ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 9/1 ojú ìwé 25-28
  • Mo Dúpẹ́ Mo Tọ́pẹ́ Dá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Dúpẹ́ Mo Tọ́pẹ́ Dá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Dúpẹ́ fún Àwọn Àpẹẹrẹ Rere
  • Ìdúró Mi fún Òtítọ́
  • Mo Dúpẹ́ fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Mi
  • Jíjèrè Alábàákẹ́gbẹ́ Olùṣòtítọ́
  • Mo Dúpẹ́ fún Ìgbésí Ayé Wa Tí A Lò Pa Pọ̀
  • Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Gbogbo Ìgbà Ni Mò Ń Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ní Ẹni 80 Ọdún Iṣẹ́ Àyànfúnni Mi Yí Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 9/1 ojú ìwé 25-28

Mo Dúpẹ́ Mo Tọ́pẹ́ Dá

GẸ́GẸ́ BÍ JOHN WYNN TI SỌ Ọ́

Ẹ wo bí mo ṣe kọ lílọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ tó! N óò díbọ́n bí ẹni tí inú ń run tàbí tí orí ń fọ́—ohunkóhun láti lè yẹra fún lílọ sí ìpàdé. Ṣùgbọ́n àìgbagbẹ̀rẹ́ màmá mi máa ń mú kí irú òjòjò bẹ́ẹ̀ fò lọ lójú ẹsẹ̀ nígbà gbogbo, tí n óò sì bá a rìnrìn kìlómítà mẹ́ta lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ní títẹ́tí sí bí ó ṣe ń jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ẹnì kan tí ó dàgbà jù ú tí a jọ máa ń lọ.

ÈYÍ kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan: Lọ́nà onífẹ̀ẹ́, kò yẹ kí àwọn òbí fọwọ́ dẹgbẹrẹ mú ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run rárá. (Òwe 29:15, 17) Kò yẹ kí wọ́n gbàgbé àṣẹ àtọ̀runwá náà láé pé “kí a má máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì.” (Hébérù 10:25) Bí mo ti ronú pa dà wo ìgbésí ayé mi, ẹ wo bí mo ti kún fún ọpẹ́ tó pé ìyá mi mú kí n ṣe ohun tí ó dára jù lọ fún ara mi!

Mo Dúpẹ́ fún Àwọn Àpẹẹrẹ Rere

Bí bàbá mi tilẹ̀ jẹ́ aláìgbàgbọ́, ó fàyè gba ìgbàgbọ́ Màmá nígbà tí ó di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, orúkọ tí a fi mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ní 1913, màmá mi lọ gbọ́ àsọyé náà, “Lẹ́yìn Isà Òkú,” tí Charles T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society, sọ. Ṣùgbọ́n, ó pẹ́ kí ó tó dé ibẹ̀, kò sì sí àga kankan tí ó ṣófo. Nítorí náà, wọ́n ké sí i láti wá jókòó pẹ̀lú àwọn apẹ́lẹ́yìn míràn, nítòsí pèpéle, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Pásítọ̀ Russell. Ọ̀rọ̀ yẹn wú u lórí púpọ̀. A tẹ̀ ẹ́ jáde ní ọjọ́ kejì nínú ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò, ó sì tọ́jú ẹ̀dà kan pa mọ́, tí ó máa ń kà ní gbogbo ìgbà.

Lẹ́yìn ìpàdé, Màmá fún wọn ní bébà tí ó kọ orúkọ rẹ̀ sí, kò sì pẹ́ tí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan fi kàn sí i. Bí àkókò ti ń lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé àṣàrò kúkúrú tí a gbé karí Bíbélì láti ilé dé ilé ní ìlú ìbílẹ̀ wa ní Gloucester, England. Láti ìgbà tí èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi méjèèjì ti wà ní kékeré ni a ti ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú Màmá.

Nígbà tí Harry Francis, Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítara kan, ṣí wá sí Gloucester, Màmá tẹ́wọ́ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, ó fi ìfẹ́ hàn nínú mi, ìṣírí rẹ̀ sì jẹ́ ìdí pàtàkì ti mo fi di aṣáájú ọ̀nà, orúkọ tí a ń pe àwọn alákòókò kíkún. Àpẹẹrẹ Arákùnrin Francis kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan: Ó yẹ kí àwọn tí ó dàgbà máa wá àyè láti fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí.

Nígbà tí ìyá mi di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ẹlòmíràn ní Gloucester ṣe ohun kan náà pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n, díẹ̀ lára àwọn alàgbà nínú ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í ka ara wọn sí pàtàkì ju bí ó ti yẹ lọ, àwọn mẹ́ńbà kíláàsì—orúkọ ti a fi ń pe ìjọ nígbà náà lọ́hùn-ún—sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ènìyàn. Nínú ìpàdé kan, àwọn kan ń fọwọ́ tọ́ Màmá, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kí ó nawọ́ sókè fún àwọn alàgbà kan. Ṣùgbọ́n Màmá mọ̀ pé wọn kò fi àpẹẹrẹ tí ó bójú mu lélẹ̀, ó sì kọ̀ láti jẹ́ kí a fipá mú òun. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ní òpin àwọn ọdún 1920, ọ̀pọ̀ ṣubú, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà òtítọ́ mọ́. (Pétérù Kejì 2:2) Síbẹ̀, Màmá kò yà bàrá láé kúrò nínú fífi ìdúróṣinṣin ti ètò àjọ náà lẹ́yìn, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún mi.

Ìdúró Mi fún Òtítọ́

Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní June 1939, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 18, mo ṣe ìrìbọmi nínú Odò Severn. A yàn mí ṣe ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ẹ̀rọ ní ọdún kan náà. Ní ayé ọjọ́un, a máa ń lo ẹ̀rọ agbóhùnjáde ńlá tí máa ń gbé ìhìn iṣẹ́ “Ìsìn Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó” jáde ní àwọn ibi tí èrò wà. Kókó ìtẹnumọ́ nígbà náà lọ́hùn-ún jẹ́ títú àgàbàgebè àti ẹ̀kọ́ èké Kirisẹ́ńdọ̀mù fó.

Nígbà kan, mo wà níwájú èrò tí ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ rìn, mo gbé ọ̀págun kan tí àkọlé náà, “Ìsìn Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó” wà lójú kan rẹ̀, tí “Sin Ọlọ́run àti Kristi Ọba” sì wà lójú kejì. Ẹṣin kékeré kan, tí a lẹ ìsọfúnni gàdàgbà gàdàgbà mọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì, tí ń polongo àsọyé fún gbogbo ènìyàn, ń rìn bọ̀ lẹ́yìn. Ẹ wo bí ìtọ́wọ̀ọ́rìn náà yóò ti wúni lórí tó láàárín ìlú àwọn ẹlẹ́sìn ní Gloucester!

Láìka ìṣòro ìṣúnná owó tí a ní nílé sí, Màmá fún mi níṣìírí láti di aṣáájú ọ̀nà. Nítorí náà, ní September 1939, ní ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì, mo gúnlẹ̀ sí ibi àkọ́kọ́ tí a yàn fún mi gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní Leamington, ìlú kékeré kan ní Warwickshire. Ìlú náà jẹ́ ibi tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì mélòó kan tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì fi ṣelé.

A lo ohun èlò agbóhùnjáde kan tí kò wúwo nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé, ní gbígbé ohùn àsọyé Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà yẹn, sáfẹ́fẹ́. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀rọ agbóhùnjáde wa (tí a lè lo fún àwọn àwùjọ tí ó pọ̀ sí i) wúwo gidigidi, a sì máa ń fi kẹ̀kẹ́ ọmọdé tì í kiri. Nígbà míràn, àwọn àlùfáà, tí inú bí nítorí ìhìn iṣẹ́ tí ń tú ìsìn èké fó, máa ń lé wa kúrò ní sàkání ilé wọn. Ṣùgbọ́n a kò rẹ̀wẹ̀sì. Jèhófà bù kún iṣẹ́ wa, ìjọ tí ó ní Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ń bẹ ní Leamington lónìí.

Ní 1941, bí Ogun Àgbáyé Kejì ti ń jà ràn-ìn, mo ṣí lọ sí Wales, níbi tí mo ti ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìlú Haverfordwest, Carmarthen, àti Wrexham. Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, a yọ mí sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ológun, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kò lóye àìdásí tọ̀tún tòsì wa. Nítorí náà, wọ́n ka èmi àti ìkejì mi sí amí tàbí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́. Ní òru ọjọ́ kan, àwọn ọlọ́pàá yí ilé àgbérìn wa ká. Ìkejì mi, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ darí dé láti ibi iṣẹ́ wíwa èédú, yọ orí síta láti wo ẹni tí ó wà níbẹ̀. Èédú ti bo gbogbo ojú rẹ̀, lójú àwọn ọlọ́pàá náà, ó dà bí ẹni tí ó ń múra láti gbé sùnmọ̀mí lọ sí ibì kan. A ní láti ṣàlàyé ẹnu wa!

A bù kún wa ní jìngbìnnì nínú iṣẹ́ àyànfúnni wa. Nígbà kan, nígbà tí a wà ní Carmarthen, John Barr láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ní London (tí ó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso nísinsìnyí) ṣe ìbẹ̀wò oníṣìírí sọ́dọ̀ wa. Ní àkókò yẹn, akéde méjì péré ni ó wà ní Carmarthen; àwọn tí ó wà níbẹ̀ lónìí lé ní ọgọ́rùn-ún. Ìjọ mẹ́ta ni ó wà ní Wrexham ní lọ́ọ́lọ́ọ́, mo sì láǹfààní yíya Gbọ̀ngàn Ìjọba dáradára kan sí mímọ́ láìpẹ́ yìí ní Haverfordwest.—Kọ́ríńtì Kíní 3:6.

Mo Dúpẹ́ fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Mi

Nígbà tí a wà ní Swansea, Gúúsù Wales, a kò yọ ìkejì mi, Don Rendell, sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn ológun. A fi í sẹ́wọ̀n láìka pé ó ṣàlàyé pé ẹ̀rí ọkàn òun kò ní yọ̀ǹda fún òun láti lọ gbógun ti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ òun ní àwọn ilẹ̀ míràn. (Aísáyà 2:2-4; Jòhánù 13:34, 35) Láti fún un níṣìírí, àti láti jẹ́rìí fún àwọn aládùúgbò, mo gbé ẹ̀rọ agbóhùnjáde náà sí ìtòsí, mo sì gbé ohùn àwọn àsọyé Bíbélì sáfẹ́fẹ́.

Ṣùgbọ́n, àwọn obìnrin tí ń bẹ ládùúgbò kò nífẹ̀ẹ́ sí èyí rárá, wọ́n gbé igbá owó kiri, wọ́n sì kówó jọ láti fún àwọn sójà láti lu èmi àti ìkejì mi bolẹ̀. A sáré, ẹsẹ̀ wa fẹ́rẹ̀ẹ́ máa kan ìpàkọ́—mo tún ń ti kẹ̀kẹ́ ọmọdé tí ẹ̀rọ agbóhùnjáde wà nínú rẹ̀—ní sísáré lọ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ààbò. Ṣùgbọ́n nígbà tí a débẹ̀, títìpa ni ilẹ̀kùn wà! Dídá tí àwọn ọlọ́pàá dá sí i lásìkò nìkan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ lílù wá lálùbolẹ̀.

Ó ṣe kedere pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà di ohun tí ọ̀pọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀. Nígbà tí mo ń wàásù ní ìlú kan nítòsí Swansea ní àkókò kan lẹ́yìn náà, ọkùnrin kan sọ fún mi lọ́nà tí ó dùn mọ́ ọn nínú pé: “Ẹ̀sìn Kristẹni ni ẹ ń gbèjà, bí ọ̀dọ́kùnrin kan ní Swansea, tí ó fi ìgboyà polongo ohun tí ó gbà gbọ́, tí ó sì ní láti sá lọ láti dáàbò bo ẹ̀mí rẹ̀.” Ẹ wo bí o ti yà á lẹ́nu tó láti mọ̀ pé èmi ni ọ̀dọ́kùnrin náà!

Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà kò rọrùn ní àwọn ọdún tí ogun ń jà yẹn. A kò ní àwọn ohun ìní ti ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ohun tí a ní, a mọrírì wọn, a sì gbádùn wọn. A máa ń gba ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí déédéé, a kò sì pa ìpàdé jẹ rí, àyàfi ìgbà tí a bá ń ṣàìsàn. Mo ra kẹ̀kẹ́ ògbólógbòó kan, a sì ṣe apẹ̀rẹ̀ ńlá kan sórí rẹ̀ láti lè gbé ohun èlò agbóhùnjáde àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú rẹ̀. Nígbà míràn, mo máa ń rìnrìn àjò kìlómítà 80 lójúmọ́ lórí kẹ̀kẹ́ náà! Mo ṣe aṣáájú ọ̀nà fún nǹkan bí ọdún méje, inú mi sì máa ń dùn bí mo bá rántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn.

Ní 1946, lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, a ké sí mi láti wá ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, orúkọ tí a ń pe ilé iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà. Ní 34 Craven Terrace ni Bẹ́tẹ́lì wa wà nígbà náà, ní ilé tí ó gbe London Tabernacle. Mo gbádùn kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà tí ó wà níbẹ̀, bí Alice Hart, tí a gbà gbọ́ pé bàbá rẹ̀, Tom Hart, ni Ẹlẹ́rìí àkọ́kọ́ ní England.

Jíjèrè Alábàákẹ́gbẹ́ Olùṣòtítọ́

Ní 1956, mo fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀ láti lọ fẹ́ Etty, aṣáájú ọ̀nà kan tí mo dojúlùmọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó wá láti Netherlands láti bẹ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ń gbé ní London wò. Bí ogun tí ń lọ sópin, Etty kọ́ni ní bí a ti ń tẹ̀wé àti bí a ti ń fi àmì kọ̀wé ní ilé ẹ̀kọ́ ìṣòwò kan ní Tilburg, gúúsù Netherlands. Ní ọjọ́ kan, olùkọ́ kan yọ̀ǹda láti gun kẹ̀kẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, láti rí i dájú pé ó délé láyọ̀. Ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì ni. Nígbà tí wọ́n délé, ìjíròrò kan jẹ yọ pẹ̀lú àwọn òbí Etty tí wọ́n jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì. Wọ́n di ọ̀rẹ́, olùkọ́ náà sì di ẹni tí ń ṣèbẹ̀wò lemọ́lemọ́ sí ilé wọn.

Kété lẹ́yìn ogun, olùkọ́ yìí wá sí ilé àwọn Etty, tí ó ń kígbe pé, “Mo ti rí òtítọ́!”

Bàbá Etty fèsì pé, “Mo rò pé o sọ pé o ní òtítọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì!”

Ó fèsì tìdùnnútìdùnnú pé, “Rárá! Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó ní òtítọ́ lọ́wọ́!”

Wọ́n lo ìrọ̀lẹ́ yẹn àti ọ̀pọ̀ míràn tí ó tẹ̀ lé e nínú ìjíròrò jíjinlẹ̀ nínú Bíbélì. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Etty di aṣáájú ọ̀nà. Òun pẹ̀lú kojú àtakò líle koko nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì, ní Netherlands. Àwọn ọmọ tí àwọn àlùfáà kì láyà máa ń da ìjíròrò rẹ̀ rú nígbà tí ó bá ń lọ láti ilé dé ilé, wọ́n ba kẹ̀kẹ́ rẹ̀ jẹ́ nígbà kan. Ó gbé kẹ̀kẹ́ rẹ̀ lọ fún atúnkẹ̀kẹ́ṣe kan, tí ó ti gba ìwé kékeré kan lọ́wọ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó sọ tomijétomijé pé: “Ṣé o rí ohun tí àwọn ọmọ yẹn ṣe!”

Ọkùnrin náà fèsì tàánútàánú pé: “Má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nísinsìnyí. Iṣẹ́ àtàtà ni o ń ṣe. N óò tún kẹ̀kẹ́ rẹ ṣe láìgba ohunkóhun.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Etty rí i pé àwọn àlùfáà kì í fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú àwọn ọmọ ìjọ wọn títí di ìgbà tí òun bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé yóò wá láti jin ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn náà nínú Bíbélì àti nínú Jèhófà lẹ́sẹ̀. Láìka èyí sí, ó gbádùn ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó méso wá.

Mo Dúpẹ́ fún Ìgbésí Ayé Wa Tí A Lò Pa Pọ̀

Lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, a yan èmi àti Etty sí iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní England, fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún márùn-ún, a bẹ àwọn ìjọ wò láti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn náà, mo gba ìkésíni láti lọ sí kíláàsì kẹrìndínlógójì ti Gilead, tí a ń ṣe ní orílé-iṣẹ́ àgbáyé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York. Ẹ̀kọ́ olóṣù mẹ́wàá náà, tí a parí ní November 1961, ní pàtàkì jẹ́ láti dá àwọn ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti bójú tó iṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí n kò sí nílé, Etty dúró sí England, ní Bẹ́tẹ́lì ní London. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́yege mi, a yàn wá síbẹ̀ pa pọ̀.

Fún ọdún 16 tí ó tẹ̀ lé e, mo ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn, ní bíbójútó àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ ìgbòkègbodò ìjọ. Lẹ́yìn náà, ní 1978, nígbà tí alábòójútó Ìdílé Bẹ́tẹ́lì, Pryce Hughes, kú, wọ́n yàn mí sípò rẹ̀. Bíbójútó ire àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa tí ń pọ̀ sí i—a ti lé ní 260 nínú ìdílé wa nísinsìnyí—ti jẹ́ iṣẹ́ tí ó mérè wá fún mi fún ọ̀pọ̀ ọdún wọ̀nyí.

Ní 1971, ìyá mi kú ní ẹni ọdún 85. Èmi àti Etty pa dà sí Gloucester fún ìsìnkú náà, níbi tí arákùnrin kan ti jíròrò lọ́nà tí ó dára nípa ìrètí ọ̀run tí Màmá ní. (Fílípì 3:14) Mo mọrírì ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ tí àwọn ẹ̀gbọ́n mi, Doris àti Grace, fún Màmá ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún èmi àti Etty láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún wa nìṣó.

Èmi àti Etty sábà máa ń ronú nípa àwọn òbí wa, àti bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́, aláìgbagbẹ̀rẹ́. Ẹ wo irú gbèsè ńlá tí a jẹ wọ́n! Ìyá mi ní pàtàkì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi, ní gbígbin ìmọrírì fún Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ sínú wa.

Ní tòótọ́, a ń dúpẹ́, a ń tọ́pẹ́ dá, bí a ti ń ronú nípa ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí ń wọlé wá nínú iṣẹ́ ìsìn Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà. Ẹ wo irú Ọlọ́run àgbàyanu, onífẹ̀ẹ́ tí ó jẹ́! Onísáàmù náà nínú Bíbélì sọ ìmọ̀lára wa jáde nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Èmi óò gbé ọ ga, Ọlọ́run mi, ọba mi; èmi óò sì máa fi ìbùkún fún orúkọ rẹ láé àti láéláé. Ní ojoojúmọ́ ni èmi óò máa fi ìbùkún fún ọ; èmi óò sì máa yin orúkọ rẹ láé àti láéláé.”—Orin Dáfídì 145:1, 2.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Pẹ̀lú aya mi, Etty

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́