Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Pé Jehofa Yóò Mú Ète Rẹ̀ Ṣẹ
“Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” —ORIN DAFIDI 37:29.
1. Kí ni ète Jehofa fún àwọn ènìyàn àti fún ilẹ̀-ayé yìí?
NÍGBÀ tí Jehofa dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Adamu àti Efa, ó dá wọn ní pípé. Ó sì dá wọn kí wọ́n baà lè gbé títíláé lórí ilẹ̀-ayé yìí—bí wọ́n bá ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀. (Genesisi 1:26, 27; 2:17) Síwájú síi, Ọlọrun fi wọ́n sínú àwọn àyíká tí ó jẹ́ ti paradise. (Genesisi 2:8, 9) Jehofa sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bí síi, kí ẹ sì máa rẹ̀, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀.” (Genesisi 1:28) Nípa báyìí, àwọn ọmọ wọn yóò tàn káàkiri ilẹ̀-ayé ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, plánẹ́ẹ̀tì yìí yóò sì di paradise kan tí ó kún fún ìran ènìyàn aláyọ̀, tí ó pé. Ẹ wo ìbẹ̀rẹ̀ rere tí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn ní! “Ọlọrun sì rí ohun gbogbo tí ó dá, sì kíyèsí i, dáradára ni.”—Genesisi 1:31.
2. Ipò àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn gbé àwọn ìbéèrè wo dìde?
2 Síbẹ̀, ipò àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti wà fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún kò ní ìfarajọra kankan pẹ̀lú ète Ọlọrun ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Aráyé jìnnà réré sí ìjẹ́pípé wọn kò sì láyọ̀. Àwọn ipò ayé ti jẹ́ adaniláàmú, wọ́n sì ti burú síi lọ́nà àràmàǹdà ní àkókò tiwa, gẹ́gẹ́ bí a ti sọtẹ́lẹ̀.” (2 Timoteu 3:1-5, 13) Nítorí náà báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé ète Ọlọrun fún ẹ̀dá ènìyàn yóò ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́? Ọ̀pọ̀ àkókò gígùn síi yóò ha kọjá pẹ̀lú àwọn ipò tí ń daniláàmú tí ń bá a nìṣó bí?
Kí Ni Ó Fa Sábàbí?
3. Èéṣe tí Jehofa kò fòpin sí ìṣọ̀tẹ̀ aráyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?
3 Àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mísí mọ ìdí tí Jehofa fi gba àwọn ipò búburú wọ̀nyí láyè. Wọ́n mọ ohun tí yóò ṣe nípa wọn pẹ̀lú. Láti inú àkọsílẹ̀ Bibeli, wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣi ẹ̀bùn àgbàyanu ti òmìnira yíyàn tí Ọlọrun ti fifún ẹ̀dá ènìyàn lò. (Fiwé 1 Peteru 2:16.) Lọ́nà tí kò tọ́, wọ́n yan ipa-ọ̀nà òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. (Genesisi, orí 2 àti 3) Ìṣọ̀tẹ́ wọn gbé àwọn ìbéèrè ṣíṣepàtàkì jùlọ dìde, bíi: Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé ha ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso lé àwọn ẹ̀dá ènìyàn lórí bí? Ìṣàkóso rẹ̀ ha ni èyí tí ó dára jùlọ fún wọn bí? Ìṣàkóso ènìyàn ha lè kẹ́sẹjárí láìsí àbójútó Ọlọrun bí? Ọ̀nà dídájú tí a lè gbà wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni láti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn rékọjá. Ìyọrísí náà yóò fihàn rékọjá iyèméjì èyíkéyìí yálà àwọn ènìyàn lè ṣàṣeyọrísírere láìní ọwọ́ Ẹlẹ́dàá wọn nínú.
4, 5. (a) Kí ni ó ti jẹ́ ìyọrísí kíkọ̀ tí ènìyàn kọ ìṣàkóso Ọlọrun sílẹ̀? (b) Kí ni àkókò tí ó ti kọjá fihàn rékọjá iyèméjì èyíkéyìí?
4 Nígbà tí Adamu àti Efa kọ Ọlọrun sílẹ̀, òun kò tún fún wọn ní ìtìlẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé mọ́. Láìsí ìtìlẹ́yìn rẹ̀, wọ́n di ẹni tí ìlọsẹ́yìn débá. Ìyọrísí náà jẹ́ àìpé, ọjọ́ ogbó, àti pabambarì rẹ̀ ikú. Nípasẹ̀ àwọn òfin àjogúnbá, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ta àtaré àwọn ànímọ́ búburú wọ̀nyẹn sórí gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn, títíkan àwa. (Romu 5:12) Kí sì ni nípa ti ìyọrísí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn? Ó ti jẹ́ alájàálù, gan-an gẹ́gẹ́ bí Oniwasu 8:9 ti sọ níti tòótọ́ pé: “Ẹnìkan ń ṣe olórí ẹnìkejì fún ìfarapa rẹ̀.”
5 Àkókò tí ó ti kọjá ti fihàn rékọjá iyèméjì èyíkéyìí pé àwọn ènìyàn kò ní agbára láti darí àwọn àlámọ̀rí wọn lọ́nà yíyọrísírere láìní ọwọ́ Ẹlẹ́dàá wọn nínú. Jeremiah òǹkọ̀wé Bibeli tí a mísí náà polongo pé: “Oluwa! èmi mọ̀ pé, ọ̀nà ènìyàn kò sí ní ipa araarẹ̀: kò sí ní ipa ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.”—Jeremiah 10:23; Deuteronomi 32:4, 5; Oniwasu 7:29.
Ète Ọlọrun Kò Tíì Yípadà
6, 7. (a) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ọ̀rọ̀-ìtàn ha ti yí ète Jehofa padà bí? (b) Kí ni ó wémọ́ ète Jehofa?
6 Ǹjẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí ó ti kọjá lọ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn ẹ̀dá ènìyàn—tí ó kúnfọ́fọ́ gan-an fún ìwà-burúkú àti ìjìyà—ha ti yí ète Ọlọrun padà bí? Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Báyìí ni Oluwa wí, ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run; Ọlọrun tìkáraarẹ̀ tí ó mọ ayé, tí ó sì ṣe é; ó ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò dá a lásán, ó mọ ọ́n kí a lè gbé inú rẹ̀.” (Isaiah 45:18) Nítorí náà Ọlọrun dá ilẹ̀-ayé kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn lè gbé inú rẹ̀, ìyẹn ṣì jẹ́ ète rẹ̀ síbẹ̀.
7 Kìí ṣe pé Jehofa dá ilẹ̀-ayé kí a lè gbé inú rẹ̀ nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún pète pé kí ó di paradise kan tí àwọn ènìyàn pípé, aláyọ̀ yóò gbádùn. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Bibeli fi sọtẹ́lẹ̀ pé “ayé titun,” ẹgbẹ́-àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn titun kan, nínú èyí tí “òdodo ń gbé” yóò wà. (2 Peteru 3:13) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sì sọ fún wa ní Ìfihàn 21:4 pé nínú ayé titun rẹ̀, “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [aráyé]; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́.” Nítorí irúfẹ́ àwọn ìdí bẹ́ẹ̀ ni Jesu fi lè sọ̀rọ̀ nípa ayé titun orí ilẹ̀-ayé tí ń bọ̀ yẹn gẹ́gẹ́ bíi “Paradise.”—Luku 23:43.
8. Èéṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé Jehofa yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ?
8 Níwọ̀n bí Jehofa ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá àgbáyé, alágbára gbogbo, ọlọ́gbọ́n gbogbo, kò sí ẹni tí ó lè ké ète rẹ̀ nígbèrí. “Oluwa àwọn ọmọ-ogun ti búra, wí pé, Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.” (Isaiah 14:24) Nípa báyìí, nígbà tí Ọlọrun sọ pé òun yóò sọ ilẹ̀-ayé yìí di paradise kan tí àwọn ènìyàn pípé yóò máa gbé, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Jesu wí pé: “Alábùkúnfún ni àwọn ọlọ́kàn-tútù: nítorí wọn ó jogún ayé.” (Matteu 5:5; fiwé Orin Dafidi 37:29.) Àwa lè gbáralé ìmúṣẹ ìlérí yẹn. Ní tòótọ́, a lè fi ìwàláàyè wa wewu nítorí rẹ̀.
Wọ́n Gbẹ́kẹ̀lé Jehofa
9. Kí ni Abrahamu ṣe tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Jehofa hàn?
9 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn olùbẹ̀rù Ọlọrun jálẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn ti fi ìwàláàyè wọn wewu nítorí ète Ọlọrun fún ilẹ̀-ayé nítorí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tí ó dájú pé òun yóò mú un ṣẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ wọn lè ṣaláì tó nǹkan, wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun wọ́n sì kọ́ ìgbésí-ayé wọn yíká ṣíṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. A ní Abrahamu, ẹni tí ó wàláàyè ní nǹkan bíi 2,000 ọdún ṣáájú kí Jesu tó rìn lórí ilẹ̀-ayé—tipẹ́tipẹ́ kí a tò bẹ̀rẹ̀ sí kọ Bibeli, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan. Ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jehofa yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ó jọ pé, Abrahamu kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá láti ọ̀dọ̀ Ṣemu, babańlá rẹ̀ olùṣòtítọ́, ẹni tí Noa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Nítorí náà nígbà tí Ọlọrun sọ fún Abrahamu láti jáde kúrò ní ìlú Uri ti Kaldea tí ó ní aásìkí láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani tí kò gbajúmọ̀ tí ó sì léwu, babańlá yẹn mọ̀ pé òun lè gbẹ́kẹ̀lé Jehofa, àti nítorí náà ó lọ. (Heberu 11:8) Nígbà tí ó yá, Jehofa sọ fún un pé: “Èmi óò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.”—Genesisi 12:2.
10, 11. Èéṣe tí Abrahamu fi múratán láti fi ọmọkùnrin bíbí-kanṣoṣo rẹ̀, Isaaki rúbọ?
10 Kí ni ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí a bí Isaaki fún Abrahamu? Jehofa fihan Abrahamu pé nípasẹ̀ Isaaki ní àwọn ọmọ-ìran rẹ̀ yóò gbèrú di orílẹ̀-èdè ńlá kan. (Genesisi 21:12) Nípa báyìí, ó ti gbọ́dọ̀ dàbí ohun kan tí ó takora gan-an nígbà tí Jehofa sọ fún Abrahamu, gẹ́gẹ́ bí ìdánwò ìgbàgbọ́ rẹ̀, pé kí ó fi Isaaki ọmọkùnrin rẹ̀ rúbọ. (Genesisi 22:2) Síbẹ̀, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jehofa, Abrahamu gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti ṣègbọràn, ní mímú ọbẹ rẹ̀ láti fi dúḿbú Isaaki níti gidi. Ní ìṣẹ́jú tí ó kẹ́yìn, Ọlọrun rán angẹli kan láti dá Abrahamu dúró.—Genesisi 22:9-14.
11 Èéṣe tí Abrahamu fi jẹ́ onígbọràn tóbẹ́ẹ̀? Heberu 11:17-19 ṣípayá pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu, nígbà tí a dán an wò, fi Isaaki rúbọ: ẹni tí ó sì ti fi ayọ̀ gba ìlérí wọnnì fi ọmọ-bíbí rẹ̀ kanṣoṣo rúbọ. Níti ẹni tí a wí pé, Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ: ó sì parí rẹ̀ sí pé Ọlọrun tilẹ̀ lè gbé e dìde, àní kúrò nínú òkú, àti ibi tí ó ti gbà á padà pẹ̀lú ní àpẹẹrẹ.” Romu 4:20, 21 bákan náà sọ pé: “[Abrahamu] kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì ìlérí Ọlọrun; . . . nígbà tí ó sá ti mọ̀ dájúdájú pé, ohun tí [Ọlọrun] bá ti lérí, ó sì lè ṣe é.”
12. Báwo ni a ṣe san èrè fún Abrahamu nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀?
12 Abrahamu ni a san èrè fún nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kìí ṣe nípa dídá ẹ̀mí Isaaki sí àti mímú “orílẹ̀-èdè ńlá” kan ti ipasẹ̀ rẹ̀ wá nìkan ni ṣùgbọ́n ní ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú. Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé: “Àti nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé: nítorí tí ìwọ ti gba ohùn mi gbọ́.” (Genesisi 22:18) Báwo? Ọba Ìjọba Ọlọrun lókè ọ̀run yóò wá nípasẹ̀ ìlà ìran Abrahamu. Ìjọba yẹn yóò fọ́ ayé búburú tí ó wà lábẹ́ Satani yìí túútúú di aláìsí. (Danieli 2:44; Romu 16:20; Ìfihàn 19:11-21) Nígbà náà, nínú ayé kan tí a ti fọ̀mọ́ lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba, a óò mú Paradise gbèrú kárí ilẹ̀-ayé, àwọn ènìyàn tí ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun láti “gbogbo orílẹ̀-èdè” yóò sì gbádùn ìlera àti ìwàláàyè pípé títíláé. (1 Johannu 2:15-17) Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé òye Abrahamu nípa Ìjọba náà kò tó nǹkan, ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ó sì fojúsọ́nà fún ìgbékalẹ̀ rẹ̀.—Heberu 11:10.
13, 14. Èéṣe tí Jobu fi gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun?
13 Ní ọgọ́rùn ún ọdún mélòókan lẹ́yìn náà, a rí àpẹẹrẹ ti Jobu, tí ó gbé láàárín ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkẹrìndínlógún B.C.E. ní ibi tí a mọ̀ sí Arabia nísinsìnyí. Òun pẹ̀lú gbé láyé ṣáájú kí a tó bẹ̀rẹ̀ síí kọ Bibeli. Jobu “ṣe olóòótọ́, ó dúróṣinṣin, ẹni tí ó sì bẹ̀rù Ọlọrun, tí ó sì kórìíra ìwà búburú.” (Jobu 1:1) Nígbà tí Satani fi òkùnrùn aronilára, tí ó kóninírìíra gidigidi pọ́n Jobu lójú, ọkùnrin olùṣòtítọ́ yẹn “kò sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kanṣoṣo péré jáde” ní gbogbo ìgbà tí ó fi ní ìrírí agbonijìgì náà. (Jobu 2:10, The New English Bible) Jobu gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun. Nígbà tí ó jẹ́ pé òun kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdí tí òun fi ń jìyà púpọ̀ bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí ìwàláàyè òun sinmi lórí Ọlọrun àti àwọn ìlérí Rẹ̀.
14 Jobu mọ̀ pé bí òun tilẹ̀ kú, Ọlọrun lè dá òun padà sí ìwàláàyè lọ́jọ́ kan nípasẹ̀ àjíǹde. Ó fi ìrètí yìí hàn nígbà tí ó sọ fún Jehofa Ọlọrun pé: “Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò-òkú, . . . ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi. Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí? . . . Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn.” (Jobu 14:13-15) Bí ó tilẹ̀ ń jẹ̀rora, Jobu fi ìgbàgbọ́ hàn nínú ipò-ọba-aláṣẹ Jehofa, ní wíwí pé: “Títí èmi ó fi kú èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.”—Jobu 27:5.
15. Báwo ni Dafidi ṣe sọ̀rọ̀jáde nípa ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú ìlérí Jehofa?
15 Ní nǹkan bí ọ̀rúndún mẹ́fà lẹ́yìn Jobu àti ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí Jesu tó wá sórí ilẹ̀-ayé, Dafidi sọ̀rọ̀jáde nípa ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú ayé titun kan. Ó sọ nínú àwọn psalmu pé: “Àwọn tí ó dúró de Oluwa ní yóò jogún ayé. Nítorí pé nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn ó sì máa ṣe inúdídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” Nítorí ìgbàgbọ́ aláìyẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi rọni pé: “Gbẹ́kẹ̀lé Oluwa . . . Ṣe inúdídùn sí Oluwa pẹ̀lú, òun ó sì fi ìfẹ́-inú rẹ fún ọ.”—Orin Dafidi 37:3, 4, 9-11, 29.
16. Ìrètí wo ni ‘àwọsánmà ńlá ti àwọn ẹlẹ́rìí’ ní?
16 Láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí wá, àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ ti ní ìrètí yìí kan-náà nípa ìyè ayérayé lórí ilẹ̀-ayé. Ní tòótọ́, wọ́n parapọ̀ di ‘àwọsánmà ńlá ti àwọn ẹlẹ́rìí’ tí wọ́n fi ìwàláàyè wọn wewu níti gidi nítorí àwọn ìlérí Jehofa. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹlẹ́rìí Jehofa ìgbàanì wọ̀nyẹn ni a dálóró tí a sì ṣekúpa nítorí ìgbàgbọ́ wọn, “kí wọn kí ó lè rí àjíǹde tí ó dára jù gbà.” Báwo ni ìyẹn yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀? Nínú ayé titun, Ọlọrun yóò fi àjíǹde tí ó dára jù àti ìfojúsọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun san èrè fún wọn.—Johannu 5:28, 29; Heberu 11:35; 12:1.
Àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí Gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun
17. Báwo ni àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé gbọnyingbọnyin nínú Jehofa tó?
17 Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., Jehofa ṣípayá àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ púpọ̀ síi nípa Ìjọba náà àti àkóso rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé fún ìjọ Kristian tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbékalẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀mí rẹ̀ mísí aposteli Johannu láti kọ̀wé pé iye àwọn tí yóò darapọ̀ mọ́ Jesu Kristi nínú Ìjọba ti ọ̀run yóò jẹ́ 144,000. Àwọn wọ̀nyí yóò jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ ti Ọlọrun tí a ti “rà padà láti inú ayé wá.” (Ìfihàn 7:4; 14:1-4) Wọn yóò ṣàkóso lé ilẹ̀-ayé lórí ‘gẹ́gẹ́ bí ọba’ pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Ìfihàn 20:4-6) Gbọnyingbọnyin ni àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní wọ̀nyí ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jehofa yóò mú ète rẹ̀ fún Ìjọba ti òkè ọ̀run àti pápá-àkóso rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé ṣẹ débi tí wọ́n fi wà ní ìmúratán láti jọ̀wọ́ ìwàláàyè wọn nítìtorí ìgbàgbọ́ wọn. Ohun tí púpọ̀ nínú wọn ṣe gan-an nìyẹn.
18. Báwo ní àwọn Ẹlẹ́ríì Jehofa lónìí ṣe ń farawé àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ti ìgbà àtijọ́?
18 Lónìí, nǹkan bíi million márùn ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé kan-náà nínú Ọlọrun bíi ti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n wàláàyè ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ọjọ́ wa wọ̀nyí pẹ̀lú ti fi ìwàláàyè wọn wewu nítorí àwọn ìlérí Ọlọrun. Wọ́n ti ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ fún un wọ́n sì ní odidi Bibeli láti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. (2 Timoteu 3:14-17) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ọjọ́ wa wọ̀nyí ṣàfarawé àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu ọ̀rúndún kìn-ín-ní tí wọ́n polongo pé àwọn yóò “gbọ́ ti Ọlọrun ju ti ènìyàn lọ.” (Iṣe 5:29) Ní ọ̀rúndún yìí ọ̀pọ̀ nínú àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ni a ti ṣenúnibíni sí lọ́nà ìkà. Àwọn kan ni a tilẹ̀ ti ṣekúpa nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn mìíràn ti kú nítorí àìsàn, jàm̀bá, tàbí ọjọ́ ogbó. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá, wọ́n ti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun nítorí pé wọ́n mọ̀ pé yóò dá wọn padà sí ìwàláàyè nínú ayé titun rẹ̀ nípasẹ̀ àjíǹde.—Johannu 5:28, 29; Iṣe 24:15; Ìfihàn 20:12, 13.
19, 20. Kí ni a mọ̀dájú nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli fún ọjọ́ wa?
19 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọrírì rẹ̀ pé mímú tí a mú wọn jáde láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo wá sínú ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé kan ní a ti sọtẹ́lẹ̀ tipẹ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli. (Isaiah 2:2-4; Ìfihàn 7:4, 9-17) Jehofa sì ń mú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé láti kó àwọn olóòótọ́-ọkàn mìíràn síi jọ sínú ojúrere àti ààbò rẹ̀. (Owe 18:10; Matteu 24:14; Romu 10:13) Gbogbo àwọn wọ̀nyí fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Jehofa, ní mímọ̀ pé òun kò ní pẹ́ mú ayé titun àgbàyanu rẹ̀ wá.—Fiwé 1 Korinti 15:58; Heberu 6:10.
20 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli fihàn pé ayé Satani ti wà nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀ fún ohun tí ó súnmọ́ 80 ọdún nísinsìnyí, láti ọdún ṣíṣekókó náà 1914. Ayé yìí ń súnmọ́ òpin rẹ̀. (Romu 16:20; 2 Korinti 4:4; 2 Timoteu 3:1-5) Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ́kàn nítorí pé wọ́n mọ̀ pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọrun yóò gba ìṣàkóso gbogbo àwọn àlámọ̀rí ilẹ̀-ayé pátá. Nípa mímú ayé búburú ti ìsinsìnyí wá sópin àti mímú ayé titun òdodo rẹ̀ wá, Ọlọrun yóò pa àwọn ipò búburú tí ó ti wà lórí ilẹ̀-ayé fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún rẹ́ pátápátá.—Owe 2:21, 22.
21. Èéṣe ti a fi lè yọ̀ láìka àwọn wàhálà wa ìsinsìnyí sí?
21 Nígbà náà, títí ayérayé, Ọlọrun yóò fi ìbìkítà ńlá rẹ̀ hàn fún wa nípa rírọ̀jò àwọn ìbùkún tí yóò rọ́pò ìpalára èyíkéyìí tí a ti rígbà ní ìgbà tí ó kọjá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Àwọn ohun rere púpọ̀ jaburata yóò ṣẹlẹ̀ sí wa nínú ayé titun náà débi tí àwọn wàhálà wa yóò fi pòórá kúrò nínú ìrántí wa. Báwo ni ó ti tuninínú tó láti mọ̀ pé nígbà náà ni Jehofa yóò ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀, tí yóò sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.’—Orin Dafidi 145:16; Isaiah 65:17, 18.
22. Èéṣe tí a fi níláti fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Jehofa?
22 Nínú ayé titun náà, aráyé olùṣòtítọ́ yóò rí ìmúṣẹ Romu 8:21 pé: “A ó sọ ẹ̀dá tìkaláraarẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọrun.” Wọn yóò rí i tí àdúrà tí Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò ní ìmúṣẹ: “Kí ìjọba rẹ dé; ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bíi ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.” (Matteu 6:10) Nítorí náà, fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ kíkún sínú Jehofa nítorí pé ìlérí rẹ̀ tí kò lè ní àṣìṣe nínú ni pé: “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.”—Orin Dafidi 37:29.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ète Jehofa fún àwọn ènìyàn àti fún ilẹ̀-ayé yìí?
◻ Èéṣe tí Ọlọrun fi fàyègba àwọn ipò búburú lórí ilẹ̀-ayé?
◻ Báwo ni àwọn ènìyàn olùṣòtítọ́ ti ìgbà àtijọ́ ṣe fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Jehofa hàn?
◻ Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lónìí fi gbẹ́kẹ̀lé Jehofa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọlọrun dá àwọn ènìyàn láti wàláàyè títíláé nínú ayọ̀ lórí paradise ilẹ̀-ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Abrahamu fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú agbára Jehofa láti jí òkú dìde