ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 10/15 ojú ìwé 13-18
  • Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Tí O Ṣe Tọkàntọkàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Tí O Ṣe Tọkàntọkàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹwà Iṣẹ́ Ìsìn Tí A Ṣe Tọkàntọkàn
  • A Kò Fi Wá Wéra
  • Ẹ̀bùn “Olówó Ńlá Gan-an” Tí Obìnrin Onímọrírì Kan Fúnni
  • “Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì” ti Opó Kan
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Iṣẹ́ Ìsìn Tí A Ṣe Tọkàntọkàn
  • Jẹ́ Ẹni Tí Ń Fi Tọkàntọkàn Ṣiṣẹ́!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ó Fara Da Ọgbẹ́ Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Mo Ti Rí Olúwa!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 10/15 ojú ìwé 13-18

Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Tí O Ṣe Tọkàntọkàn

“Ohun yòó wù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ lẹ́nu rẹ̀ bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.”—KÓLÓSÈ 3:23.

1, 2. (a) Àǹfààní gíga lọ́lá jù lọ wo ni a lè ní? (b) Èé ṣe tí ó fi lè má ṣeé ṣe fún wa nígbà míràn láti ṣe gbogbo ohun tí a fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

SÍSIN Jèhófà ni àǹfààní gíga lọ́lá jù lọ tí a lè ní. Fún ìdí rere, ìwé ìròyìn yí ti rọ àwọn Kristẹni fún ìgbà pípẹ́ láti fi ara wọn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí wọ́n tilẹ̀ sìn “lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ sí i” nígbàkigbà tí ó bá ṣeé ṣe. (Tẹsalóníkà Kíní 4:1) Ṣùgbọ́n, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ó ń ṣeé ṣe fún wa láti ṣe gbogbo ohun tí ọkàn wa ń fẹ́ ṣe nínú sísin Ọlọ́run. Arábìnrin àpọ́n kan, tí ó ṣèrìbọmi ní nǹkan bí 40 ọdún sẹ́yìn, ṣàlàyé pé: “Àyíká ipò mi ń béèrè pé kí a fi gbogbo wákàtí ṣiṣẹ́. Kì í ṣe tìtorí àtikó aṣọ tí ó jojú ní gbèsè jọ tàbí àtigbafẹ́ lọ ni mo ṣe ń ṣiṣẹ́, bí kò ṣe láti bójú tó àwọn ohun kòṣeémánìí, títí kan ìnáwó ìṣègùn àti ti eyín. Mo nímọ̀lára pé èyí tí ó ṣẹ́ kù nínú àkókò àti okun mi ni mò ń fún Jèhófà.”

2 Ìfẹ́ fún Ọlọ́run ń sún wa láti fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ṣùgbọ́n àyíká ipò ìgbésí ayé sábà máa ń dín ohun tí a lè ṣe kù. Bíbójútó àwọn ẹrù iṣẹ́ mìíràn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, títí kan ojúṣe ìdílé, lè gba èyí tí ó pọ̀ jù nínú àkókò àti okun wa. (Tímótì Kíní 5:4, 8) Ní “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí, ìgbésí ayé túbọ̀ ń nira sí i. (Tímótì Kejì 3:1) Nígbà tí kò bá ṣeé ṣe fún wa láti ṣe gbogbo ohun tí a fẹ́ láti ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ọkàn wa lè dà wá láàmú dé ìwọ̀n kan. A lè máa ṣe kàyéfì bóyá inú Ọlọ́run dùn sí ìjọsìn wa.

Ẹwà Iṣẹ́ Ìsìn Tí A Ṣe Tọkàntọkàn

3. Kí ni Jèhófà ń retí láti ọ̀dọ̀ gbogbo wa?

3 Ní Orin Dáfídì 103:14, Bíbélì mú un dáni lójú lọ́nà tí ó dùn mọ́ni pé Jèhófà “mọ ẹ̀dá wa; ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.” Ó mọ ibi tí agbára wa mọ, ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Kì í béèrè ju ohun tí agbára wa gbé lọ. Kí ni òun ń retí? Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan, láìka ipò ìgbésí ayé rẹ̀ sí, lè ṣe: “Ohun yòó wù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ lẹ́nu rẹ̀ bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.” (Kólósè 3:23) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà retí pé kí gbogbo wa—gbogbo wa pátá—sìn ín tọkàntọkàn.

4. Kí ni ó túmọ̀ sí láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà tọkàntọkàn?

4 Kí ni ó túmọ̀ sí láti sin Jèhófà tọkàntọkàn? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “tọkàntọkàn,” ní ṣangiliti túmọ̀ sí “láti inú ọkàn.” “Ọkàn” tọ́ka sí ènìyàn lódindi, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ nípa tara àti ti èrò orí. Nípa bẹ́ẹ̀, sísìn tọkàntọkàn túmọ̀ sí fífi ara wa fúnni, lílo gbogbo agbára wa àti dídarí gbogbo okun wa sínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run dé ìwọ̀n kíkúnrẹ́rẹ́ tí ó bá ti ṣeé ṣe tó. Ní kúkúrú, ó túmọ̀ sí ṣíṣe gbogbo ohun tí ọkàn wa bá lè ṣe.—Máàkù 12:29, 30.

5. Báwo ni àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì ṣe fi hàn pé kò pọn dandan fún gbogbo wa láti ṣe ohun kan náà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?

5 Fífi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ha túmọ̀ sí pé gbogbo wa gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan náà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bí? Ìyẹn kò lè ṣeé ṣe, nítorí àyíká ipò àti agbára ọkàn kan yàtọ̀ sí ti èkejì. Gbé àwọn olùṣòtítọ́ àpọ́sítélì Jésù yẹ̀ wò. Gbogbo wọn kò lágbára àtiṣe ìwọ̀n kan náà. Fún àpẹẹrẹ, ohun tí a mọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn àpọ́sítélì, irú bíi Símónì tí í ṣe ará Kánánéánì àti Jákọ́bù ọmọ Álífíọ́sì, kò tó nǹkan. Ó ṣeé ṣe kí ìgbòkègbodò wọn gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì má fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. (Mátíù 10:2-4) Ní ìyàtọ̀ pátápátá, ó ṣeé ṣe fún Pétérù láti tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ wíwúwo—họ́wù, Jésù tilẹ̀ fún un ní “kọ́kọ́rọ́ ìjọba” pàápàá! (Mátíù 16:19) Síbẹ̀, a kò gbé Pétérù ga ju àwọn yòó kù lọ. Nígbà tí Jòhánù rí ìran Jerúsálẹ́mù Tuntun nínú Ìṣípayá (ní nǹkan bí 96 Sànmánì Tiwa), ó rí òkúta ìpìlẹ̀ 12, tí a kọ “orúkọ méjìlá ti àwọn àpọ́sítélì méjìlá” sí lára.a (Ìṣípayá 21:14) Jèhófà mọyì iṣẹ́ ìsìn gbogbo àwọn àpọ́sítélì náà, bí ó tilẹ̀ ṣe kedere pé ó ṣeé ṣe fún àwọn kan láti ṣe púpọ̀ sí i ju àwọn mìíràn lọ.

6. Nínú àkàwé Jésù nípa afúnrúngbìn, kí ní ṣẹlẹ̀ sí irúgbìn tí a gbìn sórí “erùpẹ̀ àtàtà,” àwọn ìbéèrè wo sì ni ó dìde?

6 Lọ́nà kan náà, Jèhófà kì í béèrè fún ìwọ̀n kan náà nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́ gbogbo wa. Jésù fi èyí hàn nínú òwe afúnrúngbìn, tí ó fi iṣẹ́ ìwàásù wé fífúnrúngbìn. Ilẹ̀ tí ó yàtọ̀ síra ni irúgbìn náà bọ́ sí, ní ṣíṣàpèjúwe ipò ọkàn àyà yíyàtọ̀síra tí àwọn tí ó gbọ́ ìhìn iṣẹ́ náà fi hàn. Jésù ṣàlàyé pé: “Ní ti èyí tí a fún sórí erùpẹ̀ àtàtà, èyí ni ẹni náà tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí òye rẹ̀ sì ń yé e, ẹni tí ń so èso ní ti gidi tí ó sì ń mú èso jáde, eléyìí ìlọ́po ọgọ́rùn-ún, èyíinì ọgọ́ta, òmíràn ọgbọ̀n.” (Mátíù 13:3-8, 18-23) Kí ni èso yìí, èé sì ti ṣe tí iye tí ó so fi yàtọ̀ síra?

7. Kí ni èso irúgbìn tí a gbìn, èé sì ti ṣe tí ó mú onírúurú iye jáde?

7 Níwọ̀n bí irúgbìn tí a gbìn ti jẹ́ “ọ̀rọ̀ ìjọba náà,” síso èso tọ́ka sí títan ọ̀rọ̀ yẹn kiri, sísọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 13:19) Iye tí ó so yàtọ̀ síra—láti orí ọgbọ̀n sí ọgọ́rùn-ún—nítorí agbára àti àyíká ipò wa nínú ìgbésí ayé yàtọ̀ síra. Ó lè ṣeé ṣe fún ẹni tí ìlera rẹ̀ jí pépé, tí ó sì lókun láti lo ọ̀pọ̀ àkókò nínú wíwàásù ju ẹnì kan tí ipò àìlera tàbí ọjọ́ ogbó ti tán lókun. Ó lè ṣeé ṣe fún ọ̀dọ́ àpọ́n kan, tí kò ní ẹrù iṣẹ́ ìdílé láti ṣe púpọ̀ sí i ju ẹnì kan tí ó ní láti fi gbogbo wákàtí ṣiṣẹ́ láti pèsè fún ìdílé rẹ̀.—Fi wé Òwe 20:29.

8. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tí ó ṣe gbogbo ohun tí ọkàn wọ́n lè ṣe?

8 Ní ojú ìwòye Ọlọ́run, ìṣòtítọ́ ẹni tí ń ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn, tí ó mú èso ọgbọ̀n jáde kò ha kéré sí ti ẹni tí ó mú èso ọgọ́rùn-ún jáde bí? Rárá o! Iye èso tí a mú jáde lè yàtọ̀ síra, ṣùgbọ́n inú Jèhófà dùn níwọ̀n ìgbà tí iṣẹ́ ìsìn wa jẹ́ gbogbo èyí tí ọkàn wa lè ṣe. Rántí pé, iye èso yíyàtọ̀síra tí a mú jáde wá láti inú ọkàn àyà tí ó jẹ́ “erùpẹ̀ àtàtà.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà (ka·losʹ) tí a tú sí “àtàtà” ṣàpèjúwe ohun kan tí ó “rẹwà” tí ó sì “mú ọkàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, tí ó sì jojú ní gbèsè.” Ẹ wo bí ó ti tuni nínú tó láti mọ̀ pé, nígbà tí a bá ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, ọkàn àyà wa yóò rẹwà lójú Ọlọ́run!

A Kò Fi Wá Wéra

9, 10. (a) Ìrònú òdì wo ni ọkàn àyà wa lè mú kí a rò? (b) Báwo ni àkàwé tí ó wà nínú Kọ́ríńtì Kíní 12:14-26 ṣe fi hàn pé Jèhófà kì í fi wá wé àwọn ẹlòmíràn nínú ohun tí a ṣe?

9 Ṣùgbọ́n, ọkàn àyà wa aláìpé lè rí ohun kan ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Ó lè fi iṣẹ́ ìsìn wa wé tí àwọn ẹlòmíràn. Ó lè ronú pé, ‘Àwọn yòó kù ń ṣe jù mí lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Báwo ni inú Jèhófà ṣe lè dùn sí iṣẹ́ ìsìn mi láé?’—Fi wé Jòhánù Kíní 3:19, 20.

10 Èrò àti ọ̀nà Jèhófà ga gan-an ju tiwa lọ. (Aísáyà 55:9) A túbọ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye sí i nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ìsapá ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú Kọ́ríńtì Kíní 12:14-26, níbi tí a ti fi ìjọ wé ara tí ó ní ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara—ojú, ọwọ́, ẹsẹ̀, etí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gbé ara gidi yẹ̀ wò fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Wó bí yóò ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti fi ojú rẹ wé ọwọ́ rẹ tàbí láti fi ẹsẹ̀ rẹ wé etí rẹ! Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ń ṣiṣẹ́ tí ó yàtọ̀ sí ti èkejì, síbẹ̀, gbogbo ẹ̀yà ni ó wúlò, tí ó sì ṣeyebíye. Lọ́nà kan náà, Jèhófà mọyì iṣẹ́ ìsìn tí o ń ṣe tọkàntọkàn, yálà àwọn mìíràn ń ṣe jù ọ́ lọ tàbí wọn kò ṣe tó ọ.—Gálátíà 6:4.

11, 12. (a) Èé ṣe tí àwọn kan fi lè nímọ̀lára pé àwọn jẹ́ “aláìlera tó” tàbí àwọn “kéré ní ọlá”? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn wa?

11 Nítorí ìkálọ́wọ́kò tí àìlera, ọjọ́ ogbó, àti àwọn àyíká ipò míràn ń mú wá, nígbà míràn àwọn kan nínú wa lè nímọ̀lára pé a jẹ́ “aláìlera tó” tàbí a “kéré ní ọlá.” Ṣùgbọ́n, ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn kọ́ nìyẹn. Bíbélì sọ fún wa pé: “Àwọn ẹ̀yà ara ti ara tí ó dà bí ẹni pé ó jẹ́ aláìlera tó jẹ́ kòṣeémánìí, àti àwọn apá . . . tí a rò pé ó kéré ní ọlá, àwọn wọ̀nyí ni a fi ọlá tí ó pọ̀ jù lọ yíká . . . Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run pá ara pọ̀ ṣọ̀kan, ní fífi ọlá tí ó pọ̀ jù lọ fún apá kan ara tí ó ṣaláìní.” (Kọ́ríńtì Kíní 12:22-24) Nítorí náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lè ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ó mọrírì iṣẹ́ ìsìn wa tí a ń ṣe dé ibi tí agbára wa mọ. Ọkàn àyà rẹ kò ha sún ọ láti fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe nínú sísin irú Ọlọ́run olóye àti onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀?

12 Nítorí náà, ohun tí ó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà ni kí o ṣe ohun tí ìwọ fúnra rẹ—ọkàn rẹ—lè ṣe, kì í ṣe pé kì o ṣe bí ẹlòmíràn ti ṣe. Ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn obìnrin méjì tí ó yàtọ̀ pátápátá síra wọn lò, ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé fi hàn pé Jèhófà mọyì ìsapá wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

Ẹ̀bùn “Olówó Ńlá Gan-an” Tí Obìnrin Onímọrírì Kan Fúnni

13. (a) Àyíká ipò wo ni ó yí dídà tí Màríà da òróró sórí àti ẹsẹ̀ Jésù ká? (b) Èló ni òróró Màríà tó?

13 Ní ìrọ̀lẹ́ Friday, Nísàn 8, Jésù dé sí Bẹ́tánì, abúlé kékeré kan ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìlà oòrùn Òkè Ólífì, nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta sí Jerúsálẹ́mù. Jésù ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà ní ìlú yìí—Màríà, Màtá, àti arákùnrin wọn, Lásárù. Jésù ti jẹ́ àlejò wọn rí, bóyá lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n ní ìrọ̀lẹ́ Saturday, Jésù àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹun ní ilé Símónì, tí ó ti fìgbà kan jẹ́ adẹ́tẹ̀, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ Jésù ni ó wò ó sàn. Bí Jésù ti rọ̀gbọ̀kú sórí tábìlì, Màríà ṣe àyẹ́sí onírẹ̀lẹ̀ kan, tí ó fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ó ní fún ọkùnrin tí ó jí arákùnrin rẹ̀ dìde hàn. Ó ṣí ike kan tí òróró onílọ́fínńdà, “olówó ńlá gan-an” wà nínú rẹ̀. Olówó ńlá gan-an ni ní tòótọ́! Ó tó 300 owó dínárì, nǹkan bí owó ọ̀yà ọdún kan. Ó da òróró títa sánsán yìí sórí àti ẹsẹ̀ Jésù. Ó tilẹ̀ fi irun rẹ̀ gbẹ ẹsẹ̀ rẹ̀.—Máàkù 14:3; Lúùkù 10:38-42; Jòhánù 11:38-44; 12:1-3.

14. (a) Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn ọmọ ẹ̀yìn sí àyẹ́sí Màríà? (b) Báwo ni Jésù ṣe gbèjà Màríà?

14 Inú bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn! Wọ́n béèrè pé, ‘Kí ní fa ìfiṣòfò yí?’ Júdásì, tí ń fi dídábàá ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìní bo ète rẹ̀ láti jalè mọ́lẹ̀, sọ pé: “Èé ṣe tí a kò ta òróró onílọ́fínńdà yí ni ọ̀ọ́dúnrún owó dínárì kí a sì fi fún àwọn òtòṣì?” Màríà kò sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ fi í sílẹ̀. Èé ṣe tí ẹ fi ń gbìyànjú láti dà á láàmú? Ó ṣe iṣẹ́ àtàtà [ti ka·losʹ] lọ́pọ̀lọpọ̀ sí mi. . . . Ó ṣe ohun tí ó lè ṣe; ó dáwọ́ lé e ṣáájú àkókò láti da òróró onílọ́fínńdà sí ara mi nítorí ìsìnkú. Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìhìn rere ní gbogbo ayé, ohun tí obìnrin yìí ṣe ni a óò sọ pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ìrántí rẹ̀.” Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tí Jésù sọ yóò ti pẹ̀tù sọ́kàn Màríà tó!—Máàkù 14:4-9; Jòhánù 12:4-8.

15. Èé ṣe tí ohun tí Màríà ṣe ṣe wú Jésù lórí tó bẹ́ẹ̀, kí sì ni a tipa báyìí kọ́ nípa iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn?

15 Ohun tí Màríà ṣe wú Jésù lórí gidigidi. Lójú rẹ̀, Màríà ṣe ohun tí ó yẹ kí a yìn ín fún. Kì í ṣe iye owó tí ẹ̀bùn yẹn to ni ó ṣe pàtàkì sí Jésù, bí kò ṣe òtítọ́ náà pé “ó ṣe ohun tí ó lè ṣe.” Ó lo àǹfààní tí ó ní, ó sì fúnni ní gbogbo ohun tí ó lè fúnni. Àwọn olùtúmọ̀ míràn ti tú ọ̀rọ̀ náà sí, “Ó ti ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe,” tàbí, “Ó ti ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ̀ gbé.” (An American Translation; The Jerusalem Bible) Ohun tí Màríà fúnni jẹ́ tọkàntọkàn, nítorí ó jẹ́ gbogbo ohun tí agbára rẹ̀ gbé. Ohun tí iṣẹ́ ìsìn tọkàntọkàn túmọ̀ sí kò ju ìyẹn lọ.

“Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì” ti Opó Kan

16. (a) Báwo ni Jésù ṣe wá kíyè sí ọrẹ opó òtòṣì kan? (b) Kí ni ẹyọ owó opó náà tó rà?

16 Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ní Nísàn 11, Jésù lo àkókò gígùn nínú tẹ́ńpìlì, níbi tí a ti gbé ìbéèrè dìde sí ọlá àṣẹ rẹ̀, tí ó sì ti dáhùn ìbéèrè akóni-sí-ṣòro, tí kò rò tẹ́lẹ̀, nípa owó orí, nípa àjíǹde, àti nípa àwọn ọ̀ràn míràn. Ó fi àwọn akọ̀wé àti Farisí bú fún ‘jíjẹ ilé àwọn opó run,’ àti fún ṣíṣe àwọn ohun mìíràn. (Máàkù 12:40) Lẹ́yìn èyí, Jésù jókòó, ó ṣe kedere pé ní Àgbàlá Àwọn Obìnrin, níbi tí àpótí ìṣúra 13 wà, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù. Ó jókòó fún àkókò díẹ̀, ó ń wo bí àwọn ènìyàn ti ń sọ ọrẹ wọn sínú wọn. Ọ̀pọ̀ ọlọ́rọ̀ wá, àwọn kan sì ti lè wá pẹ̀lú ìrísí jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni, àní pẹ̀lú ẹ̀mí ṣekárími pàápàá. (Fi wé Mátíù 6:2.) Jésù tẹjú mọ́ obìnrin kan ní pàtàkì. Ojú lásán lè ṣàìrí ohun tí ó kàmàmà nípa rẹ̀ tàbí nípa ọrẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù, tí ó lè mọ ọkàn àyà àwọn ẹlòmíràn, mọ̀ pé “òtòṣì opó” ni. Ó tún mọ iye gan-an tí ó fi tọrẹ—‘ẹyọ owó kéékèèké méjì, tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an.’b—Máàkù 12:41, 42.

17. Báwo ni Jésù ṣe ka ọrẹ opó náà sí, kí ni a sì tipa báyìí kọ́ nípa fífún Ọlọ́run ní nǹkan?

17 Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí ó fẹ́ kí wọ́n fojú ara wọn rí ẹ̀kọ́ tí ó fẹ́ kọ́ wọn. Jésù sọ pé obìnrin náà “sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra náà.” Lójú tirẹ̀, ohun tí ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo ohun tí àwọn yòó kù sọ sínú rẹ̀ lọ lápapọ̀. Ó fi “gbogbo ohun tí ó ní”—ìwọ̀nba owó tí ó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ rẹ̀—ṣètọrẹ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fi ara rẹ̀ sábẹ́ ìtọ́jú Jèhófà. Nípa báyìí, ẹni tí a fà yọ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fífún Ọlọ́run ní nǹkan ni ẹni tí ẹ̀bùn rẹ̀ kò níye lórí nípa ti ara. Ṣùgbọ́n lójú Ọlọ́run, kò ṣeé díye lé!—Máàkù 12:43, 44; Jákọ́bù 1:27.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Iṣẹ́ Ìsìn Tí A Ṣe Tọkàntọkàn

18. Kí ni a rí kọ́ nípa ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn obìnrin méjèèjì náà lò?

18 Láti inú ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn obìnrin méjì wọ̀nyí lò, a lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n mélòó kan nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn. (Jòhánù 5:19) Jésù kò fi opó náà wé Màríà. Ó mọyì ẹyọ owó kéékèèké méjì opó náà gan-an bí ó ti mọyì òróró Màríà “olówó ńlá gan-an.” Níwọ̀n bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn obìnrin náà ti ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe, ẹ̀bùn àwọn méjèèjì níye lórí lójú Ọlọ́run. Nítorí náà, bí o bá ń ní èrò àìjámọ́-nǹkan-kan nítorí pé kò ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe gbogbo ohun tí o fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, má sọ̀rètí nù. Inú Jèhófà dùn láti tẹ́wọ́ gba gbogbo ohun tí o lè fún un. Rántí pé, Jèhófà “ń wo ohun tí ọkàn àyà jẹ́,” nítorí náà, ó mọ ohun tí ọkàn àyà rẹ ń yán hànhàn fún.—Sámúẹ́lì Kíní 16:7.

19. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a ṣe lámèyítọ́ ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

19 Ojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn yẹ kí ó nípa lórí ojú tí a fi ń wo ara wa àti ọ̀nà tí a gbà ń bá ara wa lò lẹ́nì kíní kejì. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ìwà àìnífẹ̀ẹ́ tó láti ṣe lámèyítọ́ ìsapá àwọn ẹlòmíràn tàbí láti fi iṣẹ́ ìsìn ẹnì kan wé ti ẹlòmíràn! Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, Kristẹni kan kọ̀wé pé: “Nígbà míràn, àwọn kan ń mú kí o nímọ̀lára pé bí o kò bá ti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, o kò jámọ́ nǹkan kan. Ó yẹ kí a mọyì àwa tí a ń làkàkà láti máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bíi ‘kìkì’ akéde Ìjọba tí ń ṣe déédéé pẹ̀lú.” Ẹ jẹ́ kí a rántí pé a kò lọ́lá àṣẹ láti pinnu ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn, fún Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. (Róòmù 14:10-12) Jèhófà mọyì iṣẹ́ ìsìn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn mílíọ̀nù olùṣòtítọ́ akéde Ìjọba ń ṣe tọkàntọkàn, ó sì yẹ kí àwa pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀.

20. Kí ni ó sábà máa ń dára jù láti gbà nípa àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa?

20 Ṣùgbọ́n, bí ó bá jọ bí ẹni pé àwọn kan kò ṣe tó ohun tí wọ́n lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ńkọ́? Ìlọsílẹ̀ nínú ìgbòkègbodò onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kan lè jẹ́ ohun tí ń fi han àwọn alàgbà tí ó bìkítà pé onítọ̀hún nílò ìrànlọ́wọ́ tàbí ìṣírí. Lọ́wọ́ kan náà, kò yẹ kí a gbàgbé pé, fún àwọn kan, iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe tọkàntọkàn lè jọ ẹyọ owó kéékèèké tí opó náà fi ṣètọrẹ dípò òróró olówó ńlá ti Màríà. Ó sábà máa ń dára jù lọ láti gbà pé àwọn arákùnrin wa àti arábìnrin wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, pé ìfẹ́ náà yóò sì sún wọn láti ṣe gbogbo—kì í ṣe ìwọ̀nba—ohun tí wọ́n lè ṣe. Dájúdájú, kò sí ìránṣẹ́ Jèhófà tí ó mọṣẹ́ níṣẹ́ tí yóò yàn láti má ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run!—Kọ́ríńtì Kíní 13:4, 7.

21. Iṣẹ́ ìgbésí ayé tí ń mérè wá wo ni ọ̀pọ̀ ń lépa, àwọn ìbéèrè wo sì ni ó dìde?

21 Ṣùgbọ́n, fún ọ̀pọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn ti túmọ̀ sí lílépa iṣẹ́ ìgbésí ayé kan tí ń mérè wá gan-an—iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n ń rí gbà? Àwa tí kò tí ì ṣeé ṣe fún láti ṣe aṣáájú ọ̀nà ńkọ́—báwo ni a ṣe lè fi ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà hàn? A óò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Níwọ̀n bí Mátíásì ti rọ́pò Júdásì gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, orúkọ rẹ̀—kì í ṣe ti Pọ́ọ̀lù—ni ó ti ní láti fara hàn nínú àwọn tí ó wà lára àwọn òkúta ìpìlẹ̀ 12 náà. Bí Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ jẹ́ àpọ́sítélì, òun kì í ṣe ara àwọn 12.

b Lepton, ẹyọ owó àwọn Júù tí ó kéré jù lọ tí a ń ná nígbà yẹn, ni ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan yìí. Lepta méjì jẹ́ ìpín 1 nínú 64 owó ọ̀yà ọjọ́ kan. Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 10:29 ti sọ, ènìyàn lè fi ẹyọ owó assarion kan (tí ó jẹ́ lepta mẹ́jọ) ra ológoṣẹ́ méjì, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ olówó pọ́ọ́kú jù lọ, tí àwọn òtòṣì ń jẹ. Nítorí náà, opó yìí tòṣì ní ti gidi, nítorí ìdajì owó tí ó lè ra ológoṣẹ́ kan, tí kò yóni ní ìjókòó kan, ni ó ní.

Báwo Ní Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti sin Jèhófà tọkàntọkàn?

◻ Báwo ni àkàwé tí ó wà nínú Kọ́ríńtì Kíní 12:14-26 ṣe fi hàn pé Jèhófà kì í fi wá wé àwọn ẹlòmíràn?

◻ Kí ni a rí kọ́ nípa ṣíṣètọrẹ tọkàntọkàn láti inú ọ̀rọ̀ Jésù nípa òróró olówó ńlá Màríà àti ẹyọ owó kéékèèké méjì opó náà?

◻ Báwo ni ó ṣe yẹ kí ojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn nípa lórí ojú tí a fi ń wo ara wa lẹ́nì kíní kejì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Màríà ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe, ní dída òróró “olówó ńlá gan-an” sára Jésù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹyọ owó opó náà—bí kò tilẹ̀ níye lórí nípa ti ara ṣùgbọ́n kò ṣeé díye lé lójú Jèhófà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́