ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 8/1 ojú ìwé 3-4
  • Ẹ̀rí Ọkàn Ṣé ẹrù ìnira ni tàbí ohun iyebíye?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀rí Ọkàn Ṣé ẹrù ìnira ni tàbí ohun iyebíye?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀rí Ọkàn—Ojú Ìwòye Bíbélì
  • Ǹjẹ́ o Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Dáadáa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ń sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 8/1 ojú ìwé 3-4

Ẹ̀rí Ọkàn Ṣé ẹrù ìnira ni tàbí ohun iyebíye?

‘Ẹ̀RÍ ọkàn mi ń dà mí láàmú!’ Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wa ní ń nírìírí ìrora ẹ̀rí ọkàn láti ìgbà dé ìgbà. Irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ láti orí àìbalẹ̀ ọkàn lásán títí dórí ìrora gógó. Ẹ̀rí ọkàn tí ìdààmú bá tilẹ̀ lè fa ìsoríkọ́ tàbí ìmọ̀lára ìkùnà pátápátá.

Bí a bá fojú yìí wò ó, nígbà náà, ẹ̀rí ọkàn kì í ha ń ṣe ẹrù ìnira bí? Àwọn kan lè rò pé bẹ́ẹ̀ ni ó jẹ́. Àwọn onírònú àtijọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, ka ẹ̀rí ọkàn sí agbára ìrònú tí a dá mọ́ni, tí a bíni mọ́. Ọ̀pọ̀ nímọ̀lára pé, ó jẹ́ ìtọ́sọ́nà ìwà híhù tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fi fúnni ní tààràtà. Nípa bẹ́ẹ̀, a ti pe ẹ̀rí ọkàn ní “ẹ̀rí wíwà Ọlọ́run nínú ènìyàn,” “àbùdá wa ìpilẹ̀ṣẹ,” àní “ohùn Ọlọ́run” pàápàá.

Ṣùgbọ́n, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó ti di ohun tí ó wọ́pọ̀ láti sọ pé, ẹ̀rí ọkàn jẹ́ agbára ìrònú tí a mú dàgbà—ìyọrísí agbára ìdarí àwọn òbí àti àwùjọ lórí ẹni. Fún àpẹẹrẹ, àwọn afìṣe mọ̀rònú kan jiyàn pé, ọmọ kan ń kọ́ láti yẹra fún ìwà tí kò dára kìkì nítorí ìbẹ̀rù pé a óò jẹ ẹ́ níyà, ní gbígbàgbọ́ pé ohun tí a pè ní ẹ̀rí ọkàn wulẹ̀ jẹ́ sísọ ìlànà àti ìgbàgbọ́ àwọn òbí wa di tiwa. Àwọn mìíràn tọ́ka sí ipa tí àwùjọ ní gbogbogbòò ń kó nínú títàtaré àwọn ìlànà àti ọ̀pá ìdiwọ̀n. Àwọn kan ka ìrora gógó ẹ̀rí ọkàn sí kìkì ìforígbárí láàárín ohun tí a óò fẹ́ láti ṣe àti ohun tí àwùjọ afojú-ẹni-gbolẹ̀ ń fi dandan ní kí a ṣe!

Láìka àwọn àbá èrò orí wọ̀nyí sí, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ènìyàn ti ko àwọn òbí, ìdílé, àti odindi àwùjọ lójú nítorí ẹ̀rí ọkàn wọ́n sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn kan tilẹ̀ ti múra láti fi ẹ̀mí wọn rúbọ nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn! Láìka ìyàtọ̀ ńlá tí ń bẹ láàárín àwùjọ aráyé sí, àwọn ìwà bí ìṣìkàpànìyàn, olè jíjà, panṣágà, irọ́ pípa, àti bíbá ìbátan ẹni lòpọ̀, ni ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kárí ayé ni a ti kà wọ́n sí ìwà àìtọ́. Èyí kò ha fi ẹ̀rí hàn pé ẹ̀rí ọkàn jẹ́ ohun tí a dá mọ́ni, ohun tí a bíni mọ́?

Ẹ̀rí Ọkàn—Ojú Ìwòye Bíbélì

Jèhófà Ọlọ́run gan-an ni aláṣẹ lórí kókó yìí. Ó ṣe tán, “òun [Ọlọ́run] ni ó dá wa, tirẹ̀ ni àwa.” (Orin Dáfídì 100:3) Ó lóye ẹ̀dá wa látòkè délẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, ṣàlàyé pé, a dá ènìyàn ní “àwòrán” Ọlọ́run. (Gẹ́nẹ́sísì 1:26) A dá ènìyàn pẹ̀lú ìmọ̀lára ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́; láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ẹ̀rí ọkàn ti jẹ́ ohun tí a dá mọ́ ènìyàn.—Fi wé Gẹ́nẹ́sísì 2:16, 17.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí sí èyí nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Róòmù, ní kíkọ̀wé pé: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin [Ọlọ́run] bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, à ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí à ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.” (Róòmù 2:14, 15) Kíyè sí i pé, ọ̀pọ̀ tí a kò tọ́ dàgbà lábẹ́ Òfin àtọ̀runwá náà, tí a fún àwọn Júù, ṣì tẹ̀lé díẹ̀ lára ìlànà òfin Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí agbára ìdarí àwùjọ, bí kò ṣe “lọ́nà ti ẹ̀dá”!

Nítorí náà, kàkà tí yóò fi jẹ́ ẹrù ìnira, ẹ̀rí ọkàn jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run, ohun iyebíye kan. A gbà pé ó lè fa ìrora ọkàn fún wa. Ṣùgbọ́n, bí a bá ṣègbọràn sí i lọ́nà tí ó yẹ, ó lè mú kí a ní ìtẹ́lọ́rùn ńlá àti ìfọ̀kànbalẹ̀. Ó lè tọ́ wa sọ́nà, dáàbò bò wá, kí ó sì sún wa ṣiṣẹ́. Ìwé The Interpreter’s Bible ṣàlàyé pé: “Ẹnì kan lè pa ìlera ọpọlọ àti ti ìmọ̀lára mọ́ kìkì bí ẹnì náà bá ń gbìyànjú láti dí ọ̀gbun tí ó wà láàárín ohun tí ó ń ṣe àti ohun tí ó rò pé ó yẹ kí òun máa ṣe.” Ọ̀nà wo ni ẹnì kan lè gbà dí ọ̀gbun náà? Ó ha ṣeé ṣe láti tọ́, kí a sì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ bí? A óò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́