ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 5/15 ojú ìwé 3-4
  • O ha gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O ha gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Bíbélì Kọ́ni Pé Èèyàn Máa Ń Tún Ayé Wá?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ó Ha Yẹ Kí O Gbà Gbọ́ Nínú Àtúnwáyé Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ǹjẹ́ O Rò Pé Èèyàn Máa Ń Tún Ayé Wá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Èrò Náà Wọnú Àwọn Ẹ̀sìn Ìlà-Oòrùn
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 5/15 ojú ìwé 3-4

O ha gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé Bí?

MUKUNDBHAI kọ̀wé sí ọmọkùnrin rẹ̀, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì kan ní United States pé: “Ǹjẹ́ o rántí ọmọbìnrin àdúgbò wa tí ìfẹ́ rẹ̀ kó sí ọ lórí nígbà tí ẹ jọ ń dàgbà níhìn-ín ní Íńdíà? Yóò lọ sílé ọkọ ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sí i. Mo rò pé ó yẹ kí o gbọ́ nípa rẹ̀.”

Èé ṣe tí bàbá yìí fi fi ìròyìn yí tó ọmọkùnrin rẹ̀ létí? Ó ṣe tán, Mukundbhai fi gbogbo agbára fòpin sí òòfà ìfẹ́ ìgbà ọ̀dọ́langba yẹn ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Ìyẹn nìkan kọ́, ọmọkùnrin náà ti wà ní United States fún ọdún mẹ́fà báyìí, tí ń lépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gíga. Ní gbogbo àkókò yẹn, ọmọbìnrin náà kò gbúròó rẹ̀, Mukundbhai sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Nígbà náà, kí ni ó fa àníyàn náà? Mukundbhai dàníyàn nítorí pé ó gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé, tàbí àtúnbí.a Bí ó bá ṣèèṣì jẹ́ pé òòfà ìfẹ́ ìgbà ọmọdé tí ó wà láàárín àwọn méjèèjì jẹ́ nítorí pé wọ́n ti jẹ́ tọkọtaya nígbà àkọ́wáyé wọn, yóò jẹ́ ìwà òǹrorò gbáà láti yà wọ́n nípa nísinsìnyí tí wọ́n ti tó ṣe ìgbéyàwó. Mukundbhai ṣáà fẹ́ kí ọmọkùnrin rẹ̀ mọ̀ bí ipò nǹkan ti rí kí ó tó di pé ọmọbìnrin náà di aya ọkùnrin mìíràn nínú ayé eléyìí.

Gbé ọ̀ràn míràn yẹ̀ wò. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rin kan ti jẹ̀rora púpọ̀ ní ilé ìwòsàn kan ní Mumbai, Íńdíà. Ìṣòro rẹ̀ ni pé, ọ̀kan nínú àwọn òpójẹ̀ inú ọkàn àyà rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ dáradára. Àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n rí já jẹ kò lè fara da lílajú sílẹ̀ kí ọmọ wọn máa jìyà. Ṣùgbọ́n wọ́n ronú pé: “A gbọ́dọ̀ gba kámú. Ó ti ní láti ṣe láabi kan nígbà àkọ́wáyé rẹ̀ kí irú ìyà yí tó tọ́ sí i.”

Ìgbàgbọ́ nínú àtúnwáyé ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù, Búdà, Jéínì, Síìkì, àti àwọn ẹlẹ́sìn míràn tí ó pilẹ̀ ṣẹ̀ ní Íńdíà. Àwọn ìrírí ayé—láti orí kíkó sínú ìfẹ́ títí dórí ìjìyà mímúná—ni a kà sí àbájáde àwọn ìwà láabi tí ẹnì kan ti hù nínú ayé tàbí àwọn ayé tí ó ti gbé ṣáájú.

Ọ̀pọ̀ tí ń gbé ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn ayé pẹ̀lú ní ọkàn ìfẹ́ nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àtúnwáyé. Òṣèrébìnrin ará America náà, Shirley MacLaine, sọ pé òun gbà gbọ́ nínú rẹ̀. Òǹkọ̀wé, Laurel Phelan, ti Vancouver, British Columbia, Kánádà, sọ pé òun lè rántí 50 ayé tí òun ti gbé sẹ́yìn. Nínú Ìwádìíkiri èrò ará ìlú, tí a ṣe fún àwọn ilé ìròyìn CNN/USA Today, ní 1994, iye tí ó lé ní 270 nínú 1,016 àgbàlagbà sọ pé àwọn gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé. Ìgbàgbọ́ nínú àtúnwáyé tún jẹ́ apá kan àjọ ìgbòkègbodò Sànmánì Tuntun. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí wo ni ó ti ìgbàgbọ́ yìí lẹ́yìn?

Àwọn onígbàgbọ́ nínú àtúnwáyé sọ pé, “Ìrántí tí a ní nípa ayé tí a ti gbé ṣáájú ni!” Lójú ìwòye èyí, nígbà tí Ratana ní Bangkok, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta, bẹ̀rẹ̀ sí í “rántí ayé tí ó gbé ṣáájú gẹ́gẹ́ bí obìnrin onífọkànsìn tí ó kú nígbà tí ó lé ní 60 ọdún,” ọ̀pọ̀ olùṣàkíyèsí gba ọ̀ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé àtúnwáyé ń bẹ.

Àmọ́, iyè méjì pọ̀ lọ jàra. Àwọn ọ̀nà míràn ṣì wà tí a lè gbà ṣàlàyé àwọn ìrántí tí a so mọ́ ayé tí a gbé ṣáájú.b Nínú ìwé rẹ̀ Hinduism: Its Meaning for the Liberation of the Spirit, ọlọ́gbọ́n èrò orí tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù, Nikhilananda, sọ pé ‘èrò níní ìrírí lẹ́yìn ikú jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.’ Síbẹ̀, ó gbà pé “ṣíṣeéṣe pé ìgbàgbọ́ àtúnbí wà ga ju pé kò sí lọ.”

Ṣùgbọ́n Bíbélì ha ti ẹ̀kọ́ yìí lẹ́yìn bí? Ìrètí wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí sì sọ fúnni pé ó wà fún àwọn òkú?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica, sọ pé “àtúnwáyé jẹ́ àtúnbí ọkàn tí ó tún ayé wá lẹ́ẹ̀kan tàbí lọ́pọ̀ ìgbà léraléra, bóyá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, ẹranko, tàbí, nígbà míràn, gẹ́gẹ́ bí irúgbìn.” A tún lo ọ̀rọ̀ náà, “àtúnbí,” láti ṣàpèjúwe ohun abàmì yí, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “àtúnwáyé,” ni a tẹ́wọ́ gbà níbi gbogbo. Ọ̀pọ̀ ìwé atúmọ̀ èdè Íńdíà lo ọ̀rọ̀ méjèèjì láti rọ́pò ara wọn.

b Wo ojú ìwé 5 sí 7 ìtẹ̀jáde Jí!, June 8, 1994.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

A ha ń jẹ ẹ́ níyà nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá nígbà àkọ́wáyé rẹ̀ bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́