Tẹ́tíọ́sì—Olóòótọ́ Akọ̀wé Pọ́ọ̀lù
TẸ́TÍỌ́SÌ dojú kọ ìpèníjà kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fẹ́ lò ó gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé rẹ̀, nígbà tí ó ń kọ lẹ́tà gígùn jàn-ànràn jan-anran kan sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Róòmù. Iṣẹ́ aláápọn ni èyí jẹ́.
Èé ṣe tí ó fi gba aápọn tó bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ akọ̀wé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa? Báwo ni a ṣe ṣe irú iṣẹ́ yẹn? Àwọn ohun èlò ìkọ̀wé wo ni a lò?
Àwọn Akọ̀wé Nígbà Ìṣẹ̀ǹbáyé
Láwùjọ àwọn Gíríìkì àti àwọn ará Róòmù ìgbàanì, onírúurú àwọn akọ̀wé ní ń bẹ. Àwọn kan ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìjọba—àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn gíwá. Àwọn akọ̀wé gbogbogbòò tún ń bẹ, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún àwọn aráàlú ní ojú ọjà. Àwọn ọlọ́rọ̀ máa ń gba akọ̀wé (tí wọ́n sábà máa ń jẹ́ ẹrú) fún ara wọn. Bákan náà pẹ̀lú, àwọn ọ̀rẹ́ kan máa ń fínnú fíndọ̀ bá àwọn ẹlòmíràn kọ lẹ́tà, tìdùnnútìdùnnú. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ E. Randolph Richards ti sọ, òye iṣẹ́ àwọn akọ̀wé tí kò níwèé àṣẹ wọ̀nyí “lè bẹ̀rẹ̀ láti orí níní ìmọ̀ díẹ̀ nípa èdè náà àti bí a ṣe ń kọ̀wé sílẹ̀ tàbí kí ó jẹ́ ọ̀kan nínú méjèèjì, dé òrí jíjáfáfá lọ́nà gíga jù lọ ní ti àtilè yára kọ lẹ́tà tí ó péye, tí ó gún régé, tí ó sì dùn ún gbọ́ sétí.”
Àwọn wo ni yóò lo akọ̀wé? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn tí kò mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. Ọ̀pọ̀ ìwé àdéhùn àti ìwé ìdókòwò ìgbàanì ni a mú wá sí ìparí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí akọ̀wé náà fi jẹ́wọ́ pé òun kọ ìwé náà nítorí pé ẹni tí ó gbé iṣẹ́ náà fún òun kò mọ̀wèé kọ. A ṣàkàwé ìdí kejì fún gbígba akọ̀wé nínú lẹ́tà ìgbàanì kan láti Tíbésì, Íjíbítì. Ẹnì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Asklepiades ni a bá kọ ọ́, ìparí lẹ́tà náà kà pé: “Eumelus, ọmọkùnrin Herma, ni ó bá a kọ ọ́ . . . nítorí tí kò lè yára kọ̀wé.”
Síbẹ̀, kò jọ bíi pé mímọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ni kókó abájọ tí ń pinnu lílo akọ̀wé. Gẹ́gẹ́ bí alálàyé Bíbélì náà, John L. McKenzie, ti sọ, “ó ṣeé ṣe kí ó má tilẹ̀ jẹ́ àníyàn nípa ṣíṣeékà, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ àníyàn nípa ìkọ̀wé tí ó gún régé, tàbí ó kéré tán kí ó jẹ́ àníyàn nípa ìkọ̀wé rekete” ni ó sún àwọn ènìyàn láti yíjú sí àwọn akọ̀wé. Àní fún àwọn ọ̀mọ̀wé pàápàá, iṣẹ́ tí ń kó àárẹ̀ báni ni ìwé kíkọ jẹ́, ní pàtàkì tí ó bá jẹ́ ìwé tí ó gùn jàn-ànràn jan-anran, tí ó sì ní àlàyé rẹpẹtẹ ni a fẹ́ kọ. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ J. A. Eschlimann sọ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá lágbára àtigba akọ̀wé “ń fi tayọ̀tayọ̀ yẹra fún òpò yí, ní fífi í síkàáwọ́ àwọn ẹrú, àwọn akọ̀wé amọṣẹ́dunjú.” Ní àfikún sí i, nígbà tí a bá ronú lórí ohun èlò tí a ń lò àti ipò tí ó rọ̀ mọ́ iṣẹ́ náà, ó rọrùn láti lóye ìdí tí àwọn ènìyàn kò fi fẹ́ láti máa fúnra wọn kọ lẹ́tà ara wọn.
Òrépèté ni ohun èlò ìkọ̀wé tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ni ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. A ń rí àwọn ẹ̀là tẹ́ẹ́rẹ́ láti ara irúgbìn yí nípa líla àwọn ìtì rẹ̀ sí méjì-méjì gbẹrẹgẹdẹ. A óò tẹ́ àwọn ẹ̀là náà sílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. A óò wá fi àwọn ẹ̀là míràn dábùú èyí tí a kọ́kọ́ tẹ́ sílẹ̀. A óò gbé ohun tí ó lọ́ọ̀rìn lé wọn mọ́lẹ̀ kí wọn baà lè lẹ̀ mọ́ra, ní pípèsè abala “bébà” kan.
Kò rọrùn láti kọ nǹkan sórí rẹ̀. Kò jọ̀lọ̀, ó sì kún fún fọ́nrán. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Angelo Penna ti sọ, “àwọn fọ́nrán múlọ́múlọ́ tí òrépèté ní dá kún mímú kí tàdáwà máa ṣàn sílẹ̀, pàápàá ní àwọn ibi tí ó ní ihò fóófòòfó láàárín àwọn ẹ̀là tẹ́ẹ́rẹ́ náà.” Akọ̀wé náà lè jókòó sí ilẹ̀yílẹ̀, kí ó sì ká ẹsẹ̀ lẹ́sẹ̀, kí ó fi ọwọ́ kan di abala òrépèté tí ó fi sórí pátákó pẹlẹbẹ mú. Bí ó bá jẹ́ ọ̀gbẹ̀rì nínú iṣẹ́ yìí tàbí bí ohun èlò náà bá jẹ́ gbàrọgùdù, kálàmù rẹ̀, tàbí gègé esùsú rẹ̀, lè máa há sínú òrépèté náà, abala náà lè ya, tàbí kí ohun tí ó kọ má ṣeé kà.
Màjàlà àti oje igi ni a fi ṣe tàdáwà náà. A máa ń gé e tà ni, ó nílò kí a fi omi pò ó nínú ìgò tàdáwà kí a tó lè lò ó láti fi kọ̀wé. Lára àwọn ohun èlò míràn tí ó ṣeé ṣe kí akọ̀wé bíi Tẹ́tíọ́sì ní lọ́wọ́ ni, ọ̀bẹ tí yóò fi máa gbẹ́ gègé esùsú àti kàn-ìn-kàn-ìn tí ó rẹ tí yóò fi máa pa àṣìṣe tí ó ṣe rẹ́. Ó gbọ́dọ̀ fi ìṣọ́ra kọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀. Nítorí náà, ìkọ̀wé máa ń bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, ó sì ń mú ìṣòro díẹ̀ lọ́wọ́.
‘Èmi, Tẹ́tíọ́sì, Kí Yín’
Ìkíni akọ̀wé Pọ́ọ̀lù, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Èmi, Tẹ́tíọ́sì, tí mo kọ lẹ́tà yí, kí yín nínú Olúwa,” wà lára àwọn ìkíni tí a fi mú lẹ́tà sí àwọn ará Róòmù wá sí òpin. (Róòmù 16:22) Èyí ni ìgbà kan ṣoṣo nínú àwọn ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ, tí a tọ́ka sí ọ̀kan lára àwọn akọ̀wé rẹ̀ lọ́nà ti ó ṣe kedere.
A kò mọ ohun púpọ̀ nípa Tẹ́tíọ́sì. Láti inú ìkíni rẹ̀ “nínú Olúwa,” a lè dé ìparí èrò pé òun jẹ́ Kristẹni olùṣòtítọ́. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ tí ó wà ní Kọ́ríńtì, ó sì ti lè mọ ọ̀pọ̀ Kristẹni tí wọ́n wà ní Róòmù. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bíbélì Giuseppe Barbaglio, sọ pé ẹrú tàbí ẹrú tí ó ti gbòmìnira ni Tẹ́tíọ́sì. Èé ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, nítorí pé “àwọn akọ̀wé ní gbogbogbòò wá láti inú ẹgbẹ́ yìí; lẹ́yìn náà, nítorí orúkọ èdè Látìn tí ó ń jẹ́ . . . wọ́pọ̀ gidigidi láàárín àwọn ẹrú àti àwọn tí ó ti gbòmìnira.” Barbaglio sọ pé: “Nítorí náà, kì í ṣe òǹkọ̀wé amọṣẹ́dunjú ‘tí ọ̀ràn kò kàn,’ ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù tí ó tipa báyìí ràn án lọ́wọ́ láti ṣàkójọ ìwé rẹ̀ tí ó gùn jù lọ, tí ó sì ṣe kedere jù lọ: iṣẹ́ kan tí ó ṣeyebíye, tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti lo àkókò yẹn fún ohun mìíràn, kí àárẹ̀ rẹ̀ sì mọ níwọ̀n.”
Iṣẹ́ Tẹ́tíọ́sì yí ṣeyebíye gidigidi. Bárúkù bá Jeremáyà ṣe irú iṣẹ́ kan náà, àní bí Sílífánù pàápàá ti ṣe fún Pétérù. (Jeremáyà 36:4; Pétérù Kíní 5:12) Ẹ wo irú àǹfààní ńláǹlà tí irú àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ ní!
Kíkọ̀wé sí Àwọn Ará Róòmù
A kọ lẹ́tà náà sí àwọn ará Róòmù nígbà tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ àlejò Gáyọ́sì, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ní Kọ́ríńtì. Ìyẹn jẹ́ ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Tiwa, nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì kẹta tí àpọ́sítélì náà ṣe. (Róòmù 16:23) Bí a tilẹ̀ mọ̀ dájú ṣáká pé Pọ́ọ̀lù lo Tẹ́tíọ́sì gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé rẹ̀ láti kọ lẹ́tà yí, kò dá wa lójú bí ó ṣe lò ó. Ọ̀nà yòó wù tí ó lò, iṣẹ́ náà kò lè jẹ́ èyí tí ó rọrùn. Ṣùgbọ́n èyí dá wa lójú pé: Gẹ́gẹ́ bí àwọn apá yòó kù nínú Bíbélì, “Ọlọ́run mí sí” lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Róòmù.—Tímótì Kejì 3:16, 17.
Nígbà tí a óò fi kọ lẹ́tà yí tán, Tẹ́tíọ́sì àti Pọ́ọ̀lù ti kọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀rọ̀, wọ́n sì ti lo ọ̀pọ̀ abala òrépèté. Lẹ́yìn tí a ti fi àtè lẹ̀ wọ́n mọ́ ara wọn ní eteetí, àwọn abala wọ̀nyí di àkájọ ìwé, tí ó lè tó nǹkan bíi mítà mẹ́ta sí mẹ́rin ní gígùn. A rọ́ra ká lẹ́tà náà róbótó, a sì fi èdìdì dì í. Lẹ́yìn náà, ó dà bíi pé Fébè, arábìnrin kan láti Kẹnkíríà, tí ó fẹ gbéra lọ sí Róòmù, ni Pọ́ọ̀lù fà á lé lọ́wọ́.—Róòmù 16:1, 2.
Láti ọ̀rúndún kìíní, ọ̀nà tí a gbà ń mú ohun èlò ìkọ̀wé jáde ti yí pa dà gidigidi. Ṣùgbọ́n jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, Ọlọ́run pa lẹ́tà náà tí a kọ sí àwọn Kristẹni ní Róòmù mọ́. Ẹ wo bí ó ti yẹ kí a mọrírì apá yìí nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà tó, tí a ti ọwọ́ akọ̀wé Pọ́ọ̀lù, Tẹ́tíọ́sì, tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ àti òṣìṣẹ́ aláápọn kọ!