Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Títan Irúgbìn Ìjọba Kálẹ̀ ní Gbogbo Ìgbà
Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, rọni láti jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn. Ọba Sólómọ́nì wí pé: “Ní kùtùkùtù fún irúgbìn rẹ, àti ní àṣálẹ́ má ṣe dá ọwọ́ rẹ dúró: nítorí tí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere, yálà èyí tàbí èyíinì, tàbí bí àwọn méjèèjì yóò dára bákan náà.”—Oníwàásù 11:6.
Ní gbogbo ìgbà yíyẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fún “irúgbìn” nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ní àwọn ilẹ̀ àti àgbájọ erékùṣù tí ó lé ní 230, wọ́n ń bá a nìṣó “láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:42) Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ṣàkàwé bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ‘kò ṣe jẹ́ kí ọwọ́ wọn kí ó dẹ̀’ nínú iṣẹ́ ìwàásù.
◻ Ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Cape Verde, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan, nígbà tí ó ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Nínú àgbàlá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan jókòó sórí igi. Ní ṣíṣàkíyèsí Ẹlẹ́rìí náà nísàlẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà rọ̀ ọ́ pé kí ó fún àwọn ní ìwé ìròyìn díẹ̀. Ẹlẹ́rìí náà di ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! díẹ̀ mọ́ òkúta kan, ó sì jù ú gba orí ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ìyọrísí ọkàn ìfẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ yìí ni pé, a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 12. Mẹ́ta lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi. Ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ti ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún, tàbí aṣáájú ọ̀nà, fún ohun tí ó lé ní ọdún kan nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n, báwo ni wọ́n ṣe ń darí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a pín ọgbà ẹ̀wọ̀n náà sí àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀. Lẹ́yìn náà, a pín àgbègbè ìpínlẹ̀ náà láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta náà, wọ́n sì ń jẹ́rìí láti yàrá ọgbà ẹ̀wọ̀n kan sí èkejì. Àwọn olùpòkìkí Ìjọba wọ̀nyí ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi ọkàn ìfẹ́ hàn gẹ́gẹ́ bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti ń ṣe—nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò. Ṣùgbọ́n, ìyàtọ̀ kan tí ó wà ni bí a ṣe ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tó. Kàkà tí wọn yóò fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀méjì láàárín ọ̀sẹ̀ kan fún wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan ń kẹ́kọ̀ọ́ lójoojúmọ́! Ní àfikún sí i, ọ̀gá àgbà ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ti yọ̀ǹda fún Àwọn Ẹlẹ́rìí láti máa darí gbogbo ìpàdé ìjọ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.
◻ Obìnrin kan tí ó jẹ́ ará Potogí jogún ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde Watch Tower lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ àgbà kú. Níwọ̀n bí òun kò ti jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò ní ọkàn ìfẹ́ nínú títọ́jú àwọn ìwé náà. Ṣùgbọ́n, kò fẹ́ run wọ́n. Ní ọjọ́ kan, ó sọ nípa ibi ìkówèésí náà fún ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó kàn sí i nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹnu ọ̀nà sí ẹnu ọ̀nà. Ẹlẹ́rìí náà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó bá mọ bí ibi ìkówèésí náà ṣe níye lórí tó. Obìnrin náà fèsì pé: “Ní tòótọ́, n kò mọ bí wọ́n ṣe níye lórí tó, ṣùgbọ́n báwo ni mo se lè mọ̀ ọ́n?” Obìnrin náà tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣìkẹ́ ibi ìkówèésí ìyá rẹ̀ àgbà. Nísinsìnyí, òun pẹ̀lú ti di Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, tí ó ti ṣe ìrìbọmi. Ìyẹn nìkan kọ́, ọmọbìnrin rẹ̀, àti ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan fún ìdílé náà ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú. Ẹ wo irú ogún níníye lórí ti àwọn ìwé wọ̀nyí jẹ́!