Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láti Wẹni Mọ́
A RÒYÌN pé èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ajoògùnyó ni ó máa ń pa dà sídìí àṣà wọn lẹ́yìn tí a bá ti tú wọn sílẹ̀ ní ilé ìgbàtọ́jú. Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣe ohun tí àwọn ilé ìgbàtọ́jú sábà máa ń kùnà láti ṣe. (Hébérù 4:12) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá ìjoògùnyó, kí wọ́n sì fi ìmọ̀ràn yí sílò: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.”—Kọ́ríńtì Kejì 7:1.
Ìrírí kan láti Myanmar fi èyí hàn. Ọkùnrin kan tí ó ti bá àṣà ìjoògùnyó jìjàkadì fún ọ̀pọ̀ ọdún ròyìn pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í joògùn yó láti ìgbà tí mo ti wà ní ọ̀dọ́langba. Mo gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti ṣẹ́pá rẹ̀, ṣùgbọ́n n kò lè ṣe é. Láti lè máa bá àṣà ìjoògùnyó mi lọ, mo di ẹni tí ń jalè. Nítorí èyí, ní 1988, a rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún kan.
“Lẹ́yìn tí wọ́n tú mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, mo tún pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí mo fi pa dà sínú àṣà ìjoògùnyó mi. Ipa ọ̀nà ìfọwọ́-ara-ẹni-run-ara-ẹni yìí sún àwọn mẹ́ńbà ìdílé mi láti pa mí tì pátápátá. Ní àfikún sí i, ìwà ọlọ̀tẹ̀ mi sún ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àdúgbò mi láti máa bẹ̀rù mi, àwọn pẹ̀lú sì bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fún mi.
“Lẹ́yìn náà, ní ọjọ́ kan, ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ ṣẹlẹ̀—ojú pọ́n mi fún jíjoògùnyó. A rán mi pa dà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nísinsìnyí fún ọdún mẹ́ta. Bí ìgbésí ayé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tilẹ̀ le koko, mo là á já lọ́nà kan ṣáá.
“Lẹ́yìn tí mo pa dà délé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ìdílé mi fún àwọn àṣìṣe mi àtijọ́. Wọ́n tẹ́wọ́ gbà mí pa dà tọwọ́tẹsẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ọ̀rẹ́ sún mi sí pípadà sínú àwọn ọ̀nà mi àtijọ́.
“Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìyá bàbá mi dábàá fún àlùfáà àdúgbò pé kí n máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àlùfáà náà fohùn ṣọ̀kan. Ṣùgbọ́n, kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ, àbúrò bàbá mi, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ pé bí n bá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tòótọ́, pé kí n kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí.
“Mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n sì fi mi mọ ọkùnrin kan tí ó gbà láti máa bá mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ tí ó wà nípàdé kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà, wọ́n sì gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀.
“Lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, ìfẹ́ ọkàn láti sún mọ́ Ọlọ́run pẹ́kípẹ́kí rọ́pò ìfàsí ọkàn láti joògùnyó. Ní ọdún kan lẹ́yìn náà, mo ti tẹ̀ síwájú dórí yíya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run, mo sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.
“Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, bí mo ti ń lọ láti ilé dé ilé, mo pàdé ọ̀kan lára àwọn ajoògùnyó ẹlẹgbẹ́ mi àtijọ́. Ó ṣòro fún un láti lóye ìyípadà ńlá tí mo ti ṣe nínú ìgbésí ayé mi. Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjẹ́rìí, ó sí ṣeé ṣe fún mi láti bá a sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Ìjọba.
“Mo ti rí ète àti ìtumọ̀ tòótọ́ nínú ìgbésí ayé mi nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ìrànlọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn Ọlọ́run láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún mi nísinsìnyí láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti já ara wọn gbà lọ́wọ́ àṣà ìjoògùnyó tí ń da ìgbésí ayé ẹni rú.”