ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 5/15 ojú ìwé 7-9
  • Yùníìsì àti Lọ́ìsì—Àwọn Olùkọ́ni Àwòfiṣàpẹẹrẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yùníìsì àti Lọ́ìsì—Àwọn Olùkọ́ni Àwòfiṣàpẹẹrẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ “Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló”
  • Lílọ Tímótì Kúrò Nílé
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Níníyelórí Tí A Lè Rí Kọ́
  • Ẹ̀yin Ìyá, Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Yùníìsì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • “Ọmọ Mi Olùfẹ́ Ọ̀wọ́n àti Olùṣòtítọ́ Nínú Olúwa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Tímótì Fẹ́ Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
    Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa Lépa Ohun Tó Máa Gbórúkọ Ọlọ́run Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 5/15 ojú ìwé 7-9

Yùníìsì àti Lọ́ìsì—Àwọn Olùkọ́ni Àwòfiṣàpẹẹrẹ

Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a mọ̀ pé pípèsè ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí ó gbéṣẹ́ fún àwọn ọmọ wa jẹ́ ojúṣe pàtàkì. Kódà ní àwọn ipò tí ó rọni lọ́rùn jù lọ, iṣẹ́ taakuntaakun yìí lè kún fún onírúurú ìdènà àti ìṣòro. Pàápàá jù lọ nígbà tí Kristẹni òbí bá dojú kọ ìpèníjà yẹn nínú agbo ilé tí ó pínyà ní ti ẹ̀sìn. Irú ipò bẹ́ẹ̀ kì í ṣe tuntun. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa nípa òbí kan tí ó bá ara rẹ̀ nínú irú ipò yìí ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa.

Ìdílé obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yùníìsì ń gbé ní Lísírà, ìlú kan ní ẹkùn ilẹ̀ Likaóníà ní gúúsù àárín Éṣíà Kékeré. Lísírà jẹ́ ìlú eréko tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀. Ó jẹ́ ìlú tí Róòmù ń ti òkèèrè ṣàkóso, èyí tí a ń pè ní Julia Felix Gemina Lustra, tí Ọ̀gọ́sítọ́sì Késárì tẹ̀ dó láti bomi paná ìgbòkègbodò àwọn ìgárá ní àgbègbè ibẹ̀. Yùníìsì jẹ́ Kristẹni tí í ṣe Júù, tí ń gbé nínú agbo ilé tí ó pínyà ní ti ẹ̀sìn, ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tí í ṣe Gíríìkì, àti ọmọ rẹ̀ Tímótì, àti ìyá rẹ̀ Lọ́ìsì.—Ìṣe 16:1-3.

Ó jọ pé àwọn Júù tí ń gbé ní Lísírà kò pọ̀ níye, níwọ̀n bí Bíbélì kò ti mẹ́nu kàn án pé sínágọ́gù kankan wà níbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwùjọ àwọn Júù wà ní Íkóníónì, nǹkan bí 30 kìlómítà sí ibẹ̀. (Ìṣe 14:19) Nítorí náà, kò lè rọrùn fún Yùníìsì láti máa ṣe ẹ̀sìn rẹ̀. Òtítọ́ náà pé a kò dádọ̀dọ́ Tímótì, ọmọ rẹ̀, lẹ́yìn tí ó bí i, mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan parí èrò sí pé ọkọ Yùníìsì ta ko èrò náà.

Àmọ́ ṣáá o, Yùníìsì kò dá wà nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó jọ pé Tímótì gba ìtọ́ni nínú “ìwé mímọ́” láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ àti láti ọ̀dọ̀ ìyá ìyá rẹ̀, èyíinì ni Lọ́ìsì.a Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn àti pé láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.”—2 Tímótì 3:14, 15.

Ẹ̀kọ́ “Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló”

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni a ti gbin ẹ̀kọ́ tí Tímótì kọ́ láti inú “ìwé mímọ́” sí i lọ́kàn, ó jọ pé èyí túmọ̀ sí láti ìgbà ọmọ ọwọ́. Èyí jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Gíríìkì (breʹphos) tí ó lò, èyí tí a sábà máa ń lò fún ọmọ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. (Fi wé Lúùkù 2:12, 16.) Yùníìsì tipa báyìí fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fún un, láìfi àkókò ṣòfò kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí fún Tímótì ní ìtọ́ni tí yóò ràn án lọ́wọ́ láti dàgbà di ìránṣẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run.—Diutarónómì 6:6-9; Òwe 1:8.

A yí Tímótì “lérò padà láti gba” àwọn òtítọ́ láti inú Ìwé Mímọ́ gbọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè Gíríìkì kan ti wí, ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò níhìn-ín túmọ̀ sí “kí a yíni lérò padà pátápátá nípa nǹkan kan; kí nǹkan kan dáni lójú.” Láìsí àní-àní, ó gba àkókò àti ìsapá tí kò kéré láti mú kí irú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára tó bẹ́ẹ̀ ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà Tímótì, kí ó ràn án lọ́wọ́ láti ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Fún ìdí yìí, ó hàn gbangba pé Yùníìsì àti Lọ́ìsì ṣiṣẹ́ kára láti fi Ìwé Mímọ́ kọ́ Tímótì lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ sì wo èrè ńláǹlà tí àwọn obìnrin olùbẹ̀rù Ọlọ́run wọ̀nyí jẹ! Ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé sí Tímótì pé: “Mo rántí ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú rẹ láìsí àgàbàgebè kankan, èyí tí ó kọ́kọ́ wà nínú ìyá rẹ àgbà Lọ́ìsì àti ìyá rẹ Yùníìsì, ṣùgbọ́n èyí tí mo ní ìgbọ́kànlé pé ó wà nínú rẹ pẹ̀lú.”—2 Tímótì 1:5.

Ẹ wo ipa pàtàkì tí Yùníìsì àti Lọ́ìsì kó nínú ìgbésí ayé Tímótì! Ní ti kókó yìí, òǹkọ̀wé náà David Read, sọ pé: “Bí ó bá ṣe pé àpọ́sítélì náà gbà gbọ́ pé yíyí tí a yí Tímótì lọ́kàn padà nìkan ni ó ṣe pàtàkì jù, òun ì bá ti rán an létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun àkọ́kọ́ tí ó ní í sọ nípa ìgbàgbọ́ Tímótì ni pé ó ti kọ́kọ́ ‘wà nínú . . . Lọ́ìsì àti . . . Yùníìsì.’” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìgbàgbọ́ Lọ́ìsì, Yùníìsì, àti Tímótì fi hàn pé ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí àwọn òbí àti àwọn òbí àgbà pàápàá bá fi kọ́ ọmọ nílé, ní àárọ̀ ọjọ́, sábà máa ń ṣe pàtàkì ní pípinnu ohun tí a lè retí nípa ọjọ́ ọ̀la ọmọ náà nípa tẹ̀mí. Kò ha yẹ kí èyí mú kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe láti rí sí i pé wọ́n ṣe ojúṣe yìí níwájú Ọlọ́run àti fún àwọn ọmọ wọn?

Bóyá Pọ́ọ̀lù tún ń ronú nípa irú ẹ̀mí tí Lọ́ìsì àti Yùníìsì mú kí ó wà nínú ilé wọn. Ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì náà ti ṣèbẹ̀wò sí ilé wọn nígbà tí ó kọ́kọ́ wá sí Lísírà, ní nǹkan bí ọdún 47 sí 48 Sànmánì Tiwa. Ó jọ pé ìgbà yẹn ni àwọn obìnrin méjèèjì wọ̀nyí tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni. (Ìṣe 14:8-20) Bóyá àjọṣepọ̀ ọlọ́yàyà àti aláyọ̀ tí Pọ́ọ̀lù gbádùn nínú agbo ilé yẹn ni ó fà á tí Pọ́ọ̀lù fi lo irú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lò nígbà tí ó pe Lọ́ìsì ní “ìyá àgbà” Tímótì. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Ceslas Spicq sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí ó lò (mamʹme, ní ìfiwéra pẹ̀lú teʹthe tí ó bá ìgbà mu tí ó sì jẹ́ èdè ìbọ̀wọ̀fúnni) jẹ́ “ọ̀rọ̀ tí ó fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn èyí tí ọmọdé ń lò” fún ìyá rẹ̀ àgbà, ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ pé nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí ó ní “ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ ti ìbátan tímọ́tímọ́ àti ìfẹ́ni.”

Lílọ Tímótì Kúrò Nílé

A kò mọ ipò tí Yùníìsì wà dájú ní ti ìdè ìgbéyàwó nígbà tí Pọ́ọ̀lù bẹ Lísírà wò lẹ́ẹ̀kejì (ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Tiwa). Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ méfò pé opó ni. Bí ó ti wù kí ó rí, lábẹ́ ìtọ́sọ́nà ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà, Tímótì ti dàgbà di géńdé, bóyá ẹni nǹkan bí 20 ọdún nígbà yẹn. “Àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì sì ròyìn rẹ̀ dáadáa.” (Ìṣe 16:2) Ó hàn gbangba pé a ti gbin ìfẹ́ láti tan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀ sí Tímótì lọ́kàn, nítorí pé ó tẹ́wọ́ gba ìkésíni Pọ́ọ̀lù láti bá òun àti Sílà rìnrìn àjò nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì wọn.

Ẹ fi ojú inú wo ìmọ̀lára tí Yùníìsì àti Lọ́ìsì yóò ní nígbà tí Tímótì fẹ́ láti kúrò nílé! Wọ́n mọ̀ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ bẹ ìlú wọn wò, wọn sọ àpọ́sítélì náà lókùúta, wọ́n sì fi í sílẹ̀ nítorí wọ́n rò pé ó ti kú. (Ìṣe 14:19) Nípa báyìí, ó lè má rọrùn fún wọn láti jẹ́ kí Tímótì tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ lọ. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe kàyéfì nípa bí yóò ti pẹ́ tó lẹ́nu ìrìn àjò ọ̀hún, àti pé bóyá yóò padà dé láyọ̀. Láìka irú àníyàn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n lè ní sí, kò sí iyèméjì pé ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà fún un ní ìṣírí pé kí ó tẹ́wọ́ gba àǹfààní pàtàkì yìí tí yóò jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún un láti túbọ̀ sin Jèhófà lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Níníyelórí Tí A Lè Rí Kọ́

A lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ nípa fífarabalẹ̀ ronú nípa Yùníìsì àti Lọ́ìsì. Ìgbàgbọ́ sún wọn láti tọ́ Tímótì dàgbà lọ́nà tí ó yè kooro nípa tẹ̀mí. Àpẹẹrẹ tí ó fi ìdàgbàdénú hàn tí ó sì wà déédéé ti ìfọkànsin Ọlọ́run, èyí tí àwọn òbí àgbà ń fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ọmọ wọn àti àwọn ẹlòmíràn lè ṣàǹfààní dájúdájú fún ìjọ Kristẹni lápapọ̀. (Títù 2:3-5) Àpẹẹrẹ Yùníìsì tún rán àwọn ìyá tí ó ní ọkọ tí kò gbà gbọ́ létí nípa ojúṣe àti èrè gbígbin ìtọ́ni tẹ̀mí sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. Ṣíṣe èyí lè nílò ìgboyà ńláǹlà nígbà mìíràn, ní pàtàkì bí bàbá kò bá fi ojú rere wo ẹ̀sìn ìyàwó rẹ̀. Ó tún ń béèrè fún ọgbọ́n, níwọ̀n bí aya tí í ṣe Kristẹni gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ipò orí ọkọ rẹ̀.

A san èrè fún ìgbàgbọ́, ìsapá, àti ìsẹ́ra ẹni tí Lọ́ìsì àti Yùníìsì lò nígbà tí wọ́n rí ìtẹ̀síwájú Tímótì nípa tẹ̀mí títí dé orí dídi míṣọ́nnárì àti alábòójútó títayọ. (Fílípì 2:19-22) Bákan náà lónìí, fífi àwọn òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ kọ́ àwọn ọmọ wa ń béèrè àkókò, sùúrù, àti ìpinnu, àbáyọrí rere tí ń ti inú rẹ̀ wá ń mú kí gbogbo ìsapá náà di ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe lóòótọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ, àwọn tí a ti kọ́ ‘ní ìwé mímọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló’ nínú ilé tí ó pínyà ní ti ẹ̀sìn, ń mú ayọ̀ ńláǹlà wá bá òbí wọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Òdodo ọ̀rọ̀ ni òwe tí ó sọ pé: ‘Obìnrin tí ó bí ọlọ́gbọ́n yóò kún fún ìdùnnú’!—Òwe 23:23-25.

Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ní ti àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó dà bí Yùníìsì àti Lọ́ìsì, àwọn olùkọ́ni àwòfiṣàpẹẹrẹ, ní ìmọ̀lára kan náà tí a gbé jáde nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Títú u sí “ìyá ìyá rẹ̀” ní 2 Tímótì 1:5 ní èdè Síríákì fi hàn pé Lọ́ìsì kì í ṣe ìyá bàbá Tímótì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́