ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 5/15 ojú ìwé 15-20
  • Máa Rìn Ní Ọ̀nà Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Rìn Ní Ọ̀nà Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjẹ́pàtàkì Ìgbẹ́kẹ̀lé àti Ìdúróṣinṣin
  • Ìrànlọ́wọ́ Nínú Rírìn ní Ọ̀nà Ọlọ́run
  • Ìpinnu
  • ‘Ọlọ́run Wà fún Wa’
  • Ṣé Wàá Bá Ọlọ́run Rìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Bíbá Ọlọ́run Rìn—Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́, Má Ṣe Rìn Nípa Ohun Tó O Lè Fojú Rí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Bíbá Ọlọ́run Rìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 5/15 ojú ìwé 15-20

Máa Rìn Ní Ọ̀nà Jèhófà

“Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé.”—SÁÀMÙ 37:34.

1, 2. Kí ni rírìn ní ọ̀nà Jèhófà wé mọ́ fún Ọba Dáfídì, kí sì ni èyí ń béèrè lọ́wọ́ wa lónìí?

“MÚ MI mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí n máa rìn, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.” (Sáàmù 143:8) Àwọn Kristẹni lónìí ń fi tọkàntọkàn sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní àsọtúnsọ. Tọkàntara ni wọ́n fi ń fẹ́ láti wu Jèhófà, kí wọ́n sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Kí ni èyí wé mọ́? Ní ti Dáfídì, ó túmọ̀ sí pípa òfin Ọlọ́run mọ́. Ó wé mọ́ gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà dípò gbígbẹ́kẹ̀lé ìmùlẹ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè. Bẹ́ẹ̀ ni, ó túmọ̀ sí fífi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà, kì í ṣe sísin àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn tí ń bẹ lágbègbè wa. Ní ti àwọn Kristẹni, rírìn ní ọ̀nà Jèhófà wé mọ́ ohun tó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

2 Lápá kan, rírìn ní ọ̀nà Jèhófà lónìí túmọ̀ sí lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, gbígbà pé òun ní “ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” (Jòhánù 3:16; 14:6; Hébérù 5:9) Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó tún túmọ̀ sí pípa “òfin Kristi” mọ́, èyí tó ní nínú, fífi ìfẹ́ hàn sí ara wa, pàápàá sí àwọn arákùnrin Kristi ẹni àmì òróró. (Gálátíà 6:2; Mátíù 25:34-40) Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà fẹ́ràn àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀. (Sáàmù 119:97; Òwe 4:5, 6) Wọ́n ń fojú ribiribi wo àǹfààní ṣíṣeyebíye ti kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. (Kólósè 4:17; 2 Tímótì 4:5) Àdúrà gbígbà déédéé jẹ́ apá kan ìgbésí ayé wọn. (Róòmù 12:12) Wọ́n sì ‘máa ń ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí wọ́n ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n.’ (Éfésù 5:15) Dájúdájú, wọn kì í fi ọrọ̀ tẹ̀mí rúbọ nítorí àwọn nǹkan ti ara tí kì í tọ́jọ́, tàbí nítorí afẹ́ ayé. (Mátíù 6:19, 20; 1 Jòhánù 2:15-17) Síwájú sí i, ìdúróṣinṣin ti Jèhófà àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ ṣe kókó. (2 Kọ́ríńtì 1:9; 10:5; Éfésù 4:24) Èé ṣe? Nítorí ipò tí a wà lóde òní kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti Ísírẹ́lì ìgbàanì.

Ìjẹ́pàtàkì Ìgbẹ́kẹ̀lé àti Ìdúróṣinṣin

3. Èé ṣe tí ìdúróṣinṣin, ìgbàgbọ́, àti ìgbẹ́kẹ̀lé yóò fi ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn nìṣó ní ọ̀nà Jèhófà?

3 Ísírẹ́lì jẹ́ orílẹ̀-èdè kékeré táwọn ọ̀tá yí ká, àwọn ọ̀tá tí ń ṣe àwọn àṣeyẹ oníwàkiwà nígbà tí wọ́n bá ń bọ àwọn òrìṣà wọn. (1 Kíróníkà 16:26) Ísírẹ́lì nìkan ló ń sin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo tí a kò lè rí, ó sì béèrè pé kí wọ́n fọwọ́ dan-in dan-in mú ọ̀ràn ìwà rere. (Diutarónómì 6:4) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, ìwọ̀nba mílíọ̀nù díẹ̀ lára ẹ̀dá ènìyàn ló ń sin Jèhófà, wọ́n sì ń gbé láàárín àwọn èèyàn ayé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́fà, àwọn èèyàn tí ọ̀pá ìdiwọ̀n wọn àti ojú ìwòye wọn nípa ẹ̀sìn yàtọ̀ gédégédé sí tiwọn. Báa bá wà lára mílíọ̀nù kéréje yìí, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí wọ́n má bàa mú wa tọ ọ̀nà búburú. Lọ́nà wo? Ìdúróṣinṣin ti Jèhófà Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àti ìgbẹ́kẹ̀lé láìmikàn pé òun yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ yóò ṣèrànwọ́. (Hébérù 11:6) Èyí kò ní jẹ́ kí a gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ohun tí ayé fi ṣe àgbẹ́kẹ̀lé wọn.—Òwe 20:22; 1 Tímótì 6:17.

4. Èé ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi wà “nínú òkùnkùn ní ti èrò orí”?

4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn bó ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni yàtọ̀ sí ayé tó, nígbà tó kọ̀wé pé: “Nítorí náà, èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí sí nínú Olúwa, pé kí ẹ má ṣe máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn, bí wọ́n ti wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, nítorí àìmọ̀kan tí ń bẹ nínú wọn, nítorí yíyigbì ọkàn-àyà wọn.” (Éfésù 4:17, 18) Jésù ni “ìmọ́lẹ̀ tòótọ́.” (Jòhánù 1:9) Ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tàbí tó sọ pé òun gbà á gbọ́ ṣùgbọ́n tí kò ṣègbọràn sí “òfin Kristi” wà “nínú òkùnkùn ní ti èrò orí.” Ní ìyàtọ̀ gédégédé sí rírìn ní ọ̀nà Jèhófà, wọ́n ti “di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run.” Bó ti wù kí wọ́n rò pé àwọn lọ́gbọ́n ayé tó, ‘wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan’ nípa ìmọ̀ kan ṣoṣo tí ń sini lọ sí ìyè, ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi.—Jòhánù 17:3; 1 Kọ́ríńtì 3:19.

5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń ràn kárí ayé, èé ṣe tí ọkàn-àyà ọ̀pọ̀ èèyàn fi gíràn-án?

5 Síbẹ̀síbẹ̀ náà, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ rèé tí ń ràn kárí ayé! (Sáàmù 43:3; Fílípì 2:15) “Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké sókè ní ojú pópó gan-an.” (Òwe 1:20) Lọ́dún tó kọjá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo wákàtí tó pọ̀ ju bílíọ̀nù kan lẹ́nu sísọ fún àwọn aládùúgbò wọn nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. Ẹgbẹẹgbàárùn-ún ló ní etí ìgbọ́ àti àyà ìgbàṣe. Ṣùgbọ́n, ṣé ó wá yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ àwọn yòókù kọ etí ikún sí i? Rárá o. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “yíyigbì ọkàn-àyà wọn.” Ọkàn-àyà àwọn kan ti gíràn-án nítorí ìmọtara-ẹni-nìkan tàbí nítorí ìfẹ́ owó. Ẹ̀sìn èké tàbí ojú ìwòye pé ẹ̀sìn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, tó tàn kálẹ̀ lónìí ti nípa lórí àwọn mìíràn. Àwọn ìrírí lílekoko nínú ìgbésí ayé ti mú kí àwọn kan kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Àwọn mìíràn kọ̀ láti dé ojú ìlà ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere gíga ti Jèhófà. (Jòhánù 3:20) Ǹjẹ́ ọkàn-àyà ẹnì kan tí ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà ha lè yigbì ní irú àwọn ọ̀nà táa mẹ́nu kàn wọ̀nyí bí?

6, 7. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tilẹ̀ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà, kí ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú wọn ṣáko lọ, èé sì ti ṣe?

6 Èyí ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì ìgbàanì, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti fi hàn. Ó kọ̀wé pé: “Nǹkan wọ̀nyí di àpẹẹrẹ fún wa, kí àwa má bàa jẹ́ ẹni tí ń ní ìfẹ́-ọkàn sí àwọn ohun tí ń ṣeni léṣe, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe ní ìfẹ́-ọkàn sí wọn. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe; gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣe ìwà hù, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe àgbèrè, kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.”—1 Kọ́ríńtì 10:6-8.

7 Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ tọ́ka sí ìgbà tí Ísírẹ́lì jọ́sìn ère ọmọ màlúù oníwúrà ní ẹsẹ̀ Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 32:5, 6) Èyí jẹ́ àìgbọràn ní tààràtà sí àṣẹ Ọlọ́run tí wọ́n ṣàdéhùn pé àwọn yóò ṣègbọràn sí níwọ̀nba ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. (Ẹ́kísódù 20:4-6; 24:3) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù wá tọ́ka sí àkókò tí Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọbìnrin Móábù tẹrí ba fún Báálì. (Númérì 25:1-9) Ìjọsìn ọmọ màlúù kún fún ìkẹ́ra ẹni bàjẹ́ tó bùáyà, ‘gbígbádùn ara ẹni.’a Ìjọsìn Báálì máa ń kún fún ìṣekúṣe tó ré kọjá ààlà. (Ìṣípayá 2:14) Èé ṣe táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi dá ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ti jẹ́ kí ọkàn-àyà wọn di èyí tí “ń ní ìfẹ́-ọkàn sí àwọn ohun tí ń ṣeni léṣe”—ì báà jẹ́ ìbọ̀rìṣà tàbí àwọn ìwà pálapàla tí ń bá a rìn.

8. Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ìrírí Ísírẹ́lì?

8 Pọ́ọ̀lù sọ pé ó yẹ kí a kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n nínú ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́? Kò ṣeé ronú kàn, pé Kristẹni kan yóò bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún ère ọmọ màlúù oníwúrà tàbí ọlọ́run Móábù ìgbàanì. Ṣùgbọ́n ìṣekúṣe àti ìkẹ́ra ẹni bàjẹ́ ńkọ́? Ìwọ̀nyí wọ́pọ̀ lónìí, báa bá sì gbà kí ìfẹ́ fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dàgbà nínú ọkàn-àyà wa, wọn yóò yà wá nípa sí Jèhófà. Àbájáde rẹ̀ kò ní yàtọ̀ sí lílọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà—yóò sì sọ wá di ọ̀tá Ọlọ́run. (Fi wé Kólósè 3:5; Fílípì 3:19.) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kádìí ìjíròrò rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn nípa gbígba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.”—1 Kọ́ríńtì 10:14.

Ìrànlọ́wọ́ Nínú Rírìn ní Ọ̀nà Ọlọ́run

9. (a) Ìrànlọ́wọ́ wo la ní, láti lè máa rìn nìṣó ní ọ̀nà Jèhófà? (b) Kí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà táa fi ń gbọ́ ‘ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wa’?

9 Báa bá ti pinnu pé a óò máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà, ìrànlọ́wọ́ ń bẹ. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísáyà 30:21) Báwo ni ‘etí wa’ ṣe ń gbọ́ ‘ọ̀rọ̀ yẹn lẹ́yìn wa’? Tóò, kò sẹ́nikẹ́ni lónìí tí ń gbọ́ ohùn Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́nikẹ́ni tó ń rí iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. “Ọ̀rọ̀” táa ń gbọ́ ń dé ọ̀dọ̀ gbogbo wa lọ́nà kan náà. Lákọ̀ọ́kọ́, ó máa ń wá nípasẹ̀ Bíbélì, Ìwé Mímọ́ táa mí sí, èyí tó ní èrò Ọlọ́run nínú, tó sì tún jẹ́ àkọsílẹ̀ bó ṣe bá àwọn ènìyàn lò. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ojoojúmọ́ ayé la ń gbọ́ ìgbékèéyíde tí ń jáde látẹnu àwọn tó ti “di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run,” fún ìlera wa nípa tẹ̀mí, ó pọndandan pé kí a máa ka Bíbélì, kí a sì máa ṣàṣàrò lé e lórí déédéé. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún àwọn “ohun asán,” kí a sì di ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (Ìṣe 14:14, 15; 2 Tímótì 3:16, 17) Yóò fún wa lókun, yóò sọ agbára wa dọ̀tun, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti ‘mú kí ọ̀nà wa yọrí sí rere.’ (Jóṣúà 1:7, 8) Ìdí nìyí tí Ọ̀rọ̀ Jèhófà fi rọ̀ wá pé: “Wàyí o, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi; bẹ́ẹ̀ ni, àní aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ọ̀nà mi mọ́. Ẹ fetí sí ìbáwí kí ẹ sì di ọlọ́gbọ́n, ẹ má sì fi ìwà àìnáání èyíkéyìí hàn.”—Òwe 8:32, 33.

10. Kí ni ọ̀nà kejì táa fi ń gbọ́ ‘ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wa’?

10 ‘Ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wa’ tún máa ń wá nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tí ń pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’ (Mátíù 24:45-47) Ọ̀nà kan táa fi ń rí ìpèsè oúnjẹ yìí ni nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì, oúnjẹ ọ̀hún sì kúnlé-kúnnà lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti mú kí òye wa gún régé sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀. Nínú ìwé ìròyìn yìí, a ti fún wa ní ìṣírí láti máa forí tì í nìṣó nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn láìka ìwà àgunlá sí, a ti ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún jíjìn sọ́fìn, a sì ti rọ̀ wá láti mú àwọn ànímọ́ rere ti Kristẹni dàgbà. A mà mọyì irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ táa ń pèsè ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu o!

11. Ṣàlàyé ọ̀nà kẹta táa fi lè gbọ́ ‘ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wa.’

11 Ẹrú olóòótọ́ àti olóye tún ń pèsè oúnjẹ nípasẹ̀ àwọn ìpàdé táa ń ṣe déédéé. Lára ìwọ̀nyí ni àwọn ìpàdé ìjọ àdúgbò, àwọn ìpàdé tí àwa táa wà láyìíká kan náà ń ṣe lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, àtàwọn àpéjọpọ̀ ńlá táa ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Kristẹni olóòótọ́ wo ni kò mọrírì irú àwọn àpéjọ bẹ́ẹ̀? Wọ́n jẹ́ ìrànlọ́wọ́ tí kò ṣeé má nìí, tí ń tì wá lẹ́yìn láti máa rìn nìṣó ní ọ̀nà Jèhófà. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ti ń lo àkókò púpọ̀ níbi iṣẹ́ tàbí ní iléèwé ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wọn, ìfararora pẹ̀lú àwọn Kristẹni ń gbẹ̀mí là ní ti gidi. Àwọn ìpàdé ń fún wa láǹfààní “láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Hébérù 10:24) A nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, a sì fẹ́ láti máa bá wọn kẹ́gbẹ́.—Sáàmù 133:1.

12. Ìpinnu wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe, báwo sì ni wọ́n ṣe gbé èyí jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí?

12 Iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà ló ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà lónìí nítorí pé irú oúnjẹ tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ń fún wọn lókun, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti lè mọ báwọn náà ṣe lè máa rìn ní ọ̀nà yẹn. Ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àárẹ̀ ha bá wọn nítorí pé wọ́n kéré níye ní ìfiwéra pẹ̀lú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tó wà lórí ilẹ̀ ayé? Kí a má rí i! Wọ́n ti pinnu pé àwọn yóò máa fetí sí ‘ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wọn,’ wọn yóò máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà láìyẹsẹ̀. Láti sọ fáyé gbọ́ pé ìpinnu wọn rèé lóòótọ́, ní Àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè àti ti Àgbáyé tí wọ́n ṣe lọ́dún 1998 sí 1999, tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,” àwọn tó wá sí àpéjọpọ̀ náà tẹ́wọ́ gba ìpinnu kan tó fi ìdúró àtọkànwá wọn hàn. Ọ̀rọ̀ inú ìpinnu náà ló tẹ̀ lé e yìí.

Ìpinnu

13, 14. Ojú ìwòye wo tó jẹ́ òótọ́ nípa ipò nǹkan nínú ayé ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní?

13 “Àwa, gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó péjọ sí Àpéjọpọ̀ ‘Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,’ fi tọkàntọkàn gbà pé ọ̀nà Ọlọ́run ni ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ. Àmọ́ ṣá o, a mọ̀ pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú aráyé lónìí kò gbà bẹ́ẹ̀. Àwọn ènìyàn ti ṣe ìfidánrawò àìmọye èròǹgbà, àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí, àti onírúurú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn nípa ohun tó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ. Ká sòótọ́, ìtàn ènìyàn àti àwọn ipò ayé lónìí jẹ́rìí sí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú Jeremáyà 10:23 pé: ‘Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.’

14 “Ojoojúmọ́ là ń rí ẹ̀rí púpọ̀ sí i tí ń fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwùjọ ènìyàn ní ń dágunlá sí ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn èèyàn kàn ń lépa ohun tó bá dára lójú tiwọn ni. Àbájáde rẹ̀ mà burú o—ìdílé ń tú ká, láìsí ìtọ́sọ́nà fún àwọn ọmọdé; fífi gbogbo ìgbésí ayé ẹni lépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tí ń yọrí sí ìmúlẹ̀mófo àti ìjákulẹ̀; ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá tó burú jáì, tó ti gbẹ̀mí àìmọye ènìyàn; àwọn rògbòdìyàn àti ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, tó ti fa ìpakúpa tìrìgàngàn; ìwà ìṣekúṣe tó gbalẹ̀ kan, tí ń fa àjàkálẹ̀ àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré. Ká kàn mẹ́nu kan díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìṣòro apinnilẹ́mìí tí ń ṣèdíwọ́ fún lílépa ayọ̀, àlàáfíà, àti ààbò.

15, 16. Ní ti ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́, èrò àtọkànwá wo la gbé jáde nínú ìpinnu náà?

15 “Nítorí ipò ìbànújẹ́ tí aráyé wà yìí àti nítorí pé “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tí a ń pè ní Amágẹ́dọ́nì (Ìṣípayá 16:14, 16) ti sún mọ́lé gírígírí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pinnu pé:

16 “Ení: A gbà pé ti Jèhófà Ọlọ́run ni àwa í ṣe, níwọ̀n bí olúkúlùkù wa ti ya ara wa sí mímọ́ fún un láìkù síbì kan, a ó sì máa bá a lọ láti ní ìgbàgbọ́ tí kò ṣeé mì nínú ìràpadà tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. A ti pinnu láti máa rìn ní ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́, a óò máa sìn ín gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀, a óò sì fi ara wa sábẹ́ ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ tí ìṣàkóso Jésù Kristi ń ṣojú fún.

17, 18. Ipò wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò máa bá a lọ láti dì mú ní ti ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere àti nípa ẹgbẹ́ àwọn ará ti Kristẹni?

17 “Èjì: A óò máa bá a lọ láti rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga inú Bíbélì nípa ìwà rere àti nípa tẹ̀mí. A ti pinnu láti yàgò fún rírìn bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn. (Éfésù 4:17-19) Ìpinnu wa ni láti wà ní mímọ́ tónítóní níwájú Jèhófà àti láìní èérí nínú ayé yìí.—Jákọ́bù 1:27.

18 “Ẹ̀ta: A ó rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ipò tí a ti dì mú ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará Kristẹni kárí ayé. A ò ní yẹsẹ̀ kúrò nínú ìdúró àìdásí tọ̀tún tòsì tí àwọn Kristẹni mú láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, a ò ní jẹ́ bá wọn lọ́wọ́ sí ìkórìíra tàbí aáwọ̀ láàárín ẹ̀yà tàbí ìran tàbí orílẹ̀-èdè.

19, 20. (a) Kí ni àwọn Kristẹni òbí yóò máa ṣe? (b) Báwo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ yóò ṣe máa bá a lọ láti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi?

19 “Ẹ̀rin: Àwa táa jẹ́ òbí yóò gbin ọ̀nà Ọlọ́run sínú àwọn ọmọ wa. A óò máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni, èyí tí ó ní nínú, kíka Bíbélì déédéé, ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àti fífi tọkàntọkàn nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò ìjọ Kristẹni àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.

20 “Àrún: Gbogbo wa yóò máa sapá láti mú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí Ẹlẹ́dàá wa ti fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀ dàgbà, a ó sì máa sapá láti fara wé àkópọ̀ ìwà rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Éfésù 5:1) A ti pinnu láti jẹ́ kí gbogbo ohun tí a bá ń ṣe máa jẹ́ nínú ìfẹ́, a ó sì tipa báyìí máa fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi.—Jòhánù 13:35.

21-23. Kí ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò máa bá a lọ láti ṣe, kí sì ni ó dá wọn lójú?

21 “Ẹ̀fà: Láìdáwọ́ dúró, a óò máa bá a lọ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti láti sọni di ọmọlẹ́yìn, a ó sì máa kọ́ wọn ní ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́, a ó sì máa fún wọn níṣìírí láti máa wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ sí i nínú àwọn ìpàdé ìjọ.—Mátíù 24:14; 28:19, 20; Hébérù 10:24, 25.

22 “Èje: Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ètò ẹ̀sìn, a óò máa bá a lọ láti fi ohun tí Ọlọ́run fẹ́ sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa. Báa ti ń lo Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí atọ́nà wa, a ò ní yà sọ́tùn-ún tàbí sósì, a ó sì tipa báyìí fi hàn gbangba pé ọ̀nà Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju àwọn ọ̀nà ayé. A ti pinnu láti máa tọ ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́—láìyẹsẹ̀ àti láìmikàn, nísinsìnyí àti títí láé!

23 “A ṣe ìpinnu yìí nítorí pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìlérí onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ṣe pé ẹni tó bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé. A ṣe ìpinnu yìí nítorí pé ó dá wa lójú pé gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà, ìmọ̀ràn, àti ìṣílétí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ lónìí, ó sì fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ọjọ́ iwájú, kí a lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí. (1 Tímótì 6:19; 2 Tímótì 4:7b, 8) Lékè gbogbo rẹ̀, a ṣe ìpinnu yìí nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa, èrò inú wa, àti okun wa!

24, 25. Báwo ni a ṣe dáhùn sí ìpinnu táa gbé kalẹ̀ náà, kí sì ni àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà ti pinnu láti ṣe?

24 “Ẹ jọ̀wọ́, kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ yìí, tí ẹ sì fara mọ́ ìpinnu yìí, sọ pé BẸ́Ẹ̀ NI!”

25 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún pápá ìṣiré kárí ayé ni ohùn àwọn èèyàn tó pé jọ mì tìtì, bí wọ́n ti dáhùn ní ohùn rara pé “BẸ́Ẹ̀ NI!” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ṣiyèméjì rárá pé àwọn yóò máa bá a lọ ní rírìn ní ọ̀nà Jèhófà. Wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ pé òun yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Wọ́n dúró tì í gbágbáágbá, láìka ohun yòówù tó lè dé sí. Wọn sì ti pinnu láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nìṣó.

‘Ọlọ́run Wà fún Wa’

26. Kí ni ipò ayọ̀ tí àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà wà?

26 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rántí ọ̀rọ̀ ìyànjú onísáàmù náà tó sọ pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:34) Wọn ò jẹ́ gbàgbé ọ̀rọ̀ ìṣírí Pọ́ọ̀lù pé: “Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa? Ẹni tí kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa, èé ṣe tí òun kò ní tún fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀?” (Róòmù 8:31, 32) Bẹ́ẹ̀ ni, báa bá ń bá a lọ ní rírìn ní ọ̀nà Jèhófà, yóò “pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.” (1 Tímótì 6:17) Ibòmíràn wo ló tún dára ju ibi táa wà yìí—rírìn ní ọ̀nà Jèhófà, ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n. Níwọ̀n bí Jèhófà ti dúró tì wá, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti dúró síbẹ̀, kí a sì fara dà á títí dé òpin, nínú ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé ní àkókò títọ́ lójú rẹ̀, ojú wa ni yóò ṣe nígbà tó bá mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ láìku ẹyọ kan.—Títù 1:2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni alálàyé kan ń ṣàlàyé nípa ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa tú sí “gbádùn ara wọn” níhìn-ín, ó sọ pé ó tọ́ka sí àwọn ijó tí wọ́n máa ń jó níbi ayẹyẹ àwọn abọ̀rìṣà, ó wá fi kún un pé: “Ohun tí gbogbo èèyàn mọ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ irú ijó bẹ́ẹ̀ ni a pète ní tààràtà láti fi ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó burú jáì sókè.”

Ǹjẹ́ O Rántí?

◻ Kí la ń béèrè lọ́wọ́ Kristẹni tó bá fẹ́ máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà?

◻ Èé ṣe tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì dúró ṣinṣin tì í?

◻ Ìrànlọ́wọ́ wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa báa ti ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà?

◻ Mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì-pàtàkì tó wà nínú ìpinnu táa tẹ́wọ́ gbà níbi àwọn Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

A tẹ́wọ́ gba ìpinnu pàtàkì kan níbi Àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè àti ti Àgbáyé náà, “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́