A Mú Ìdájọ́ Ṣẹ Ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Ti Ìpinnu
“Jẹ́ kí . . . àwọn orílẹ̀-èdè . . . gòkè wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì; nítorí ibẹ̀ ni èmi yóò jókòó sí, kí n bàa lè ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—JÓẸ́LÌ 3:12.
1. Èé ṣe tí Jóẹ́lì fi rí àwọn ogunlọ́gọ̀ tí ó péjọ sí “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu”?
“OGUNLỌ́GỌ̀, ogunlọ́gọ̀ wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu”! A ka àwọn ọ̀rọ̀ tí ń runi sókè wọ̀nyẹn nínú Jóẹ́lì 3:14. Èé ṣe tí àwọn ogunlọ́gọ̀ wọ̀nyí sì fi kó ara wọn jọ? Jóẹ́lì dáhùn pé: “Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.” Ó jẹ́ ọjọ́ ńlá ti ìdáláre Jèhófà—ọjọ́ ìmúdàájọ́ṣẹ sórí ògìdìgbó àwọn tí wọ́n ti kọ Ìjọba Ọlọ́run tí a gbé kalẹ̀ lábẹ́ Kristi Jésù. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, “àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin” inú Ìṣípayá orí 7 yóò ní láti jọ̀wọ́ “ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé” tí wọ́n ti dì mú pinpin náà, èyí yóò sì yọrí sí “ìpọ́njú ńlá . . . irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.”—Ìṣípayá 7:1; Mátíù 24:21.
2. (a) Èé ṣe tí a fi pe ibi ìmúdàájọ́ṣẹ ti Jèhófà ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì,” lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú? (b) Báwo ni Jèhóṣáfátì ti hùwà padà lọ́nà yíyẹ nígbà tí a gbógun tì í?
2 Nínú Jóẹ́lì 3:12, a pe ibi ìmúdàájọ́ṣẹ yìí ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì.” Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, ní àkókò rúkèrúdò kan nínú ìtàn Júdà, Jèhófà múdàájọ́ ṣẹ níbẹ̀ nítorí Ọba Jèhóṣáfátì oníwà rere, ẹni tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Onídàájọ́.” Ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọrírì ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò tiwa láìpẹ́. Àkọsílẹ̀ náà wà nínù 2 Kíróníkà orí 20. Ní ẹsẹ 1 orí yẹn, a kà pé “àwọn ọmọ Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn kan lára àwọn Ámónímù pẹ̀lú wọn wá láti dojú kọ Jèhóṣáfátì nínú ogun.” Báwo ni Jèhóṣáfátì ṣe hùwà padà? Ó ṣe ohun tí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà sábà máa ń ṣe nígbà yánpọnyánrin. Ó yíjú sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà, nípa gbígbàdúrà tọkàntọkàn pé: “Ìwọ Ọlọ́run wa, ìwọ kì yóò ha mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún lé wọn lórí? Nítorí pé kò sí agbára kankan nínú wa níwájú ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí tí ń bọ̀ wá gbéjà kò wá; àwa alára kò sì mọ ohun tí à bá ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.”—2 Kíróníkà 20:12.
Jèhófà Dáhùn Àdúrà
3. Ìtọ́ni wo ni Jèhófà fún Júdà nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká gbógun gbígbóná tì í?
3 Nígbà tí “gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ti Júdà wà lórí ìdúró níwájú Jèhófà, àní àwọn ọmọ wọn kéékèèké, àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn pàápàá,” Jèhófà dáhùn. (2 Kíróníkà 20:13) Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” rẹ̀ lónìí, bẹ́ẹ̀ ni Olùgbọ́ àdúrà ńlá náà fún wòlíì Jahasíẹ́lì ti ìdílé Léfì lágbára láti pèsè ìdáhùn Rẹ̀ fún àwọn tí ó pé jọ. (Mátíù 24:45) A kà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún yín, ‘Ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà nítorí ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí; nítorí pé ìjà ogun náà kì í ṣe tiyín, bí kò ṣe ti Ọlọ́run. . . . Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín. . . . Ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà. Lọ́la, ẹ jáde sí wọn, Jèhófà yóò sì wà pẹ̀lú yín.’”—2 Kíróníkà 20:15-17.
4. Ní ọ̀nà wo ni Jèhófà fi béèrè pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ aláápọn, kí wọ́n má jókòó gẹlẹtẹ, nígbà tí wọ́n dojú kọ ìpèníjà ọ̀tá wọn?
4 Ohun tí Jèhófà béèrè pé kí Ọba Jèhóṣáfátì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣe ju wíwulẹ̀ jókòó gẹlẹtẹ láìṣe nǹkan kan, kí wọ́n máa retí ìdáǹdè oníṣẹ́ ìyanu. Wọ́n gbọ́dọ̀ lo àtinúdá ní kíkojú ìpèníjà àwọn ọ̀tá. Ọba àti ‘gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ti Júdà, àní àwọn ọmọ wọn kéékèèké, àwọn aya wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn pàápàá,’ fi ìgbàgbọ́ tí ó mú hánhán hàn bí wọ́n ṣe ṣègbọràn, tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, tí wọ́n sì yan jáde lọ pàdé ogunlọ́gọ̀ tí ń gbógun bọ̀ náà. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọba ń pèsè ìtọ́ni àtọ̀runwá àti ìṣírí síwájú sí i, ó ń rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run yín kí ẹ lè wà pẹ́. Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀, kí ẹ sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àṣeyọrí sí rere.” (2 Kíróníkà 20:20) Ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà! Ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀! Àṣírí àṣeyọrí sí rere nìyẹn. Bákan náà lónìí, bí a ti ń jẹ́ aláápọn nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ǹjẹ́ kí a má ṣe ṣiyèméjì láé pé òun yóò mú kí ìgbàgbọ́ wa borí!
5. Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ṣe jẹ́ aláápọn bí wọ́n ti ń yin Jèhófà?
5 Bí ti àwọn ará Jùdíà ní ọjọ́ Jèhóṣáfátì, a gbọ́dọ̀ “fi ìyìn fún Jèhófà, nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Báwo ni a ṣe ń fi ìyìn yìí fún un? Nípa ìwàásù Ìjọba aláápọn tí a ń ṣe! Bí àwọn ará Jùdíà wọ̀nyẹn ṣe “bẹ̀rẹ̀ igbe ìdùnnú àti ìyìn,” bẹ́ẹ̀ náà ni àwa ń fi àwọn iṣẹ́ kún ìgbàgbọ́ wa. (2 Kíróníkà 20:21, 22) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ jẹ́ kí á fi irú ìgbàgbọ́ tí ó mú hánhán bẹ́ẹ̀ hàn bí Jèhófà ṣe ń múra sílẹ̀ láti gbésẹ̀ lòdì sí àwọn ọ̀tá rẹ̀! Bí ọ̀nà náà tilẹ̀ jọ bí èyí tí ó jìn, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti forí tì í, kí ìgbàgbọ́ wa máa gbéṣẹ́, bí àwọn ènìyàn rẹ̀ ajàjàṣẹ́gun ti ń ṣe ní àwọn àgbègbè tí ipò nǹkan ti le koko lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Ní àwọn ilẹ̀ kan tí inúnibíni, ìwà ipá, ìyàn, àti ipò ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ ti gbòde kan, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń rí ìbísí gbígbàfiyèsí, gẹ́gẹ́ bí ìwé ọdọọdún 1998 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ti ròyìn rẹ̀.
Jèhófà Gba Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Là
6. Báwo ni ìgbàgbọ́ lílágbára ṣe ṣèrànwọ́ láti mú kí a jẹ́ adúróṣinṣin lónìí?
6 Àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run, tí ó yí Júdà ká, gbìyànjú láti bo àwọn ènìyàn Ọlọ́run mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dáhùn padà nípa kíkọ orin ìyìn rẹ̀. A lè fi ìgbàgbọ́ kan náà hàn lónìí. Nípa mímú kí ìgbésí ayé wa kún fún àwọn iṣẹ́ tí ń fi ìyìn fún Jèhófà, a ń fún ìhámọ́ra wa tẹ̀mí lókun, láìfi àyè kankan sílẹ̀ fún àwọn ìhùmọ̀ àrékérekè Sátánì láti wọlé. (Éfésù 6:11) Ìgbàgbọ́ lílágbára kò ní jẹ́ kí a di ẹni tí àwọn eré ìnàjú dídíbàjẹ́, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, àti ẹ̀mí ìdágunlá tí ó jẹ́ àmì ìdánimọ̀ ayé tí ó yí wa ká tí ń kú lọ yìí, pín ọkàn-àyà rẹ̀ níyà. Ìgbàgbọ́ tí kò ṣeé ṣẹ́gun yìí yóò mú kí a máa bá a lọ ní fífi ìdúróṣinṣin sìn pẹ̀lú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” bí a ti ń fi oúnjẹ tẹ̀mí tí a ń pèsè “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” bọ́ wa léraléra.—Mátíù 24:45.
7. Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe dáhùn padà sí onírúurú àtakò tí a gbé kò wọ́n?
7 Ìgbàgbọ́ wa tí a gbé karí Bíbélì yóò fún wa lókun láti dúró gbọn-in lòdì sí àwọn ìgbétáásì ìkórìíra tí àwọn tí ń fi ẹ̀mí “ẹrú búburú” tí a mẹ́nu kàn nínú Mátíù 24:48-51 hàn ń ru sókè. Ní mímú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lọ́nà kíkàmàmà, àwọn apẹ̀yìndà ń fúnrúgbìn irọ́ àti ìgbékèéyíde ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí, tí wọ́n tilẹ̀ ń lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n wà ní ipò yíyọrí ọlá nínú àwọn orílẹ̀-èdè. Níbi tí ó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dáhùn padà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàpèjúwe nínú Fílípì 1:7, nípa “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.” Fún àpẹẹrẹ, ní September 26, 1996, nínú ẹjọ́ kan láti Gíríìsì, àwọn adájọ́ mẹ́sẹ̀ẹ̀sán ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe, ní Strasbourg, pa ohùn pọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i pé “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá àpèjúwe ‘ẹ̀sìn tí a mọ̀ dunjú’ mu,” ó yẹ kí wọ́n jàǹfààní òmìnira ìrònú, òmìnira ẹ̀rí ọkàn, òmìnira ìgbàgbọ́, àti ẹ̀tọ́ láti sọ ìgbàgbọ́ wọn di mímọ̀. Ní ti àwọn apẹ̀yìndà, ìdájọ́ Ọlọ́run sọ pé: “Òwe tòótọ́ náà ti a máa ń pa ti ṣẹ sí wọn lára: ‘Ajá ti padà sínú èébì ara rẹ̀, àti abo ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀ sínú yíyígbiri nínú ẹrẹ̀.’”—2 Pétérù 2:22.
8. Ní ọjọ́ Jèhóṣáfátì, báwo ni Jèhófà ṣe múdàájọ́ ṣẹ sórí àwọn ọ̀tá àwọn ènìyàn Rẹ̀?
8 Lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní ọjọ́ Jèhóṣáfátì, Jèhófà múdàájọ́ ṣẹ sórí àwọn tí o fẹ́ pa àwọn ènìyàn Rẹ̀ lára. A kà pé: “Jèhófà fi àwọn ènìyàn sí ibùba de àwọn ọmọ Ámónì, Móábù àti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì tí ń bọ̀ ní Júdà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Àwọn ọmọ Ámónì àti Móábù sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde sí àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun àti láti pa wọ́n rẹ́ ráúráú; gbàrà tí wọ́n sì ti yanjú àwọn olùgbé Séírì tán, wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ ẹnì kìíní láti run ẹnì kejì rẹ̀.” (2 Kíróníkà 20:22, 23) Àwọn ará Jùdíà sọ orúkọ ibẹ̀ ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Bérákà, Bérákà sì túmọ̀ sí “Ìbùkún.” Lóde òní pẹ̀lú, ìmúdàájọ́ṣẹ Jèhófà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò yọrí sí ìbùkún fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
9, 10. Àwọn wo ni wọ́n ti fi hàn pé àwọn yẹ fún ìdájọ́ mímúná ti Jèhófà?
9 A wá lè béèrè pé, Àwọn wo ni yóò gba ìdájọ́ ẹ̀bi gbígbóná láti ọ̀dọ̀ Jèhófà lóde òní? Láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà, a ní láti padà sí àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì. Jóẹ́lì 3:3 sọ nípa àwọn ọ̀tá àwọn ènìyàn rẹ̀, tí wọn yóò “fi àwọn ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin gba kárùwà, ọmọ tí ó jẹ́ obìnrin ni wọ́n sì tà nítorí wáìnì.” Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń wo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bí ẹni tí ó kéré sí wọn pátápátá, tí ìníyelórí àwọn ọmọ wọn kò ju iye owó tí a ń san fún kárùwà tàbí iye owó ife wáìnì kan. Wọn yóò jíhìn fún ìyẹn.
10 Àwọn tí ó tún yẹ fún ìdájọ́ ni àwọn tí ó ṣaṣẹ́wó nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 17:3-6) Àwọn tí ń ru àwọn aláṣẹ òṣèlú sókè láti ṣe inúnibíni sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì ń dí ìgbòkègbodò wọn lọ́wọ́, bí àwọn aṣáájú ìsìn kan tí wọ́n máa ń ru àwùjọ ènìyànkénìyàn sókè ti ń ṣe ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ni ìdájọ́ tọ́ sí jù lọ. Jèhófà sọ ìpinnu rẹ̀ jáde láti gbégbèésẹ̀ lòdì sí irú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀sẹ̀ bẹ́ẹ̀.—Jóẹ́lì 3:4-8.
“Ẹ Sọ Ogun Di Mímọ́!”
11. Báwo ni Jèhófà ṣe pe àwọn ọ̀tá rẹ̀ níjà láti jagun?
11 Lẹ́yìn èyí, Jèhófà ké sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti pòkìkí ìpèníjà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Ẹ sọ ogun di mímọ́! Ẹ ru àwọn ọkùnrin alágbára dìde! Ẹ jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ tòsí! Ẹ jẹ́ kí wọ́n gòkè wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun!” (Jóẹ́lì 3:9) Ìkéde ogun kan tí ó yàtọ̀ pátápátá nìyí—ogun ododo. Àwọn Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin fún Jèhófà gbára lé àwọn ohun ìjà ogun tẹ̀mí bí wọ́n tí ń dáhùn padà sí ìgbékèéyíde èké, wọ́n ń fi òtítọ́ kọjú ìjà sí èké. (2 Kọ́ríńtì 10:4; Éfésù 6:17) Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò ya “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” sí mímọ́. Yóò gbá gbogbo àwọn alátakò ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kì yóò kó ipa gidi kankan nínú rẹ̀. Ní gidi àti lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n ti ‘fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn sì ti fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.’ (Aísáyà 2:4) Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Jèhófà pe àwọn orílẹ̀-èdè alátakò níjà láti ṣe òdì kejì rẹ̀, ó wí pé: “Ẹ fi àwọn abẹ ohun ìtúlẹ̀ yín rọ idà, kí ẹ sì fi àwọn ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn yín rọ aṣóró.” (Jóẹ́lì 3:10) Ó ké sí wọn láti lo gbogbo ẹ̀rọ ogun àti ohun ìjà òde òní tí wọ́n ti tò jọ pelemọ láti fi jagun náà. Ṣùgbọ́n, wọn kò lè ṣàṣeyọrí, nítorí pé, ogun náà àti ìṣẹ́gun náà jẹ́ ti Jèhófà!
12, 13. (a) Láìka pé Ogun Tútù ti dópin sí, báwo ni ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ṣe fi hàn pé àwọn ṣì nífẹ̀ẹ́ ogun? (b) Kí ni àwọn orílẹ̀-èdè kò múra fún?
12 Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, àwọn orílẹ̀-èdè kéde pé Ogun Tútù ti parí. Lójú ìwòye èyí, ọwọ́ ha ti tẹ góńgó ìpìlẹ̀ tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń lépa, ti mímú àlàáfíà àti ààbò wá bí? Ó dájú pé ọwọ́ kò tíì tẹ̀ ẹ́! Kí ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní Burundi, Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Congo, Iraq, Liberia, Rwanda, Somalia, àti Yugoslavia àtijọ́ ń sọ fún wa? Nínú ọ̀rọ̀ Jeremáyà 6:14, wọ́n ń sọ pé: “‘Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!’ nígbà tí kò sí àlàáfíà.”
13 Bí ogun tilẹ̀ parí ní àwọn ibì kan, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà àjọ UN ṣì ń bá ara wọn díje nínú ṣíṣe àwọn ohun ìjà ogun tí ó túbọ̀ ń díjú si. Àwọn kan ṣì ń náwó sórí ìtòjọpelemọ àwọn ohun ìjà àtọ́míìkì. Àwọn mìíràn n mú àwọn ohun ìjà ogun ti oníkẹ́míkà tàbí oníbakitéríà tí ń ṣèparun lọ́pọ̀lọpọ̀ jáde. Bí àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì ṣe ń gbára jọ sí ibi tí a ń pè ní Amágẹ́dọ́nì, ó pè wọ́n níjà pé: “Ní ti aláìlera, kí ó sọ pé: ‘Ọkùnrin alágbára ni mí.’ Ẹ fúnni ní àrànṣe yín, kí ẹ sì wá, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè yíká-yíká, kí ẹ sì kó ara yín jọpọ̀.” Jóẹ́lì wá fi ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ tirẹ̀ há a láàárín pé: “Jèhófà, mú àwọn alágbára rẹ sọ̀ kalẹ̀ wá sí ibẹ̀ yẹn.”—Jóẹ́lì 3:10, 11.
Jèhófà Ń Dáàbò Bo Àwọn Tirẹ̀
14. Àwọn wo ni àwọn alágbára ti Jèhófà?
14 Àwọn wo ni àwọn alágbára ti Jèhófà? Ní nǹkan bí 280 ìgbà nínú Bíbélì, a pe Ọlọ́run tòótọ́ náà ní “Jèhófà àwọn ọmọ ogun.” (2 Àwọn Ọba 3:14) Àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ni àwọn ògìdìgbó áńgẹ́lì ọ̀run tí wọ́n dúró ní ìmúratán láti mú àṣẹ Jèhófà ṣẹ. Nígbà tí àwọn ará Síríà gbìyànjú láti mú Èlíṣà, Jèhófà la ojú ẹmẹ̀wà Èlíṣà níkẹyìn, kí ó lè rí ìdí tí wọn kò fi ní ṣàṣeyọrí: “Wò ó! ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná yí Èlíṣà ká.” (2 Àwọn Ọba 6:17) Jésù sọ pé òun lè ké gbàjarè sí Bàbá òun láti pèsè “àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá” lọ. (Mátíù 26:53) Nígbà tí Ìṣípayá ń ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe ń gẹṣin lọ láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní Amágẹ́dọ́nì, ó sọ pé: “Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run ń tẹ̀ lé e lórí àwọn ẹṣin funfun, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, funfun, tí ó mọ́. Idà gígùn mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, kí ó lè fi í ṣá àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn. Bákan náà, ó ń tẹ ìfúntí wáìnì ìbínú ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 19:14, 15) A ṣàpèjúwe ìfúntí wáìnì ìṣàpẹẹrẹ yẹn ni kedere gẹ́gẹ́ bí “ìfúntí wáìnì ńlá ti ìbínú Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 14:17-20.
15. Báwo ni Jóẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe ogun tí Jèhófà yóò bá àwọn orílẹ̀-èdè jà?
15 Nígbà náà, báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ Jóẹ́lì láti mú àwọn alágbára ti Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ wá? Nínú àwọn ọ̀rọ̀ àfiyàwòrán wọ̀nyí ni, tí ó kà pé: “Jẹ́ kí a ru àwọn orílẹ̀-èdè dìde, kí wọ́n sì gòkè wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì; nítorí ibẹ̀ ni èmi yóò jókòó sí, kí n bàa lè ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yíká-yíká. Ẹ ti dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè ti pọ́n. Ẹ wá, ẹ sọ̀ kalẹ̀, nítorí ìfúntí wáìnì ti kún. Àwọn ẹkù ìfúntí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ ní ti tòótọ́; nítorí ìwà búburú wọn ti pọ̀ yanturu. Ogunlọ́gọ̀, ogunlọ́gọ̀ wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu, nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu. Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn dájúdájú, gbogbo àwọn ìràwọ̀ yóò sì fawọ́ mímọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn dájúdájú. Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò sì ké ramúramù láti Síónì, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerúsálẹ́mù. Dájúdáju, ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò mì jìgìjìgì.”—Jóẹ́lì 3:12-16.
16. Ta ni yóò wà lára àwọn tí Jèhófà yóò múdàájọ́ ṣẹ lé lórí?
16 Bí ó ti dájú pé orúkọ náà, Jèhóṣáfátì, túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Onídàájọ́,” bẹ́ẹ̀ náà ni ó ti dájú tó pé Ọlọ́run wa, Jèhófà, yóò dá ara rẹ̀ láre ní kíkún nípa mímú ìdájọ́ ṣẹ. Àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣàpèjúwe àwọn tí ó gba ìdájọ́ ẹ̀bi gẹ́gẹ́ bí ‘ogunlọ́gọ̀, ogunlọ́gọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu.’ Agbátẹrù èyíkéyìí tó bá ṣẹ́ kù fún ìsìn èké yóò wà lára àwọn ogunlọ́gọ̀ wọ̀nyẹn. Àwọn tí a ṣàpèjúwe nínú Sáàmù kejì—àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè, àwọn ọba ilẹ̀ ayé, àti àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga—tí wọ́n yan ètò ìgbékalẹ̀ bíbàjẹ́bàlùmọ̀ ti ayé yìí láàyò ju ‘fífi ìbẹ̀rù sin Jèhófà,’ pẹ̀lú wà láàárín wọn. Àwọn wọ̀nyí kọ̀ láti “fi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu.” (Sáàmù 2:1, 2, 11, 12) Wọn kò gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba alábàákẹ́gbẹ́ ti Jèhófà. Síwájú si, àwọn ogunlọ́gọ̀ tí a sàmì sí fún ìparun yóò ní gbogbo àwọn ènìyàn tí Ọba ológo náà yóò dá lẹ́jọ́ pé wọ́n jẹ́ “ewúrẹ́,” nínú. (Mátíù 25:33, 41) Ní àkókò tí ó tọ́ lójú Jèhófà láti ké ramúramù láti Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run, Ọba àwọn ọba tí ó ti yàn yóò gẹṣin lọ láti mú ìdájọ́ yẹn ṣẹ. Dájúdájú, ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò mì jìgìjìgì! Ṣùgbọ́n, a mú un dá wa lójú pé: “Jèhófà yóò jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àti odi agbára fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—Jóẹ́lì 3:16.
17, 18. Àwọn wo ni a fi hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn olùla ìpọ́njú ńlá já, àwọn ipò wo sì ni wọn yóò gbádùn?
17 Ìṣípayá 7:9-17 fi àwọn tí ó la ìpọ́njú ńlá náà hàn gẹ́gẹ́ bí “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí ó parapọ̀ jẹ́ àwọn tí ó lo ìgbàgbọ́ nínú agbára ìràpadà tí ẹ̀jẹ̀ Jésù ní. Àwọn wọ̀nyí yóò rí ààbò ní ọjọ́ Jèhófà, nígbà tí àwọn ogunlọ́gọ̀ tí ń kóra jọ tí Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ yóò gba ìdájọ́ ẹ̀bi mímúná. Jóẹ́lì sọ fún àwọn olùlàájá pé: “Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ń gbé Síónì òkè ńlá mímọ́ mi,”—ibi tí Jèhófà ń gbé ní ọ̀run.—Jóẹ́lì 3:17a.
18 Àsọtẹ́lẹ̀ náà wá sọ fún wa pé, ibi ìṣàkóso Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run, “yóò . . . di ibi mímọ́; àti ní ti àwọn àjèjì, wọn kì yóò tún gbà á kọjá mọ́.” (Jóẹ́lì 3:17b) Kì yóò sí àwọn àjèjì nínú ọ̀run àti ní ilẹ̀ ìṣàkóso Ìjọba ọ̀run yẹn lórí ilẹ̀ ayé, nítorí pé a óò so gbogbo wọn pọ̀ ṣọ̀kan nínú ìjọsìn mímọ́gaara.
19. Báwo ni Jóẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe ayọ̀ párádísè ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí?
19 Àní lónìí pàápàá, ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà gbòde kan láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Ní ìsopọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ń pòkìkí ìdájọ́ rẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó lé ní 230 àti ní nǹkan bí 300 èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Jóẹ́lì ṣàpèjúwe aásìkí wọn lọ́nà tí ó dára, nígbà tí ó sọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé, àwọn òkè ńlá yóò máa sẹ̀ fún wáìnì dídùn, àwọn òkè kéékèèké yóò sì máa ṣàn fún wàrà, gbogbo ojú ìṣàn omi Júdà ni yóò sì máa ṣàn fún omi.” (Jóẹ́lì 3:18) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò máa bá a lọ láti tú àwọn ìbùkún aláyọ̀ àti aásìkí àti ìbísí òtítọ́ ṣíṣeyebíye tí ń kún àkúnwọ́sílẹ̀ jáde sórí àwọn olùyìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. A óò ti dá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre ní kíkún ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu, ayọ̀ yóò sì pọ̀ yanturu bí ó ṣe ń gbé láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a rà pa dà títí láéláé.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Jèhóṣáfátì?
◻ Ta ni Jèhófà sọ pé ó tọ́ sí ìparun ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu”?
◻ Àwọn wo ni àwọn alágbára ti Ọlọ́run, ipa wo sì ni wọn yóò kó nínú ìjà ogun àjàkágbá náà?
◻ Ayọ̀ wo ni àwọn olùjọsìn tòótọ́ ń gbádùn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
A sọ fún Júdà pé: ‘Má fòyà nítorí pé ìjà ogun náà kì í ṣe tiyín, bí kò ṣe ti Ọlọ́run’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jèhófà pe àwọn ọ̀tá rẹ̀ níjà láti fi ‘abẹ ohun ìtúlẹ̀ wọn rọ idà’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bíbélì fi ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn olùla ìpọ́njú ńlá já hàn