Orin 85
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Èrè Látọ̀dọ̀ Jèhófà
1. Olóòótọ́ ni Jèhófà, ó ńrí gbogbo
Àwọn tó ńsìnín tọkàntọkàn.
Ó mọ ohun tí wọ́n ńpàdánù torí
Ìtara òun ìfọkànsìn.
Tóo bá ti filé, fẹbí, fọ̀rẹ́ sílẹ̀,
Gbogbo rẹ̀ ni Ọlọ́run rí.
Ó fi ẹgbẹ́ ará ọ̀wọ́n sanán fún ọ
Wàá tún ríyè láyé tuntun.
(ÈGBÈ)
Kí Jáà Ọlọ́run ìtùnú wò ọ́;
Kó fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.
Kó fi ìyẹ́ rẹ̀ dáàbò bò ọ́.
Jèhófà jólóòótọ́; àtolódodo.
2. Àwọn kan yàn láti wà nípò àpọ́n,
Tàbí kí wọ́n ṣàì rẹ́ni fẹ́.
Wọ́n máa ńjèrè ìfọkànsìn Ọlọ́run,
Torí wọ́n ńwá Ìjọba rẹ̀.
A mọ̀ pé wọ́n máa ńmọ̀ọ́n lára nígbà míì,
Bí wọn kò ṣe lẹ́nì kejì.
Àwa ni ẹbí fáwọn olóòótọ́ yìí,
Ká máa kẹ́ wọn, ká máa gẹ̀ wọ́n.
(ÈGBÈ)
Kí Jáà Ọlọ́run ìtùnú wò ọ́;
Kó fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.
Kó fi ìyẹ́ rẹ̀ dáàbò bò ọ́.
Jèhófà jólóòótọ́; àtolódodo.
(Tún wo Oníd. 11:38-40; Rúùtù 2:12; Mát. 19:12.)