ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 1/15 ojú ìwé 3-7
  • Ẹ̀sìn Kristẹni Lẹ́nu Iṣẹ́ Láàárín Pákáǹleke

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀sìn Kristẹni Lẹ́nu Iṣẹ́ Láàárín Pákáǹleke
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ogun Jà Ní Kóńgò
  • Gbígbé Àìní Yẹ̀ Wò
  • Àwọn Ènìyàn Fi Ọ̀làwọ́ Fúnni Ní Nǹkan
  • Ìpínfúnni ní Kóńgò
  • Ìrànwọ́ fún Àwọn Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí
  • Ibùdó Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi
  • Bí Òṣì Ò Ṣe Ní Sí Mọ́
    Jí!—2005
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Bá A Ṣe Pèsè Ìrànwọ́ Lọ́dún 2021—A Ò Pa Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Wa Tì
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Àjèjì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa ‘Fayọ̀ Sin Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 1/15 ojú ìwé 3-7

Ẹ̀sìn Kristẹni Lẹ́nu Iṣẹ́ Láàárín Pákáǹleke

GBOGBO rẹ̀ ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kan ní April ọdún 1994. Jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú ṣekú pa ààrẹ ilẹ̀ Burundi àti ti Rwanda. Láàárín wákàtí díẹ̀, ìwà ipá tí ń kó jìnnìjìnnì báni ti gba ilẹ̀ Rwanda kan. Ní ohun tí ó lé díẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, iye tí ó ju 500,000 àwọn ará Rwanda—ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé—ti kú. Àwọn kan pe sáà náà ní ti “ìparun ẹ̀yà.”

Ìlàjì nínú mílíọ̀nù 7.5 olùgbé Rwanda ní láti sá. Èyí ní mílíọ̀nù 2.4 àwọn tí ó wá ìsádi lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà nítòsí nínú. Nínú ìtàn ìjádelọ àwọn olùwá-ibi-ìsádi lóde òní, òun ṣì ni ó gbòòrò jù lọ, tí ó sì yá kánkán jù lọ. Kíá ni a tẹ àwọn ibùdó ibi ìsádi dó ní Zaire (tí a ń pè ní Democratic Republic of Congo nísinsìnyí), ní Tanzania, àti ní Burundi. Díẹ̀ nínú àwọn ibùdó wọ̀nyí—tí ó tóbi jù lọ lágbàáyé—jẹ́ ilé fún 200,000 ènìyàn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà tí ń fi ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn, wà lára àwọn olùwá-ibi-ìsádi yìí. Ilẹ̀ yòó wù tí wọ́n lè máa gbé, wọ́n ń di ipò àìdásí tọ̀tún tòsì wọn mú láìgbagbẹ̀rẹ́, wọ́n sì ń fi ìlànà tí ó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Aísáyà 2:4 sílò pé: “Wọn óò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ ogun jíjà mọ́.” A mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo sí àwùjọ ìsìn kan tí kò lọ́wọ́ nínú ìparun ẹ̀yà tí ó wáyé ní Rwanda.

Jésù Kristi wí pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun “kì í ṣe apá kan ayé.” Ṣùgbọ́n, nítorí pé wọ́n wà “nínú ayé,” wọn kò lè fìgbà gbogbo yè bọ́ nínú pákáǹleke àwọn orílẹ̀-èdè. (Jòhánù 17:11, 14) Nígbà tí ìparun ẹ̀yà ṣẹlẹ̀ ní Rwanda, nǹkan bí 400 Ẹlẹ́rìí ni ó pàdánù ẹ̀mí wọn. Nǹkan bí 2,000 Ẹlẹ́rìí àti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà di olùwá-ibi-ìsádi.

Ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé ha túmọ̀ sí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fọwọ́ lẹ́rán nígbà tí àjálù bá bẹ́ sílẹ̀ bí? Rárá o. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Bí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan bá wà ní inú ipò ìhòòhò tí ó sì ṣaláìní oúnjẹ tí ó tó fún òòjọ́, síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa lọ ní àlàáfíà, kí ara yín yá gágá kí ẹ sì jẹun yó dáadáa,’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò fún wọn ní àwọn ohun kòṣeémánìí fún ara wọn, àǹfààní wo ni ó jẹ́? Bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.” (Jákọ́bù 2:15-17) Ìfẹ́ fún àwọn aládùúgbò pẹ̀lú sún Àwọn Ẹlẹ́rìí láti ran àwọn tí wọn kò ṣàjọpín èrò ìgbàgbọ́ wọn lọ́wọ́.—Mátíù 22:37-40.

Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yíká ayé tilẹ̀ yán hànhàn láti ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó dojú kọ ipò àjálù ní Rwanda lọ́wọ́, Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù ni a yan ṣíṣe kòkáárí ìpèsè ìrànwọ́ náà fún. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1994, àwùjọ òṣìṣẹ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti Yúróòpù gbéra lẹ́yẹ-ò-ṣọkà láti ran àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wọn tí ń bẹ ní Áfíríkà lọ́wọ́. Wọ́n gbé àwọn ibùdó tí a ṣètò dáradára àti àwọn ilé ìwòsàn onígbà díẹ̀ kalẹ̀ fún àwọn olùwá-ibi-ìsádi ní Rwanda. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ aṣọ, kúbùsù, oúnjẹ, àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ sí wọn nípasẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú tàbí nípasẹ̀ ọ̀nà míràn tí a lè gbà kẹ́rù ránṣẹ́. Iye tí ó lé ní 7,000 àwọn tí ìpọ́njú dé bá—iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́ta Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ní Rwanda ní àkókò yẹn—jàǹfààní nínú ìpèsè ìrànwọ́ náà. Nígbà tí yóò fi di December ọdún yẹn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùwá-ibi-ìsádi, títí kan ọ̀pọ̀ jù lọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pa dà sí Rwanda láti tún ilé wọn kọ́ àti láti bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò wọn lákọ̀tun.

Ogun Jà Ní Kóńgò

Ní ọdún 1996, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní ẹkùn ìlà oòrùn Democratic Republic of Congo. Àgbègbè yí ni ààlà Rwanda àti Burundi. Ìfipábáni-lòpọ̀ àti ìpànìyàn tún wáyé. Láàárín àwọn ọta ìbọn tí ń já ṣòòròṣò àti àwọn abúlé tí ń jóná, àwọn ènìyàn sá lọ nítorí ẹ̀mí wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ríbi sá lọ nínú pákáǹleke náà, nǹkan bí 50 sì kú. Àwọn ọta ìbọn tí ń só fòóòrò ṣekú pa àwọn kan. A pa àwọn mìíràn nítorí pé wọ́n jẹ́ àwùjọ ẹ̀yà kan pàtó tàbí nítorí pé a rò pé wọ́n jẹ́ ọ̀tá. A dáná sun abúlé kan tí 150 Àwọn Ẹlẹ́rìí ń gbé. Ní àwọn abúlé mìíràn, a dáná sun ọ̀pọ̀ ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba díẹ̀. Nítorí tí a fi ilé àti dúkìá wọn dù wọ́n, Àwọn Ẹlẹ́rìí sá lọ sí àwọn àgbègbè míràn, àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń gbé níbẹ̀ sì ràn wọ́n lọ́wọ́.

Níwọ̀n bí a ti run irè oko, tí a ti jí àwọn oúnjẹ kó ní ibi ìkóúnjẹpamọ́-sí, tí kò sì sí àǹfààní láti fi ìpèsè ránṣẹ́, ebi tẹ̀ lé ogun. Ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó wà wọ́n gógó. Ní Kisangani, ní ìbẹ̀rẹ̀ May ọdún 1997, ànàmọ́ kìlógíráàmù kan tó nǹkan bíi dọ́là mẹ́ta, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ni kò sì lówó láti rà á. Agbára ọ̀pọ̀ kò gbé ju oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lọ lójúmọ́. Kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ, àìsàn tẹ̀ lé ọ̀wọ́n oúnjẹ. Àìjẹunrekánú kó àárẹ̀ bá agbára ara láti dènà ibà, ìgbẹ́ ọ̀rìn, àti inú rírun. Ní pàtàkì, àwọn ọmọdé jìyà, wọ́n sì kú.

Gbígbé Àìní Yẹ̀ Wò

Lẹ́ẹ̀kan sí i, kíá ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Yúróòpù dáhùn pa dà sí àìní náà. Nígbà tí yóò fi di April ọdún 1997, àwùjọ òṣìṣẹ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó ní dókítà méjì nínú ti fi ọkọ̀ òfuurufú kó egbòogi àti owó wá síbẹ̀. Ní Goma, Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ládùúgbò ti ṣètò àwọn ìgbìmọ̀ ìpèsè ìrànwọ́ láti gbé ipò náà yẹ̀ wò, kí a lè ṣèrànwọ́ ojú ẹsẹ̀. Àwùjọ òṣìṣẹ́ náà yẹ ìlú náà àti àgbègbè rẹ̀ wò. A rán àwọn ońṣẹ́ jáde láti gba ìsọfúnni láti àwọn ibi jíjìnnà réré. A tún gba ìsọfúnni láti Kisangani, tí ó wà ní 1,000 kìlómítà sí ìwọ̀ oòrùn Goma. Àwọn arákùnrin tí ń bẹ ládùúgbò ṣèrànwọ́ láti ṣe kòkáárí ìpèsè ìrànwọ́ ní Goma, níbi tí nǹkan bí 700 Ẹlẹ́rìí ń gbé.

Ọ̀kan lára àwọn Kristẹni alàgbà ní Goma wí pé: “Ó wú wa lórí gidigidi láti rí àwọn arákùnrin wa tí wọ́n ti ọ̀nà jíjìn wá láti ràn wá lọ́wọ́. Kí wọ́n tó dé, a ran ara wa lọ́wọ́. Àwọn ará ní láti sá láti àgbègbè àrọko wá sí Goma. Àwọn kan ti pàdánù ilé wọn, wọ́n sì ti fi oko wọn sílẹ̀. A gbà wọ́n sí ilé wa, a sì ṣàjọpín aṣọ wa àti oúnjẹ díẹ̀ tí a ní pẹ̀lú wọn. Ohun tí a lè ṣe lábẹ́lé kò tó nǹkan. Àwọn kan nínú wa ń jìyà àìjẹunrekánú.

“Ṣùgbọ́n, àwọn arákùnrin láti Yúróòpù mú owó tí a lè fi ra oúnjẹ tí ó wọ́n gógó, tí ó sì gbówó lórí, wá. Oúnjẹ náà bọ́ sákòókò gan-an, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ kò ti ní ohunkóhun láti jẹ nínú ilé wọn. A pín oúnjẹ náà fún Àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Bí ìrànwọ́ náà kò bá wá nígbà tí ó wá yẹn, ọ̀pọ̀ ì bá ti kú, pàápàá àwọn ọmọdé. Jèhófà dẹ́mìí àwọn ènìyàn rẹ̀ sí. Ó wú àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lórí. Ọ̀pọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ sọ pé ìsìn wa ni ìsìn tòótọ́.”

Bí a tilẹ̀ ra oúnjẹ lábẹ́lé tí a sì fúnni ní egbòogi, a ṣì nílò ohun púpọ̀ sí i. A nílò aṣọ àti kúbùsù, àti àwọn ìpèsè púpọ̀ míràn ti oúnjẹ àti egbòogi. A tún nílò ìrànwọ́ láti tún àwọn ilé tí a ti run kọ́.

Àwọn Ènìyàn Fi Ọ̀làwọ́ Fúnni Ní Nǹkan

Àwọn ará ní Yúróòpù tún ti ń hára gàgà láti ṣèrànwọ́. Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Louviers, ní ilẹ̀ Faransé, pe ìpè náà ní àwọn ìjọ tí ó wà ní Àfonífojì Rhône àti ní Normandy, àti ní apá kan àgbègbè Paris. Níhìn-ín, a fi ìlànà Ìwé Mímọ́ mìíràn sílò: “Ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn kín-ún yóò ká kín-ún pẹ̀lú; ẹni tí ó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu yóò ká yanturu pẹ̀lú. Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí òun ti [pinnu] nínú ọkàn àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—Kọ́ríńtì Kejì 9:6, 7.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lo àǹfààní náà láti fúnni ní nǹkan tayọ̀tayọ̀. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kún fún àpótí àti àpò aṣọ, bàtà, àti àwọn nǹkan mìíràn, lẹ́yìn náà, a kó wọn lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé. Níbẹ̀ 400 àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ti wà ní sẹpẹ́ láti lọ́wọ́ nínú ìpele kejì ti ètò “Ṣèrànwọ́ fún Zaire.” Bí àwọn ẹrù tí a fi ṣètọrẹ náà ṣe ń rọ́ wọlé, àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni wọ̀nyí ń tò wọ́n lónírúurú, wọ́n ń ká wọn, wọ́n sì ń di àwọn aṣọ náà sínú àpótí tí a tò gègèrè lọ́gbọọgbọ̀n sórí pákó ìkẹ́rù kọ̀ọ̀kan. Àwọn ọmọdé ronú nípa àwọn ọ̀dọ́mọdé arákùnrin àti arábìnrin wọn ní Áfíríkà, wọ́n sì fi ohun ìṣeré ránṣẹ́—ọkọ̀ ọmọdé tí ń dán gbinrin, bàlúù ọmọdé, ọmọláńgidi, àti béárì àtọwọ́dá. A di ìwọ̀nyí pọ̀ mọ́ àwọn nǹkan kòṣeémánìí mìíràn. Lápapọ̀, àwọn ohun ìkóǹkansí mẹ́sàn-án tí ó ga ní mítà 12 kún bámúbámú, a sì kó wọn ránṣẹ́ sí Kóńgò.

Báwo ni ìpèsè ìrànwọ́ tí a fi ránṣẹ́ sí Àárín Gbùngbùn Áfíríkà pẹ̀lú ìrànwọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Belgium, ilẹ̀ Faransé, àti Switzerland ti pọ̀ tó? Nígbà tí yóò fi di June ọdún 1997, àpapọ̀ gbogbo rẹ̀ jẹ́ 500 kìlógíráàmù egbòogi, tọ́ọ̀nù 10 bisikí eléròjà protein púpọ̀, 20 tọ́ọ̀nù àwọn oúnjẹ mìíràn, 90 tọ́ọ̀nù aṣọ, 18,500 bàtà, àti 1,000 kúbùsù. A tún fi ọkọ̀ òfuurufú kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọlé. Gbogbo èyí ni a mọrírì gidigidi, ó tu àwọn olùwá-ibi-ìsádi nínú, ó sì ṣèrànwọ́ fún wọn láti fara da àdánwò náà. Iye tí gbogbo ìpèsè ìrànwọ́ náà náni fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,000,000 dọ́là, ti United States. Irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí ìdè ẹgbẹ́ ará àti ìfẹ́ tí ó wà láàárín àwọn tí ń sin Jèhófà.

Ìpínfúnni ní Kóńgò

Bí àwọn ẹrù náà ti ń dé Kóńgò, arákùnrin méjì pẹ̀lú arábìnrin kan wá láti ilẹ̀ Faransé láti bá àwọn Ìgbìmọ̀ ìpèsè ìrànwọ́ náà ṣiṣẹ́. Nípa ìmọrírì tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Kóńgò fi hàn, Joseline wí pé: “A gba ọ̀pọ̀ lẹ́tà ìmọrírì. Arábìnrin kan tí ó jẹ́ tálákà fún mi ní ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi bàbà ṣe. Àwọn mìíràn fún wa ní fọ́tò wọn. Bí a ti ń fibẹ̀ sílẹ̀, àwọn arábìnrin fẹnu kò mí lẹ́nu, wọ́n gbá mi mọ́ra, wọ́n sì bú sẹ́kún. Èmi náà sọkún. Ọ̀pọ̀ sọ àwọn gbólóhùn bí, ‘Ẹni rere mà ni Jèhófà o. Jèhófà ń ronú nípa wa.’ Nítorí náà wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ni ìyìn ohun tí a fún wọn tọ́ sí. Nígbà tí a ń pín oúnjẹ, àwọn arákùnrin àti arábìnrin fi orin Ìjọba yin Jèhófà. Ó mórí ẹni wú gan-an.”

Dókítà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Loic jẹ́ ọ̀kan lára àwùjọ òṣìṣẹ́ náà. Èrò kún inú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, wọ́n sì mú sùúrù títí tí ó fi kàn wọ́n láti rí i. Ní fífẹ́ láti ṣe ohun kan, arábìnrin kan ará Kóńgò ṣe 40 dónọ́ọ̀tì fún àwọn tí ń dúró láti rí dókítà, ó sì pín in fún wọn. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nǹkan bí 80 ènìyàn ni ó dúró, ẹnì kọ̀ọ̀kan rí ìlàjì dónọ́ọ̀tì kan gbà.

Ìrànwọ́ fún Àwọn Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí

Kì í ṣe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni a ṣe ìrànwọ́ afẹ́dàáfẹ́re yìí fún. Àwọn mìíràn pẹ̀lú jàǹfààní nínú rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ti ṣe ní ọdún 1994. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú Gálátíà 6:10, tí ó sọ pé: “Ní ti gidi, nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí àwa bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn wọnnì tí wọ́n bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí pín egbòogi àti aṣọ dé ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé àwọn ọmọ òrukàn nítòsí Goma. Ilé àwọn ọmọ òrukàn náà ní àwọn ọmọdé 85. Nínú ìrìn àjò ìṣáájú láti yẹ ipò náà wò, àwùjọ òṣìṣẹ́ apèsè ìrànwọ́ náà ṣèbẹ̀wò sí ilé àwọn ọmọ òrukàn náà, wọ́n sì ṣèlérí láti pèsè 50 àpótí bisikí tí ó ní èròjà protein púpọ̀, àwọn àpótí aṣọ, 100 kúbùsù, egbòogi, àti ohun ìṣeré ọmọdé. Àwọn ọmọ náà tò sí àgbàlá, wọ́n sì kọrin fún àwọn olùṣèbẹ̀wò. Lẹ́yìn náà, wọ́n béèrè ohun àrà ọ̀tọ̀ kan—a ha lè bá wọn wá bọ́ọ̀lù kan tí wọn yóò máa gbá?

Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, àwùjọ òṣìṣẹ́ apèsè ìrànwọ́ náà mú ìlérí wọn ṣẹ láti kó àwọn ìpèsè ìrànwọ́ wá. Nítorí tí ìwà ọ̀làwọ́ àti ohun tí ó ti kà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n fún un wú u lórí, olùdarí ilé àwọn ọmọ òrukàn náà wí pé òun ti ń múra láti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ha pèsè bọ́ọ̀lù kan fún àwọn ọmọ náà bí? Claude, olùṣekòkáárí ìpèsè ìrànwọ́ náà láti ilẹ̀ Faransé fèsì pé: “Rárá o. A fún wọn ní bọ́ọ̀lù méjì.”

Ibùdó Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi

Kì í ṣe Kóńgò nìkan ni a kó ìpèsè ìrànwọ́ lọ. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti sá kúrò ní ibi tí ọwọ́ ogun ti le lọ sí orílẹ̀-èdè tí ó wà nítòsí, níbi tí a ti yára dá ibùdó mẹ́ta sílẹ̀ fún àwọn olùwá-ibi-ìsádi. Àwọn Ẹlẹ́rìí rin ìrìn àjò lọ síbẹ̀ pẹ̀lú, láti lè rí ohun tí àwọn lè ṣe. Nígbà tí a ń kọ ìròyìn yí, àwọn ibùdó náà ní 211,000 olùwá-ibi-ìsádi, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn wá láti Kóńgò. Nǹkan bí 800 jẹ́ Ẹlẹ́rìí, àwọn ọmọ wọn àti ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn tí ó lọ́kàn ìfẹ́ nínú ìhìn rere Ìjọba náà. Olórí ìṣòro tí ó wà ní àwọn ibùdó náà ni àìsóúnjẹ. Ní ibùdó kan, oúnjẹ ọjọ́ mẹ́ta péré ni ó ṣẹ́ kù, ọ̀kan nínú oúnjẹ náà ni ẹ̀wà àtọdún mẹ́ta.

Síbẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí kò rẹ̀wẹ̀sì. Bí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ní kò tilẹ̀ to nǹkan, wọ́n ń ṣe ìpàdé déédéé ní ibi gbàgede láti lè gbé ara wọn ró nípa tẹ̀mí. Ọwọ́ wọn tún dí fọ́fọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn nínú àwọn ibùdó náà.—Mátíù 24:14; Hébérù 10:24, 25.

Àwùjọ òṣìṣẹ́ olùwádìí ti Àwọn Ẹlẹ́rìí ní dókítà kan nínú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba ọjọ́ díẹ̀ ni àwọn aláṣẹ gbà kí wọ́n lò ní ibùdó kọ̀ọ̀kan, wọ́n tọ́jú àwọn aláìsàn. Wọ́n kó egbòogi àti owó sílẹ̀ fún àwọn Kristẹni alàgbà. Nípa báyìí, àwọn ará lè là á já. Wọ́n tún nírètí pé láìpẹ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wà ní àwọn ibùdó náà yóò pa dà sí ìlú wọn.

Ọjọ́ ọ̀la ńkọ́? Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ wa yóò jẹ́ àkókò onípákáǹleke ńlá, àkókò kan tí ogun àti ọ̀wọ́n oúnjẹ sàmì sí. (Mátíù 24:7) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni ó lè fòpin sí ìyà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí. Lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, ilé wa orí ilẹ̀ ayé yóò di párádísè alálàáfíà, ọlọ́pọ̀ yanturu, àti ti ayọ̀ àìnípẹ̀kun fún aráyé onígbọràn. (Orin Dáfídì 72:1, 3, 16) Ní báyìí ná, Àwọn Ẹlẹ́rìí yóò máa polongo ìhìn rere ti Ìjọba ọ̀run yẹn, wọn yóò sì máa bá a nìṣó láti ran àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn mìíràn lọ́wọ́ ní àkókò àìní.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Láti ọdún 1994, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Yúróòpù ti dá fi ohun tí ó lé ní 190 tọ́ọ̀nù oúnjẹ, aṣọ, egbòogi, àti àwọn ìpèsè ìrànwọ́ mìíràn ránṣẹ́ sí ẹkùn Àwọn Adágún Ńlá ti Áfíríkà

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Wọ́n Lo Ìfẹ́ Kristẹni

Ruth Danner jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n fi ìháragàgà lọ́wọ́ nínú ètò “Ṣèrànwọ́ fún Zaire,” ní ilẹ̀ Faransé. Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, a fi í sẹ́wọ̀n ní ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti ìjọba Nazi nítorí ìgbàgbọ́ Kristẹni rẹ̀. Ó sọ pé: “Inú wa dùn jọjọ láti ṣe ohun kan fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Áfíríkà! Ṣùgbọ́n ohun kan wà tí ó mú kí ayọ̀ mi légbá kan. Ní ọdún 1945, nígbà tí a darí dé láti Germany, a kò ní ohunkóhun. Kódà, títọrọ ni a tọrọ aṣọ tí a wọ̀. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́, a rí ìpèsè ìrànwọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ará wa nípa tẹ̀mí ní Amẹ́ríkà. Nítorí náà, ìpèsè ìrànwọ́ yìí fún mi láǹfààní láti san inú rere tí a fi hàn sí wa nígbà pípẹ́ sẹ́yìn pa dà. Ẹ wo irú àǹfààní tí ó jẹ́ láti jẹ́ apá kan ìdílé ńlá ti àwọn ará tí wọ́n ń lo ìfẹ́ Kristẹni!”—Jòhánù 13:34, 35.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Láìpẹ́—párádísè ilẹ̀ ayé kan pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu fún gbogbo ènìyàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́