Orin 66
Fífi Gbogbo Ọkàn Sin Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà, Ọba Aláṣẹ,
Ìwọ ni mo fẹ́, tìẹ ni mo ńgbọ́.
Ìwọ ni n óò máa jọ́sìn;
Èmi kò ní ṣohun tóo kò fẹ́.
Èmi yóò máa tẹ̀ lé àṣẹ rẹ;
Èmi yóò fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, ìwọ ló tọ́ sí;
Gbogbo ọkàn ni màá fi sìn ọ́.
2. Baba, iṣẹ́ rẹ ńgbé ọ ga.
Ayé, òṣùpá, àtìràwọ̀.
Èmi yóò fayé mi sìn ọ́;
Èmi yóò fokun mi kéde rẹ.
Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́,
Nígbà ìyàsímímọ́ mi.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, ìwọ ló tọ́ sí;
Gbogbo ọkàn ni màá fi sìn ọ́.
(Tún wo Diu. 6:15; Sm. 40:8; 113:1-3; Oníw. 5:4; Jòh. 4:34.)