Bíbélì Ìwé Tí Kò Láfiwé
A ti pè é ní ìwé tí ó tà jù lọ lágbàáyé, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́. Bíbélì ni a ń kà tí a sì ń ṣìkẹ́ju ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ. Di báyìí, a fojú díwọ̀n pé ìpínkiri rẹ̀ (lódindi tàbí lápá kan) ti tó bílíọ̀nù mẹ́rin ẹ̀dà, ní èdè tí ó lé ní 2,000. Ṣùgbọ́n, ohun tí ó túbọ̀ runi lọ́kàn sókè ju ìpínkiri Bíbélì ni, sísọ tí ó sọ pé òun jẹ́ ìwé Ọlọ́run. Kristẹni náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (Tímótì Kejì 3:16) Kí ni èyí túmọ̀ sí? Àpólà ọ̀rọ̀ náà, “ni Ọlọ́run mí sí,” (lédè Gíríìkì, the·oʹpneu·stos) ní òwuuru túmọ̀ sí “Ọlọ́run mí èémí sí.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tí ó fara pẹ́ ẹ, pneuʹma, túmọ̀ sí “ẹ̀mí.” Nítorí náà, ohun tí ó ń sọ ni pé, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sún àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn, ní mímí èémí sí wọn, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, kí a baà lè sọ ní tòótọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ohun tí wọ́n mú jáde nígbẹ̀yìngbẹ́yín, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ènìyàn. Ní tòótọ́, ẹnu ya ọ̀pọ̀ tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí ìṣọ̀kan tí ó ní látòkè délẹ̀, ìṣerẹ́gí rẹ̀ ní ti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àìlábòsí àti òótọ́ inú àwọn tí ó kọ ọ́, àti ní pàtàkì jù lọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó ní ìmúṣẹ—gbogbo èyí tí ó ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn onílàákàyè òǹkàwé gbà pé ìwé yìí jẹ́ láti orísun kan tí ó ga ju ènìyàn lọ.a
Ṣùgbọ́n báwo ni Ọlọ́run ṣe darí kíkọ Bíbélì láìgba gbẹ̀rẹ́ tó? Àwọn kan sọ pé pípè ni ó pe ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ́kọ̀ọ̀kan, tí a sì ń kọ ọ́ sílẹ̀. Àwọn mìíràn sọ pé èrò tí a rí nínú Bíbélì nìkan ni ó mí sí, kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní ti gidi, a kò lè fi ìmísí mọ sórí ọ̀nà kan ṣoṣo, nítorí Ọlọ́run ‘tipasẹ̀ àwọn wòlíì bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà.’ (Hébérù 1:1; fi wé Kọ́ríńtì Kíní 12:6.) Nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e, a óò ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá àwọn òǹkọ̀wé bí 40 tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n kọ Bíbélì sọ̀rọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo ojú ìwé 53 sí 54, àti 98 sí 161 ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s?, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.