Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Sísá Wá Sínú Ètò Àjọ Ìṣàkóso Jèhófà
TIPẸ́TIPẸ́ sẹ́yìn, a sún wòlíì Aísáyà láti polongo pé: ‘Wọn yóò máa yin Jèhófà lógo ní àwọn erékùṣù òkun.’ (Aísáyà 24:15, NW) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka àwọn erékùṣù òkun sí ara “ilẹ̀ ayé tí a ń gbé,” tí Jésù sọ pé, ‘a ní láti wàásù ìhìn rere náà.’—Mátíù 24:14; Máàkù 13:10.
Àwọn Erékùṣù Marquesas wà ní 1,400 kìlómítà sí àríwá ìlà oòrùn Tahiti. Wọ́n jẹ́ apá kan àgbájọ erékùṣù jíjìnnà réré ní Gúúsù Pàsífíìkì tí a ń pè ní French Polynesia. Pẹ̀lú ilẹ̀ ọlọ́ràá, tí ó jẹ́ àbájáde ìrusókè òkè ayọnáyèéfín, àti ipò ojú ọjọ́ tí ó lọ́ wọ́ọ́rọ́ àti ọ̀rinrin, àwọn ewébẹ̀ máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní àwọn erékùṣù wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, àwọn Marquesas náà tún ń so irú èso mìíràn. Gbé ọ̀ràn ìdílé kan tí wọ́n dáhùn pa dà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba ní erékùṣù Hiva Oa yẹ̀ wò.
Inú Jean àti aya rẹ̀, Nadine, kò dùn sí ohun tí a pè ní àwùjọ ọlọ́làjú ti Ìwọ̀ Oòrùn Europe tí wọ́n ń gbé. Nítorí èyí, wọ́n pinnu láti fi ìgbésí ayé aṣiṣẹ́ bí aago yẹn sílẹ̀, kí àwọn àti ọmọ wọ́n sì ṣí lọ sí àwọn Erékùṣù Marquesas. Ilé wọn tuntun, tí wọ́n fi ọparun kọ́, ń bẹ ní àfonífojì kan tí ó jìnnà gan-an sí ìlú. Láti lè dé ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò tí ó sún mọ́ wọn jù lọ, wọ́n ní láti rìn gba ọ̀nà orí òkè kan tí ó ṣe kọ́lọkọ̀lọ, fún wákàtí méjì. Yóò gba wákàtí mẹ́ta pẹ̀lú ọkọ̀ tí ó lè rin ọ̀nà tí kò fi bẹ́ẹ̀ dára láti dé abúlé tí ó sún mọ́ wọn jù lọ, tí ó ní dókítà, ilé ẹ̀kọ́, àti ìsọ̀ ńlá.
Jean àti Nadine kò lọ́kàn ìfẹ́ nínú ìsìn. Ṣùgbọ́n, wọ́n máa ń jíròrò nípa orísun ìwàláàyè. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń fẹ àwọn àbá èrò orí lílọ́júpọ̀ ti ẹfolúṣọ̀n lójú. Ṣùgbọ́n, kò sí ìkankan nínú àbá èrò orí wọn tí ó mú ìtẹ́lọ́rùn wá fún wọn.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé ní àdádó fún ọdún mẹ́fà, ó yà wọ́n lẹ́nu láti gba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì lálejò. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti gbọ́ nípa ibi tí Jean àti Nadine wà lẹ́nu àwọn ará abúlé tí wọ́n wà nítòsí. Bí ó ti sábà máa ń rí, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ náà yọrí sí ìjíròrò lórí àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n. Sí ìdùnnú tọkọtaya náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ní ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? lọ́wọ́, tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Inú Jean àti Nadine dùn láti ní ìwé tí ó gbé àyẹ̀wò fínnífínní lórí bí ìwàláàyè ṣe déhìn-ín kalẹ̀.
Kò pẹ́ kò jìnnà lẹ́yìn náà, a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Láàárín ọdún mẹ́ta, Jean àti Nadine tẹ̀ síwájú dáradára. Ó wá dá wọn lójú pé, láìpẹ́, ilẹ̀ ayé látòkè délẹ̀ yóò di párádísè kan. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ wọ́n ti pé mẹ́ta, rírìnrìn àjò fún wákàtí mẹ́rin lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wá di ìpèníjà ńlá. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò ní kí wọ́n má lọ. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Jean àti Nadine fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi. Wọ́n ṣe èyí ní àpéjọpọ̀ tí a ṣe ní olórí abúlé tí ó wà ní àgbègbè náà, níbi tí góńgó iye ènìyàn tí ó wá jẹ́ 38!
Láti baà lè ran àwùjọ akéde Ìjọba tí kò tó nǹkan náà lọ́wọ́, ìdílé náà pinnu láti fi ilé àdádó wọn sílẹ̀. Wọ́n ṣí lọ sí abúlé kan tí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ènìyàn ń gbé nínú rẹ̀, níbi tí Jean ti ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àdúgbò. Ìdílé yìí, tí wọ́n sá lọ sí erékùṣù náà láti lè bọ́ lọ́wọ́ ọ̀làjú, kà á sí àǹfààní láti rí ibi ìsádi tòótọ́ kan ṣoṣo náà, ètò àjọ ìṣàkóso Jèhófà.