ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 9/15 ojú ìwé 16-20
  • Ta Ni Yóò La “Ọjọ́ Jèhófà” Já?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Yóò La “Ọjọ́ Jèhófà” Já?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ànímọ́ Ìwà-bí-Ọlọ́run Ṣe Kókó
  • “Ta Ní Ń Ṣe Ti Èmi? Ta Ni?”
  • Ìtìlẹ́yìn Àtọkànwá fún Ìjọsìn Tòótọ́
  • Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Amúnijígìrì Wà Gẹ́rẹ́ Níwájú!
  • Fífìtara Sìn Bíi Ti Èlíṣà
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Èlíṣà Rí Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Oníná—Ṣé Ìwọ Náà Rí I?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpẹẹrẹ Ìfara-Ẹni-Rúbọ àti Ìdúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 9/15 ojú ìwé 16-20

Ta Ni Yóò La “Ọjọ́ Jèhófà” Já?

“Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú àwọn ìṣe mímọ́ ní ìwà àti àwọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!”—PÉTÉRÙ KEJÌ 3:11, 12.

1. Àwọn wo ni wọ́n ti fi ẹ̀mí àti agbára Èlíjà ṣiṣẹ́?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ti yan àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí yóò di àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, nínú Ìjọba ọ̀run, láàárín aráyé. (Róòmù 8:16, 17) Nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fí ẹ̀mí àti agbára Èlíjà ṣiṣẹ́. (Lúùkù 1:17) Nínú àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú, a sọ àwọn ìdọ́gba kan tí ó wà láàárín ìgbòkègbodò wọn àti ti wòlíì Èlíjà. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ wòlíì Èlíṣà, tí ó gbapò lọ́wọ́ Èlíjà, ńkọ́?—Àwọn Ọba Kìíní 19:15, 16.

2. (a) Iṣẹ́ ìyanu wo ni Èlíjà ṣe kẹ́yìn, èwo sì ni Èlíṣà kọ́kọ́ ṣe? (b) Ẹ̀rí wo ni ó wà pé Èlíjà kò lọ sí ọ̀run?

2 Iṣẹ́ ìyanu tí Èlíjà ṣe kẹ́yìn ni pípín omi Odò Jọ́dánì níyà nípa fífi ẹ̀wù òye rẹ̀ lù ú. Èyí mú kí ó ṣeé ṣe fún Èlíjà àti Èlíṣà láti gba orí ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá. Bí wọ́n ti ń rìn lọ ní apá ìlà oòrùn odò náà, ìjì líle kan gbé Èlíjà lọ sí apá ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé. (Wo àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 15, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ọ̀run Wo Ni Èlíjà Gòkè Lọ?”) Èlíjà kò mú ẹ̀wù òye rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí Èlíṣà lò ó láti fi lu Jọ́dánì, omi rẹ̀ tún pínyà, tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún un láti gba orí ìyàngbẹ ilẹ̀ pa dà. Iṣẹ́ ìyanu yìí mú kí ó ṣe kedere pé Èlíṣà ti gbapò Èlíjà nínú gbígbé ìsìn tòótọ́ lárugẹ ní Ísírẹ́lì.—Àwọn Ọba Kejì 2:6-15.

Ànímọ́ Ìwà-bí-Ọlọ́run Ṣe Kókó

3. Kí ni Pọ́ọ̀lù àti Pétérù sọ nípa wíwàníhìn-ín Jésù àti “ọjọ́ Jèhófà”?

3 Ní àwọn ọ̀rúndún lẹ́yìn ọjọ́ Èlíjà àti Èlíṣà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù so dídé “ọjọ́ Jèhófà” mọ́ wíwàníhìn-ín Jésù Kristi àti “àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun kan” ti ọjọ́ iwájú nígbà náà lọ́hùn-ún. (Tẹsalóníkà Kejì 2:1, 2; Pétérù Kejì 3:10-13) Láti la ọjọ́ ńlá Jèhófà já—nígbà tí Ọlọ́run yóò pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run, tí yóò sì gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là—a gbọ́dọ̀ wá Jèhófà, kí a sì fi ọkàn tútù àti òdodo hàn. (Sefanáyà 2:1-3) Ṣùgbọ́n àwọn ànímọ́ mìíràn tún fara hàn kedere bí a ti ń gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú wòlíì Èlíṣà yẹ̀ wò.

4. Ipa wo ni ìtara ń kó nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

4 Ìtara fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ṣe kókó bí a bá fẹ́ la “ọjọ́ Jèhófà” já. Èlíjà àti Èlíṣà jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Pẹ̀lú irú ìtara kan náà, àṣẹ́kù Kristẹni ẹni àmì òróró lónìí ń ṣiṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà, wọ́n sì ń mú ipò iwájú nínú wíwàásù ìhìn rere.a Láti àárín àwọn ọdún 1930, wọ́n ti rọ gbogbo àwọn tí ń tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Ìjọba, tí wọ́n sì nírètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe batisí. (Máàkù 8:34; Pétérù Kíní 3:21) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti dáhùn pa dà sí ìṣírí yìí lọ́nà rere. Nígbà kan rí, wọ́n wà nínú òkùnkùn biribiri tẹ̀mí, tí ẹ̀ṣẹ̀ sì ti wọ̀ wọ́n lára, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, wọ́n ti kọ́ òtítọ́ Ọlọ́run, wọ́n ti fayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìrètí ìyè ayérayé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé kan, wọ́n sì jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Orin Dáfídì 37:29; Ìṣípayá 21:3-5) Nípa ìtara, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, aájò àlejò, àti àwọn iṣẹ́ rere mìíràn wọn, wọ́n ń mú ìtura ńlá wá fún àwọn arákùnrin Kristi nípa tẹ̀mí, tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 25:31-46.

5. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ṣe rere fún “àwọn arákùnrin” Jésù, àpẹẹrẹ wo sì ni a ní ní ọjọ́ Èlíṣà?

5 Àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere fún “àwọn arákùnrin” Jésù nítorí àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí jẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ní ìrètí líla “ọjọ́ Jèhófà” já. A bù kún tọkọtaya kan gidigidi ní abúlé Ṣúnémù fún inúure àti aájò àlejò tí wọ́n ṣe sí Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀. Tọkọtaya yìí kò ní ọmọ, ọkọ sì ti darúgbó. Ṣùgbọ́n Èlíṣà ṣèlérí fún obìnrin ará Ṣúnémù náà pé yóò bí ọmọkùnrin kan, èyí sì ṣẹlẹ̀. Nígbà tí ọmọkùnrin kan ṣoṣo yìí kú ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, Èlíṣà lọ sí Ṣúnémù ó sì jí i dìde. (Àwọn Ọba Kejì 4:8-17, 32-37) Ẹ wo irú ìbùkún ńlá tí èyí jẹ́ fún fífi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí Èlíṣà!

6, 7. Àpẹẹrẹ wo ni Náámánì fi lélẹ̀, kí sì ni èyí ní í ṣe pẹ̀lú líla “ọjọ́ Jèhófà” já?

6 A nílò ìrẹ̀lẹ̀ láti lè gba ìtọ́sọ́nà tí a gbé karí Bíbélì láti ọ̀dọ̀ “àwọn arákùnrin” Kristi, pẹ̀lú ìrètí líla ọjọ́ Jèhófà já. Ọ̀gágun ará Síríà adẹ́tẹ̀ náà, Náámánì, ní láti fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn láti lè tẹ̀lé àbá ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan tí a mú nígbèkùn, kí ó sì wá ìmúláradá nípa lílọ sí Ísírẹ́lì láti lọ wá Èlíṣà. Kàkà tí òun yóò fi jáde láti ilé rẹ̀ láti pàdé Náámánì, Èlíṣà fi ìhìn iṣẹ́ yìí ránṣẹ́ sí i pé: “Lọ, kí o sì wẹ̀ ní Jọ́dánì nígbà méje, ẹran ara rẹ yóò sì tún bọ̀ sípò fún ọ, ìwọ óò sì mọ́.” (Àwọn Ọba Kejì 5:10) A fi ìwọ̀sí lọ Náámánì, inú sì bí i, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó fi ìrẹ̀lẹ̀ lọ, tí ó sì bẹ́ sínú odò Jọ́dánì nígbà méje, “ẹran ara rẹ̀ . . . tún pa dà bọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹran ara ọmọ kékeré, òun sì mọ́.” (Àwọn Ọba Kejì 5:14) Kí ó tó pa dà sílé, Náámánì rìnrìn àjò pa dà sí Samáríà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ wòlíì Jèhófà. Ní pípinnu láti má ṣe jèrè ọrọ̀ àlùmọ́nì láti inú agbára tí Ọlọ́run fi fún un, Èlíṣà jáde láti pàdé Náámánì, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gba ẹ̀bùn èyíkéyìí. Náámánì sọ fún Èlíṣà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Láti òní lọ, ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rúbọ sísun, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rúbọ sì àwọn ọlọ́run mìíràn, bí kò ṣe sí Olúwa.”—Àwọn Ọba Kejì 5:17.

7 Nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni àmì òróró, a ń bù kún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ní jìngbìnnì lónìí. Ní àfikún sí i, nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, a ti wẹ àwọn aláìlábòsí ọkàn wọ̀nyí mọ́ nípa tẹ̀mí. Nísinsìnyí, wọ́n ń gbádùn àǹfààní jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (Orin Dáfídì 15:1, 2; Lúùkù 16:9) A óò sì san èrè fún ìfọkànsin wọn sí Ọlọ́run àti fún fífi tí wọ́n fara jin iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, nípa dídá wọn sí nínú ìparun ayérayé tí yóò dé bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ onígbèéraga, aláìronúpìwàdà nínú “ọjọ́ Jèhófà” tí ń yára sún mọ́lé.—Lúùkù 13:24; Jòhánù Kíní 1:7.

“Ta Ní Ń Ṣe Ti Èmi? Ta Ni?”

8. (a) Ẹ̀mí ìrònú wo ni àwọn tí yóò la “ọjọ́ Jèhófà” já ní sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? (b) Iṣẹ́ wo ni a fún Jéhù? (d) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Jésíbẹ́lì?

8 Àwọn tí ń retí láti la “ọjọ́ Jèhófà” já tún ní láti ṣèpinnu gúnmọ́ ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Èlíjà fi ìgboyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun tí yóò dé bá ìdílé Ọba Áhábù apànìyàn, olùjọsìn Báálì. (Àwọn Ọba Kìíní 21:17-26) Ṣùgbọ́n, kí a tó mú ìparun yìí wá, Èlíṣà tí ó gbapò Èlíjà ní láti parí iṣẹ́ kan tí ó ṣẹ́ kù. (Àwọn Ọba Kìíní 19:15-17) Nígbà tí ó tó àkókò lójú Jèhófà, Èlíṣà pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ kan láti lọ fòróró yan ọ̀gágun Jéhù gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì tuntun. Lẹ́yìn tí ó da òróró sórí Jéhù, ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé: “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, Èmi ti fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí ènìyàn Olúwa, lórí Ísírẹ́lì. Ìwọ óò sì kọlu ilé Áhábù olúwa rẹ, kí èmi ó lè gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ mi, àti ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Olúwa lọ́wọ́ Jésíbẹ́lì. Nítorí gbogbo ilé Áhábù ni yóò ṣègbé.” A óò ju Ayaba Jésíbẹ́lì sí àwọn ajá, a kò sì ní sin ín re.—Àwọn Ọba Kejì 9:1-10.

9, 10. Báwo ni a ṣe mú ọ̀rọ̀ Èlíjà ṣẹ nínú ọ̀ràn Jésíbẹ́lì?

9 Àwọn ọkùnrin Jéhù gbà pé ìfòróróyàn rẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọ́n sì polongo rẹ̀ ní ọba Ísírẹ́lì tuntun. Ní ṣíṣe ìpinnu tí ó ṣe gúnmọ́, Jéhù forí lé Jésíréélì láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pípa àwọn apẹ̀yìndà ògúnná gbòǹgbò olùjọsìn Báálì. Ọba Jèhórámù, ọmọkùnrin Áhábù, ni ọfà Jéhù kọ́kọ́ bà lára. Ó gun ẹṣin jáde láti inú ìlú láti béèrè bí Jéhù bá bá iṣẹ́ àlàáfíà wá. Jéhù fèsì pé: “Àlàáfíà kí ni, níwọ̀n bí ìwà àgbèrè Jésíbẹ́lì ìyá rẹ àti iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?” Pẹ̀lú ìyẹn, ọfà Jéhù gba inú ọkàn Jèhórámù jáde.—Àwọn Ọba Kejì 9:22-24.

10 Àwọn obìnrin oníwà-bí-Ọlọ́run ń yẹra fún dídà bíi Jésíbẹ́lì tàbí irú obìnrin bíi tirẹ̀. (Ìṣípayá 2:18-23) Nígbà tí Jéhù yóò fi dé Jésíréélì, ó ti gbìyànjú láti ṣe ara rẹ̀ lóge. Ní wíwòsàlẹ̀ láti ojú fèrèsé, ó fi ìhalẹ̀mọ́ni tí kò ṣe kedere kí i káàbọ̀. Jéhù bi àwọn ìránṣẹ́ Jésíbẹ́lì pé: “Ta ní ń ṣe ti èmi? Ta ni?” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ méjì tàbí mẹ́ta láàfin bojú wo ìsàlẹ̀. Wọ́n ha wà lẹ́yìn Jéhù bí? Ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ tari rẹ̀ sílẹ̀.” Látàrí èyí, wọ́n gbégbèésẹ̀ tí ó ṣe gúnmọ́, ní títari Jésíbẹ́lì olubi láti ojú fèrèsé. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pátákò ẹṣin ni ó tẹ̀ ẹ́ ní àtẹ̀rẹ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn wá láti sin ín, “wọn kò rí nínú rẹ̀ ju agbárí, àti ẹsẹ̀ àti àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ lọ.” Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Èlíjà tí ó sọ, pé: “Ajá yóò jẹ ẹran ara Jésíbẹ́lì” ti nímùúṣẹ lọ́nà kíkàmàmà tó!—Àwọn Ọba Kejì 9:30-37.

Ìtìlẹ́yìn Àtọkànwá fún Ìjọsìn Tòótọ́

11. Ta ni Jèhónádábù, báwo ni ó sì ṣe fi ìtìlẹ́yìn rẹ̀ fún ìjọsìn tòótọ́ hàn?

11 Àwọn tí ń retí láti la “ọjọ́ Jèhófà” já, kí wọ́n sì gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé gbọ́dọ̀ ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn tọkàntọkàn. Wọ́n gbọ́dọ̀ dà bí Jèhónádábù tàbí Jónádábù, olùjọsìn Jèhófà tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Bí Jéhù ti ń bá a lọ láti mú iṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ tìtaratìtara, Jèhónádábù fẹ́ láti fi ìtẹ́wọ́gbà àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀ hàn. Nítorí náà, ó jáde lọ pàdé ọba Ísírẹ́lì tuntun, tí ó forí lé Samáríà láti lọ pa àwọn tí ó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù. Rírí tí ó rí Jèhónádábù, Jéhù bi í pé: “Ọkàn rẹ ha ṣe déédéé bí ọkàn mi ti rí sí ọkàn rẹ?” Ìdáhùnpadà Jèhónádábù lọ́nà rere sún Jéhù láti nawọ́ rẹ̀ jáde, kí ó sì késí Jèhónádábù sínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sọ pé: “Bá mi lọ, kí o sì wo ìtara mi fún Olúwa.” Láìjáfara, Jèhónádábù tẹ́wọ́ gba àǹfààní fífi ìtìlẹ́yìn rẹ̀ hàn fún amúdàájọ́ṣẹ Jèhófà tí a fi òróró yàn.—Àwọn Ọba Kejì 10:15-17.

12. Èé ṣe tí Jèhófà fi fẹ̀tọ́ béèrè fún ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe?

12 Ṣíṣètìlẹ́yìn àtọkànwá fún ìjọsìn tòótọ́ jẹ́ ohun tí ó bá a mu ní tòótọ́, nítorí Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, tí ó fẹ̀tọ́ béèrè fún ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe, tí ó sì tọ́ sí i. Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Ẹ́kísódù 20:4, 5, NW) Àwọn tí wọ́n nírètí àtila “ọjọ́ Jèhófà” já gbọ́dọ̀ jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:23, 24) Wọ́n gbọ́dọ̀ dúró ṣinṣin ti ìjọsìn tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Èlíjà, Èlíṣà, àti Jèhónádábù ti ṣe.

13. Gẹ́gẹ́ bí ọkàn àyà Jèhónádábù ti ṣe déédéé pẹ̀lú ti Jéhù, àwọn wo ni ó tẹ́wọ́ gba Mèsáyà Ọba, ọ̀nà wo sì ni wọ́n gbà fi èyí hàn?

13 Lẹ́yìn pípa ilé Áhábù run, Ọba Jéhù gbé àwọn ìgbésẹ̀ míràn láti dá àwọn olùjọ́sìn Báálì mọ̀ yà tọ̀, àti láti mú òpin pátápátá dé bá ìsìn èké yìí ní Ísírẹ́lì. (Àwọn Ọba Kejì 10:18-28) Lónìí, a ti yan Jésù Kristi Ọba ọ̀run láti pa àwọn ọ̀tá Jèhófà, kí ó sì dá ipò ọba aláṣẹ Rẹ̀ láre. Bí ọkàn àyà Jèhónádábù ti ṣe déédéé pẹ̀lú ti Jéhù, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn míràn” ti Jésù lónìí ń fi gbogbo ọkàn tẹ́wọ́ gba Kristi gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba wọn, wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 7:9, 10; Jòhánù 10:16) Wọ́n ń fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ṣíṣe ìsìn tòótọ́, àti nípa fífi ìtara nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, ní kíkìlọ̀ fún àwọn ọ̀tá Ọlọ́run nípa “ọjọ́ Jèhófà” tí ó ń yára kánkán sún mọ́lé.—Mátíù 10:32, 33; Róòmù 10:9, 10.

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Amúnijígìrì Wà Gẹ́rẹ́ Níwájú!

14. Kí ní ń bẹ níwájú fún ìsìn èké?

14 Jéhù gbé ìgbésẹ̀ láti mú ìjọsìn Báálì ní Ísírẹ́lì wá sí òpin. Ní ọjọ́ wa, nípasẹ̀ Jéhù Títóbi Jù náà, Jésù Kristi, Ọlọ́run yóò mú ìparun dé bá Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Láìpẹ́, a óò rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì náà sí àpọ́sítélì Jòhánù pé: “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí, àti ẹranko ẹhànnà náà, àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà [Bábílónì Ńlá] wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá. Nítorí Ọlọ́run fi í sínú ọkàn àyà wọn láti mú ìrònú òun ṣẹ, àní láti mú ìrònú kan ṣoṣo tiwọn ṣẹ nípa fífún ẹranko ẹhànnà náà ní ìjọba wọn, títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi di èyí tí a ṣe ní àṣeparí.” (Ìṣípayá 17:16, 17; 18:2-5) “Ìwo mẹ́wàá” náà dúró fún àwọn agbára òṣèlú ológun tí ń ṣàkóso lórí ayé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣe panṣágà nípa tẹ̀mí pẹ̀lú Bábílónì Ńlá nísinsìnyí, àkókò rẹ̀ ti kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn òṣèlú ayé yìí yóò pa ìsìn èké run, “ẹranko ẹhànnà” náà—Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè—yóò kó ipa pàtàkì pẹ̀lú “ìwo mẹ́wàá” náà nínú pípa á run dahoro.b Ẹ wo irú àǹfààní tí èyí yóò jẹ́ láti yin Jèhófà!—Ìṣípayá 19:1-6.

15. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá gbìdánwò láti pa ètò àjọ Ọlọ́run tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé run?

15 Lẹ́yìn ogun gbígbóná janjan tí Ọba Jéhù gbé ti ìjọsìn Báálì, ilé ọlọ́ba rẹ̀ yíjú sí àwọn òṣèlú ọ̀tá Ísírẹ́lì. Jésù Kristi Ọba yóò gbé ìgbésẹ̀ kan náà. Àwọn alágbára òṣèlú yóò ṣì wà lẹ́yìn ìparun ìsìn èké bíi ti Báálì. Lábẹ́ ìdarí Sátánì Èṣù, àwọn ọ̀tá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà wọ̀nyí yóò fi gbogbo agbára gbéjà koni nínú ìgbìdánwò wọn láti pa ètò àjọ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé run. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:14-16) Ṣùgbọ́n Jèhófà yóò mú kí Jésù Kristi Ọba bì wọ́n ṣubú nípa pípa wọ́n run ní Ha–Mágẹ́dọ́nì, “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” ní ṣíṣàṣepé ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jèhófà.—Ìṣípayá 16:14, 16; 19:11-21; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:18-23.

Fífìtara Sìn Bíi Ti Èlíṣà

16, 17. (a) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Èlíṣà jẹ́ onítara títí dé òpin ìgbésí ayé rẹ̀? (b) Kí ló yẹ kí a ṣe pẹ̀lú ọfà òtítọ́?

16 Títí di ìgbà tí “ọjọ́ Jèhófà” yóò mú òpin dé bá ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan Sátánì látòkè délẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yóò jẹ́ onígboyà àti onítara bí Èlíṣà. Yàtọ̀ sí pé ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Èlíjà, Èlíṣà nìkan sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Jèhófà fún ohun tí ó lé ní 50 ọdún! Èlíṣà sì jẹ́ onítara jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ gígùn. Kété ṣáájú ikú rẹ̀, Ọba Jèhóáṣì, ọmọ ọmọ Jéhù ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Èlíṣà sọ fún un pé kí ó ta ọfà láti ojú fèrèsé. Ọfà náà gúnlẹ̀ sí ibi tí a fẹ́ kí ó gúnlẹ̀ sí, Èlíṣà sì kígbe pé: “Ọfà ìgbàlà Olúwa, àti ọfà ìgbàlà lọ́wọ́ Síríà: nítorí ìwọ óò kọlu àwọn ará Síríà ní Áfékì, títí ìwọ yóò fi run wọ́n.” Pẹ̀lú àṣẹ Èlíṣà, Jèhóáṣì ta àwọn ọfà rẹ̀ sí ilẹ̀ lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n ó ṣe èyí láìlo ìtara, ní títa á lẹ́ẹ̀mẹta péré. Lẹ́yìn náà, Èlíṣà sọ pé, nítorí èyí, a óò jẹ́ kí Jèhóáṣì ṣẹ́gun lórí Síríà lẹ́ẹ̀mẹ́ta péré, ohun tí ó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. (Àwọn Ọba Kejì 13:14-19, 25) Ọba Jèhóáṣì kò ṣá àwọn ará Síríà balẹ̀ tán pátápátá, ‘títí tí yóò fi run wọ́n.’

17 Bí ó ti wù kí ó rí, pẹ̀lú ìtara bíi ti Èlíṣà, àwọn ẹni àmì òróró ń bá ìjà náà lọ lòdì sí ìjọsìn èké. Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tí ó ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé ń ṣe ohun kan náà. Ní àfikún sí i, gbogbo àwọn tí ń retí láti la “ọjọ́ Jèhófà” já yóò ṣe dáradára láti ní àwọn ọ̀rọ̀ onítara Èlíṣà nípa títa ọfà sí ilẹ̀ lọ́kàn. Ẹ jẹ́ kí a mú ọfà òtítọ́, kí a sì fi ìtara ta á luni—léraléra—bẹ́ẹ̀ ni, títí dìgbà tí Jèhófà bá sọ pé iṣẹ́ wa pẹ̀lú wọn ti parí.

18. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a dáhùn pa dà sí ọ̀rọ̀ inú Pétérù Kejì 3:11, 12?

18 “Ọjọ́ Jèhófà” yóò mú òpin wá bá ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí láìpẹ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ kí ọ̀rọ̀ oníṣìírí àpọ́sítélì Pétérù yí sún wa gbégbèésẹ̀. Pétérù sọ pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú àwọn ìṣe mímọ́ ní ìwà àti àwọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!” (Pétérù Kejì 3:11, 12) Nígbà tí iná ìbínú Ọlọ́run, tí yóò mú jáde nípasẹ̀ Jésù Kristi, bá yọ́ gbogbo apá ètò ìgbékalẹ̀ yí dà nù, kìkì àwọn tí wọ́n ní àkọsílẹ̀ ìwà ìdúróṣinṣin àti ìfọkànsìn Ọlọ́run ni yóò yè bọ́. Ìjẹ́mímọ́ ní ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí ṣe kókó. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni, tí a ń fi hàn nípa dídáhùn sí àìní wọn, pàápàá jù lọ lọ́nà tẹ̀mí, nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa.

19. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti la “ọjọ́ Jèhófà” já?

19 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ àti ìṣe rẹ ha ń fi ọ́ hàn gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́, onítara ìránṣẹ́ Ọlọ́run bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè fọkàn ṣìkẹ́ ìrètí líla “ọjọ́ Jèhófà” já sínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Bẹ́ẹ̀ ni, o lè nírìírí lílà á já bí o bá ṣe rere sí àwọn arákùnrin Kristi nípa tẹ̀mí, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya Ṣúnémù ṣe ṣe aájò àlejò Èlíṣà. Láti lè là á já, o tún ní láti dà bí Náámánì, tí ó fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìtọ́ni àtọ̀runwá, tí ó sì di olùjọsìn Jèhófà. Bí o bá yán hànhàn láti wà láàyè títí láé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé, o gbọ́dọ̀ fi ìtìlẹ́yìn àtọkànwá hàn sí ìjọsìn tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Jèhónádábù ti ṣe. Nígbà náà, o lè wà lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, tí yóò tó nírìírí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Jésù tí ó sọ pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Bàbá mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.”—Mátíù 25:34.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo orí 18 àti 19 ìwé “Let Your Name Be Sanctified,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

b Wo ojú ìwé 254 sí 256 nínú ìwé Revelation—Its Grand Climax At Hand!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?

◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tí a nílò bí a óò bá la “ọjọ́ Jèhófà” já?

◻ Àpẹẹrẹ wo ni tọkọtaya Ṣúnémù ọjọ́ Èlíṣà fi lélẹ̀?

◻ Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ lára Náámánì?

◻ Báwo ni a ṣe lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jèhónádábù?

◻ Báwo ni ó ṣe yẹ kí Pétérù Kejì 3:11, 12 nípa lórí wa?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́