ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 4/15 ojú ìwé 14-19
  • Jèhófà Ń Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ Fún Àwọn Olùṣòtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ń Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ Fún Àwọn Olùṣòtítọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbàgbọ́ Tòótọ́ ní Ìgbà Ìjímìjí
  • Àbájáde Àìnígbàgbọ́
  • A Fi Ìgbàgbọ́ Hàn ní Ọjọ́ Wa
  • Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu fún Àwọn Olùṣòtítọ́
  • A Mú Ọjọ́ Ọ̀la Aláyọ̀ Dáni Lójú
  • Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Pé Jehofa Yóò Mú Ète Rẹ̀ Ṣẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Nípa Ìgbàgbọ́ Ni Àwa Ń Rìn, Kì Í Ṣe Nípa Ohun Tí A Rí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • “Ẹ Fìdí Ọkàn-àyà Yín Múlẹ̀ Gbọn-in”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Lo Igbagbọ Ti A Gbekari Otitọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 4/15 ojú ìwé 14-19

Jèhófà Ń Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ Fún Àwọn Olùṣòtítọ́

“Olùṣòtítọ́ ni ẹni tí ó ṣèlérí.”—HÉBÉRÙ 10:23.

1, 2. Èé ṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú àwọn ìlérí Jèhófà?

JÈHÓFÀ ń béèrè pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mú ìgbàgbọ́ fífẹsẹ̀múlẹ̀ dàgbà nínú òun àti nínú ìlérí òun, kí wọ́n sì pa á mọ́. Pẹ̀lú irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ẹnì kan lè gbára lé Jèhófà pátápátá pé yóò ṣe ohun tí ó ti ṣèlérí pé òun yóò ṣe. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a mí sí polongo pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti búra, pé: ‘Dájúdájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀; àti gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu, èyíinì ni yóò ṣẹ.’”—Aísáyà 14:24.

2 Gbólóhùn náà, “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti búra,” fi hàn pé ó búra lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi lè sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Nígbà tí a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tí a sì jẹ́ kí ọgbọ́n rẹ̀ darí wa, dájúdájú ọ̀nà wa yóò sìn wá lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, nítorí ọgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ “igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú.”—Òwe 3:18; Jòhánù 17:3.

Ìgbàgbọ́ Tòótọ́ ní Ìgbà Ìjímìjí

3. Báwo ni Nóà ṣe fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Jèhófà?

3 Àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìṣe Jèhófà sí àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ jẹ́rìí sí i pé ó ṣeé gbára lé. Fún àpẹẹrẹ, ní iye tí ó lé ní 4,400 ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé a óò pa ayé tí ó wà ní àkókò rẹ̀ run nínú Ìkún Omi kan tí yóò kárí ayé. Ó fún Nóà nítọ̀ọ́ni láti kan áàkì títóbi fàkìàfakia kan láti pa ẹ̀mí ènìyàn àti ẹranko mọ́. Kí ni Nóà ṣe? Hébérù 11:7 sọ fún wa pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tí ì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì kan fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.” Èé ṣe tí Nóà fi ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí, ohun tí a ‘kò tí ì rí’? Nítorí pé ó ní ìmọ̀ tí ó pọ̀ tó nípa bí Ọlọ́run ṣe bá ìdílé ẹ̀dá ènìyàn lò ṣáájú, tí ó fi mọ̀ pé ohunkóhun tí Ọlọ́run bá sọ yóò ní ìmúṣẹ. Nítorí náà, Nóà ní ìdánilójú pé Ìkún Omi náà pẹ̀lú yóò wáyé.—Jẹ́nẹ́sísì 6:9-22.

4, 5. Èé ṣe tí Ábúráhámù fi gbára lé Jèhófà pátápátá?

4 Ábúráhámù jẹ́ àpẹẹrẹ mìíràn nípa ìgbàgbọ́ tòótọ́. Ní nǹkan bí 3,900 ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run sọ fún un pé kí ó fi Ísákì, ọmọ kan ṣoṣo tí Sárà, aya rẹ̀ bí fún un, rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì 22:1-10) Báwo ni Ábúráhámù ṣe hùwà padà? Hébérù 11:17 sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dán an wò, kí a kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán.” Ṣùgbọ́n, ní ìkẹyìn pátápátá, áńgẹ́lì Jèhófà dá Ábúráhámù dúró. (Jẹ́nẹ́sísì 22:11, 12) Síbẹ̀, èé ṣe tí Ábúráhámù fi ronú ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rárá? Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Hébérù 11:19 ṣe sọ, “ó ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé [Ísákì] dìde, àní kúrò nínú òkú.” Ṣùgbọ́n, báwo ni Ábúráhámù ṣe lè nígbàgbọ́ nínú àjíǹde nígbà tí kò tí ì rí ọ̀kan rí, tí kò sì sí àkọsílẹ̀ ṣáájú nípa ọ̀kan?

5 Rántí pé ẹni ọdún 89 ni Sárà nígbà tí Ọlọ́run ṣèlérí ọmọkùnrin kan fún wọn. Ilé ọlẹ̀ Sárà kì í ṣe èyí tí ọmọ lè dúró nínú rẹ̀ mọ́—kí a kúkú sọ pé ó ti kú. (Jẹ́nẹ́sísì 18:9-14) Ọlọ́run mú ilé ọlẹ̀ Sárà padà bọ̀ sí ìyè, ó sì bí Ísákì. (Jẹ́nẹ́sísì 21:1-3) Ábúráhámù mọ̀ pé níwọ̀n bí Ọlọ́run ti lè mú ilé ọlẹ̀ Sárà tí ó ti kú padà bọ̀ sí ìyè, nígbà náà, Òun lè mú Ísákì padà bọ̀ sí ìyè pẹ̀lú, bí ó bá pọndandan. Róòmù 4:20, 21 sọ nípa Ábúráhámù pé: “Nítorí ìlérí Ọlọ́run, kò mikàn nínú àìnígbàgbọ́, ṣùgbọ́n ó di alágbára nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó ń fi ògo fún Ọlọ́run, ó sì gbà gbọ́ ní kíkún pé ohun tí ó ti ṣèlérí ni ó lè ṣe pẹ̀lú.”

6. Báwo ni Jóṣúà ṣe fi ìgbọ́kànlé hàn nínú Jèhófà?

6 Ní èyí tí ó lé ní 3,400 ọdún sẹ́yìn, nígbà tí Jóṣúà ti lé ní ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, àti lẹ́yìn ìgbésí ayé nínírìírí bí Ọlọ́run ti ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó, ó sọ ìdí yìí fún ìgbọ́kànlé rẹ̀: “Ẹ̀yin . . . mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.”—Jóṣúà 23:14.

7, 8. Ipa ọ̀nà tí ń gbẹ̀mí là wo ni àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ tọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, èé sì ti ṣe?

7 Ní nǹkan bí 1,900 ọdún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ fi ìgbàgbọ́ tòótọ́ hàn. Wọ́n mọ̀ láti inú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pé Jésù ni Mèsáyà náà, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Bí wọ́n ti ní ìpìlẹ̀ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú àwọn òkodoro òtítọ́ àti nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí Jésù fi kọ́ni. Nípa báyìí, nígbà tí Jésù sọ pé ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀ sórí Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù nítorí àìṣòtítọ́ wọn, wọ́n gbà á gbọ́. Nígbà tí ó sì sọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe láti gba ẹ̀mí wọn là, wọ́n ṣe é.

8 Jésù sọ fún àwọn onígbàgbọ́ pé nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun bá yí Jerúsálẹ́mù ká, kí wọ́n sá lọ. Ní tòótọ́, ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kọjúùjà sí Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, láìmọ ohun tí ó fà á, àwọn ará Róòmù náà bá tiwọn lọ. Ìyẹn jẹ́ àmì fún àwọn Kristẹni láti fi ìlú náà sílẹ̀, nítorí Jésù ti sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:20, 21) Àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ fi Jerúsálẹ́mù àti àgbègbè tí ó yí i ká sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ sí ibi ààbò.

Àbájáde Àìnígbàgbọ́

9, 10. (a) Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn ṣe fi àìnígbàgbọ́ wọn hàn nínú Jésù? (b) Kí ni àbájáde àìnígbàgbọ́ yẹn?

9 Kí ni àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ ṣe? Wọn kò sá nígbà tí wọ́n ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n ronú pé àwọn aṣáájú àwọn lè gba àwọn là. Síbẹ̀, àwọn aṣáájú wọ̀nyẹn àti àwọn ọmọlẹ́yìn wọn pẹ̀lú rí ẹ̀rí pé Jésù ni Mèsáyà náà. Nítorí náà, èé ṣe tí wọn kò fi tẹ́wọ́ gba ohun tí ó sọ? Ó jẹ́ nítorí pé ipò ọkàn-àyà wọ́n burú. Èyí ti kọ́kọ́ wá sí ojútáyé nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn gbáàtúù tí wọ́n ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Jésù, lẹ́yìn tí ó jí Lásárù dìde. Jòhánù 11:47, 48 ròyìn pé: “Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kó Sànhẹ́dírìn [ilé ẹjọ́ gíga ti àwọn Júù] jọpọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: ‘Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí [Jésù] ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì? Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ará Róòmù yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.’” Ẹsẹ 53 wí pé: “Nítorí náà, láti ọjọ́ yẹn lọ, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.”

10 Ẹ wo àgbàyanu iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe—mímú Lásárù padà wá láti inú òkú! Ṣùgbọ́n, àwọn aṣáájú ìsìn ń fẹ́ pa Jésù fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ìwà búburú wọn tí ó lé kenkà ni a túbọ̀ tú fó nígbà tí “àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ pọ̀ . . . láti pa Lásárù pẹ̀lú, nítorí pé ní tìtorí rẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù ń lọ sí ibẹ̀, wọ́n sì ń ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù.” (Jòhánù 12:10, 11) A ṣẹ̀ṣẹ̀ jí Lásárù dìde kúrò nínú òkú ni, àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn sì tún fẹ́ kí ó padà kú! Wọn kò ṣàníyàn nípa ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí nípa ire àwọn ènìyàn. Tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ipò àti àǹfààní tiwọn nìkan ni ó jẹ wọ́n lógún. “Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo ènìyàn ju ògo Ọlọ́run pàápàá.” (Jòhánù 12:43) Ṣùgbọ́n wọ́n jìyà àìnígbàgbọ́ wọn. Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù padà wá, wọ́n sì run àyè wọn àti orílẹ̀ èdè wọn, títí kan púpọ̀ lára wọn.

A Fi Ìgbàgbọ́ Hàn ní Ọjọ́ Wa

11. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, báwo ni a ṣe fi ìgbàgbọ́ tòótọ́ hàn?

11 Ní ọ̀rúndún yìí, ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́ ti wà pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900, àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la alálàáfíà àti aláásìkí. Ní àsìkò kan náà, àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà ń kéde pé aráyé ti fẹ́ wọnú sànmánì kan tí yóò rí wàhálà tí kò tí ì sí irú rẹ̀ rí títí di ìgbà yẹn. Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nìyẹn nínú Mátíù orí 24, 2 Tímótì orí 3, àti ní àwọn ibòmíràn. Ohun tí àwọn ẹni ìgbàgbọ́ yẹn sọ ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ogun Àgbáyé Kìíní ní ọdún 1914. Ní tòótọ́, ayé wọnú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” pẹ̀lú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” tí a sọ tẹ́lẹ̀. (2 Tímótì 3:1) Èé ṣe tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi mọ òtítọ́ nípa ipò ayé nígbà náà lọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n tí àwọn ẹlòmíràn kò mọ̀ ọ́n? Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bi Jóṣúà, wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí yóò kùnà.

12. Lónìí, ìlérí Jèhófà wo ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú rẹ̀?

12 Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, ti ń lọ sí mílíọ̀nù mẹ́fà yíká ayé. Wọ́n mọ̀ láti inú ẹ̀rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run pé láìpẹ́, òun yóò mú ètò àwọn nǹkan oníwà ipá àti oníwà pálapàla yìí wá sópin. Nítorí náà, wọ́n ní ìgbọ́kànlé pé àkókò náà ti sún mọ́lé nígbà tí wọn yóò rí ìmúṣẹ 1 Jòhánù 2:17, tí ó wí pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé Jèhófà yóò mú ìlérí yìí ṣẹ.

13. Ibo ni o lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dé?

13 Ibo ni o lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dé? O lè gbẹ́kẹ̀ lé E títí dójú ikú! Àní bí o bá pàdánù ìwàláàyè rẹ nísinsìnyí nítorí sísìn ín, òun yóò fún ọ ní ìwàláàyè tí ó sàn jù gan-an nígbà àjíǹde. Jésù mú un dá wa lójú pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú àwọn ibojì ìrántí [ìyẹn ni, nínú ìrántí Ọlọ́run] yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) O ha mọ dókítà, aṣáájú òṣèlú, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, oníṣòwò, tàbí ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tí ó lè ṣe ìyẹn bí? Àkọsílẹ̀ wọn àtẹ̀yìnwá fi hàn pé wọn kò lè ṣe é. Jèhófà lè ṣe é, òun yóò sì ṣe é!

Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu fún Àwọn Olùṣòtítọ́

14. Ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn olùṣòtítọ́?

14 Jésù fi ìdánilójú ayé tuntun lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ọ̀run hàn nígbà tí ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Ìyẹn túbọ̀ fún ìlérí Ọlọ́run tí a rí nínú Sáàmù 37:29 lókun, pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Kété kí Jésù sì tó kú, nígbà tí aṣebi kan fi ìgbàgbọ́ hàn nínú rẹ̀, Jésù wí fún ọkùnrin yẹn pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run, Jésù yóò rí sí i pé a jí ọkùnrin yìí dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àǹfààní gbígbé títí láé nínú Párádísè yẹn. Lónìí, àwọn tí ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Ìjọba Jèhófà lè máa fojú sọ́nà pẹ̀lú fún gbígbé nínú Párádísè nígbà tí “[Ọlọ́run] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, [tí] ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.

15, 16. Èé ṣe tí ìgbésí ayé yóò ṣe kún fún àlàáfíà nínú ayé tuntun?

15 Ẹ jẹ́ kí a finú wòye pé a wà nínú ayé tuntun yẹn. Kí a ronú pé a ti ń gbé nínú rẹ̀ báyìí. Lójú ẹsẹ̀, a rí àwọn ènìyàn aláyọ̀ níbi gbogbo tí wọ́n ń gbé pa pọ̀ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàáfíà. Wọ́n ń gbádùn ipò tí ó jọra pẹ̀lú èyí tí a ṣàpèjúwe nínú Aísáyà 14:7, pé: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn ènìyàn ti tújú ká pẹ̀lú igbe ìdùnnú.” Èé ṣe tí wọ́n fi ń hùwà lọ́nà yẹn? Àkọ́kọ́ ná, ṣàkíyèsí pé àwọn ilẹ̀kùn ilé kò ní kọ́kọ́rọ́. A kò nílò wọn, níwọ̀n bí kò ti sí ìwà ọ̀daràn tàbí ìwà ipá. Ó rí gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ pé yóò rí, pé: “Wọn yóò . . . jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4.

16 Bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ogun mọ́, nítorí pé a ti fi òfin de ogun nínú ayé tuntun yìí. A ti sọ gbogbo ohun ìjà di àwọn ohun èlò àlàáfíà. Ní èrò kíkún rẹ́rẹ́, Aísáyà 2:4 ti ní ìmúṣẹ: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” Ṣùgbọ́n ṣáá, ohun tí a retí náà nìyẹn! Èé ṣe? Nítorí pé àwọn olùgbé ayé tuntun náà kọ́ láti ṣe ìyẹn nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run nínú ayé ti àtijọ́.

17. Àwọn ipò ìgbésí ayé wo ni yóò wà káàkiri nínú Ìjọba Ọlọ́run?

17 Ohun mìíràn tí o tún ṣàkíyèsí ni pé kò sí ipò òṣì. Kò sẹ́ni tí ń gbé nínú ahéré tàbí tí ń wọ àkísà tàbí tí kò ní ilé. Gbogbo ènìyàn ni ó ní ibùgbé tí ó rọni lọ́rùn àti àwọn ilé tí a bójú tó dáradára, tí ó ní àwọn igi àti òdòdó tí ó fani mọ́ra. (Aísáyà 35:1, 2; 65:21, 22; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:27) Kò sì sí ebi nítorí Ọlọ́run ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu yóò wà fún gbogbo ènìyàn: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) Ní tòótọ́, lábẹ́ ìdarí Ìjọba Ọlọ́run, párádísè ológo kan gbòòrò kárí ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pète nígbà náà lọ́hùn-ún ní Édẹ́nì.—Jẹ́nẹ́sísì 2:8.

18. Nínú ayé tuntun, àwọn ohun wo ni kì yóò wu àwọn ènìyàn léwu mọ́?

18 Ẹnu tún yà ọ́ nítorí agbára kíkún tí gbogbo ènìyàn ní. Èyí jẹ́ nítorí pé wọ́n ní ara àti èrò inú pípé nísinsìnyí. Kò sí àìsàn, ìrora, àti ikú mọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni lórí àga arọ tàbí lórí ibùsùn ilé ìwòsàn. Gbogbo ìyẹn ti kọjá lọ pátá. (Aísáyà 33:24; 35:5, 6) Họ́wù, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ẹranko tí ó ń wu ìwàláàyè ènìyàn léwu, nítorí pé agbára Ọlọ́run ti mú kí wọ́n jẹ́ alálàáfíà!—Aísáyà 11:6-8; 65:25; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:25.

19. Èé ṣe tí gbogbo ọjọ́ nínú ayé tuntun yóò fi kún fún “inú dídùn kíkọyọyọ”?

19 Ẹ wo irú àgbàyanu ipò ọ̀làjú tí àwọn olùṣòtítọ́ olùgbé nínú ayé tuntun yìí ti gbé ró! Wọ́n ń lo agbára àti òye iṣẹ́ wọn, àti ọrọ̀ ilẹ̀ ayé fún ìlépa tí ó ṣàǹfààní, kì í ṣe fún èyí tí ń pani lára; fún fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, kì í ṣe fún bíbá wọn díje. Gbogbo ẹni tí o bá bá pàdé jẹ́ ẹni tí o lè gbẹ́kẹ̀ lé, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣèlérí, gbogbo ènìyàn jẹ́ “àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 54:13) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òfin Ọlọ́run ní ń darí gbogbo ènìyàn, ayé “kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Ní tòótọ́, ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ayé tuntun yìí jẹ́ ohun tí Sáàmù 37:11 sọ pé yóò jẹ́, ọ̀kan tí ó kún fún “inú dídùn kíkọyọyọ.”

A Mú Ọjọ́ Ọ̀la Aláyọ̀ Dáni Lójú

20. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti gbádùn ọjọ́ ọ̀la alálàáfíà?

20 Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti jẹ́ apá kan ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ yẹn? Aísáyà 55:6 sọ fún wa pé: “Ẹ wá Jèhófà, nígbà tí ẹ lè rí i. Ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.” Bí a sì ti ń wá a, ẹ̀mí ìrònú wa gbọ́dọ̀ jẹ́ irú èyí tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Sáàmù 143:10 pé: “Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi.” Àwọn tí wọ́n ń ṣe èyí lè rìn láìlẹ́bi níwájú Jèhófà nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, wọ́n sì lè fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la tí ó dára. “Máa ṣọ́ aláìlẹ́bi, kí o sì máa wo adúróṣánṣán, nítorí pé ọjọ́ ọ̀la ẹni yẹn yóò kún fún àlàáfíà. Ṣùgbọ́n ó dájú pé a ó pa àwọn olùrélànàkọjá rẹ́ ráúráú lápapọ̀; ọjọ́ ọ̀la àwọn ènìyàn burúkú ni a óò ké kúrò ní tòótọ́.”—Sáàmù 37:37, 38.

21, 22. Kí ni Ọlọ́run ń dá sílẹ̀ lónìí, báwo sì ni a ṣe ń ṣàṣeparí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà?

21 Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, Jèhófà ń kó àwọn tí ó fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀ jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó sì ń sọ wọ́n di ìpìlẹ̀ àwùjọ ayé tuntun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti sọ, pé: “Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ [àkókò tí a ń gbé nínú rẹ̀ nísinsìnyí] . . . ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà [ìjọsìn tòótọ́ rẹ̀ tí a gbé ga] . . . Òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’”—Aísáyà 2:2, 3.

22 Ìṣípayá 7:9 ṣàpèjúwe àwọn wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Ẹsẹ 14 wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà,” wọ́n la òpin ètò ìsinsìnyí já. Ìpìlẹ̀ ayé tuntun yìí ti ń lọ sí mílíọ̀nù mẹ́fà ní iye, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun tí ń dara pọ̀ mọ́ ọn lọ́dọọdún. Gbogbo àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí ni a ń dá lẹ́kọ̀ọ́ fún ìyè nínú ayé tuntun rẹ̀. Wọ́n ń kọ́ òye tẹ̀mí àti àwọn òye mìíràn tí a ń fẹ́ láti sọ ilẹ̀ ayé yìí di párádísè kan. Wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé Párádísè yẹn yóò wáyé ní tòótọ́ nítorí “olùṣòtítọ́ ni ẹni tí ó ṣèlérí.”—Hébérù 10:23.

Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Kí ni àbájáde tí àìnígbàgbọ́ mú wá ní ọ̀rúndún kìíní?

◻ Ibo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè gbẹ́kẹ̀ lé e dé?

◻ Ọjọ́ ọ̀la wo ni ó wà ní ìpamọ́ fún àwọn olùṣòtítọ́?

◻ Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti mú ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ dájú fún ara wa nínú ayé tuntun Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Lọ́wọ́lọ́wọ́, Jèhófà ń dá ìpìlẹ̀ àwùjọ ayé tuntun kan sílẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́