26

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Kì í Kùnà

“Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín.”—JÓṢÚÀ 23:14.

1. Ta ni Jóṣúà, kí ló sì ṣe nígbà tó ń sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀?

ỌKÙNRIN kan wà tó jẹ́ akínkanjú, ọ̀gágun tí kì í bẹ̀rù sì ni, ó tún nígbàgbọ́, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ó bá Mósè rìn, òun ni Jèhófà sì yàn láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti inú aginjù tó bani lẹ́rù gan-an lọ sí ilẹ̀ kan tó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin. Jóṣúà ni ọkùnrin tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, àwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an. Nígbà tó ń sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀, ó sọ ọ̀rọ̀ ìdágbére kan tó wọni lọ́kàn gan-an fáwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn tó gbọ́rọ̀ náà túbọ̀ lágbára sí i. Ó sì lè mú kí ìgbàgbọ́ tìrẹ náà túbọ̀ lágbára sí i.

2, 3. Ipò wo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà lákòókò tí Jóṣúà bá àwọn àgbà ọkùnrin ibẹ̀ sọ̀rọ̀, kí ni Jóṣúà sì sọ fún wọn?

2 Fojú inú wo ipò tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà lákòókò yẹn gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́, ó ní: “Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn tí Jèhófà ti fún Ísírẹ́lì ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá wọn yí ká, nígbà tí Jóṣúà darúgbó, tí ó sì pọ̀ ní ọjọ́, pé Jóṣúà bẹ̀rẹ̀ sí pe gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn àgbà ọkùnrin rẹ̀ àti àwọn olórí rẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ rẹ̀ àti àwọn onípò àṣẹ láàárín rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé: ‘Ní tèmi, mo ti di arúgbó, mo ti pọ̀ ní ọjọ́.’”—Jóṣúà 23:1, 2.

3 Jóṣúà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni àádọ́fà ọdún lákòókò yẹn, àkókò tó gbé ayé sì jẹ́ àkókò táwọn nǹkan tó yani lẹ́nu gan-an ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó ti fojú ara rẹ̀ rí àwọn iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ṣe, ó sì tún rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nímùúṣẹ. Gbogbo àwọn ohun tó fojú ara rẹ̀ rí yìí ló mú kó fọwọ́ sọ̀yà pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.”—Jóṣúà 23:14.

4. Àwọn ohun wo ni Jèhófà ṣèlérí rẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

4 Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà sọ tó sì nímùúṣẹ nígbà ayé Jóṣúà? A ó ṣàyẹ̀wò ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Jèhófà ṣèlérí rẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìkíní, Ọlọ́run yóò dá wọn nídè kúrò lóko ẹrú. Èkejì, yóò dáàbò bò wọ́n. Ìkẹta, yóò pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Jèhófà ti ṣèlérí kan náà fáwọn èèyàn rẹ̀ ayé òde òní. Àwa náà ti rí i pé wọ́n ti nímùúṣẹ nígbà ayé wa. Àmọ́, ká tó sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe lákòókò tiwa yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ṣe nígbà ayé Jóṣúà.

Jèhófà Dá Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nídè

5, 6. Báwo ni Jèhófà ṣe mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, kí sì ni èyí fi hàn?

5 Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Ọlọ́run nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà nílẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà gbọ́ igbe wọn. (Ẹ́kísódù 2:23-25) Nígbà tí Jèhófà ń bá Mósè sọ̀rọ̀ níbi igbó tó ń jó, ó sọ fún un pé: “Èmi ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti dá [àwọn èèyàn mi] nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, kí n sì mú wọn gòkè wá láti ilẹ̀ yẹn sí ilẹ̀ kan tí ó dára tí ó sì ní àyè gbígbòòrò, sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kísódù 3:8) Inú wọn á mà dùn gan-an o nígbà tí Jèhófà bá ṣe ohun tó sọ yìí! Nígbà tí Fáráò kọ̀ láti jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, Mósè sọ fún un pé Ọlọ́run yóò sọ omi Odò Náílì di ẹ̀jẹ̀. Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣẹ. Omi Odò Náílì di ẹ̀jẹ̀ lóòótọ́. Àwọn ẹja inú rẹ̀ kú, omi odò náà ò sì ṣeé mu mọ́. (Ẹ́kísódù 7:14-21) Síbẹ̀, Fáráò ṣorí kunkun, Jèhófà sì jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn mẹ́sàn-án mìíràn wáyé nílẹ̀ Íjíbítì, ó ṣàlàyé bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àjàkálẹ̀ àrùn náà ṣe máa rí kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. (Ẹ́kísódù, orí 8 sí 12) Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn kẹwàá pa gbogbo ọmọ tó jẹ́ àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì, Fáráò ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa lọ, wọ́n sì lọ lóòótọ́!—Ẹ́kísódù 12:29-32.

6 Ìdáǹdè yẹn ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún sísọ tí Jèhófà sọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè tí òun yàn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà jẹ́ Ẹni tó máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò lè kùnà láé. Ó tún fi hàn pé Jèhófà lágbára ju gbogbo ọlọ́rùn àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Bá a ṣe ń ka nípa ìdáǹdè yẹn, ó ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára wa ká ní àwa náà wà níbẹ̀! Jóṣúà rí i pé láìsí àní-àní, Jèhófà ni “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.

Jèhófà Ń Dáàbò Bo Àwọn Èèyàn Rẹ̀

7. Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ogun Fáráò?

7 Ohun kejì tí Jèhófà sọ pé òun máa ṣe ńkọ́, pé òun á dáàbò bò wọ́n? Èyí hàn nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun yóò kó àwọn èèyàn òun kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, òun á sì mú wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Rántí pé ńṣe ni Fáráò tínú ń bí àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tó lágbára gan-an pẹ̀lú ọgọ́rọ̀ọ̀rún kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbá tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn. Ẹ wo bí ọkàn Fáráò onígbèéraga yẹn á ṣe balẹ̀ tó, àgàgà nígbà tó dà bíi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti há nítorí pé àwọn òkè tó yí wọn ká àti òkun tó wà níwájú wọn kò jẹ́ kí wọ́n rọ́nà gbà! Àkókò yẹn gan-an ni Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nípa mímú kí àwọsánmà kan wà láàárín àwọn ọmọ ogun Fáráò àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Òkùnkùn ṣú lápá ibi táwọn ará Íjíbítì wà àmọ́ ìmọ́lẹ̀ wà lápá ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà. Nígbà tí àwọsánmà náà kò jẹ́ káwọn ará Íjíbítì lọ mọ́, Mósè na ọ̀pá rẹ̀ sí òkun, omi Òkun Pupa sì pínyà. Èyí wá ṣí ọ̀nà àbáyọ sílẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ pańpẹ́ ló jẹ́ fáwọn ará Íjíbítì. Jèhófà pa ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò àti kẹ̀kẹ́ ogun wọn run yán-ányán-án, ó sì dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tó dájú pé wọn ì bá ṣẹ́gun wọn.—Ẹ́kísódù 14:19-28.

8. Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (a) nínú aginjù àti (b) nígbà tí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí?

8 Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Òkun Pupa, wọ́n ń rìn kiri lórí ilẹ̀ kan tí Bíbélì pè ní ‘aginjù ńlá tí ó ní ẹ̀rù, tí ó ní àwọn ejò olóró àti àwọn àkekèé àti pẹ̀lú ìyàngbẹ ilẹ̀ tí kò ní omi kankan.’ (Diutarónómì 8:15) Jèhófà tún dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú. Nígbà tí wọ́n tún fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí ńkọ́? Ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Kénáánì tí wọ́n lágbára gan-an tún gbógun tì wọ́n. Síbẹ̀, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Dìde nísinsìnyí, kí o sì sọdá Jọ́dánì yìí, ìwọ àti gbogbo ènìyàn yìí, sórí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn, fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹnikẹ́ni kì yóò mú ìdúró gbọn-in gbọn-in níwájú rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti wà pẹ̀lú Mósè ni èmi yóò ṣe wà pẹ̀lú rẹ. Èmi kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá.” (Jóṣúà 1:2, 5) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yẹn nímùúṣẹ. Láàárín nǹkan bí ọdún mẹ́fà péré, Jóṣúà ṣẹ́gun àwọn ọba mọ́kànlélọ́gbọ̀n, ó sì gba èyí tó pọ̀ jù lọ lára Ilẹ̀ Ìlérí. (Jóṣúà 12:7-24) Kò sọ́gbọ́n tí ìṣẹ́gun yẹn ì bá fi ṣeé ṣe tí kì í bá ṣe pé Jèhófà dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ ó sì bìkítà nípa wọn.

Jèhófà Ń Pèsè Ohun Táwọn Èèyàn Rẹ̀ Nílò

9, 10. Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò fún wọn nínú aginjù?

9 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun kẹta tí Jèhófà sọ pé òun á ṣe fáwọn èèyàn òun, pé òun á pèsè ohun tí wọ́n nílò. Kété lẹ́yìn ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nílẹ̀ Íjíbítì ni Ọlọ́run ṣèlérí fún wọn pé: “Kíyè sí i, èmi yóò rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run; àwọn ènìyàn náà yóò sì jáde, olúkúlùkù yóò sì kó iye tirẹ̀ ti òòjọ́ fún òòjọ́.” Ọlọ́run ṣe ohun tó sọ yìí lóòótọ́, ó pèsè ‘oúnjẹ láti ọ̀run.’ “Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: ‘Kí ni èyí?’” Mánà ni, oúnjẹ tí Jèhófà ṣèlérí rẹ̀ fún wọn.—Ẹ́kísódù 16:4, 13-15.

10 Odindi ogójì ọdún gbáko làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wà nínú aginjù, Jèhófà sì bójú tó wọn, ó pèsè oúnjẹ àti omi fún wọn. Kódà, ó rí i dájú pé aṣọ àlàbora wọn kò gbó mọ́ wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wọn kò wú. (Diutarónómì 8:3, 4) Jóṣúà rí gbogbo rẹ̀. Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè, ó dáàbò bò wọ́n, ó sì pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn, bó ti ṣèlérí rẹ̀ gẹ́lẹ́.

Bí Jèhófà Ṣe Dá Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nídè Lóde Òní

11. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Brooklyn, New York, lọ́dún 1914, àkókò wo ló sì tó nígbà náà?

11 Àkókò tiwa yìí wá ńkọ́? Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Friday, October 2, 1914, Arákùnrin Charles Taze Russell tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lákòókò yẹn wọ ilé ìjẹun tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn, New York. Ó sì fi tayọ̀tayọ̀ sọ pé: “Ẹ káàárọ̀ o.” Lẹ́yìn ìyẹn, kó tóó jókòó, ó fayọ̀ kéde pé: “Àwọn àkókò Kèfèrí ti dópin; àwọn ọba wọn ti lo ìgbà wọn kọjá.” Àkókò tún tó lẹ́ẹ̀kan sí i fún Jèhófà Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run láti dá sí ọ̀ràn àwọn èèyàn rẹ̀. Ó sì dá sí i lóòótọ́!

12. Ìdáǹdè wo ló wáyé lọ́dún 1919, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

12 Ọdún márùn-ún péré lẹ́yìn ìyẹn ni Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò ní “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn gbogbo ìsìn èké ayé lápapọ̀. (Ìṣípayá 18:2) Àwọn tó jẹ́ àgbàlagbà lára wa tí wọ́n fojú ara wọn rí ìdáǹdè amóríyá yìí kò pọ̀ mọ́. Àmọ́, a rí àbájáde rẹ̀ kedere. Jèhófà mú kí ìjọsìn tòótọ́ tún padà fìdí múlẹ̀, ó sì mú káwọn tó fẹ́ jọ́sìn òun wà níṣọ̀kan. Wòlíì Aísáyà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ èyí ṣáájú, ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀.”—Aísáyà 2:2.

13. Kí nìdí tó o fi lè sọ pé àwọn èèyàn Jèhófà ń pọ̀ sí i?

13 Ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ yìí kò ṣàì nímùúṣẹ. Lọ́dún 1919, àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ sí í fìgboyà jẹ́rìí jákèjádò ayé, iṣẹ́ ìjẹ́rìí yìí sì gbé ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ ga gan-an. Ní nǹkan bí àádọ́rin ọdún sẹ́yìn, ó wá hàn kedere pé Jèhófà ti pe àwọn “àgùntàn mìíràn” láti lọ́wọ́ nínú ìjọsìn mímọ́. (Jòhánù 10:16) Àwọn tó ń ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn yìí kọ́kọ́ jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún, lẹ́yìn náà wọ́n di ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún, wọ́n sì ti di àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí! Nínú ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, ó sọ pé wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Kí ni o ti rí látìgbà tó o ti dáyé? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mélòó ló wà láyé nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Iye àwọn tó ń sin Jèhófà lóde òní ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje [6,700,000]. Dídá tí Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò ní Bábílónì ńlá ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún pípọ̀ tá à ń pọ̀ sí i kárí ayé, èyí tá à ń rí báyìí tó sì ń múnú wa dùn.

14. Ìdáǹdè wo ló ṣì ń bọ̀ lọ́nà?

14 Ìdáǹdè kan ṣì tún ń bọ̀ lọ́nà o, èyí tó máa kan gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátá! Jèhófà á lo agbára rẹ̀ lọ́nà kíkàmàmà, yóò pa gbogbo àwọn tó ń ta kò ó run, yóò sì mú àwọn èèyàn rẹ̀ wọnú ayé tuntun tí òdodo yóò máa gbé. Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu gbáà ló máa jẹ́, nígbà tá a bá rí i pé ìwà ibi kò sí mọ́, tí àkókò tó tíì dára jù lọ nínú ìtàn ìran èèyàn sì wọlé dé wẹ́rẹ́!—Ìṣípayá 21:1-4.

Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Lónìí

15. Kí nìdí tá a fi nílò ààbò Jèhófà lóde òní?

15 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́ Jóṣúà nílò ààbò Jèhófà. Ṣé àwọn tó jẹ́ èèyàn Jèhófà láyé òde òní ò nílò ààbò rẹ̀ ni? Dájúdájú wọ́n nílò rẹ̀! Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 24:9) Ó ti pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fara da àtakò tó burú jáì àti inúnibíni líle koko ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Síbẹ̀, a ti rí i dájú pé Jèhófà ò fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀. (Róòmù 8:31) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un dá wa lójú pé kò sí ohunkóhun, ìyẹn ni pé ‘kò sí ohun ìjà èyíkéyìí tó lè dìde sí wa’ tí yóò dá iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe dúró.—Aísáyà 54:17.

16. Ẹ̀rí wo lo ti rí tó fi hàn pé Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?

16 Pẹ̀lú báyé ṣe kórìíra àwa èèyàn Jèhófà tó, ńṣe là ń pọ̀ sí i. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pọ̀ sí i ní igba ilẹ̀ ó lé mẹ́rìndínlógójì [236] báyìí, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí tó mú un dáni lójú pé Jèhófà ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa wa run àtàwọn tó fẹ́ dá iṣẹ́ wa dúró. Ǹjẹ́ o lè rántí orúkọ àwọn olóṣèlú tó lágbára gan-an tàbí àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n ti ṣàtakò tó burú jáì sáwọn èèyàn Ọlọ́run látìgbà tó o ti dáyé? Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ibo ni wọ́n wà lónìí? Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ti ṣègbé, bíi ti Fáráò ìgbà ayé Mósè àti ìgbà ayé Jóṣúà. Àwọn tó jólóòótọ́ títí dójú ikú lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní wá ńkọ́? Jèhófà dáàbò bò wọ́n nítorí pé ó ń rántí wọn. Kò sí ààbò mìíràn tó jùyẹn lọ. Láìsí àní-àní, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ààbò, àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà ti nímùúṣẹ.

Jèhófà Ń Pèsè Ohun Táwọn Èèyàn Rẹ̀ Nílò Lónìí

17. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nípa oúnjẹ tẹ̀mí?

17 Jèhófà pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò nínú aginjù, ó tún ń pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn lóde òní pẹ̀lú. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa. (Mátíù 24:45) A ń gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́, èyí tó ti jẹ́ àṣírí láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Áńgẹ́lì kan sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, kí o sì fi èdìdì di ìwé náà, títí di àkókò òpin. Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.”—Dáníẹ́lì 12:4.

18. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìmọ̀ tòótọ́ ti pọ̀ yanturu lóde òní?

18 A ti wà ní àkókò òpin náà báyìí, ìmọ̀ tòótọ́ sì ti pọ̀ yanturu. Jákèjádò ayé ni ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ síbi tí wọ́n á ti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run tòótọ́ tí wọ́n á sì tún mọ ohun tó fẹ́ ṣe fún ọmọ aráyé. Bíbélì ti pọ̀ gan-an lóde òní, àwọn ìwé tó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Bíbélì sì pọ̀ rẹpẹtẹ. Bí àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?a tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Díẹ̀ lára àwọn àkòrí tó wà níbẹ̀ ni: “Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?,” “Ibo Làwọn Òkú Wà?,” “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?,” àti “Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?” Ọmọ aráyé ti ń ronú lórí irú àwọn ìbéèrè bí èyí láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Ìdáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn ti wá wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn èèyàn fi jẹ́ aláìmọ̀kan táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sì ń fi ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà kọ́ni, síbẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run borí, ó sì pèsè ohun tí gbogbo àwọn tó fẹ́ sin Jèhófà nílò fún wọn.

19. Àwọn ìlérí wo lo fojú ara rẹ rí i pé wọ́n ti nímùúṣẹ, èrò wo nìyẹn sì ti mú kó o ní nípa Ọlọ́run?

19 Láìsí àní-àní, pẹ̀lú ohun tá a ti fojú ara wa rí, a lè sọ pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.” (Jóṣúà 23:14) Jèhófà ń dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè, ó ń dáàbò bò wọ́n, ó sì tún ń pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Ǹjẹ́ o lè mẹ́nu kan ìlérí kan tí Jèhófà ṣe tí kò sì nímùúṣẹ lákòókò tó sọ pé òun máa mú un ṣẹ? Kó sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká fọkàn tán Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeé gbára lé.

20. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ bá a ti ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

20 Ọjọ́ iwájú ńkọ́? Jèhófà ti sọ fún wa pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára wa yóò làǹfààní láti gbé lórí ilẹ̀ ayé tó máa di Párádísè aláyọ̀. Àwọn díẹ̀ lára wa tún nírètí àtibá Kristi ṣàkóso lókè ọ̀run. Èyí ó wù kó jẹ́ tiwa níbẹ̀, kò sídìí tí kò fi yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ títí dópin bíi ti Jóṣúà. Ọjọ́ kan ń bọ̀ tí gbogbo ohun tá à ń retí yóò tẹ̀ wá lọ́wọ́. Ìgbà yẹn la óò rántí gbogbo ìlérí tí Jèhófà ti ṣe, táwa náà á wá sọ pé: “Gbogbo wọn ti ṣẹ.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Àwọn ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ tí Jóṣúà sì fojú ara rẹ̀ rí i pé ó nímùúṣẹ?

• Àwọn ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe tó o sì ti fojú ara rẹ rí i pé wọ́n nímùúṣẹ?

• Kí ló dá wa lójú nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Jèhófà dá sí ọ̀ràn àwọn èèyàn rẹ̀ ó sì dá wọn nídè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ ní Òkun Pupa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò nínú aginjù?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Jèhófà ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́