Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Jóẹ́lì
1. Báwo la ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bíi ti Jóẹ́lì?
1 Ta ni wòlíì Jóẹ́lì? Ohun kan ṣoṣo tó sọ nípa ara rẹ̀ ni pé òun jẹ́ “ọmọkùnrin Pétúélì.” (Jóẹ́lì 1:1) Jóẹ́lì kò fi ipò tó wà ṣe fọ́ńté, Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni wòlíì onírẹ̀lẹ̀ yìí ń tẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn lọ́kàn. Tí àwa náà bá ń wàásù, dípò ká máa fẹ́ káwọn èèyàn yìn wá tàbí ká máa pe àfiyèsí sí ara wa, ṣe ló yẹ ká máa darí àfiyèsí àwọn èèyàn sọ́dọ̀ Jèhófà àti sínú Bíbélì. (1 Kọ́r. 9:16; 2 Kọ́r. 3:5) Ká má gbàgbé pé iṣẹ́ ìwàásù yìí ń gbé wa ró, ó sì ń fún wa lókun! Àmọ́, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Jóẹ́lì wo ló máa mú kí àwa náà túbọ̀ ní ìtara àti ìrètí?
2. Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, kí ló yẹ ká máa ṣe?
2 “Ọjọ́ Jèhófà Sún Mọ́lé” (Jóẹ́lì 1:15): Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yìí ti wà ní àkọsílẹ̀ láti ẹgbẹ̀rún ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, àkókò tó máa ní ìmúṣe tó kẹ́yìn la wà yìí. Bí ayé ṣe ń bà jẹ́ sí i, táwọn èèyàn ń kọ etí ikún sí ìhìn rere, tí wọ́n sì ń fi wá ṣèṣín, ó túbọ̀ ń ṣe kedere pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. (2 Tím. 3:1-5; 2 Pét. 3:3, 4) Tá a bá sì wo bí òpin ṣe sún mọ́lé tó, ṣe ló yẹ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa láìjáfara.—2 Pét. 3:11, 12.
3. Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù wa fi túbọ̀ ṣe pàtàkì bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń sún mọ́lé?
3 “Jèhófà Yóò Jẹ́ Ibi Ìsádi fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀” (Jóẹ́lì 3:16): Mími ọ̀run àti ilẹ̀ ayé jìgìjìgì tí ìwé Jóẹ́lì 3:16 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ń tọ́ka sí ìdájọ́ tí Jèhófà máa ṣe nígbà ìpọ́njú ńlá. Ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà yóò gba àwa èèyàn rẹ̀ là lọ́jọ́ náà. (Ìṣí. 7:9, 14) Bá a ti ń wàásù, à ń rí bí Jèhófà ṣe ń pa wá mọ́ tó sì ń fún wa lókun, èyí ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ lẹ́mìí ìfaradà, irú ẹ̀mí yìí ló yẹ ká ní lákòókò ìpọ́njú ńlá tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ yìí.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa láyọ̀, ká má sì bẹ̀rù àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀?
4 Àwọn kan sọ pé ọ̀rọ̀ wòlíì Jóẹ́lì ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni, àmọ́ ṣe ni àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì yẹn fún àwa èèyàn Ọlọ́run nírètí pé Ọlọ́run yóò gbà wá là. (Jóẹ́lì 2:32) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká bẹ̀rù àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, ká má sì jẹ́ kí ìtara wa dín kù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bá a ti ń fi ohun tó wà nínú Jóẹ́lì 2:23 sọ́kàn pé: “Ẹ kún fún ìdùnnú, kí ẹ sì máa yọ̀ nínú Jèhófà Ọlọ́run yín.”