Jẹ́ Ẹni Tí Ń Fi Tọkàntọkàn Ṣiṣẹ́!
1 A ní ìdí tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa. Èyí ní nínú àwọn nǹkan tí ó ti ṣe fún wa ní ìgbà tí ó kọjá, àwọn nǹkan tí ó ń ṣe fún wa nísinsìnyí, àti àwọn nǹkan tí yóò sì ṣe fún wa síbẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Kí ni ìmọrírì wa yẹ kí ó sún wa láti ṣe? Orin Dafidi kan dáhùn rẹ̀ pé: “Èmi ó máa fi ìbùkún fún Oluwa nígbà gbogbo: Ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.”—Orin Da. 34:1.
2 Bibeli fi hàn ní kedere pé a pa á láṣẹ fún wa láti wàásù. Èyí jẹ́ iṣẹ́ tí a ní láti ṣe “tọkàntọkàn . . . bí ẹni pé fún Jehofa.” (Kol. 3:23) Báwo ni ohun tí a óò ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò ti pọ̀ tó bí a bá jẹ́ ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ní tòótọ́? Nígbà tí a bá ronú nípa ìfẹ́ tí Jehofa fi hàn sí wa, ó dájú pé ọkàn wa yóò sún wa láti ní ìpín kíkún sí i nínú sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀ àti nípa àwọn ète oníyebíye rẹ̀! A óò sún wa láti ṣe ohun tí a bá lè ṣe.
3 Ó jẹ́ ohun tí ó bọ́gbọ́n mu láti retí kí ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ náà tọkàntọkàn fẹ́ láti kó àfíyèsí rẹ̀ jọ sórí iṣẹ́ ìsìn mímọ́. Onipsalmu náà, tí ó ṣe kedere pé ó nímọ̀lára lọ́nà yẹn, kéde pé: “Nígbà méje ní òòjọ́ ni èmi yìn ọ́ nítorí òdodo ìdájọ́ rẹ.” (Orin Da. 119:164) Àwọn tí wọn ní irú ìmọ̀lára tí onipsalmu náà ní ń wọ́nà láti lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti yin Jehofa. Bí ipò àyíká wọn ti yọ̀ǹda, wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn tìtaratìtara bí ó ti lè ṣeé ṣe tó.
4 Ọ̀pọ̀ Àǹfààní Láti Yin Jehofa Yí Wa Ká: Kò di ìgbà tí a bá ń ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ilé-dé-ilé kí a tó lè wàásù ìhìn rere náà. Gbogbo àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wa, mọ̀lẹ́bí wa, àti àwọn ojúlùmọ̀ wa yẹ kí ó gbọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò, a lè bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó lè ṣamọ̀nà sí jíjẹ́rìí fún àwọn tí a jọ wọkọ̀, àwọn òṣìṣẹ́ hòtẹ́ẹ̀lì, òṣìṣẹ́ ilé àrójẹ, òṣìṣẹ́ ilé epo, tàbí awakọ̀ takisí. Nígbà tí a bá wà nílé, a lè jẹ́rìí fún àwọn aládùúgbò tàbí àwọn àlejò. Bí wọ́n bá gbà wá sí ilé ìwòsàn, àwọn nọ́ọ̀sì, dókítà, àti àwọn aláìsàn wà tí a lè jẹ́rìí fún láìjẹ́-bí-àṣà.
5 Ìjẹ́rìí Láìjẹ́-Bí-Àṣà Méso Jáde: Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì ń rìn lọ nínú ọgbà ìtura kan ní ọjọ́ kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú géńdé ọkùnrin kan tí ń gbatẹ́gùn kiri pẹ̀lú ọmọ rẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, òun àti ìyàwó rẹ̀ wá sínú òtítọ́. Géńdé ọkùnrin náà ṣí i payá nígbà tí ó yá pé kò pẹ́ tí òún gbàdúrà sí Ọlọrun, tí òún sì bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Bí o bá wà, jẹ́ kí n mọ̀ ọ́,’ ni òún ṣalábàápàdé àwọn Ẹlẹ́rìí méjì náà fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó ka ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà ìtura náà sí ìdáhùn Jehofa sí àdúrà rẹ̀.
6 Àwọn tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn wọn láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí ń ní ayọ̀ púpọ̀. Wọ́n mọ̀ pé irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú “àyà pípé,” ń mú inú Jehofa dùn.—1 Kron. 28:9.