Ṣọ́ra fún Àwọn Olùyọṣùtì!
Lónìí, àwítẹ́lẹ̀ ń di púpọ̀ gidigidi, sísọ nípa ọjọ́ ọ̀la sì ti di iṣẹ́ tí ń búrẹ́kẹ. Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti London sọ pé: “Bí ọdún 2000 ti ń sún mọ́lé, ohun kan tí ó ṣàjèjì, tí a kò sì ṣàìretí ń ṣẹlẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn káàkiri àgbáyé lọ́pọ̀ ìgbà ń ní ìrònú tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀, tí ó sì ń bani lẹ́rù nípa ọjọ́ ọ̀la.” Lójú ọ̀pọ̀ àwọn tí ń kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ, ìfẹ́-ọkàn jíjinlẹ̀
nínú ọjọ́ ọ̀la yìí wulẹ̀ jẹ́ pípadà ronú lórí àwọn ìyípadà
tí a ti ń retí, ṣùgbọ́n, tí kò tí ì ṣẹlẹ̀.
NÍGBÀ tí àwọn kẹ̀kẹ́ tí a ń fi ẹṣin fà bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ọkùnrin kan sàsọtẹ́lẹ̀ pé, bópẹ́bóyá ìgbẹ́ ẹṣin kò ní jẹ́ kí àwọn olùgbé ìlú ńlá Yúróòpù rímú mí mọ́. Àmọ́ ṣáá o, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kò ṣẹ. Nípa báyìí, ní pípe àfiyèsí sí ọ̀nà tí àsọtẹ́lẹ̀ gbà ń kùnà léraléra, ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé: “Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wulẹ̀ dà bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa òkìtì ìgbẹ́ ẹṣin.”
Àwọn mìíràn máa ń yọ ṣùtì sí àwọn tí ń rí ewu tí ó wà níwájú. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìdókòwò ní yunifásítì kan ní United States pe àwọn tí wọ́n kìlọ̀ nípa àyíká tí ń bà jẹ́ níjà pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn jọ kọ́ ọ, bí ìtẹ̀sí náà yóò bá burú sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ti sọ, ó ní “ìgbésí ayé wa ń sunwọ̀n sí i, yóò sì máa sunwọ̀n sí i títí láé.”
Láàárín ọ̀pọ̀ èròǹgbà tí ń fa ìdàrúdàpọ̀ àti èyí tí ó takora, ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé ohun gbogbo yóò máa wà bí ó ti ṣe wà rí. Ní yíyọṣùtì sí èrò èyíkéyìí pé Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn ènìyàn, wọ́n fi ìwà tí ó jọ ti àwọn olùyọṣùtì ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa hàn.
Ṣé Ohun Gbogbo Ṣì Wà Bó Ṣe Wà?
Lẹ́tà onímìísí kejì tí Kristẹni àpọ́sítélì Pétérù kọ ní nǹkan bí ọdún 64 Sànmánì Tiwa, kìlọ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn.”—2 Pétérù 3:3.
Àwọn olùyọṣùtì máa ń fẹ́ kí ẹni tí wọ́n ń yọ ṣùtì sí di ẹni àfiṣẹ̀sín. Ẹni tí ó bá juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀mí ìyọṣùtì lè ṣubú sínú ọ̀fìn dídi onímọtara-ẹni-nìkan nítorí pé lọ́pọ̀ ìgbà olùyọṣùtì ń fẹ́ kí àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ òun tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye òun. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn olùyọṣùtì tí Pétérù kìlọ̀ nípa wọn jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀, tí ń “rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn.” Ní mímú kí àwọn òǹkàwé rẹ̀ wà lójúfò, àpọ́sítélì náà lo ọ̀rọ̀ tí ń tẹnu mọ́ nǹkan. Ó kìlọ̀ nípa dídé “àwọn olùyọṣùtì . . . pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn.”
Àwọn olùyọṣùtì ní ọ̀rúndún kìíní jiyàn nípa ìjótìítọ́ ‘wíwàníhìn-ín Kristi tí a ti ṣèlérí,’ wọ́n ń sọ pé: “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.” (2 Pétérù 3:4) Bí ó ṣe rí lójú wọn nìyẹn. Síbẹ̀, ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àjálù tí yóò dé bá ìlú Jerúsálẹ́mù. Ó polongo pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé bá ọ, nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká, wọn yóò sì ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo, wọn yóò sì fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tí ń bẹ nínú rẹ mọ́lẹ̀, wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ.” Àṣìṣe ńlá gbáà mà ni àwọn olùyọṣùtì wọnnì ṣe o! Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù sàga ti Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì pa ìlú náà run, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àwọn olùgbé rẹ̀ sì ṣòfò. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ jù lọ olùgbé ìlú náà kò fi múra sílẹ̀ fún àgbákò yìí? Nítorí pé wọn kò fòye mọ̀ pé Ọlọ́run ti bẹ̀ wọ́n wò nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù.—Lúùkù 19:43, 44.
Àpọ́sítélì Pétérù ń tọ́ka sí dídá tí Ọlọ́run Olódùmarè yóò dá sí ọ̀ràn aráyé ní ọjọ́ ọ̀la. Pétérù kìlọ̀ pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè.” (2 Pétérù 3:10) Ní àkókò yẹn, Ọlọ́run yóò mú àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ kúrò ní gbogbo àgbáyé, yóò sì dá àwọn tí a bá rí i pé ó jẹ́ olódodo sí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn yìí ti máa ń fìgbà gbogbo ṣàlàyé, “wíwàníhìn-ín” Kristi Jésù bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914. Ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ tí yóò gbé gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ Ọlọ́run láti mú ìwà ibi kúrò ṣì wà ní ọjọ́ iwájú. Lójú ìwòye èyí, ìkìlọ̀ àpọ́sítélì náà láti ṣọ́ra fún àwọn olùyọṣùtì kàn wá gbọ̀ngbọ̀n nísinsìnyí.
Ó ti lè pẹ́ tí o ti ń mú sùúrù pé kí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn aráyé. Kí ni ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó láti mú sùúrù láìkó sọ́wọ́ àwọn olùyọṣùtì? Jọ̀wọ́ máa ka ìwé yìí nìṣó.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
“Àwọn ọjọ́ yóò dé bá ọ, nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò . . . ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ̀ láti ìhà gbogbo, . . . wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ.” Ìyẹn kì í ṣe ìkìlọ̀ tí ó yẹ kí a yọ ṣùtì sí. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sì ṣòfò.