Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Bíbá Ọlọ́run Rìn
“Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí ẹ̀yin kì yóò sì ṣe ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara rárá.”—GÁLÁTÍÀ 5:16.
1. (a) Lójú àwọn ipò wo ni Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn, fún ọdún mélòó sì ni? (b) Ọdún mélòó ni Nóà fi bá Ọlọ́run rìn, àwọn ẹrù iṣẹ́ wíwúwo wo sì ni òun ní?
BÍBÉLÌ sọ fún wa pé, Énọ́kù ‘ń bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.’ Láìka ọ̀rọ̀ amúnigbọ̀nrìrì àti ìwà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti àwọn ènìyàn tí ó yí i ká sí, ó tẹpẹlẹ mọ́ bíbá Ọlọ́run rìn títí di òpin ìgbésí ayé rẹ̀ ni ẹni ọdún 365. (Jẹ́nẹ́sísì 5:23, 24, NW; Júúdà 14, 15) Nóà pẹ̀lú “bá Ọlọ́run rìn.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀ bí ó ti ń tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, bí ó ti ń kojú ayé tí àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ọmọ wọn oníwà ipá ń nípa lé lórí, àti bí ó ti ń bójú tó gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú kíkan áàkì gìrìwò, tí ó tóbi ju ọkọ̀ òkun èyíkéyìí ní ayé ìgbàanì. Ó ń bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn lẹ́yìn Àkúnya Omi náà, àní nígbà tí ìṣọ̀tẹ̀ lòdì sí Jèhófà tún jẹ yọ ní Bábélì. Ní tòótọ́, Nóà ń bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ ní ẹni 950 ọdún.—Jẹ́nẹ́sísì 6:9; 9:29.
2. Kí ni ‘bíbá Ọlọ́run rìn’ túmọ̀ sí?
2 Nígbà tí ó ń sọ pé àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́ wọ̀nyí “rìn” pẹ̀lú Ọlọ́run, Bíbélì ń lo èdè náà lọ́nà àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́. Ó túmọ̀ sí pé Énọ́kù àti Nóà hùwà lọ́nà kan tí ó fẹ̀rí hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Ọlọ́run. Wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún wọn, wọ́n sì gbé ìgbésí ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀, láti inú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú aráyé. (Fi wé Kíróníkà Kejì 7:17.) Kì í ṣe pé wọ́n gbà nínú ọkàn wọn pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run sọ, tí ó sì ṣe nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún gbégbèésẹ̀ lórí gbogbo ohun tí ó béèrè—kì í ṣe díẹ̀ lára rẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ pátá dé ibi tí ó ṣeé ṣe fún wọn dé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. Nípa báyìí, Nóà, fún àpẹẹrẹ, ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 6:22) Nóà kò ṣe kọjá ìtọ́ni tí a fún un, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jáfara. Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí ó gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, tí ó lómìnira láti gbàdúrà sí Ọlọ́run, tí ó sì ṣìkẹ́ ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá, ó ń bá Ọlọ́run rìn. Ìwọ ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí?
Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí A Óò Máa Tọ̀ Lọ
3. Kí ni ó ṣe pàtàkì gidi fún gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ àti batisí?
3 Ó ń múni lọ́kàn yọ̀ láti rí àwọn ènìyàn tí ń bẹ̀rẹ̀ sí í bá Ọlọ́run rìn. Bí wọ́n ti ń gbé ìgbésẹ̀ tí ó dára ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà, wọ́n ń fi ẹ̀rí ìgbàgbọ́ wọn hàn, èyí tí ẹnikẹ́ni kò lè wu Ọlọ́run láìní i. (Hébérù 11:6) Ẹ wo bí inú wá ti dùn tó pé lọ́dọọdún, ní ìpíndọ́gba fún ọdún márùn-ún tí ó kọjá, iye ènìyàn tí ó lé ní 320,000 ti ya ara wọn sí mímọ́ sí Jèhófà, tí wọ́n sì ti yọ̀ǹda ara wọn fún ìrìbọmi! Ṣùgbọ́n, ó tún ṣe pàtàkì fún wọn àti fún gbogbo wa pátá láti máa bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn.—Mátíù 24:13; Ìṣípayá 2:10.
4. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ìgbàgbọ́ díẹ̀ hàn, èé ṣe tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó fi Íjíbítì sílẹ̀ kò fi wọ Ilẹ̀ Ìlérí?
4 Ní ọjọ́ Mósè, ó gba ìgbàgbọ́ fún ìdílé Ísírẹ́lì kan láti ṣayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá ní Íjíbítì, kí wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àwọn òpó ilẹ̀kùn àti àtẹ́rígbà ẹnu ọ̀nà ilé wọn. (Ẹ́kísódù 12:1-28) Ṣùgbọ́n, ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ mì nígbà tí wọ́n rí i tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò dé lẹ́yìn wọn ní Òkun Pupa. (Ẹ́kísódù 14:9-12) Orin Dáfídì 106:12 fi hàn pé nígbà tí wọ́n ti la ilẹ̀ òkun gbígbẹ kọjá láìséwu, tí wọ́n sì rí i tí omi tí ń ru gùdù pa ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Íjíbítì run ráúráú, lẹ́ẹ̀kan sí i wọ́n “gba ọ̀rọ̀ [Jèhófà] gbọ́.” Ṣùgbọ́n láàárín àkókò kúkúrú, lẹ́yìn tí wọ́n dé inú aginjù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé nípa omi mímu, oúnjẹ, àti àbójútó. Ìròyìn burúkú tí 10 lára àwọn amí 12 náà tí wọ́n pa dà dé láti Ilẹ̀ Ìlérí sọ mú kí wọ́n bẹ̀rù. Lábẹ́ irú àwọn àyíká ipò wọ̀nyẹn, gẹ́gẹ́ bí Orin Dáfídì 106:24 ṣe sọ, “wọn kò gba ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run] gbọ́.” Wọ́n fẹ́ pa dà sí Íjíbítì. (Númérì 14:1-4) Ìgbàgbọ́ yòó wù kí wọ́n ní máa ń fara hàn kedere kìkì nígbà tí wọ́n rí àwọn ìfihàn agbára àtọ̀runwá lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Wọn kò bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn. Nítorí ìdí èyí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn kò wọnú Ilẹ̀ Ìlérí.—Orin Dáfídì 95:10, 11.
5. Báwo ni Kọ́ríńtì Kejì 13:5 àti Òwe 3:5, 6 ṣe tan mọ́ bíbá Ọlọ́run rìn?
5 Bíbélì ṣí wa létí pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ̀yin wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (Kọ́ríńtì Kejì 13:5) Wíwà “nínú ìgbàgbọ́” túmọ̀ sí rírọ̀ mọ́ àwọn ìgbàgbọ́ Kristẹni. Èyí ṣe kókó bí a óò bá ṣàṣeyọrí nínú bíbá Ọlọ́run rìn ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé wa. Láti bá Ọlọ́run rìn, a tún gbọ́dọ̀ lo ànímọ́ ìgbàgbọ́, ní gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà pátápátá. (Òwe 3:5, 6) Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ páńpẹ́ àti ọ̀fìn ni ó wà tí àwọn tí ó bá kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀ lè kó sí. Kí ni díẹ̀ nínú ìwọ̀nyí?
Yẹra fún Ìdẹkùn Ìdára-Ẹni-Lójú
6. Kí ni gbogbo Kristẹni mọ̀ nípa àgbèrè àti panṣágà, ojú wo sì ni wọ́n fi wo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí?
6 Olúkúlùkù ẹni tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí ó ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, tí ó sì ti ṣe batisí, mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ka àgbèrè àti panṣágà léèwọ̀. (Tẹsalóníkà Kíní 4:1-3; Hébérù 13:4) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbà pé èyí tọ̀nà. Wọ́n fẹ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Síbẹ̀, ìwà pálapàla ń bá a lọ láti jẹ́ ọ̀kan lára ìdẹkùn Sátánì tí ó gbéṣẹ́ jù lọ. Èé ṣe?
7. Lórí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, báwo ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ṣe di ẹni tí ó kó wọnú ìwà tí wọ́n mọ̀ pé kò tọ̀nà?
7 Ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú irú ìwà pálapàla bẹ́ẹ̀ lè má wéwèé láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù. Sí àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí ìgbésí ayé nínú aginjù ti sú, ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn obìnrin Móábù àti Mídíánì tí ó ré wọ́n lọ lè jọ bí ọ̀rẹ́ àti ẹlẹ́mìí àlejò. Ṣùgbọ́n kí ní ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ́wọ́ gba ìkésíni láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń jọ́sìn Báálì dípò Jèhófà, àwọn ènìyàn tí ó yọ̀ǹda kí àwọn ọmọbìnrin wọ́n (àní láti inú àwọn ìdílé tí ó gbajúmọ̀ pàápàá) ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí kò fẹ́ wọn sílé? Nígbà tí àwọn ọkùnrin láti inú àgọ́ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í wo irú ìbákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó fani lọ́kàn mọ́ra, a ré wọ́n lọ sínú ṣíṣe ohun tí wọ́n mọ̀ pé kò dára, èyí sì ná wọn ní ìwàláàyè wọn.—Númérì 22:1; 25:1-15; 31:16; Ìṣípayá 2:14.
8. Ní ọjọ́ wa, kí ní lè sún Kristẹni kan sínú ìwà pálapàla?
8 Kí ní lè mú kí ẹnì kan kó sínú irú ìdẹkùn bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ wa? Bí ó tilẹ̀ lè mọ ewu tí ó wà nínú ìwà pálapàla, bí kò bá mọ ewu tí ó wà nínú ìdára-ẹni-lójú pẹ̀lú, ó lè bá ara rẹ̀ nínú ipò kan tí ìfẹ́ láti hùwà àìtọ́ ti lè borí ìrònú rẹ̀.—Òwe 7:6-9, 21, 22; 14:16.
9. Ìkìlọ̀ wo nínú Ìwé Mímọ́ ni ó lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ ìwà pálapàla?
9 Láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa láti má ṣe tan ara wa jẹ sínú ríronú pé a jẹ́ alágbára débi pé ẹgbẹ́ búburú kò ní lè bà wá jẹ́. Ìyẹn kan wíwo ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tí ó gbé ìgbésí ayé àwọn oníwà pálapàla yọ àti wíwo àwọn ìwé ìròyìn tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè. (Kọ́ríńtì Kíní 10:11, 12; 15:33) Àní kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa lábẹ́ àwọn ipò tí kò tọ̀nà lè ṣamọ̀nà sí ìṣòro ńlá pàápàá. Òòfà tí ó wà láàárín takọtabo lágbára púpọ̀. Nítorí náà, pẹ̀lú àníyàn onífẹ̀ẹ́, ètò àjọ Jèhófà ti kìlọ̀ nípa wíwà ní àwa nìkan àti níbi tí ojú kò tó pẹ̀lú ẹ̀yà kejì tí kì í ṣe alábàá-ṣègbéyàwó wa tàbí mẹ́ńbà ìdílé wa. Kí a baà lè máa bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ìdẹkùn ìdára-ẹni-lójú, kí a sì kọbi ara sí ìmọ̀ràn oníkìlọ̀ tí ó fún wa.—Orin Dáfídì 85:8.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Ènìyàn Nípa Lórí Rẹ
10. Báwo ni “ìbẹ̀rù ènìyàn” ṣe ń fa ìdẹkùn?
10 A fi ewu mìíràn hàn nínú Òwe 29:25 (NW), tí ó sọ pé: “Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn.” Ìdẹkùn ọdẹ sábà máa ń jẹ́ okùn tí ń fún ẹranko lọ́rùn pinpin tàbí okùn tí ń wé mọ́ ọn lẹ́sẹ̀. (Jóòbù 18:8-11) Lọ́nà kan náà, ìbẹ̀rù ènìyàn lè fún agbára ẹnì kan láti sọ̀rọ̀ fàlàlà, kí ó sì hùwà lọ́nà tí ó wu Ọlọ́run pa. Ìfẹ́ láti wu àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ìwà ẹ̀dá, àìbìkítà rárá nípa ohun tí àwọn ẹlòmíràn rò kì í ṣe ìwà Kristẹni. Ṣùgbọ́n, a ní láti wà déédéé. Nígbà tí àníyàn nípa ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìhùwàpadà àwọn ènìyàn míràn mú kí ẹnì kan ṣe ohun tí Ọlọ́run kà léèwọ̀, tàbí mú kí ó yẹra fún ṣíṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa láṣẹ, a ti dẹkùn mú ẹni náà.
11. (a) Kí ní lè yọ wá lọ́wọ́ jíjẹ́ kí ìbẹ̀rù ènìyàn nípa lórí ẹni? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń jà fitafita pẹ̀lú ìbẹ̀rù ènìyàn lọ́wọ́?
11 Ààbò sí irú ìdẹkùn bẹ́ẹ̀ ń bẹ nínú ‘gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà,’ kì í ṣe nínú ànímọ́ tí a dá mọ́ ènìyàn. (Òwe 29:25b, NW) Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó jẹ́ onítìjú pàápàá lè jẹ́ onígboyà àti adúróṣinṣin. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn pákáǹleke ti ètò àwọn nǹkan Sátánì yí bá ṣì yí wa ká, a óò ní láti wà lójúfò sí ìbẹ̀rù ènìyàn tí ń dẹkùn múni. Bí wòlíì Èlíjà tilẹ̀ jẹ́ ẹni tí ó ní àkọsílẹ̀ rere ní ti iṣẹ́ ìsìn onígboyà, nígbà tí Jésíbẹ́lì halẹ̀ mọ́ ọn láti pa á, ó sa lọ nítorí ìbẹ̀rù. (Àwọn Ọba Kìíní 19:2-18) Lábẹ́ pákáǹleke, àpọ́sítélì Pétérù fi ìbẹ̀rù sẹ́ pé òun mọ Jésù Kristi, ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó tún jẹ́ kí ìbẹ̀rù sún òun láti hùwà lọ́nà tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀nà ìgbàgbọ́. (Máàkù 14:66-71; Gálátíà 2:11, 12) Ṣùgbọ́n, Èlíjà àti Pétérù gba ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà, wọ́n ń bá a lọ láti sin Ọlọ́run lọ́nà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà.
12. Àwọn àpẹẹrẹ òde òní wo ni ó fi bí a ti ran àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti yẹra fún jíjẹ́ kí ìbẹ̀rù mú wọn lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ohun tí ó wu Ọlọ́run hàn?
12 Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà ní ọjọ́ wa pẹ̀lú ti kọ́ láti borí ìbẹ̀rù tí ń dẹkùn múni. Ọ̀dọ́langba Ẹlẹ́rìí kan ní Guyana jẹ́wọ́ pé: “Ní ilé ẹ̀kọ́, ìjàkadì láti dènà ipa tí àwọn ojúgbà ẹni ń ní lórí ẹni lágbára gan-an.” Ṣùgbọ́n, ó fi kún un pé: “Bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà lágbára gan-an.” Nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ fi ṣẹ̀sín níwájú gbogbo kíláàsì, nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ní ìdákọ́ńkọ́, ó fọgbọ́n jẹ́rìí fún olùkọ́ rẹ̀. Nígbà tí ó ṣèbẹ̀wò sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Benin, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń kọ́ nípa àwọn ohun tí Jèhófà béèrè, pinnu láti wá nǹkan ṣe sí ère kan tí bàbá rẹ̀ yá fún un. Ọ̀dọ́kùnrin náà mọ̀ pé ère náà kò lẹ́mìí, kò sì bẹ̀rù rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé àwọn ará abúlé tí inú ń bí lè wá ọ̀nà láti pa òun. Ó gbàdúrà sí Jèhófà, lẹ́yìn náà, ní alẹ́, ó gbé ère náà lọ sínú igbó, ó sì sọ ọ́ nù. (Fi wé Àwọn Onídàájọ́ 6:27-31.) Nígbà tí obìnrin kan ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Dominican bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà, ọkọ rẹ̀ pàṣẹ pé kí ó yàn láàárín òun àti Jèhófà. Ọkùnrin náà halẹ̀ mọ́ ọn pé òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ìbẹ̀rù yóò ha mú kí ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bí? Obìnrin náà fèsì pé: “Bí ó bá jẹ́ pé panṣágà ni mo ṣe, ojú yóò tì mí, ṣùgbọ́n sísin Jèhófà Ọlọ́run kò tì mí lójú!” Ó ń bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn, nígbà tí ó yá, ọkọ rẹ̀ sì dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà. Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pátápátá nínú Bàbá wa ọ̀run, àwa pẹ̀lú lè yẹra fún jíjẹ́ kí ìbẹ̀rù ènìyàn mú kí a lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ohun tí a mọ̀ pé yóò dùn mọ́ Jèhófà nínú.
Yẹra fún Fífojú Tín-ínrín Ìmọ̀ràn
13. Ìdẹkùn wo ni Tímótì Kíní 6:9 kì wá nílọ̀ rẹ̀?
13 Bí a tilẹ̀ ṣe díẹ̀ nínú àwọn ìdẹkùn tí àwọn ọdẹ ń lò láti mú ẹranko èyíkéyìí tí ó bá ṣèèṣì gba ibì kan kọjá, àwọn ìdẹkùn míràn ń fa àwọn ẹranko mọ́ra nípasẹ̀ àwọn ìdẹ tí ó wọni lójú. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, bí ọrọ̀ ti rí nìyẹn. (Mátíù 13:22) Ní Tímótì Kíní 6:8, 9, Bíbélì rọ̀ wá láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun ìgbẹ́mìíró àti ìbora. Lẹ́yìn náà, ó kìlọ̀ pé: “Àwọn wọnnì tí wọ́n [pinnu] láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ àwọn ìfẹ́ ọkàn òpònú àti aṣenilọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ìrunbàjẹ́.”
14. (a) Kí ní lè mú kí ẹnì kan má fi ìmọ̀ràn jíjẹ́ kí ohun ìgbẹ́mìíró àti ìbora tẹ́ òun lọ́rùn sílò? (b) Báwo ni àṣìlóye ọrọ̀ ṣe lè mú kí ẹnì kan fojú tín-ínrín ìkìlọ̀ tí a ṣàkọsílẹ̀ nínú Tímótì Kíní 6:9? (d) Ní ọ̀nà wo ni “ìfẹ́ ọkàn ti ojú” lè gbà fọ́ àwọn kan lójú sí ìdẹkùn tí a dẹ dè wọ́n?
14 Láìka ìkìlọ̀ yí sí, ọ̀pọ̀ ń kó sínú ìdẹkùn nítorí wọn kò mú ìmọ̀ràn náà bá ipò wọn mu. Èé ṣe? Ó ha lè jẹ́ pé ìgbéraga sún wọn sí rírinkinkin mọ́ rírọ̀ mọ́ ọ̀nà ìgbésí ayé kan tí ń béèrè fún ohun tí ó ju “ohun ìgbẹ́mìíró àti ìbora,” tí Bíbélì rọ̀ wá pé kí a jẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn? Ó ha lè jẹ́ pé wọ́n fojú tín-ínrín ìkìlọ̀ Bíbélì náà nítorí ohun tí àwọn olówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ kó jọ ni wọ́n kà sí ọrọ̀? Bíbélì wulẹ̀ fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ìpinnu láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ àti níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun ìgbẹ́mìíró àti ìbora. (Fi wé Hébérù 13:5.) “Ìfẹ́ ọkàn ti ojú”—ìfẹ́ ọkàn láti ní àwọn ohun tí wọ́n rí sójú, àní tí ó bá béèrè fún fífi ìlépa tẹ̀mí rúbọ pàápàá—ha ń mú kí wọ́n ti ire ìjọsìn tòótọ́ sípò kejì bí? (Jòhánù Kíní 2:15-17; Hágáì 1:2-8) Ẹ wo bí àwọn tí ó kọbi ara ní tòótọ́ sí ìmọ̀ràn Bíbélì náà, tí wọ́n sì ń bá Ọlọ́run rìn nípa fífi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe àníyàn àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn ti jẹ́ aláyọ̀ tó!
Ṣíṣàṣeyọrí Nínú Kíkojú Àwọn Àníyàn Ìgbésí Ayé
15. Lọ́nà tí ó yéni, àwọn ipò wo ní ń fa àníyàn fún ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn Jèhófà, ìdẹkùn wo sì ni a gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí nígbà tí a bá wà lábẹ́ irú pákáǹleke bẹ́ẹ̀?
15 Ohun tí ó wọ́pọ̀ ju ìpinnu láti di ọlọ́rọ̀ ni àníyàn nípa rírí àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbé ìgbésí ayé pẹ̀lú àwọn ohun ìní tí kò tó nǹkan. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára fún ọ̀pọ̀ wákàtí àní láti lè rí aṣọ wọ̀ sára, láti rí ibi tí ìdílé wọn yóò sùn sí lálẹ́, àti láti rí oúnjẹ díẹ̀ fún ọjọ́ náà. Àwọn mìíràn ń bá ìṣòro yí nítorí àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó tiwọn tàbí ti àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn. Ẹ wo bí ó ti rọrùn tó láti jẹ́ kí irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ fún ire tẹ̀mí pa nínú ìgbésí ayé wọn!—Mátíù 13:22.
16. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn pákáǹleke inú ìgbésí ayé?
16 Tìfẹ́tìfẹ́, Jèhófà sọ fún wa nípa ìtura tí a óò gbádùn lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà náà. (Orin Dáfídì 72:1-4, 16; Aísáyà 25:7, 8) Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn pákáǹleke inú ìgbésí ayé nísinsìnyí nípa fífún wa ní ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè gbájú mọ́ àwọn ohun àkọ́múṣe wa. (Mátíù 4:4; 6:25-34) Nípasẹ̀ àwọn àkọsílẹ̀ bí ó ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ìgbà àtijọ́, Jèhófà ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Jeremáyà 37:21; Jákọ́bù 5:11) Ó ń ki wá láyà pẹ̀lú ìmọ̀ náà pé, láìka làásìgbò èyíkéyìí tí ó lè dé bá wa sí, ìfẹ́ tí ó ní fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin kì í yẹ̀. (Róòmù 8:35-39) Sí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó polongo pé: “Dájúdájú èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5.
17. Fúnni ní àpẹẹrẹ bí ó ti ṣeé ṣe fún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n wà lábẹ́ làásìgbò láti máa bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn.
17 Ní gbígba okun láti inú ìmọ̀ yí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn dípò yíyí pa dà sí ọ̀nà ayé. Ọgbọ́n èrò orí ayé kan tí ó gbajúmọ̀ láàárín àwọn òtòṣì ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ni pé mímú nǹkan ẹni tí ó ní ohun púpọ̀, kí o baà lè bọ́ ìdílé rẹ, kì í ṣe olè jíjà. Ṣùgbọ́n, àwọn tí ń rìn nípa ìgbàgbọ́ kọ irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀. Wọ́n ka ojú rere Ọlọ́run sí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju gbogbo ohun yòó kù lọ, wọ́n sì ń wo ojú rẹ̀ láti san èrè ìwà àìlábòsí wọn fún wọn. (Òwe 30:8, 9; Kọ́ríńtì Kíní 10:13; Hébérù 13:18) Opó kan ní Íńdíà rí i pé mímúratán láti ṣiṣẹ́ àti mímọwọ́ọ́yípadà ran òun lọ́wọ́ láti gbọ́ bùkátà òun. Dípò jíjẹ́ kí ipò rẹ̀ nínú ìgbésí ayé mú un bínú, ó mọ̀ pé, bí òun bá fi Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé òun, Jèhófà yóò bù kún ìsapá òun láti rí àwọn ohun kòṣeémánìí fún ara òun àti ọmọkùnrin òun. (Mátíù 6:33, 34) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún kárí ayé fi hàn pé, láìka làásìgbò tí ó lè dojú kọ wọ́n sí, Jèhófà ni ibi ìsádi àti ibi odi agbára wọn. (Orin Dáfídì 91:2) Ìyẹn ha jẹ́ òtítọ́ nípa rẹ bí?
18. Kí ni àṣírí yíyẹra fún àwọn ìdẹkùn ayé Sátánì?
18 Níwọ̀n tí a bá ṣì ń gbé nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí, àwọn ìdẹkùn yóò máa wà tí a óò ní láti yẹra fún. (Jòhánù Kíní 5:19) Bíbélì fi ìwọ̀nyí hàn, ó sì fi bí a óò ṣe yẹra fún wọn hàn wá. Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nítòótọ́, tí wọ́n sì ní ìbẹ̀rù gbígbámúṣé ti ṣíṣàìfẹ́ ṣe ohun tí kò dùn mọ́ ọn nínú, lè ṣàṣeyọrí nínú kíkojú irú àwọn ìdẹkùn bẹ́ẹ̀. Bí wọ́n bá ń “rìn nípa ẹ̀mí,” wọn kì yóò ṣubú sínú àwọn ọ̀nà ayé. (Gálátíà 5:16-25) Fún gbogbo àwọn tí wọ́n gbé ìgbésí ayé wọ́n ka ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà, ìfojúsọ́nà ológo ti bíbá Ọlọ́run rìn, ní gbígbádùn ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ títí láé, ń bẹ níwájú wọn.—Orin Dáfídì 25:14.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Báwo ni ìdára-ẹni-lójú ṣe lè jẹ́ ìdẹkùn?
◻ Kí ní lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ jíjẹ́ kí ìbẹ̀rù ènìyàn nípa lórí wa?
◻ Kí ní lè mú kí a kùnà láti fi ìmọ̀ràn lórí ewu lílépa ọrọ̀ sílò?
◻ Kí ní lè mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti yẹra fún jíjẹ́ kí àwọn àníyàn ìgbésí ayé dẹkùn mú wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ọ̀pọ̀ ń bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn