ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 8/15 ojú ìwé 2-4
  • A Gbà Wọ́n Là Nígbà Àjálù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Gbà Wọ́n Là Nígbà Àjálù
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àkókò Kánjúkánjú
  • Yan Ìyè!
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ète Ọlọrun Yoo Ní Imuṣẹ Laipẹ
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Ọlọrun Ni Ó Ha Ń Fà Á Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Yan Ìyè, Kí o Lè Máa Wà Láàyè Nìṣó”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 8/15 ojú ìwé 2-4

A Gbà Wọ́n Là Nígbà Àjálù

ILÉ ìtajà ńlá alájà márùn-ún tí ń bẹ ní Seoul, Korea, wó lójijì, ó sì sé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn mọ́nú! Àwọn òṣìṣẹ́ agbẹ̀mílà ṣiṣẹ́ bí aago láti lè gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ṣíṣeéṣe náà láti rí olùlà á já èyíkéyìí yọ jáde nínú òkìtì kọnkéré àti irin wọ́nganwọ̀ngan bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù.

Nígbà tí ó dà bí ẹni pé gbogbo ìrètí ti pin, ohun kan tí ó ṣeni ní kàyéfì ṣẹlẹ̀. Igbe fíntínfíntín tí ó jọ ti ẹnì kan tí ń joró dún lábẹ́ àlàpà náà. Kíá mọ́sá ni àwọn agbẹ̀mílà bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwàǹwára fi ọwọ́ wọn lásán gbẹ́lẹ̀ láti baà lè yọ ọmọbìnrin ẹni ọdún 19 kan jáde, ẹni tí a ti sin láàyè fún ọjọ́ 16 gbáko. Irin ẹ̀rọ agbéniròkè kan tí ó wó lulẹ̀ ni ó bò ó lórí, kò sì jẹ́ kí ẹrù kọnkéré já lé e lórí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo omi ara rẹ̀ ti gbẹ, tí ọgbẹ́ sì wà lára rẹ̀ yánnayànna, ó bọ́ lọ́wọ́ ikú!

Lónìí, agbára káká ni oṣù kan fi ń kọjá kí a tó gbọ́ ìròyìn nípa ìjábá kan, yálà kí ó jẹ́ ìsẹ̀lẹ̀, ìjì àjàyíká, ìbújáde òkè ayọnáyèéfín, ìjàǹbá, tàbí ìyàn. Ìtàn agbàfiyèsí nípa àwọn tí a gbẹ̀mí wọn là àti àwọn tí wọ́n là á já máa ń ru ìmọ̀lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n ń tẹ́tí sí ìròyìn sókè, ó sì máa ń fà wọ́n mọ́ra. Ṣùgbọ́n, ìkìlọ̀ àjálù kan tí ń bọ̀—ọ̀kan tí ó tóbi jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn—ni a kò kọbi ara sí ní gbogbogbòò. (Mátíù 24:21) Bíbélì ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bọ̀ yí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Sá wò ó, ibi yóò jáde láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, ìjì ńláǹlà yóò ru sókè láti àgbègbè ayé. Àwọn tí Olúwa pa yóò wà ní ọjọ́ náà láti ìpẹ̀kun kìíní ayé títí dé ìpẹ̀kun kejì ayé, a kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sin wọn, wọn óò di ààtàn sórí ilẹ̀.”—Jeremáyà 25:32, 33.

Ẹ wo irú ọ̀rọ̀ amúnitagìrì tí ìyẹn jẹ́! Ṣùgbọ́n láìdà bí àwọn ìjábá ti ìsẹ̀dá tàbí ìjàǹbá ọkọ̀, àjálù yí kò ní jẹ́ èyí tí ń pa gbogbo ènìyàn láìdá ẹnì kankan sí. Ní tòótọ́, lílà á já—lílà á já rẹ—ṣeé ṣe!

Àkókò Kánjúkánjú

Láti lóye òtítọ́ yìí dáradára, lákọ̀ọ́kọ́, ẹnì kan ní láti mọ ìdí tí àjálù kárí ayé yìí fi gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. Ní tòótọ́, òun ni ojútùú kan ṣoṣo tí ó wà sí ìṣòro aráyé. Àwọn ènìyàn díẹ̀ lónìí ni wọ́n nímọ̀lára àìséwu àti ààbò. Láìka gbogbo ìsapá sáyẹ́ǹsì sí, àwọn àrùn tí ń gbèèràn túbọ̀ ń run àwọn olùgbé ayé. Àwọn ogun tí gbọ́nmisi-omi-ò-tó láàárín àwọn ìsìn, ẹ̀yà ìran, àti ìṣèlú ń fà ń gbẹ̀mi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀dá ènìyàn. Ìyàn ń fi kún òṣì àti ìyà tí ń jẹ àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Ìwà ìbàjẹ́ ti fọ́ ìpìlẹ̀ àwùjọ túútúú; àní a ti ba àwọn ọmọdé pàápàá jẹ́.

Lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí a kọ ní ohun tí ó lé ní 1,900 sẹ́yìn ṣàpèjúwe ipò wa. Ó sọ pé: “Ìwọ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò yóò kún fún ewu.”—Tímótì Kejì 3:1, The New Testament in Modern English, láti ọwọ́ J. B. Phillips; fi wé Mátíù 24:3-22.

Ìwọ ha rò pé ó bọ́gbọ́n mu pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ yóò jẹ́ aláìbìkítà sí àwọn ìnira wa bí? Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run tìkara rẹ̀ tí ó mọ ayé, tí ó sì ṣe é, . . . kò dá a lásán, ó mọ ọ́n kí a lè gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Bẹ́ẹ̀ ni, kàkà tí ì bá fi yọ̀ǹda kí a pa pílánẹ́ẹ̀tì rèǹtè rente yìí run, kí gbogbo àwọn olùgbé rẹ̀ sì wá sí òpin, Ọlọ́run yóò dá sí i. Ìbéèrè náà ni pé, Báwo ni òun yóò ṣe ṣe é?

Yan Ìyè!

Bíbélì dáhùn nínú Orin Dáfídì 92:7 pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú bíi koríko, àti ìgbà tí gbogbo àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bá ń gbèèrú: kí wọn kí ó lè run láéláé ni.” Ojútùú tí Ọlọ́run ní sí àwọn ìṣòro ilẹ̀ ayé ni láti mú ìwà ibi kúrò pátápátá. Ó dùn mọ́ni pé, èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo ènìyàn ni yóò mú kúrò pátápátá. Orin Dáfídì 37:34 mú un dá wa lójú pé: “Dúró de Olúwa, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ayé: nígbà tí a bá ké àwọn ènìyàn búburú kúrò, ìwọ óò rí i.”

Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi hàn pé àǹfààní wà pé a óò gbani là nígbà àjálù títóbi jù lọ tí yóò dé sórí aráyé. Ọlọ́run ti fún wa ní yíyàn kan. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè fi gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyànjú nígbà tí wọ́n ń múra láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí bá àwa náà mu lónìí pé: “Èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú ọmọ rẹ.” (Diutarónómì 30:19) Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnì kan ṣe lè “yan ìyè,” kí ó sì rí ìgbàlà? Kí ni ìgbàlà tòótọ́ túmọ̀ sí?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ìbúgbàù: Copyright © Gene Blevins/Los Angeles Daily News

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Yunhap News Agency/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́