Jerúsálẹ́mù ní Àkókò Tí A Kọ Bíbélì—Kí Ni Ẹ̀kọ́ Ìwalẹ̀pìtàn Ṣí Payá?
Ó DÙN mọ́ni pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìwalẹ̀pìtàn pàtàkì ti wáyé ní Jerúsálẹ́mù, ní pàtàkì láti 1967. Ní báyìí, a ti ń gba àwọn ènìyàn láyè láti wá wo ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí a ti wa nǹkan, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣèbẹ̀wò sí díẹ̀ nínú wọn, kí a sì rí bí ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn ṣe bá ìtàn Bíbélì mu.
Jerúsálẹ́mù Ti Ọba Dáfídì
Àgbègbè tí Bíbélì pè ní Òkè Síónì, lórí èyí tí a kọ́ Ìlú Ńlá ìgbàanì ti Dáfídì sí, fara hàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí kò ṣe pàtàkì rárá láàárín ìgboro Jerúsálẹ́mù ti òde òní. Wíwa ilẹ̀ Ìlú Ńlá Dáfídì, tí ọ̀jọ̀gbọ́n Yigal Shiloh tí ó ti dolóògbé jẹ́ agbátẹrù rẹ̀ ní ọdún 1978 sí 1985, ṣí òkúta ràgàjì kan, tàbí ògiri ààbò payá, ní ìhà ìlà oòrùn òkè náà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Shiloh sọ pé, ó ní láti jẹ́ àlàpà ògiri fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tí a fi ṣe ìgbátí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ náà lórí èyí tí àwọn ọmọ Jébúsì (àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kí Dáfídì tó ṣẹ́gun wọn) kọ́ ibi odi agbára sí. Ó ṣàlàyé pé òkúta ràgàjì tí òun rí lórí àwọn ògiri ìgbátí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ yìí jẹ́ ti ibi odi agbára tuntun tí Dáfídì kọ́ sórí ilẹ̀ tí ibi odi agbára àwọn ọmọ Jébúsì wà. Nínú Sámúẹ́lì Kejì 5:9, (NW) a kà pé: “Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú ibi odi agbára náà, a sì wá pè é ní Ìlú Ńlá Dáfídì; Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé yí ká láti Òkìtì wá àti sínú.”
Ẹnu ọ̀nà omi ìgbàanì tí ó jẹ́ ti ìlú ńlá náà wà lẹ́bàá ògiri yìí, apá kan èyí tí ó dà bí èyí tí ó ti wà láti ọjọ́ Dáfídì. Àwọn gbólóhùn kan nínú Bíbélì nípa ihò omi Jerúsálẹ́mù ti gbé ọ̀pọ̀ ìbéèrè dìde. Fún àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé “ẹnikẹ́ni tí ó bá kọlu àwọn ará Jébúsì, kí ó gba ti ibi ihò omi kan” ọ̀tá “lára.” (Sámúẹ́lì Kejì 5:8, NW) Jóábù olórí ogun Dáfídì ṣe èyí. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ihò omi” túmọ̀ sí gan-an?
A ti gbé àwọn ìbéèrè míràn dìde nípa Ihò Omi Sílóámù lílókìkí, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àwọn oníṣẹ́ ẹ̀rọ Ọba Hesekáyà ni ó gbẹ́ ẹ ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, tí a sì tọ́ka sí nínú Àwọn Ọba Kejì 20:20 àti Kíróníkà Kejì 32:30. Báwo ni àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì tí ń gbẹ́ ihò láti ìhà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe lè pàdé? Èé ṣe tí wọ́n fi yàn láti gbé e gba ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ, ní mímú kí ihò náà gùn ju ọ̀nà tí ó ṣe tààrà lọ? Báwo ni wọ́n ṣe rí èémí tí ó tó mí, pàápàá níwọ̀n bí ó ti ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé fìtílà tí ń lo epo ni wọ́n lò?
Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review ti pèsè àwọn ìdáhùn tí ó ṣeé ṣe sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Dan Gill, onímọ̀ nípa ilẹ̀ àti ohun inú rẹ̀ ti a kàn sí nípa ìwalẹ̀ náà, ni a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sọ pé: “Karst ti ìṣẹ̀dá wà lábẹ́ ilẹ̀ Ìlú Ńlá Dáfídì. Karst jẹ́ èdè àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ àti ohun inú rẹ̀, tí ń ṣàpèjúwe ẹkùn ilẹ̀ gbágungbàgun tí ó ní ṣẹ́ṣẹ́ funfun, ihò abẹ́lẹ̀ àti ọ̀nà tóóró tí omi abẹ́lẹ̀ gbẹ́ bí ó ti ń sun jáde, tí ó sì ń gba abẹ́ àpáta ṣàn kọjá. . . . Ìwádìí wa tí a gbé karí ìmọ̀ nípa ilẹ̀ àti ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ní ti ọ̀nà omi abẹ́lẹ̀ Ìlú Ńlá Dáfídì fi hàn pé, òye ènìyàn ni a fi mú ọ̀nà tóóró náà tí àgbàrá gbẹ́ gbòòrò sí i, tí a sì fi sọ ihò náà di ọ̀nà tí omi ń gbà.”
Èyí lè ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé bí a ṣe walẹ̀ kan Ọ̀nà Omi Sílóámù. A lè ti gbé e gba ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ ti ọ̀nà tóóró ti àgbàrá gbẹ́ tí ó wà lábẹ́ òkè náà. Nípa títún ìyẹ̀wù abẹ́lẹ̀ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ gbẹ́, àwọn ẹgbẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ ní ìhà méjèèjì lè ti gbẹ́ ọ̀nà omi kan tí a lè lò fún ìgbà díẹ̀. Lẹ́yìn náà, a gbẹ́ ọ̀nà tóóró kan tí ó da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ fún omi, kí ó lè ṣàn wá láti ṣẹ́lẹ̀rú Gíhónì lọ sí Odò Sílóámù, tí ó ṣeé ṣe kí ó wà nínú ògiri ìlú ńlá náà. Àgbà iṣẹ́ gidi ní ti ìmọ̀ ẹ̀rọ ni èyí jẹ́, níwọ̀n bí ohun tí apá méjèèjì fi ga ju ara wọn lọ kò ju sẹ̀ǹtímítà 32 péré, láìka gígùn rẹ̀ tí ó jẹ́ 533 mítà sí.
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé ṣẹ́lẹ̀rú Gíhónì ni orísun omi ìlú ńlá ìgbàanì náà. Ó wà lẹ́yìn ògiri ìlú ńlá náà, ṣùgbọ́n ó sún mọ́ ọn gan-an tí ó fi ṣeé ṣe láti gbẹ́ ọ̀nà omi kan àti ihò tí ó jìn ní mítà 11, tí yóò jẹ́ kí àwọn olùgbé ibẹ̀ lè máa pọn omi láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa jáde sẹ́yìn odi. A mọ èyí sí Ihò Warren, tí a sọ ní orúkọ Charles Warren, tí ó ṣàwárí ihò náà ní 1867. Ṣùgbọ́n nígbà wo ni a gbẹ́ ọ̀nà omi àti ihò náà? Wọ́n ha ti wà ní àkókò Dáfídì bí? Èyí ha ni ihò omi tí Jóábù lò bí? Dan Gill dáhùn pé: “Láti mọ̀ bóyá Ihò Warren ní tòótọ́ jẹ́ iho oníṣẹ́ṣẹ́ funfun ti àgbàrá gbẹ́, a ṣàyẹ̀wò èépá calcium carbonate lára ogiri rẹ̀ gbágungbàgun láti wò ó bóyá ó ní carbon-14. Kò ní i rárá, èyí tí ó fi hàn pé èépá náà tí wà fún ohun tí ó lé ní 40,000 ọdún: Èyí pèsè ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé kì í ṣe ènìyàn ni ó gbẹ́ ihò náà.”
Àwọn Àlàpà Tí Ó Ti Wà Láti Ọjọ́ Hesekáyà
Ọba Hesekáyà gbé ayé nígbà tí orílẹ̀-èdè Ásíríà ń ṣẹ́gun lọ́tùn-ún lósì. Ní ọdún kẹfà ìṣàkóso rẹ̀, àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun Samáríà, olú ìlú ńlá ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá. Ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà (ọdún 732 ṣááju Sànmánì Tiwa) àwọn ará Ásíríà tún pa dà wá, ní dídún mọ̀huru mọ̀huru mọ́ àwọn ará Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Kíróníkà Kejì 32:1-8 ṣàpèjúwe ọgbọ́n ìgbèjà tí Hesekáyà lò. Àwọn ẹ̀rí èyíkéyìí tí a lè fojú rí, tí ó jẹ́ ti sáà yí, ha wà bí?
Bẹ́ẹ̀ ni, ní ọdún 1969, Ọ̀jọ̀gbọ́n Nahman Avigad ṣàwárí àwọn àlàpà tí ó jẹ́ ti sáà náà. Ìwalẹ̀ ṣí apá kan ògiri ràgàjì kan payá, tí apá rẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ 40 mítà ní òòró, mítà 7 ní ìbú, tí a bá sì fojú díwọ̀n rẹ̀, ó ga tó mítà 8. Ògiri náà wà lórí àpáta lápá kan àti lórí àwọn ilé kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ lápá kejì. Ta ni ó mọ ògiri náà, ìgbà wo sì ni ó mọ ọ́n? Ìwé ìròyìn ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn kan sọ pé: “Àwọn àyọkà méjì nínú Bíbélì ṣèrànwọ́ fún Avigad láti mọ àkókò tí a mọ ògiri náà àti ète tí a fi mọ ọ́n.” Àwọn àyọkà náà kà báyìí: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mọ́kànle, ó sì mọ gbogbo ògiri tí a ti wó lulẹ̀, ó sì gbé àwọn ilé gogoro nà ró lé e lórí, àti ògiri mìíràn lóde.” (Kíróníkà Kejì 32:5, NW) “Ilé náà ni ẹ̀yin bì wó láti mú odi le.” (Aísáyà 22:10) Lónìí, àwọn olùṣèbẹ̀wò lè rí apá tí a ń pè ní Ògiri Fẹ̀ǹfẹ̀ yí ní Àdúgbò Àwọn Júù ní Ìlú Ńlá Àtijọ́ náà.
Onírúurú ìwalẹ̀ tún sí i payá pé ní àkókò yí, Jerúsálẹ́mù tóbi gan-an ju bí a ti rò tẹ́lẹ̀ lọ, bóyá nítorí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n rọ́ wọ inú rẹ̀ láti ìjọba àríwá lẹ́yìn tí àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun rẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Shiloh fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìlú ńlá àwọn ọmọ Jébúsì náà gbòòrò dé àgbègbè tí ó tó nǹkan bíi hẹ́kítà 6. Ní àkókò Sólómọ́nì ó gbòòrò tó hẹ́kítà 16. Nígbà tí yóò fi di àkókò Ọba Hesekáyà, ní 300 ọdún lẹ́yìn náà, ibi odi agbára náà ti gbòòrò tó nǹkan bí 60 hẹ́kítà.
Àwọn Itẹ́ Òkú Láti Ìgbà Tẹ́ńpìlì Àkọ́kọ́
Àwọn itẹ́ òkú láti ìgbà Tẹ́ńpìlì Àkọ́kọ́, ìyẹn ni pé, ṣáájú kí àwọn ará Bábílónì tó pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ti jẹ́ orísun ìsọfúnni mìíràn. A ṣàwárí àwọn ohun agbàfiyèsí nígbà tí a gbẹ́ àwọn ihò ìsìnkú tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Àfonífojì Hínómù ní 1979 sí 1980. Awalẹ̀pìtàn náà, Gabriel Barkay, sọ pé: “Nínú gbogbo ìtàn ìwádìí ìmọ̀ ìwalẹ̀pìtàn ní Jerúsálẹ́mù, èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi ìkẹ́rùsí díẹ̀ ti Tẹ́ńpìlì Àkọ́kọ́ tí a óò kọ́kọ́ rí pẹ̀lú ẹrù inú rẹ̀. Ó ní ẹrù tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún nínú.” Ó fi kún un pé: “Ìrètí gíga lọ́lá jù lọ ti awalẹ̀pìtàn èyíkéyìí tí ń ṣiṣẹ́ ní Ísírẹ́lì, pàápàá ní Jerúsálẹ́mù ní ni, láti ṣàwárí àwọn àkọsílẹ̀.” A ṣàwárí àwọn àkájọ kékeré méjì onífàdákà, kí ni ó wà nínú wọn?
Barkay ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo rí àkájọ tí a fi fàdákà ṣe, tí a nà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ náà, tí mo sì gbé e sábẹ́ awò asọǹkan-di-ńlá, mo rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè tètè parẹ́ ni ó wà lórí rẹ̀, tí a fi ohun èlò mímú bérébéré gbẹ́ sí ara fàdákà náà. . . . Lẹ́tà Hébérù mẹ́rin ti ìkọ̀wé èdè Hébérù ìgbàanì ni a fi kọ Orúkọ Àtọ̀runwá náà tí ó fara hàn kedere lára àkọlé náà, yod-he-waw-he.” Nínú ìtẹ̀jáde kan lẹ́yìn náà, Barkay fi kún un pé: “Sí ìyàlẹ́nu wa, wàláà onífàdákà méjèèjì náà ni a kọ àwọn ìbùkún sí, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá Àdúrà Àlùfáà inú Bíbélì mu.” (Númérì 6:24-26) Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a óò rí orúkọ Jèhófà lára àkọlé tí a ṣàwárí ní Jerúsálẹ́mù.
Báwo ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ṣe mọ ìgbà tí a kọ àwọn àkájọ wọ̀nyí? Ní pàtàkì, nípa àyíká tí a ti ṣàwárí wọn ní ti ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn ni. A rí àwọn ohun àfamọ̀ṣe tí ó lé ní 300 níbi ìkẹ́rùsí náà, tí ń tọ́ka sí ọ̀rúndún keje àti ìkẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa. Àkájọ náà, nígbà tí a fi wé àwọn àkọlé mìíràn tí ó ní àkókò, tọ́ka sí àkókò kan náà. A pàtẹ àwọn àkájọ náà sí Ilé Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé ti Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù.
Ìparun Jerúsálẹ́mù ní Ọdún 607 Ṣááju Sànmánì Tiwa
Bíbélì sọ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, nínú Àwọn Ọba Kejì orí 25, Kíróníkà Kejì orí 36, àti Jeremáyà orí 39, ní ríròyìn pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun Nebukadinésárì dáná sun ìlú ńlá náà. Ìwalẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ha ti jẹ́rìí sí àkọsílẹ̀ ìtàn yí bí? Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Yigal Shiloh ṣe sọ ọ́, “ẹ̀rí tí Bíbélì fi hàn ní ti [bí àwọn ará Bábílónì ṣe pa á run] . . . ni ẹ̀rí ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn tí ó ṣe kedere tì lẹ́yìn; àwọn ilé tí a pa run pátápátá, àti iná aṣèparun tí ó jó onírúurú apá tí a fi igi kọ́ lára àwọn ilé náà.” Ó sọ síwájú sí i pé: “A ti rí ipa ìparun yìí nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwalẹ̀ tí a ṣe ní Jerúsálẹ́mù.”
Àwọn olùṣèbẹ̀wò lè rí àwọn àlàpà ti ìparun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ohun tí ó lé ní 2,500 ọdún sẹ́yìn. Ilé Ìṣọ́ Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì, Ilé Jíjóná, àti Ilé Amọ̀ jẹ́ orúkọ àwọn ibi ìwalẹ̀pìtàn tí ó gbajúmọ̀ tí a pa mọ́, tí ó sì wà fún gbogbo ènìyàn láti wò. Àwọn awalẹ̀pìtàn náà, Jane M. Cahill àti David Tarler, ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ nínú ìwé, Ancient Jerusalem Revealed, pé: “Kì í ṣe kìkì ìtòjọ gègèrè àwọn àjókù àlàpà tí a wú jáde nínú àwọn ilé bíi Yàrá Jíjóná àti Ilé Amọ̀ ni ó fi bí àwọn ará Bábílónì ṣe pa Jerúsálẹ́mù run lọ́nà tí ó lékenkà hàn, ṣùgbọ́n àwọn àfọ́kù òkúta tí a wú jáde nínú ilẹ̀ àwọn ilé tí ó ti wó lulẹ̀, tí a rí tí ó bo gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìlà oòrùn pẹ̀lú fi í hàn. Àpèjúwe Bíbélì nípa ìparun ìlú ńlá náà . . . ti ẹ̀rí ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn lẹ́yìn.”
Nípa báyìí, ìwalẹ̀ ti ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn tí a ti ń ṣe láti ọdún 25 sẹ́yìn jẹ́rìí sí bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìrísí Jerúsálẹ́mù láti ọjọ́ Dáfídì títí di ìgbà ti a pa á run ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, Jerúsálẹ́mù ti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa ńkọ́?
Jerúsálẹ́mù ní Ọjọ́ Jésù
Ìwalẹ̀, Bíbélì, òpìtàn Júù ọ̀rúndún kìíní, Josephus, àti àwọn orísun mìíràn ran àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lọ́wọ́ láti rí bí Jerúsálẹ́mù ṣe rí gan-an ní ọjọ́ Jésù, ṣáájú kí àwọn ará Róòmù tó pa á run ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. A máa ń tún àwòrán kan tí ó jọ ọ́, tí a pàtẹ rẹ̀ sí ẹ̀yìn hòtẹ́ẹ̀lì ńlá kan ní Jerúsálẹ́mù yà déédéé, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwalẹ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe bá ṣí payá. Òkè Tẹ́ńpìlì, tí Hẹ́rọ́dù ti mú gbòòrò sí i ní ìlọ́po méjì ju ti ìgbà Sólómọ́nì lọ, ni apá pàtàkì ìlú ńlá náà. Ohun ni pèpéle àtọwọ́dá tí ó tóbi jù lọ ní ayé ìgbàanì, ó jẹ́ nǹkan bí 480 mítà àti 280 mítà níbùú lóòró. Àwọn òkúta ìkọ́lé kan wọ̀n tó 50 tọ́ọ̀nù, ọ̀kan tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 400 tọ́ọ̀nù “kò sì sí ẹlẹgbẹ́ wọn ní títóbi ní ayé ìgbàanì,” gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ.
Abájọ tí ẹnu fi ya àwọn ènìyàn kan nígbà tí wọ́n gbọ́ tí Jésù sọ pé: “Ẹ wó tẹ́ńpìlì yí lulẹ̀, ní ọjọ́ mẹ́ta èmi yóò sì gbé e dìde dájúdájú.” Wọ́n rò pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì gàgàrà náà, ṣùgbọ́n “tẹ́ńpìlì ara rẹ̀” ni ó ní lọ́kàn. Nítorí náà, wọ́n wí pé: “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹ́ńpìlì yí, ìwọ yóò ha sì gbé e dìde ní ọjọ́ mẹ́ta?” (Jòhánù 2:19-21) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìwalẹ̀ àyíká Òkè Tẹ́ńpìlì náà, àwọn olùṣèbẹ̀wò lè rí àwọn apá ògiri àti iṣẹ́ ọnà míràn tí ó ti wà láti ìgbà Jésù, wọ́n sì lè rin orí àtẹ̀gùn tí ó ṣeé ṣe kí òun pàápàá ti rìn lọ sí ẹnubodè ìhà gúúsù tẹ́ńpìlì náà.
Ibi ìwalẹ̀ méjì láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú pa dà bọ̀ sípò, tí a mọ̀ sí Ilé Jíjóná àti Àdúgbò Hẹ́rọ́dù, wà nítòsí ìhà ìwọ̀ oòrùn ògiri Òkè Tẹ́ńpìlì, ní Àdúgbò Àwọn Júù ní Ìlú Ńlá Àtijọ́. Lẹ́yìn ṣíṣàwárí Ilé Jíjóná náà, awalẹ̀pìtàn náà, Nahman Avigad, kọ̀wé pé: “Ó ti wá ṣe kedere nísinsìnyí pé àwọn ará Róòmù ní 70 ọdún Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa ni ó dáná sun ilé yìí, nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù. Nígbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ìwalẹ̀ ní ìlú ńlá náà, ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro, tí ó sì ṣe kedere nípa dídáná sun ìlú ńlá náà ti wá sí ojú táyé.”—Wo àwọn fọ́tò tí ó wà ní ojú ìwé 12.
Díẹ̀ lára àwọn àwárí wọ̀nyí mú kí díẹ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbésí ayé Jésù túbọ̀ ṣe kedere. Àwọn ilé náà wà ní Ìlú Ńlá Apá Òkè, níbi tí àwọn ọlọ́rọ̀ Jerúsálẹ́mù ń gbé, títí kan àwọn àlùfáà àgbà. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ilé ìwẹ̀ aláàtò ìsìn ni a rí nínú ilé náà. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ilé ìwẹ̀ jẹ́rìí sí i pé àwọn olùgbé Ìlú Ńlá Apá Òkè náà kò fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú òfin ìjẹ́mímọ́ aláàtò ìsìn ní àkókò Tẹ́ńpìlì Kejì. (A kọ àwọn òfin wọ̀nyí sínú Mishnah, tí ó ya orí mẹ́wàá sọ́tọ̀ fún kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa mikveh.)” Ìsọfúnni yìí ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sí àwọn Farisí àti akọ̀wé lórí ààtò ìsìn yí.—Mátíù 15:1-20; Máàkù 7:1-15.
A tún ti rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun èlò tí a fi òkúta ṣe ní Jerúsálẹ́mù. Nahman Avigad sọ pé: “Nígbà náà, èé ṣe tí wọ́n fi fara hàn lójijì àti ní iye púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú agbo ilé àwọn ará Jerúsálẹ́mù? Ìdáhùn rẹ̀ wà nínú halakhah, òfin ìjẹ́mímọ́, ti àwọn Júù. Ìwé Mishnah sọ fún wa pé àwọn ohun èlò tí a fi òkúta ṣe wà lára àwọn ohun wọnnì tí a kò kà sí àìmọ́ . . . A kò ka òkúta sí ohun tí a lè sọ di aláìmọ́ ní ti ààtò ìsìn.” A sọ pé èyí ṣàlàyé ìdí tí a fi pọn omi tí Jésù sọ di wáìní pa mọ́ sínú ohun èlò òkúta dípò ohun èlò amọ̀.—Léfítíkù 11:33; Jòhánù 2:6.
Ìbẹ̀wò sí ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Ísírẹ́lì yóò fi àpótí ìkégungun-òkú-sí méjì tí ó ṣàjèjì hàn. Ìwé Biblical Archaeology Review ṣàlàyé pé: “A lo àwọn àpótí ìkégungun-òkú-sí ní pàtàkì jù ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí àwọn ará Róòmù tó pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. . . . A óò gbé òkú sínú ihò kan tí a gbẹ́ sára ògiri ihò ìsìnkú; lẹ́yìn ti ara rẹ̀ bá ti jẹrà, a óò gbá egungun rẹ̀ jọ, a óò sì kó o sínú àpótí ìkégungun-òkú-sí—ó sábà máa ń jẹ́ àpótí kan tí a fi ṣẹ́ṣẹ́ funfun ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.” A rí àwọn méjèèjì tí a pàtẹ náà ní inú ihò ìsìnkú kan ní November 1990. Awalẹ̀pìtàn náà, Zvi Greenhut, ròyìn pé: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ ọ̀rọ̀ náà . . . ‘Káyáfà’ tí a kọ sórí àwọn àpótí ìkégungun-òkú-sí méjì náà fara hàn níhìn-ín nínú àyíká ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ orúkọ ìdílé Àlùfáà Àgbà Káyáfà, tí a mẹ́nu kàn . . . nínú Májẹ̀mú Tuntun . . . Nínú ilé rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní a ti fi Jésù lé alákòóso ẹkùn náà lábẹ́ ìjọba Róòmù, Pọ́ńtíù Pílátù lọ́wọ́.” Àpótí ìkégungun-òkú-sí kan ní egungun ọkùnrin kan tí ó tó nǹkan bí 60 ọdún nínú. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ méfò pé egungun Káyáfà gan-an ni. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tọ́ka sí àwárí náà bí èyí tí ó ti wà láti àkókò Jésù: “Hẹ́rọ́dù Ágírípà (ọdún 37 sí 44 Sànmánì Tiwa) ni ó rọ owó ṣílè tí a rí nínú ọ̀kan nínú àpótí ìkégungun-òkú-sí náà. Àpótí ìkégungun-òkú-sí méjì ti Káyáfà náà ti lè wà láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún náà.”
William G. Dever, ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn Itòsí Ìwọ̀ Oòrùn ní Yunifásítì ti Arizona, sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé: “Kì í ṣe àsọdùn rárá láti sọ pé a ti kọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa ìtàn ìwalẹ̀pìtàn ibi pàtàkì yìí ní ọdún 15 tí ó ti kọjá ju àpapọ̀ èyí tí a kọ́ ní 150 ọdún tí ó ṣáájú lọ.” Dájúdájú, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìwalẹ̀pìtàn ní Jerúsálẹ́mù ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ ti gbé àwárí tí ó mú ìtàn Bíbélì túbọ̀ ṣe kedere jáde.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Ẹ̀dà àmújáde Ìlú Ńlá Jerúsálẹ́mù ní àkókò Tẹ́ńpìlì Kejì – ó wà ní àgbègbè Hòtẹ́ẹ̀lì Holyland, Jerúsálẹ́mù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Lókè: Apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn Òkè Tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù
Ọwọ́ ọ̀tún: Gbígba ọ̀nà omi Hesekáyà kọjá