ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 11/1 ojú ìwé 13-18
  • Wọ́n Wà Nínú Ayé Ṣùgbọ́n Wọn Kì í Ṣe Apá Kan Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Wà Nínú Ayé Ṣùgbọ́n Wọn Kì í Ṣe Apá Kan Rẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìfarahàn Àwọn Agbára Ayé
  • Ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run Tí Ń Bọ̀
  • Yíyẹra fún ‘Àmì Ẹranko Ẹhànnà Náà’
  • “Ẹranko Ẹhànnà Náà” àti “Késárì”
  • Àwọn Ọlọ̀tọ̀ Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ń Darí
  • Àwọn Kristẹni Tí Kì í Dá Sí Tọ̀túntòsì Láwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ọlọrun àti Kesari
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Ohun Tí Ìwé Ìfihàn Sọ Pé Ó Máa Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Ọ̀tá Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 11/1 ojú ìwé 13-18

Wọ́n Wà Nínú Ayé Ṣùgbọ́n Wọn Kì í Ṣe Apá Kan Rẹ̀

“Nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, . . . ayé . . . kórìíra yín.”—JÒHÁNÙ 15:19.

1. Ipò ìbátan wo ni àwọn Kristẹni ní pẹ̀lú ayé, síbẹ̀ ojú wo ni ayé fi ń wò wọ́n?

NÍ ALẸ́ tí ó lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.” Ayé wo ni ó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Òun kò ha ti sọ níṣàájú pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà parun ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun”? (Jòhánù 3:16) Ó ṣe kedere pé àwọn ọmọlẹ́yìn náà jẹ́ apá kan ayé yẹn nítorí pé àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù kí wọ́n lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, èé ṣe tí Jésù fi sọ nísinsìnyí pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yàtọ̀ sí ayé? Èé sì ti ṣe tí ó fi sọ pẹ̀lú pé: “Nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, . . . ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín”?—Jòhánù 15:19.

2, 3. (a) “Ayé” wo ni àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan rẹ̀? (b) Kí ni Bíbélì sọ nípa “ayé” tí àwọn Kristẹni kì í ṣe apá kan rẹ̀?

2 Ìdáhùn náà ni pé, Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, “ayé,” (koʹsmos, Gíríìkì), ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú, nígbà míràn nínú Bíbélì, “ayé” máa ń tọ́ka sí aráyé lápapọ̀. Èyí ni ayé tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́, tí Jésù sì kú fún. Ṣùgbọ́n, ìwé The Oxford History of Christianity sọ pé: “‘Ayé’ tún jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí àwọn Kristẹni ń lò fún ohun kan tí a ti sọ dàjèjì sí Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra Rẹ̀.” Báwo ni èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó? Òǹṣèwé onísìn Kátólíìkì náà, Roland Minnerath, nínú ìwé rẹ̀, Les chrétiens et le monde (Àwọn Kristẹni àti Ayé), ṣàlàyé pé: “Bí a bá lò ó lọ́nà tí ó bu nǹkan kù, a óò tipa ìyẹn rí ayé gẹ́gẹ́ bí . . . ilẹ̀ àkóso tí àwọn agbára tí ó kórìíra Ọlọ́run ti ń bá ìgbòkègbodò wọn lọ, tí wọ́n sì para pọ̀ di ilẹ̀ àkóso ọ̀tá tí ó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì, nípa títa tí wọ́n ta ko ìṣàkóso aṣẹ́gun ti Kristi.” “Ayé” yìí jẹ́ àpapọ̀ ìran ènìyàn tí a sọ dàjèjì sí Ọlọ́run. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe apá kan ayé yìí, ó sì kórìíra wọn.

3 Nígbà tí ọ̀rúndún kìíní ń lọ sópin, ayé yìí ni Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Bàbá kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara àti ìfẹ́ ọkàn ti ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Bàbá, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.” (Jòhánù Kíní 2:15, 16) Ó tún kọ̀wé pé: “Àwa mọ̀ pé a pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù Kíní 5:19) Jésù alára pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé yìí.”—Jòhánù 12:31; 16:11.

Ìfarahàn Àwọn Agbára Ayé

4. Báwo ni àwọn agbára ayé ṣe wá sí ojútáyé?

4 Ayé aráyé tí ó wà nísinsìnyí, tí a ti sọ dàjèjì sí Ọlọ́run, bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn kété lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, nígbà tí ọ̀pọ̀ àtọmọdọ́mọ Nóà kò jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run mọ́. Lára àwọn tí ó lókìkí ní ayé ìgbàanì ni Nímírọ́dù, ẹni tí ó kọ́ ìlú ńlá kan, tí ó sì jẹ́ “ògbójú ọdẹ níwájú OLÚWA.” (Jẹ́nẹ́sísì 10:8-12) Ní àwọn ọdún wọnnì, a ṣètò ọ̀pọ̀ ayé tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí sí àwọn ilẹ̀ ọba onílùú kéékèèké, tí wọ́n máa ń para pọ̀ láti ìgbàdégbà, tí wọ́n sì máa ń bá ara wọn jagun. (Jẹ́nẹ́sísì 14:1-9) Àwọn ilẹ̀ ọba onílùú mélòó kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí àwọn yòó kù láti di agbára ẹlẹ́kùnjẹkùn. Àwọn agbára ẹlẹ́kùnjẹkùn mélòó kan sì di agbára ayé ńlá lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

5, 6. (a) Àwọn wo ni agbára ayé méje tí ìtàn Bíbélì sọ? (b) Kí ni a fi ṣàpẹẹrẹ àwọn agbára ayé wọ̀nyí, ọ̀dọ́ ta ni agbára wọn sì ti wá?

5 Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Nímírọ́dù, àwọn olùṣàkóso agbára ayé wọnnì kò jọ́sìn Jèhófà, òtítọ́ kan tí ó fara hàn nínú ìwà òǹrorò, búburú jáì wọn. Nínú Ìwé Mímọ́, a fi àwọn ẹranko ẹhànnà ṣàpẹẹrẹ àwọn agbára ayé wọ̀nyí, àti pé jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, Bíbélì dárúkọ mẹ́fà lára wọn tí ó lo agbára ńláǹlà lórí àwọn ènìyàn Jèhófà. Ìwọ̀nyí ni Íjíbítì, Asíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, àti Róòmù. Lẹ́yìn Róòmù, a sọ tẹ́lẹ̀ pé agbára ayé keje yóò dìde. (Dáníẹ́lì 7:3-7; 8:3-7, 20, 21; Ìṣípayá 17:9, 10) Èyí jẹ́ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, tí ó ní Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú alájọṣepọ̀ rẹ̀ United States, tí ó bo ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì mọ́lẹ̀ ní ti agbára ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, nínú. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, lẹ́yìn tí ìràlẹ̀rálẹ̀ Ilẹ̀ Ọba Róòmù di àfẹ́kù ni Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrú.a

6 Nínú ìwé Ìṣípayá, a fi àwọn orí ẹranko ẹhànnà olórí méje kan tí ó ti inú òkun aráyé tí kò nísinmi jáde wá ṣàpẹẹrẹ àwọn agbára ayé méjèèje tí ó tẹ̀léra náà. (Aísáyà 17:12, 13; 57:20, 21; Ìṣípayá 13:1) Ta ni ó fún ẹranko tí ń ṣàkóso yìí ní agbára tí ó ń lò? Bíbélì fèsì pé: “Dírágónì náà sì fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.” (Ìṣípayá 13:2) Sátánì Èṣù gan-an ni dírágónì yí.—Lúùkù 4:5, 6; Ìṣípayá 12:9.

Ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run Tí Ń Bọ̀

7. Kí ni àwọn Kristẹni nírètí nínú rẹ̀, báwo sì ni èyí ṣe nípa lórí ipò ìbátan wọn pẹ̀lú àwọn ìjọba ayé?

7 Fún ohun tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000 ọdún báyìí ni àwọn Kristẹni ti ń gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ó lè mú àlàáfíà tòótọ́ wá sórí ilẹ̀ ayé. Níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí ń kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fínnífínní, ó dá wọn lójú pé a óò dáhùn àdúrà yí láìpẹ́ àti pé láìpẹ́, Ìjọba náà yóò bójú tó àlámọ̀rí ayé. (Dáníẹ́lì 2:44) Dídìrọ̀ tí wọ́n dìrọ̀ mọ́ Ìjọba yìí ń mú kí wọ́n wà láìdásí tọ̀túntòsì nínú àlámọ̀rí ìjọba ayé.

8. Báwo ni àwọn ìjọba ṣe ń hùwà pa dà sí Ìjọba Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Orin Dáfídì 2?

8 Àwọn orílẹ̀-èdè kan ń sọ pé àwọn ń pa ìlànà ìsìn mọ́. Síbẹ̀, nínú ìwà, wọ́n kò ka òtítọ́ náà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Àgbáyé àti pé ó ti gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run tí ó ní ọlá àṣẹ lórí ayé sí. (Dáníẹ́lì 4:17; Ìṣípayá 11:15) Àsọtẹ́lẹ̀ onísáàmù kan sọ pé: “Àwọn ọba ayé kẹ́sẹ̀ jọ, àti àwọn ìjòyè ń gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí Ẹni òróró rẹ̀ [Jésù] pé, Ẹ jẹ́ kí a fa ìdè wọn já, kí a sì mú okùn kúrò ní ọ̀dọ̀ wa.” (Orin Dáfídì 2:2, 3) Àwọn ìjọba kò fara mọ́ “ìdè” tàbí “okùn” àtọ̀runwá kankan tí yóò díwọ̀n bí wọn yóò ṣe lo agbára ńlá ti ìṣàkóso orílẹ̀-èdè wọn. Nítorí náà, Jèhófà sọ fún Jésù, Ọba rẹ̀ tí ó yàn pé: “Béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ ní ìní rẹ, àti ìhà òpin ilẹ̀ ní ọrọ̀ ilẹ̀ rẹ. Ọ̀pá irin ni ìwọ óò fi fọ́ wọn; ìwọ ó sì rún wọn wómúwómú, bí ohun èèlò amọ̀.” (Orin Dáfídì 2:8, 9) Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo ayé aráyé tí Jésù kú fún ni a óò “fọ́.”—Jòhánù 3:17.

Yíyẹra fún ‘Àmì Ẹranko Ẹhànnà Náà’

9, 10. (a) Kí ni a kìlọ̀ fún wa nípa rẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá? (b) Kí ni níní ‘àmì ẹranko ẹhànnà náà’ lára ń ṣàpẹẹrẹ? (d) Àmì wo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbà?

9 Ìṣípayá tí àpọ́sítélì Jòhánù rí gbà kìlọ̀ pé ayé aráyé tí a ti sọ dàjèjì sí Ọlọ́run yóò máa fi dandan béèrè, kété kí òpin tó dé, ní ṣíṣe é “ní ọ̀ranyàn fún gbogbo ènìyàn, ẹni kékeré àti ẹni ńlá, àti ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, àti òmìnira àti ẹrú, pé kí wọ́n fún àwọn wọ̀nyí ní àmì kan ní ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí ní iwájú orí wọn, àti pé kí ẹni kankan má baà lè rà tàbí tà àyàfi ẹni tí ó bá ní àmì náà.” (Ìṣípayá 13:16, 17) Kí ni èyí túmọ̀ sí? Àmì ní ọwọ́ ọ̀tún jẹ́ àpẹẹrẹ yíyẹ wẹ́kú fún ìtìlẹ́yìn gbágbágbá. Àmì ti iwájú orí ńkọ́? Ìwé The Expositor’s Greek Testament sọ pé: “Ohun ìṣàpẹẹrẹ gíga lọ́lá yìí ń tọ́ka sí àṣà fífín ara tàbí kíkọlà sí ara àwọn sójà àti àwọn ẹrú . . . ; tàbí, lọ́nà míràn, ó ń tọ́ka sí àṣà ìsìn ti síso orúkọ ọlọ́run mọ́ra gẹ́gẹ́ bí tírà.” Nípa ìwà àti ọ̀rọ̀ wọn, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ní àmì yí lára lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ní fífi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí “ẹrú” tàbí “sójà” “ẹranko ẹhànnà” náà. (Ìṣípayá 13:3, 4) Nípa ọjọ́ ọ̀la wọn, ìwé Theological Dictionary of the New Testament sọ pé: “Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ń yọ̀ǹda kí a fi [àmì] ẹranko ẹhànnà náà, nọ́ńbà ìjìnlẹ̀ tí ó ní orúkọ rẹ̀ nínú, sí iwájú orí wọn àti sí ọwọ́ wọn kan. Èyí ń fún wọn ní àǹfààní ńláǹlà ní ti ọrọ̀ ajé àti ìtẹ̀síwájú nínú ìṣòwò, ṣùgbọ́n ó ń mú wọn wá sábẹ́ ìrunú Ọlọ́run, ó sì ń yọ wọ́n sílẹ̀ nínú ìjọba ẹgbẹ̀rúndún náà, Iṣi. 13:16; 14:9; 20:4.”

10 Ó gba ìgboyà àti ìforítì gidigidi láti lè dènà fífipá múni gba “àmì” náà. (Ìṣípayá 14:9-12) Ṣùgbọ́n, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní irú okun bẹ́ẹ̀, àti nítorí èyí, a sábà máa ń kórìíra wọn, a sì ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa wọn. (Jòhánù 15:18-20; 17:14, 15) Dípò gbígba àmì ẹranko ẹhànnà náà, Aísáyà sọ pé, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ wọn pé, “Ti Olúwa ni èmi.” (Aísáyà 44:5) Ní àfikún sí i, níwọ̀n bí wọ́n “ti ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kígbe” nítorí ohun ìríra tí ìsìn apẹ̀yìndà ti ṣe, wọ́n gba àmì ìṣàpẹẹrẹ kan sí iwájú orí wọn, tí ó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó yẹ kí a dá sí nígbà tí a bá mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ.—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 9:1-7.

11. Ta ní yọ̀ǹda fún àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn láti máa ṣàkóso títí tí Ìjọba Ọlọ́run yóò fi gbà ìṣàkóso ilẹ̀ ayé?

11 Ọlọ́run fàyè gba àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn láti máa ṣàkóso títí di ìgbà tí Ìjọba ọ̀run ti Kristi bá gba ìṣàkóso pátápátá lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀jọ̀gbọ́n Oscar Cullmann sọ̀rọ̀ nípa fífi tí Ọlọ́run fàyè gba àwọn ìjọba ìṣèlú yìí nínú ìwé rẹ̀, The State in the New Testament. Ó kọ̀wé pé: “Dídí tí èrò pé Ìjọba wà fún ‘ìgbà kúkúrú’ díjú ni kò jẹ́ kí ìṣarasíhùwà àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ bá ti Ìjọba mu ní gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n tí ó fi dà bíi pé ó takora. Mo tẹnu mọ́ ọn, pé ó dà bíi pé ó rí bẹ́ẹ̀. Fífi tí a fi Róòmù 13:1 tí ó sọ pé, ‘Kí olúkúlùkù ènìyàn tẹrí ba fún àwọn agbára tí ó wà . . . ,’ àti Ìṣípayá 13 tí ó sọ pé: Ìjọba ni ẹranko ẹhànnà tí ó jáde láti inú ọ̀gbun wá,” wéra ti tó.

“Ẹranko Ẹhànnà Náà” àti “Késárì”

12. Ojú ìwòye wíwà déédéé wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nípa ìjọba ẹ̀dá ènìyàn?

12 Yóò jẹ́ ohun tí kò tọ̀nà láti parí èrò sí pé gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí ń ṣèjọba ni aṣojú Sátánì. Ọ̀pọ̀ ti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá onípinnu, irú bí alákòóso náà, Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, tí Bíbélì ṣàpèjúwe bí “ọkùnrin onílàákàyè.” (Ìṣe 13:7) Àwọn alákòóso kan tí fi àìṣojo gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn kéréje, ní jíjẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wọn darí wọn, bí wọn kò tilẹ̀ mọ Jèhófà àti ète rẹ̀ rárá. (Róòmù 2:14, 15) Rántí pé, Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, “ayé,” ní ọ̀nà méjì tí ó yàtọ̀ síra: ayé aráyé, tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́, tí ó sì yẹ kí a nífẹ̀ẹ́, àti ayé ìran ènìyàn tí a sọ dàjèjì sí Jèhófà, tí Sátánì jẹ́ ọlọ́run rẹ̀, tí a sì gbọ́dọ̀ ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú rẹ̀. (Jòhánù 1:9, 10; 17:14; Kọ́ríńtì Kejì 4:4; Jákọ́bù 4:4) Nípa báyìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ìṣarasíhùwà tí ó wà déédéé sí àwọn alákòóso ẹ̀dá ènìyàn. A kì í dá sí tọ̀tún tòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú níwọ̀n bí a ti jẹ́ ikọ̀ tàbí òjíṣẹ́ aṣojú Ìjọba Ọlọ́run, tí a sì ti ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run. (Kọ́ríńtì Kejì 5:20) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a ń fi gbogbo ọkàn tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ.

13. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn? (b) Báwo ni ìtẹríba Kristẹni fún àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn ṣe lọ jìnnà tó?

13 Ìṣarasíhùwà tí ó wà déédéé yìí fi ojú ìwòye Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ hàn. Nígbà tí àwọn agbára ayé, tàbí àwọn Orílẹ̀-Èdè tí kò tó nǹkan pàápàá, bá ṣi ọlá àṣẹ wọn lò, tí wọ́n bá ni àwọn ènìyàn wọn lára, tàbí tí wọ́n bá ṣenúnibíni sí àwọn tí ń jọ́sìn Ọlọ́run, dájúdájú, wọn yóò bá àpèjúwe alásọtẹ́lẹ̀ náà tí ó pè wọ́n ní ẹranko rírorò mu. (Dáníẹ́lì 7:19-21; Ìṣípayá 11:7) Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bá ṣiṣẹ́ fún ète Ọlọ́run ní lílo ìdájọ́ òdodo láti rí i pé òfin àti àṣẹ fìdí múlẹ̀, Ọlọ́run máa ń kà wọ́n sí ‘ìránṣẹ́ sí gbogbo ènìyàn.’ (Róòmù 13:6) Jèhófà retí pé kí àwọn ènìyàn tòun bọ̀wọ̀ fún àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn, kí wọ́n sì tẹrí ba fún wọn, ṣùgbọ́n ìtẹríba wọn ní ààlà. Nígbà tí àwọn ènìyàn bá béèrè ohun tí òfin Ọlọ́run kà léèwọ̀ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tàbí nígbà tí wọ́n bá ka ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe léèwọ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń di ìdúró tí àwọn àpọ́sítélì dì mú mú, ìyẹn ni pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

14. Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé ìtẹríba Kristẹni fún àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn? báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé rẹ̀?

14 Jésù wí pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò ní ojúṣe tí wọ́n ní láti ṣe fún ìjọba àti fún Ọlọ́run, nígbà tí ó polongo pé: “Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga . . . Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣe ohun tí ó burú, wà nínú ìbẹ̀rù: nítorí kì í ṣe láìsí ète ni ó gbé idà; nítorí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, olùgbẹ̀san láti fi ìrunú hàn jáde sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣèwà hù. Nítorí náà ìdí tí ń múni lọ́ranyàn wà fún yín láti wà lábẹ́ àṣẹ, kì í ṣe ní tìtorí ìrunú yẹn nìkan ṣùgbọ́n ní tìtorí ẹ̀rí ọkàn yín pẹ̀lú. Nítorí ìdí nìyẹn tí ẹ̀yin fi ń san owó orí pẹ̀lú.” (Róòmù 13:1, 4-6) Láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa títí di òní olónìí ni ó ti pọn dandan fún àwọn Kristẹni láti gbé àwọn ohun tí Orílẹ̀-Èdè ń béèrè lọ́wọ́ wọn yẹ̀ wò. Ó ti di ọ̀ranyàn fún wọn láti fòye mọ̀ bóyá ṣíṣe àwọn ohun tí wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ wọn wọ̀nyí yóò yọrí sí fífi ìjọsìn wọn báni dọ́rẹ̀ẹ́ tàbí bóyá irú ohun tí wọ́n béèrè bẹ́ẹ̀ tọ́, tí ó sì yẹ kí ẹ̀rí ọkàn darí wọn láti ṣe é.

Àwọn Ọlọ̀tọ̀ Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ń Darí

15. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn ṣe ń darí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti san ohun tí wọ́n jẹ Késárì fún un?

15 “Àwọn aláṣẹ onípò gíga” ti ìṣèlú jẹ́ “òjíṣẹ́” Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá ṣe ipa tí Ọlọ́run yàn fún wọn, tí ó ní ọlá àṣẹ “láti fi ìyà jẹ àwọn aṣebi ṣùgbọ́n láti yin àwọn olùṣe rere” nínú. (Pétérù Kíní 2:13, 14) Ẹ̀rí ọkàn ń darí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti san ohun tí Késárì fẹ̀tọ́ béèrè ní ti owó orí fún un, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn tí a fi Bíbélì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá yọ̀ǹda fún wọn láti ṣe ní jíjẹ́ “onígbọràn sí àwọn ìjọba àkóso àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso, láti gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (Títù 3:1) “Iṣẹ́ rere” náà kan ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, irú bíi nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú bá ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ ti jẹ́rìí sí inú rere tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi hàn sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn nínú àwọn ipò wọ̀nyí.—Gálátíà 6:10.

16. Àwọn iṣẹ́ rere wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ẹ̀rí ọkàn ń darí ń ṣe fún ìjọba àti àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn?

16 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ronú pé iṣẹ́ tí ó dára jù lọ tí àwọn lè ṣe fún wọn ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa ète Ọlọ́run tí yóò mú “àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” ti òdodo wá. (Pétérù Kejì 3:13) Nípa kíkọ́ni ní ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù gíga tí ń bẹ nínú Bíbélì àti títẹ̀lé e, wọ́n ṣeyebíye púpọ̀ fún àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, ní gbígba ọ̀pọ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwà tí kò bójú mu. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kì í ṣe arúfin, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún àwọn mínísítà ìjọba, àwọn lọ́gàá lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba, àwọn adájọ́, àti àwọn aláṣẹ ìlú, ní bíbọlá fún ‘àwọn tí ó béèrè fún ọlá.’ (Róòmù 13:7) Tayọ̀tayọ̀ ni àwọn òbí Ẹlẹ́rìí fi ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú olùkọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ dáradára, kí ó baà lè jẹ́ pé lẹ́yìnwá ọ̀la, àwọn wọ̀nyí yóò lè gbọ́ bùkátà ara wọn, tí wọn kò ní jẹ́ ẹrù ìnira fún àwùjọ. (Tẹsalóníkà Kíní 4:11, 12) Nínú ìjọ wọn, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ta ko ẹ̀tanú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́, wọ́n sì gbé ìjẹ́pàtàkì gíga karí fífún ìgbésí ayé ìdílé lókun. (Ìṣe 10:34, 35; Kólósè 3:18-21) Nítorí náà, nípa ìwà wọn, wọ́n ń fi hàn pé ẹ̀sùn tí a fi ń kàn wọ́n pé wọ́n ń tú ìdílé ká tàbí pé wọ́n kì í rán àwùjọ lọ́wọ́ jẹ́ èké. Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ òtítọ́ pé: “Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ inú Ọlọ́run jẹ́, pé nípa ṣíṣe rere kí ẹ̀yin lè dí ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan mọ́ àwọn aláìlọ́gbọ́n nínú lẹ́nu.”—Pétérù Kíní 2:15.

17. Báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè máa bá a lọ “ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní òde”?

17 Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi “kì í ṣe apá kan ayé,” wọ́n ṣì wà nínú ayé àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa bá a lọ “ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní òde.” (Jòhánù 17:16; Kólósè 4:5) Níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà bá ṣì yọ̀ǹda fún àwọn aláṣẹ onípò gíga láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ rẹ̀, a óò máa fi ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn fún wọn. (Róòmù 13:1-4) Bí a ṣe ń wà láìdásí tọ̀tún tòsì ní ti ìṣèlú, a ń gbàdúrà nípa “àwọn ọba àti gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ibi ipò gíga,” ní pàtàkì nígbà tí a bá ké sí àwọn wọ̀nyí láti ṣe ìpinnu tí ó lè nípa lórí òmìnira ìjọsìn. A óò máa bá a lọ ní ṣíṣe èyí “kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọ́run kíkún àti ìwà àgbà,” kí ‘gbogbo onírúurú ènìyàn baà lè rí ìgbàlà.’—Tímótì Kíní 2:1-4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé náà Revelation—Its Grand Climax At Hand!, orí 35, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

Ìbéèrè Àtúnyẹ̀wò

◻ “Ayé” wo ni àwọn Kristẹni jẹ́ apá kan rẹ̀, ṣùgbọ́n “ayé” wo ni wọn kò lè jẹ́ apá kan rẹ̀?

◻ Kí ni ‘àmì ẹranko ẹhànnà náà’ tí ń bẹ ní ọwọ́ tàbí iwájú orí ẹnì kan ń ṣàpẹẹrẹ, àmì wo sì ni àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ní?

◻ Ojú ìwòye wíwà déédéé wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ní nípa àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn?

◻ Àwọn ọ̀nà wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń ṣètìlẹ́yìn fún ire àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Bíbélì fi ìjọba ẹ̀dá ènìyàn hàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ẹranko ẹhànnà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Nítorí fífi àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn mìíràn, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣeyebíye púpọ̀ nínú àwùjọ tí wọ́n ń gbé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́