Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Moore?
IṢẸ́ abẹ eegun ẹ̀yìn ló mú kí Harley pààrọ̀ iṣẹ́ rẹ̀ lọ́ràn-anyàn láti oníṣẹ́ ẹ̀rọ sí akọ̀wé ọ́fíìsì. Nígbà tí a béèrè ìmọ̀lára rẹ̀ nípa ìyípadà yìí, Harley sọ pé: “Mo mọ àìṣiṣẹ́-nídìí-ẹ̀rọ yìí lára. Ṣùgbọ́n ní tòótọ́, mo láyọ̀ nídìí iṣẹ́ mi ìsinsìnyí ju tàtijọ́ lọ.”
Nígbà tí Harley ń sọ ìdí tó fi ní ìtẹ́lọ́rùn, ó sọ pé: “Ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ ló fà á. Láìdàbí àwọn tó wà níbi iṣẹ́ mi àtijọ́, alábòójútó iṣẹ́ mi lọ́wọ́lọ́wọ́ àti àwọn alájùmọ̀ṣiṣẹ́ mi mọrírì ohun tí mo ń ṣe, wọn kì í sì í lọ́ra láti gbóríyìn fún mi. Èyí ti mú ìyàtọ̀ ńláǹlà kan wá.” Nítorí pé Harley nímọ̀lára pé òun wúlò, a sì nílò òun, ó jẹ́ òṣìṣẹ́ aláyọ̀ báyìí.
Àwọn ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn tàbí ìmoore, nígbà tó bá tọ́, ń múni lọ́kàn yọ̀ ní ti gidi. Ní ìdà kejì, ipa tí àìmoore ń ní lè máa wọni lára gan-an bí Shakespeare ṣe sọ pé: “Máa fẹ́, máa fẹ́, ìwọ afẹ́fẹ́ ìgbà òtútù, o kò wọni lára tó àìmoore ẹ̀dá ènìyàn.” Ó dunni pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ti hu ìwà àìmoore sí.
Yẹra fún Ìwà Àìmoore
Àwọn àfihàn ìmoore àtọkànwá ń pòórá nínú ayé òde òní. Bí àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé kan béèrè ìbéèrè náà pé: “Bí ìyàwó ọ̀nà kan bá ráyè kọ àdírẹ́sì 200 ènìyàn sára ìwé ìpeni síbi àsè ìgbéyàwó, èé ṣe tí kò fi ní ráyè kọ ìwé ìdúpẹ́ fún 163 ẹ̀bùn ìgbéyàwó?” Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ ṣókí náà, “a dúpẹ́,” ni a kì í sọ. A ń fi ìṣarasíhùwà èmi làkọ́kọ́ rọ́pò ìwà ìmoore lọ́pọ̀ ọ̀nà. Ipò ọ̀ràn yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “O gbọ́dọ̀ mọ èyí pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò yóò léwu púpọ̀. Àwọn ènìyàn yóò mọ ti ara wọn nìkan pátápátá . . . Wọn yóò jẹ́ aláìmoore gbáà.”—2 Tímótì 3:1, 2, Phillips.
Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, a ti fi ìpọ́nni rọ́pò ìmoore. A máa ń sọ̀rọ̀ ìmoore láti inú ọkàn àyà láìronú nípa àǹfààní ara ẹni. Ṣùgbọ́n, ìpọ́nni, tí kì í sábà dénú, tó sì ń kọjá ààlà, lè wá láti inú ète wíwá ìgbéga tàbí jíjèrè àwọn àǹfààní kan fúnra ẹni. (Júúdà 16) Ní àfikún sí títan ẹni tí a ń pọ́n jẹ, irú ọ̀rọ̀ dídùn bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ èso ìgbéraga àti ìrera. Nígbà náà, ta ni yóò fẹ́ kí a sọ̀rọ̀ ìpọ́nni tí kò dénú sí òun? Ṣùgbọ́n ojúlówó ìmoore ń tuni lára ní tòótọ́.
Ẹni tí ń fi ìmoore hàn ń jàǹfààní nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀yàyà tí ó ń gbádùn, nítorí pé ó moore nínú ọkàn àyà rẹ̀, ń fi kún ayọ̀ àti àlàáfíà tó ní. (Fi wé Òwe 15:13, 15.) Nítorí pé ìmoore sì jẹ́ ànímọ́ rere, ó ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn ìmọ̀lára búburú bí ìbínú, owú, àti ìkórìíra.
‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tí Ó Kún fún Ọpẹ́’
Bíbélì rọ̀ wá láti mú ẹ̀mí ìmoore, tàbí ìṣọpẹ́, dàgbà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́. Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù nípa yín.” (1 Tẹsalóníkà 5:18) Pọ́ọ̀lù sì gba àwọn ará Kólósè nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín . . . Ẹ sì fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” (Kólósè 3:15) Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ sáàmù ló ní àwọn ọ̀rọ̀ ọpẹ́ nínú, tí ń fi hàn pé ìmoore àtọkànwá jẹ́ ànímọ́ ìwà bí Ọlọ́run. (Sáàmù 27:4; 75:1) Ó ṣe kedere pé ó ń dùn mọ́ Jèhófà Ọlọ́run nígbà tí a bá ń fi ọpẹ́ hàn nínú àwọn ọ̀ràn ìgbésí ayé ojoojúmọ́.
Àmọ́ àwọn kókó abájọ wo ni ó lè mú kí ó ṣòro fún wa láti mú ẹ̀mí ìmoore dàgbà nínú ayé aláìlọ́pẹ́ yìí? Báwo ni a ṣe lè máa fi ìwà ìmoore hàn nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́? A óò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.