ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 4/1 ojú ìwé 22-27
  • Ìgbésí Ayé Mi Gẹ́gẹ́ Bí Adẹ́tẹ̀—Mo Láyọ̀, A Sì Bù Kún Mi Nípa Tẹ̀mí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbésí Ayé Mi Gẹ́gẹ́ Bí Adẹ́tẹ̀—Mo Láyọ̀, A Sì Bù Kún Mi Nípa Tẹ̀mí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Dara Pọ̀ Mọ́ Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run
  • Ẹ̀tẹ̀ Bò Mí
  • Wọ́n Rò Pé Mo Ti Kú
  • Àtakò sí Iṣẹ́ Ìwàásù Mi
  • Ìkìmọ́lẹ̀ Láti Lé Mi Lọ Ń Bá A Nìṣó
  • Kíláàsì Mọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà
  • Gbọ̀ngàn Ìjọba Kan Nínú Ibùdó Náà
  • Wíwàásù fún Àwọn Adẹ́tẹ̀
  • Ayọ̀ Sísin Àwọn Ará Mi
  • Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Òfin Nípa Àrùn Ẹ̀tẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ǹjẹ́ O Rántí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jésù Fàánú Hàn sí Adẹ́tẹ̀ Kan, Ó sì Wò Ó Sàn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 4/1 ojú ìwé 22-27

Ìgbésí Ayé Mi Gẹ́gẹ́ Bí Adẹ́tẹ̀—Mo Láyọ̀, A Sì Bù Kún Mi Nípa Tẹ̀mí

GẸ́GẸ́ BÍ ISAIAH ADAGBONA ṢE SỌ Ọ́

Àkúrẹ́, ní Nàìjíríà, ni a gbé tọ́ mi dàgbà. Oko iṣu, ọ̀gẹ̀dẹ̀, ẹ̀gẹ́, àti kòkó ni ìdílé mi ń dá. Bàbá mi kò fẹ́ kí n lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Ó sọ fún mi pé: “Àgbẹ̀ ni ọ́. Kò dìgbà tí o kàwé, kí o tó lè mọ bí a ṣe ń dáko iṣu.”

SÍBẸ̀, ó wù mí láti mọ̀wéékà. Ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, mo máa ń dúró síwájú fèrèsé ilé kan, níbi tí olùkọ́ kan ti ń kọ́ àwọn ọmọ kékeré, mo sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀. Ọdún 1940 ni, nígbà tí mo jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún 12. Nígbà tí bàbá àwọn ọmọ náà bá rí mi, yóò kígbe, yóò sì lé mi kúrò. Ṣùgbọ́n, n kò dẹ́kun pípadà wá. Ní àwọn ìgbà kan, olùkọ́ náà kò ní wá, n óò sì rọra yọ́ wọlé, n óò sì wo ìwé àwọn ọmọ náà pẹ̀lú wọn. Wọ́n máa ń gbà kí n yá ìwé wọn, nígbà mìíràn. Bí mo ṣe kọ́ bí a ti ń kàwé nìyẹn.

Mo Dara Pọ̀ Mọ́ Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run

Kò pẹ́ kò jìnnà, mo ní Bíbélì tèmi, mo sì ń kà á déédéé kí n tó sùn. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, mo ka Mátíù orí 10, tí ó fi hàn pé àwọn ènìyàn yóò kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọn yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn.

Mo rántí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá sí ilé mi, a kò sì pọ́n wọn lé. Ó sọ sí mi lọ́kàn pé, ó lè jẹ́ àwọn ẹni tí Jésù sọ nípa rẹ̀ nìyí. Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí tún ṣèkésíni, mo gba ìwé ìròyìn kan lọ́wọ́ wọn. Bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ wọn, mo di ẹni ìyọṣùtìsí. Síbẹ̀, bí àwọn ènìyàn ti ń gbìyànjú láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi tó, ni ó túbọ̀ ń dá mi lójú pé mo ti rí ìsìn tòótọ́, tí ayọ̀ mi sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

Ohun tí ó wu mi lórí gidigidi nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí ni pé, wọn kò lú ìjọsìn wọn mọ́ àṣà àti ìṣẹ̀dálẹ̀ ti ìjọsìn òrìṣà ìbílẹ̀, bí àwọn àwùjọ ìsìn mìíràn ti máa ń ṣe. Fún àpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ Áńgílíkà ni ìdílé mi ń dara pọ̀ mọ́, bàbá mi ní ojúbọ kan fún ọlọ́run àwọn Yorùbá náà, Ògún.

Lẹ́yìn tí bàbá mí kú, èmi ni ó yẹ kí ó jogún ojúbọ náà. N kò nífẹ̀ẹ́ sí i, níwọ̀n bí mo ti mọ̀ pé Bíbélì ka ìbọ̀rìṣà léèwọ̀. Mo tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, mo sì ṣe ìrìbọmi ní December 1954.

Ẹ̀tẹ̀ Bò Mí

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn, mo kíyèsi pé ẹsẹ̀ mi ń wú, n kì í sì í nímọ̀lára níbẹ̀. Bí mo bá tẹ ẹyin iná mọ́lẹ̀, n kì í nírora. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, egbò pupa rẹ́súrẹ́sú yọ sí iwájú orí mi àti ètè mi. Èmi àti ìdílé mi kò mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀; a rò pé ifo ni. Mo lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn ìbílẹ̀ 12 láti rí ìwòsàn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀kan nínú wọ́n sọ fún mi pé ẹ̀tẹ̀ ni.

Ìyàlẹ́nu ńlá gbáà ni èyí jẹ́! Ọkàn mí dàrú, n kò sì lè sùn dáadáa. Mo ń lálàákálàá. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì ti mo ní àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí mo ní nínú Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìdánilójú.

Àwọn ènìyàn sọ fún ìyá mi pé, bí mo bá tọ babaláwo lọ láti ṣèrúbọ, ara mi yóò dá. Mo kọ̀ jálẹ̀, nítorí mo mọ̀ pé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì yóò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Ní mímọ̀ pé kò sí ẹni tí ó lè yí mi lérò padà, àwọn ọ̀rẹ́ ìyá mi sọ fún un pé kí ó mú obì, kí ó sì fi pa iwájú orí mi. Lẹ́yìn náà, ó lè mú obì náà lọ sọ́dọ̀ babaláwo, láti fi rúbọ fún mi. N kò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú irú nǹkan bẹ́ẹ̀, mo sì sọ fún ìyá mi. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó jáwọ́ nínú gbígbìyànjú láti mú mi bọ̀rìṣà.

Nígbà tí n óò fi lọ sí ilé ìwòsàn, ẹ̀tẹ̀ náà ti bò mí gan-an. Egbò wà ní gbogbo ara mi. Wọ́n fún mi lóògùn ní ilé ìwòsàn, àwọ̀ mí sì padà sípò ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.

Wọ́n Rò Pé Mo Ti Kú

Ṣùgbọ́n, ìṣòro mi kò tíì yanjú rárá. Àrùn náà ti ba ẹsẹ̀ mi ọ̀tún jẹ, wọ́n sì ní láti gé e kúrò ní ọdún 1962. Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, ìṣòro jẹyọ láti inú ìtọ́jú ti mo ń gbà. Àwọn dókítà kò retí pé n óò yè é. Àlùfáà míṣọ́nnárì kan, tí ó jẹ́ aláwọ̀ funfun, wá gbàdúrà ìkẹyìn fún mi. N kò lágbára àtisọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n nọ́ọ̀sì kan sọ fún un pé ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.

Àlùfáà náà sọ fún mi pé: “Ṣé o fẹ́ yí padà, kí o sì di Kátólíìkì, kí o baà lè lọ sí ọ̀run?” Èyí mú kí n rẹ́rìn-ín sínú. Mo gbàdúrà sí Jèhófà láti fún mi lókun, kí n lè dáhùn. Pẹ̀lú ìsapá gidigidi, ó ṣeé ṣe fún mi láti sọ pé, “Rárá o!” Àlùfáà náà yí padà, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

Ipò mi túbọ̀ burú sí i, títí tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà fi rò pé mo ti kú. Wọ́n fi aṣọ bò mí lójú. Ṣùgbọ́n, wọn kò gbé mi lọ sí ilé ìtọ́jú òkú sí, níwọ̀n bí dókítà kan tàbí nọ́ọ̀sì kan ní láti kọ́kọ́ jẹ́rìí sí i pé mo ti kú. Kò sí dókítà kankan lẹ́nu iṣẹ́, gbogbo nọ́ọ̀sì sì ti lọ síbi ayẹyẹ kan. Nítorí náà, wọn fi mi sílẹ̀ sínú yàrá ìtọ́jú títí di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Nígbà tí dókítà ń lọ káàkiri láti ṣèbẹ̀wò ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kò sí ẹni tí ó wá sídìí bẹ́ẹ̀dì mi, nítorí aṣọ ṣì wà lójú mi, tí wọ́n sì rò pé mo ti kú. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ẹnì kan kíyèsi pé “òkú” tí ó wà lábẹ́ aṣọ ń mira!

Toò, mo yè é, wọ́n sì gbé mi lọ sí Ibùdó Ìtọ́jú Àwọn Adẹ́tẹ̀ ní Abẹ́òkúta ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, ní December 1963. Ibẹ̀ ni mo ti ń gbé láti ìgbà yẹn wá.

Àtakò sí Iṣẹ́ Ìwàásù Mi

Nǹkan bí 400 adẹ́tẹ̀ ni ó wà ní àgọ́ náà nígbà tí mo débẹ̀, èmi nìkan ṣoṣo sì ni Ẹlẹ́rìí. Mo kọ̀wé sí Society, kíá ni wọ́n sì fèsì, wọ́n sọ pé kí Ìjọ Akọ́mọjẹ̀ kàn sí mi. Nítorí náà, kò sí ìgbà kan tí mo jìnnà sí àwọn ará.

Gbàrà tí mo dé sí àgọ́ náà ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù. Inú pásítọ̀ àdúgbò kò dùn sí èyí rárá, ó sì fẹjọ́ mi sun ọ̀gá tí ń bójú tó ibùdó náà. Ọ̀gá ibùdó náà jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́ orí, tí ó wá láti Germany. Ó sọ fún mi pé, n ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fi Bíbélì kọ́ àwọn ènìyàn nítorí n kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, tí n kò sì ní ìwé ẹ̀rí láti ṣe bẹ́ẹ̀; níwọ̀n bí n kò ti tóótun, ìkọ́kúkọ̀ọ́ ni n óò máa kọ́ àwọn ènìyàn. Bí n kò bá gbọ́, a lè lé mi jáde kúrò ní àgọ́ náà, kí a sì fi ìtọ́jú ìṣègùn dù mí. Kò jẹ́ kí n fèsì.

Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ mi mọ́. Nítorí èyí, àwọn tí ó ti fìfẹ́hàn tẹ́lẹ̀ ṣíwọ́ wíwá sọ́dọ̀ mi.

Mo mú ọ̀ràn náà tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà, mo béèrè fún ọgbọ́n àti ìtọ́sọ́nà. Ní Sunday tí ó tẹ̀ lé e, mo lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi tí ó wà ní àgọ́ náà, bí n kò tilẹ̀ kópa nínú ààtò ìsìn wọn. Àkókò kan wà nígbà ààtò ìsìn náà tí àwọn tí ó wà ní ìjókòó lè béèrè ìbéèrè. Mo nawọ́ mi sókè, mo sì béèrè pé: “Bí gbogbo ènìyàn rere bá ń lọ sí ọ̀run, tí gbogbo ènìyàn búburú sì ń lọ sí ibòmíràn, èé ṣe tí Aísáyà 45:18 fi sọ pé Ọlọ́run dá ayé kí a lè máa gbé inú rẹ̀?”

Ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí kùn. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, pásítọ̀ míṣọ́nnárì náà sọ pé àwámáridìí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Pẹ̀lú ìyẹn, mo fúnra mi dáhùn ìbéèrè mi nípa kíka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó fi hàn pé 144,000 yóò lọ sí ọ̀run, àti èyí tí ó fi hàn pé àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé, àwọn olódodo yóò sì gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé.—Sáàmù 37:10, 11; Ìṣípayá 14:1, 4.

Gbogbo ìjọ pàtẹ́wọ́ ní fífi ìmọrírì hàn sí ìdáhùn náà. Lẹ́yìn náà, pásítọ̀ náà wí pé: “Ẹ pàtẹ́wọ́ fún un lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí ọkùnrin yìí mọ Bíbélì ní tòótọ́.” Lẹ́yìn ìsìn, àwọn kan wá bá mi, wọ́n sì sọ fún mi pé: “Tìrẹ gan-an ju ti pásítọ̀ lọ!”

Ìkìmọ́lẹ̀ Láti Lé Mi Lọ Ń Bá A Nìṣó

Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn dá apá pàtàkì inúnibíni náà dúró, àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ mi láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣùgbọ́n, àwọn alátakò kan ṣì ń yọ ọ̀gá ibùdó náà lẹ́nu láti lé mi dànù. Ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì náà, ó pè mí, ó sì wí pé: “Èé ṣe tí o kò fi dẹ́kun wíwàásù? Àwọn ènìyàn kò nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè mi, bẹ́ẹ̀ sì ni níhìn-ín pẹ̀lú. Èé ṣe tí o fi ń fa wàhálà fún mi? Ṣe o kò mọ̀ pé mo lè lé ọ lọ ni?”

Mo fèsì pé: “Bàbá, ìdí mẹ́ta ni mo fi ń bọ̀wọ̀ fún un yín. Àkọ́kọ́, nítorí pé ẹ jù mí lọ, Bíbélì sì sọ pé kí a bọ̀wọ̀ fún orí ewú. Ìdí kejì tí mo fi ń bọ̀wọ̀ fún yín ni pé, ẹ fi orílẹ̀-èdè yín sílẹ̀ láti wá ràn wá lọ́wọ́ níhìn-ín. Ìdí kẹta ni pé, onínúure àti ọ̀làwọ́ ènìyàn ni yín, ẹ sì máa ń ran àwọn tí ó bá wà nínú ìpọ́njú lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ rò pé ẹ ní tí ẹ fi lè lé mi lọ? Ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí kò lé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ. Ọba ìlú yìí kò lé wa lọ. Bí ẹ tilẹ̀ lé mi kúrò nínú ibùdó yìí, Jèhófà yóò ṣì tọ́jú mi.”

N kò bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó ṣe ṣàkó báyìí rí, mo sì lè rí i pé ó yà á lẹ́nu. Ó kúrò lọ́dọ̀ mi láìgbin. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ẹnì kan rojọ́ mi fún un, ó fìbínú dáhùn pé: “Èmi kò fẹ́ dá sí ọ̀ràn yìí mọ́. Bí o bá níṣòro pẹ̀lú ìwàásù rẹ̀, lọ bá a sọ ọ́!”

Kíláàsì Mọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà

Àtakò sí ìwàásù mi ń bá a lọ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi tí ó wà ní ibùdó náà. Ní àkókò yìí, ọgbọ́n kan wá sí mi lórí. Mo lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá ibùdó náà, mo sì bi í bóyá mo lè dá kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà sílẹ̀. Nígbà tí ó béèrè iye tí mo fẹ́ kí wọ́n máa san fún mi, mo sọ pé ọ̀fẹ́ ni mo fẹ́ máa kọ́ni.

Wọ́n ṣètò kíláàsì, pátákó, àti ẹfun ìkọ̀wé, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn kan lára àwa tí a jọ wà níbẹ̀ ní bí a ti ń kàwé. A ń ṣe kíláàsì lójoojúmọ́. Fún 30 ìṣẹ́jú àkọ́kọ́, n óò kọ́ wọn bí a ti ń kàwé, lẹ́yìn náà, n óò sọ ìtàn kan láti inú Bíbélì, n óò sì ṣàlàyé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, a óò wá ka ìtàn náà jáde láti inú Bíbélì.

Obìnrin kan tí ń jẹ́ Nímọ́tà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó lọ́kàn ìfẹ́ gidigidi nínú àwọn ohun tẹ̀mí, ó sì máa ń béèrè ìbéèrè tí ó jẹ mọ ti ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì àti ní mọ́ṣáláṣí. Kò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀ níbẹ̀, nítorí náà, yóò wá béèrè lọ́wọ́ mi. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣe ìrìbọmi. A ṣègbéyàwó ní ọdún 1966.

Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú mẹ́ńbà ìjọ wa lónìí ni ó jẹ́ pé nínú kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà yẹn ni wọ́n ti kọ́ bí a ti ń mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Kì í ṣe láti inú ọgbọ́n mi ni àbá kíláàsì yẹn fi wá sí mi lọ́kàn. Dájúdájú, ìbùkún Jèhófà ṣe kedere. Láti ìgbà yẹn wá, ẹnì kan kò dá mi dúró wíwàásù.

Gbọ̀ngàn Ìjọba Kan Nínú Ibùdó Náà

Ìgbà tí èmi àti Nímọ́tà yóò fi ṣègbéyàwó, àwa mẹ́rin ni a máa ń pàdé pọ̀ déédéé láti kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Fún nǹkan bí ọdún kan, a ń pàdé nínú yàrá tí a ti máa ń wẹ egbò ẹ̀tẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀gá ibùdó náà, tí ó ti wá di ọ̀rẹ́ mi báyìí, sọ fún mi pé: “Ko dára pé kí ẹ máa jọ́sìn Ọlọ́run yín nínú yàrá ìtọ́jú egbò.”

Ó sọ pé a lè máa pàdé ní ìsọ̀ káfíńtà kan tí wọn kò lò mọ́. Bí àkókò ti ń lọ, a sọ ìsọ̀ náà di Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní 1992, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ará nígboro, a parí rẹ̀. Bí ẹ ti lè ri nínú àwòrán tí ó wà lójú ewé 24, gbọ̀ngàn wá jẹ́ ilé tí ó dúró rekete—tí a rẹ́, tí a sì kùn lọ́dà, tí a kọnkéré ilẹ̀ rẹ̀, tí ó sì ní òrùlé tí ó dára.

Wíwàásù fún Àwọn Adẹ́tẹ̀

Fún ọdún 33, àgọ́ àwọn adẹ́tẹ̀ ni ìpínlẹ̀ mi. Báwo ni wíwàásù fún àwọn adẹ́tẹ̀ ṣe ń rí? Níhìn-ín ní Áfíríkà, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn gbà pé àmúwá Ọlọ́run ni gbogbo nǹkan. Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀tẹ̀ bá bò wọ́n, wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló ṣokùnfà rẹ̀. Ipò àwọn kan ń mú kí wọ́n sorí kọ́. Inú máa ń bí àwọn ẹlòmíràn, wọ́n sì máa ń sọ pé: “Máà bá wa sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú kankan o. Ì bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, àìsàn yìí ò ní ti pòórá!” Lẹ́yìn náà, a óò ka Jákọ́bù 1:13, tí ó sọ pé: ‘Ọlọ́run kì í fi ibi dán ẹnikẹ́ni wò,’ a óò sì wá ronú lé e lórí. Lẹ́yìn èyí, a óò ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba àìsàn láti pọ́n àwọn ènìyàn lójú, a óò sì tọ́ka sí ìlérí tí ó ṣe nípa párádísè orí ilẹ̀ ayé kan, níbi tí kò ní sí aláìsàn kankan.—Aísáyà 33:24.

Ọ̀pọ̀ ti dáhùn padà lọ́nà rere sí ìhìn rere náà. Láti ìgbà tí mo ti dé sí ibùdó yìí, Jèhófà ti lò mí láti ran àwọn ènìyàn tí ó lé ní 30 lọ́wọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi, adẹ́tẹ̀ sì ni gbogbo wọn. Ọ̀pọ̀ ti padà sílé lẹ́yìn tí ara wọ́n ti dá, àwọn díẹ̀ sì ti kú. Ni lọ́ọ́lọ́ọ́, akéde Ìjọba 18 ni a ní, àwọn ènìyàn 25 sì ń wá sí ìpàdé déédéé. Àwa méjì ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, a sì ní ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan àti aṣáájú ọ̀nà kan. Ẹ wo bí ayọ̀ mi ti pọ̀ tó láti rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń fi òtítọ́ sin Jèhófà nísinsìnyí nínú ibùdó yìí! Nígbà tí mo débí, mo bẹ̀rù pé n óò wà ní èmi nìkan, ṣùgbọ́n Jèhófà ti bù kún mi ní ọ̀nà ìyanu.

Ayọ̀ Sísin Àwọn Ará Mi

Mo lo oògùn fún àrùn ẹ̀tẹ̀ mi láti ọdún 1960 títí di nǹkan bí ọdún márùn-ún sẹ́yìn. Ara mi ti dá pátápátá nísinsìnyí, bẹ́ẹ̀ sì ni ara àwọn yòókù nínú ìjọ pẹ̀lú. Àpá tí àrùn ẹ̀tẹ̀ fi sílẹ̀ ṣì wà lára mi—mo pàdánù ẹsẹ̀ mi kan, n kò sì lè na àwọn ọwọ́ mi—ṣùgbọ́n àrùn náà ti tán lára mi.

Níwọ̀n bí ara mi ti dá, àwọn kan ti bi mí pé, èé ṣe tí n kò fi fi ibùdó náà sílẹ̀, kí n sì padà sílé. Ìdí tí mo fi dúró pọ̀, ṣùgbọ́n olórí rẹ̀ ni pé, mo fẹ́ máa bá a lọ láti ran àwọn ará mi lọ́wọ́ níhìn-ín. Ayọ̀ bíbójútó àwọn àgùntàn Jèhófà ju ohunkóhun tí ìdílé mi lè fún mi, bí mo bá padà sílé.

Mo dúpẹ́ gidigidi pé mo mọ Jèhófà kí n tó mọ̀ pé mo ní àrùn ẹ̀tẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo lè ti pa ara mi. Ọ̀pọ̀ ìnira àti ìṣòro ti jẹ yọ ní àárín àwọn ọdún wọ̀nyí, ṣùgbọ́n kì í ṣe egbòogi ni ó gbé mi ró—Jèhófà ni. Nígbà tí mo bá ronú sẹ́yìn, inú mi máa ń dùn; nígbà tí mo bá sì ronú nípa ọjọ́ iwájú lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, inú mi túbọ̀ máa ń dùn gan-an.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

Ìsọfúnni Pàtàkì Lórí Àrùn Ẹ̀tẹ̀

Kí Ni Ó Jẹ́?

Ẹ̀tẹ̀ òde òní jẹ́ àrùn kan tí oríṣi kòkòrò àrùn kan tí Armauer Hansen ṣàwárí ní ọdún 1873 ń fà. Láti fi ìmọrírì hàn fún iṣẹ́ rẹ̀, àwọn dókítà tún máa ń tọ́ka sí ẹ̀tẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àrùn Hansen.

Kòkòrò àrùn náà máa ń ba iṣan, egungun, ojú, àti àwọn ẹ̀yà inú ara kan jẹ́. A kì í nímọ̀lára mọ́, lọ́pọ̀ ìgbà lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀. Bí a kò bá tọ́jú rẹ̀, àrùn yìí lè ba ojú, ọwọ́, àti ẹsẹ̀ ẹni jẹ́ pátápátá. Kì í sábàá pani.

Ó Ha Gbóògùn Bí?

Àwọn ènìyàn tí ẹ̀tẹ̀ kò tíì bò lára púpọ̀ máa ń sàn láìlo ohunkóhun. A lè fi oògùn wo àwọn tí ó ti bò lára gan-an sàn.

Oògùn àkọ́kọ́ tí a ṣe láti fi bá ẹ̀tẹ̀ jà, tí a mú jáde ní àwọn ọdún 1950, kò ṣiṣẹ́ dáradára, ó sì wá di èyí tí kò gbéṣẹ́ mọ́, nítorí agbára rẹ̀ kò ká kòkòrò àrùn náà mọ́. A mú àwọn oògùn tuntun jáde, láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, ìtọ́jú gbogbonìṣe ti Multi-Drug Therapy (MDT) wá di ìtọ́jú tí a ń lò jákèjádò ayé. Ìtọ́jú yìí pa lílo àwọn oògùn mẹ́ta pọ̀—Dapsone, Rifampicin, àti Clofazimine. Bí ìtọ́jú MDT tilẹ̀ ń pa kòkòrò àrùn náà, kì í ṣàtúnṣe ìbàjẹ́ tí ó ti ṣe.

Ìtọ́jú MDT gbéṣẹ́ gidigidi nínú wíwo àrùn náà sàn. Lójú ìwòye èyí, iye àwọn ènìyàn tí àrùn ẹ̀tẹ̀ ń ṣe ti lọ sílẹ̀ dòò, láti orí mílíọ̀nù 12 ní 1985 sí nǹkan bí mílíọ̀nù 1.3 ní àárín ọdún 1996.

Báwo Ni Ó Ṣe Ń Tètè Ranni Tó?

Ẹ̀tẹ̀ kì í tètè ranni; agbára ìdènà àrùn ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lágbára láti gbógun tì í. Nígbà tí ó bá sì ranni, ó sábà máa ń jẹ́ nítorí tí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti ní ìfarakanra pẹ̀lú àwọn tí ó ní àrùn náà fún ìgbà pípẹ́.

Àwọn dókítà kò mọ ọ̀nà tí kòkòrò àrùn náà ń gbà wọnú ara ènìyàn dájú, ṣùgbọ́n wọ́n ń fura sí i pé inú awọ ara tàbí imú ni ó ń gbà wọlé.

Ìrètí Ọjọ́ Iwájú

A ti fojú sùn ún pé a óò mú ẹ̀tẹ̀ “kúrò pátápátá gẹ́gẹ́ bí ìṣòro ìlera gbogbogbòò” ní ọdún 2000. Èyí túmọ̀ sí pé iye àwọn ènìyàn tí yóò ní ẹ̀tẹ̀ nínú àwùjọ èyíkéyìí kì yóò ju ènìyàn 1 nínú 10,000. Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a óò mú un kúrò pátápátá.—Aísáyà 33:24.

Orísun: Àjọ Ìlera Àgbáyé; Ẹgbẹ́ Tí Ń Gbógun Ti Àrùn Ẹ̀tẹ̀ Káàkiri Àgbáyé; àti Manson’s Tropical Diseases, Ẹ̀dà ti 1996.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]

Ẹ̀tẹ̀ Òde Òní Ha Rí Bákan Náà Pẹ̀lú ti Àkókò tí A Kọ Bíbélì Bí?

Àwọn ìwé ìṣègùn òde òní túmọ̀ ẹ̀tẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe ṣàkó; orúkọ tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fún kòkòrò àrùn tí ń fà á ni Mycobacterium leprae. Ṣùgbọ́n, Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn. Àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tí a tú sí “ẹ̀tẹ̀” nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ní ìtumọ̀ gbígbòòrò. Fún àpẹẹrẹ, kì í ṣe lára ènìyàn nìkan ni ẹ̀tẹ̀ tí a sọ nínú Bíbélì ti máa ń mú àmì àrùn tí ó ṣeé fojú rí jáde, ṣùgbọ́n ó máa ń mú un jáde lára aṣọ àti ilé pẹ̀lú, ohun tí kòkòrò àrùn kì í ṣe.—Léfítíkù 13:2, 47; 14:34.

Síwájú sí i, àwọn àmì àrùn ẹ̀tẹ̀ tí ń yọ lára ènìyàn lónìí, kò bá àpèjúwe ẹ̀tẹ̀ inú Bíbélì mu. Àwọn kan sọ pé ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ nítorí òtítọ́ náà pé àwọn àrùn máa ń yí padà bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́. Àwọn mìíràn gbà gbọ́ pé kì í ṣe àrùn kan ṣoṣo ni ẹ̀tẹ̀ inú Bíbélì ń ṣàpèjúwe, èyí sì lè ní àrùn tí kòkòrò àrùn M. leprae ń fà nínú, ó sì lè má ní in.

Ìwé Theological Dictionary of the New Testament sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì àti ti Hébérù tí a sábà máa ń tú sí ẹ̀tẹ̀ “tọ́ka sí àrùn, tàbí àwùjọ àrùn kan náà . . . Kò dájú bóyá àìsàn yìí ni ohun tí a wá ń pè ní ẹ̀tẹ̀ nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n ohun tí ìṣègùn ń pe àrùn yìí gan-an kò nípa lórí ojú ti a fi wo àkọsílẹ̀ ìmúláradá [àwọn adẹ́tẹ̀ láti ọwọ́ Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀].”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìjọ náà níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba inú ibùdó àwọn adẹ́tẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Isaiah Adagbona àti Nímọ́tà, ìyàwó rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́