ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 4/1 ojú ìwé 21
  • “Àwọn Ènìyàn Rẹ Yóò fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Àwọn Ènìyàn Rẹ Yóò fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkọ Ọ̀gá Rẹ̀ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ó Kọ́kọ́ Ṣàìgbọràn àmọ́ Nígbà Tó Yá Ó Ṣègbọràn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkùnrin Alágbára Kan Lọ́wọ́
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 4/1 ojú ìwé 21

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

“Àwọn Ènìyàn Rẹ Yóò fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn”

NÁÁMÁNÌ, alágbára, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà, ní àrùn ẹ̀tẹ̀. Bí kò bá wá nǹkan ṣe sí i, àrùn burúkú yìí lè ba ẹwà rẹ̀ jẹ́, kí ó sì ṣekú pa á. Kí ni Náámánì yóò ṣe? Ọmọdébìnrin kékeré kan, ‘òǹdè láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì,’ wà nínú agboolé Náámánì. Ó sọ̀rọ̀ láìṣojo, ó sì dárúkọ wòlíì Èlíṣà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí ó lè wo Náámánì sàn.—2 Àwọn Ọba 5:1-3.

Nítorí ìdúró onígboyà ọmọbìnrin náà, Náámánì wá Èlíṣà lọ, a sì wò ó sàn. Síwájú sí i, Náámánì di olùjọsìn Jèhófà! Ìrírí yìí, tí a kọ sílẹ̀ nínú Bíbélì, wáyé ní ọ̀rúndún kẹwàá ṣááju Sànmánì Tiwa. (2 Àwọn Ọba 5:4-15) Lónìí, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń fi irú ìgboyà kan náà hàn ní sísọ̀rọ̀ jáde nípa ire Ìjọba. Ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí láti Mòsáńbíìkì jẹ́rìí sí èyí.

Nuno ọmọ ọdún mẹ́fà jẹ́ akéde ìhìn rere tí kò tíì ṣe batisí. Àní kí ó tó di akéde tí kò tíì ṣe batisí pàápàá, Nuno yóò kó àwọn ọmọdé jọ ládùúgbò rẹ̀, yóò gbàdúrà, yóò sì kọ́ wọn ní Bíbélì, ní lílo ìtẹ̀jáde náà, Iwe Itan Bibeli Mi.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Nuno máa ń jí ní òwúrọ̀ kùtù Saturday, tí yóò sì rán ìdílé rẹ̀ létí pé: “Lónìí a óò jáde fún iṣẹ́ ìsìn pápá.” Ìtara rẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ fara hàn ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Nígbà tí ó ń bá àwọn òbí rẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ òpópónà ní Maputo, Nuno sábà máa ń dá tọ àwọn ènìyàn lọ. Ní ọ̀kan nínú irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, ọkùnrin oníṣòwò kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì bi í pé: “Èé ṣe tí o fi ń ta àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí?” Nuno wí pé: “N kò ta ìwé ìròyìn, ṣùgbọ́n mo ń gba ọrẹ láti ṣèrànwọ́ fún rírí owó ná lórí iṣẹ́ ìwàásù.” Ọkùnrin oníṣòwò náà fèsì pé: “Bí n kò tilẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i, ìwà àti ẹ̀mí rẹ wú mi lórí. N óò fẹ́ láti ṣètọrẹ fún iṣẹ́ yìí.”

Ní àkókò mìíràn, Nuno tọ ọkùnrin kan lọ ní òpópónà, ó sì fi ìwé náà, True Peace and Security—How Can You Find It?, lọ̀ ọ́. Ọkùnrin náà béèrè pé: “Ilé ẹ̀kọ́ tí ó wà lọ́ọ̀ọ́kán yẹn kọ́ ni o ń lọ ni?” Nuno fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ilé ẹ̀kọ́ yẹn ni mò ń lọ, ṣùgbọ́n lónìí mo ń kéde ìhìn iṣẹ́ pàtàkì kan láti inú ìwé yìí. Ó ń fi hàn ọ́ pé o lè gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run yóò mú wá, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú àwòrán inú ìwé yìí.” Nuno kò mọ̀ rárá pé ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ tí òun ń lọ ni ọkùnrin tí òun bá sọ̀rọ̀. Kì í ṣe pé olùkọ́ náà gba ìwé náà nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún ń gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ́wọ́ Nuno déédéé.

Nígbà tí a béèrè ìdí tí Nuno fi fẹ́ láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́ rẹ̀, ó wí pé: “Mo fẹ́ bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, kí n sì kọ́ wọn nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi.” Ó fi kún un pé: “Bí àwọn ènìyàn náà kò bá sì fẹ́ gbọ́, kò sí ìdí kankan láti bínú.”

Kárí ayé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ bí Nuno ń “fi tinútinú yọ̀ọ̀da ara wọn” láti kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run àti láti wàásù nípa rẹ̀. (Orin Dáfídì 110:3) Ṣùgbọ́n èyí kì í ṣàdédé ṣẹlẹ̀. A óò san èrè jìngbìnnì fún àwọn òbí tí ń kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà láti ìgbà ọmọdé jòjòló, tí wọ́n ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, tí wọ́n sì ń fi ìtara lépa ire Ìjọba.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́