ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 6/1 ojú ìwé 9-14
  • ‘Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Rírìn Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Kristi’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Rírìn Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Kristi’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Ha ‘Ta Gbòǹgbò Nínú Kristi’ Bí?
  • A Ha ‘Ń Gbé Ọ Ró Nínú Kristi’ Bí?
  • O Ha “Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Nínú Ìgbàgbọ́” Bí?
  • ‘Kíkún fún Ìgbàgbọ́ ní Àkúnwọ́sílẹ̀ Nínú Ìdúpẹ́’
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Gálátíà, Éfésù, Fílípì àti Kólósè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Bíbá Ọlọ́run Rìn—Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ṣé O ‘Ta Gbòǹgbò Tó O sì Fìdí Múlẹ̀ Lórí Ìpìlẹ̀ Náà’?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Máa Rìn Ní Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 6/1 ojú ìwé 9-14

‘Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Rírìn Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Kristi’

“Nítorí náà, bí ẹ ti tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—KÓLÓSÈ 2:6.

1, 2. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìgbésí ayé iṣẹ́ ìsìn ìṣòtítọ́ ti Énọ́kù sí Jèhófà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti bá òun rìn, gẹ́gẹ́ bí Kólósè 2:6, 7 ti fi hàn?

ÌWỌ ha ti fi ìgbà kan rí fara balẹ̀ wo ọmọdékùnrin kékeré kan tí ń bá bàbá rẹ̀ rìn bí? Ọmọ kékeré náà a máa ṣàfarawé gbogbo ìṣísẹ̀ bàbá rẹ̀, ìrísí ojú rẹ̀ á fi hàn pé ó jọ ọ́ lójú gan-an; bàbá rẹ̀ á di ọwọ́ rẹ̀ kan mú, ìrísí tirẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé ó kà á sí. Lọ́nà tí ó bá a mu rẹ́gí, Jèhófà lo irú àkàwé bẹ́ẹ̀ láti fi ṣàpèjúwe ìgbésí ayé iṣẹ́ ìsìn tí a fi òtítọ́ ṣe sí òun. Fún àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé Énọ́kù ọkùnrin olóòótọ́ náà “ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 5:24; 6:9.

2 Gan-an gẹ́gẹ́ bí bàbá tí ń gba tẹni rò yóò ti ran ọmọ rẹ̀ kékeré lọ́wọ́ láti bá òun rìn, Jèhófà ti fún wa ní ìrànlọ́wọ́ tí ó dára jù lọ. Ó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ilẹ̀ ayé. Nínú gbogbo ìṣísẹ̀ Jésù Kristi jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣe àgbéyọ Bàbá rẹ̀ ọ̀run lọ́nà pípé. (Jòhánù 14:9, 10; Hébérù 1:3) Nítorí náà, láti lè rìn pẹ̀lú Ọlọ́run, ó pọndandan láti rìn pẹ̀lú Jésù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí náà, bí ẹ ti tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ yín, kí ẹ máa kún fún ìgbàgbọ́ ní àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́.”—Kólósè 2:6, 7.

3. Gẹ́gẹ́ bí Kólósè 2:6, 7 ti wí, èé ṣe tí a fi lè sọ pé wíwulẹ̀ ṣe batisí nìkan kọ́ ni rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi wé mọ́?

3 Nítorí pé àwọn tí ń fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fẹ́ láti máa rìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ní sísapá láti tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pípé, wọn a ṣe ìbatisí. (Lúùkù 3:21; Hébérù 10:7-9) Kárí ayé, ní ọdún 1997 nìkan, iye tí ó ju 375,000 gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí—ìpíndọ́gba iye tí ó ju 1,000 lóòjọ́. Ìbísí yìí mà kàmàmà o! Àmọ́ ṣáá o, ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí ó wà nínú Kólósè 2:6, 7 fi hàn pé wíwulẹ̀ ṣe batisí nìkan kọ́ ni rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi wé mọ́. Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tí a tú sí “máa bá a lọ ní rírìn” ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ tí ó gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó, láìdáwọ́dúró. Síwájú sí i, Pọ́ọ̀lù fi kún un pé bíbá Kristi rìn wé mọ́ ohun mẹ́rin: kí a ta gbòǹgbò nínú Kristi, kí a máa gbé wa ró nínú rẹ̀, kí a fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, kí a sì máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí a ṣe àgbéyẹ̀wò gbólóhùn kọ̀ọ̀kan, kí a sì rí bí ó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.

O Ha ‘Ta Gbòǹgbò Nínú Kristi’ Bí?

4. Kí ni ó túmọ̀ sí láti ‘ta gbòǹgbò nínú Kristi’?

4 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé a ní láti ‘ta gbòǹgbò nínú Kristi.’ (Fi wé Mátíù 13:20, 21.) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè sapá láti rí i pé òun ta gbòǹgbò nínú Kristi? Tóò, gbòǹgbò igi kì í hàn síta, ṣùgbọ́n ó ṣe kókó fún igi náà—gbòǹgbò ní ń mú kí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ó sì ń pèsè oúnjẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ Kristi ń nípa lórí wa lọ́nà tí kò hàn síta lákọ̀ọ́kọ́, ó ń fìdí múlẹ̀ nínú èrò inú àti ọkàn-àyà wa. Níbẹ̀ wọn a máa gbé wa ró, wọn a sì máa fún wa lókun. Bí a bá gbà wọ́n láyè láti ṣàkóso ìrònú wa, àwọn ìgbésẹ̀ wa, àti àwọn ìpinnu wa, a óò sún wa láti ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà.—1 Pétérù 2:21.

5. Báwo ni a ṣe lè “ní ìyánhànhàn” fún oúnjẹ tẹ̀mí?

5 Jésù nífẹ̀ẹ́ ìmọ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ó tilẹ̀ fi wé oúnjẹ. (Mátíù 4:4) Họ́wù, nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, ìgbà 21 ni ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú ìwé mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pétérù ti gbani níyànjú—kí a “ní ìyánhànhàn” fún oúnjẹ tẹ̀mí “bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.” (1 Pétérù 2:2) Nígbà tí ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí bá ń yán hànhàn fún oúnjẹ, kì í fi ìyánhànhàn rẹ̀ pamọ́ rárá. Bí a kò bá tí ì nímọ̀lára bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí nípa oúnjẹ tẹ̀mí, àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù rọ̀ wá láti “ní” ìyánhànhàn yẹn. Lọ́nà wo? Ìlànà tí a rí nínú Sáàmù 34:8 lè ṣèrànwọ́: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” Bí a bá ń “tọ́” Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Jèhófà, “wò” déédéé, bóyá ní ṣíṣe àyọkà rẹ̀ lójoojúmọ́, a óò rí i pé ó ń ṣara lóore nípa tẹ̀mí, ó sì dára. Nígbà tí ó bá ṣe, yíyánhànhàn fún un yóò dàgbà nínú wa.

6. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti máa ṣe àṣàrò lórí ohun tí a ń kà?

6 Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe pàtàkì kí oúnjẹ dà dáadáa lẹ́yìn tí a bá jẹ ẹ́. Nítorí náà, a ní láti máa ṣe àṣàrò lórí ohun tí a kà. (Sáàmù 77:11, 12) Fún àpẹẹrẹ, bí a ti ń ka ìwé náà, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, orí kọ̀ọ̀kan yóò ṣe wá láǹfààní púpọ̀ bí a bá dáwọ́ dúró tí a sì bi ara wa pé: ‘Apá wo lára ànímọ́ Kristi ni mo rí nínú ìtàn yìí, báwo sì ni mo ṣe lè ṣàfarawé rẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi?’ Ṣíṣe àṣàrò lọ́nà yẹn yóò jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fi ohun tí a ń kọ́ sílò. Nígbà náà, bí a bá dojú kọ ìpinnu kan, a lè bi ara wa léèrè nípa ohun tí Jésù ì bá ṣe. Bí a bá ṣe ìpinnu bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a ń fi ẹ̀rí hàn pé lóòótọ́ ni a ta gbòǹgbò nínú Kristi.

7. Ojú wo ni ó yẹ kí a máa fi wo oúnjẹ tẹ̀mí líle?

7 Bákan náà, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá láti jẹ “oúnjẹ líle,” àwọn òtítọ́ jíjinlẹ̀ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Hébérù 5:14) Kíka Bíbélì látòkè délẹ̀ lè jẹ́ góńgó àkọ́kọ́ ní ṣíṣe èyí. Lẹ́yìn náà, àwọn kókó ìkẹ́kọ̀ọ́ pàtó wà, irú bí ẹbọ ìràpadà Kristi, oríṣiríṣi májẹ̀mú tí Jèhófà bá àwọn ènìyàn rẹ̀ dá, tàbí àwọn ìhìn iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn nínú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ni ó wà tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gba irúfẹ́ oúnjẹ líle bẹ́ẹ̀ sínú, kí ó sì dà. Góńgó wo ni a ń lé ní gbígba irúfẹ́ ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ sínú? Kì í ṣe láti fún wa ní ìdí láti ṣògo, bí kò ṣe láti gbé ìfẹ́ wa fún Jèhófà ró àti láti fà wá sún mọ́ ọn. (1 Kọ́ríńtì 8:1; Jákọ́bù 4:8) Bí a bá ń fi ìháragàgà gba ìmọ̀ yìí sínú, tí a ń mú un lò, tí a sì fi ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, a óò máa ṣàfarawé Kristi lóòótọ́. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ta gbòǹgbò lọ́nà yíyẹ nínú rẹ̀.

A Ha ‘Ń Gbé Ọ Ró Nínú Kristi’ Bí?

8. Kí ni ó túmọ̀ sí láti di ẹni tí a ‘gbé ró nínú Kristi’?

8 Nínú apá tí ó tẹ̀ lé e nípa rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, Pọ́ọ̀lù yí padà bìrí láti orí àwòrán kan tí a fi ojú inú yà sórí òmíràn—láti orí ti igi sí ti ilé. Nígbà tí a bá ń ronú nípa ilé kan tí a ń kọ́ lọ́wọ́, a kì í ronú nípa ìpìlẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n a tún máa ń ronú nípa ilé ńlá tí ń ga sókè sí ojútáyé, nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣekára. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a ní láti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣekára láti gbé àwọn ànímọ́ àti ìwà tí ó jọ ti Kristi ró. Irú iṣẹ́ àṣekára bẹ́ẹ̀ kì í lọ láìpe àfiyèsí, àní gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé sí Tímótì pé: ‘Jẹ́ kí ìlọsíwájú rẹ fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.’ (1 Tímótì 4:15; Mátíù 5:16) Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ Kristẹni tí ń gbé wa ró?

9. (a) Láti lè ṣàfarawé Kristi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, àwọn góńgó dídára wo ni a lè gbé kalẹ̀? (b) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí a gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

9 Jésù yàn wá láti wàásù àti láti kọ́ni ní ìhìn rere. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ó fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀, nípa jíjẹ́rìí láìṣojo àti lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. Dájúdájú, a kò lè ṣe tó bí ó ti ṣe láé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù gbé góńgó yìí kalẹ̀ fún wa: “Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Bí o kò bá nímọ̀lára pé o “wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà,” má bara jẹ́. Gbé àwọn góńgó tí ó mọ́gbọ́n dání kalẹ̀ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n yẹn. Ìmúrasílẹ̀ lè jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti yí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ padà tàbí kí o lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì nínú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. O lè gbé àwọn góńgó kalẹ̀ láti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i síta, láti ṣe ìpadàbẹ̀wò púpọ̀ sí i, tàbí láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Kò yẹ kí a gbé ìjẹ́pàtàkì ka orí bí ó ṣe pọ̀ tó nìkan—irú bí iye wákàtí, iye ìwé tí a fi sóde, tàbí iye ìkẹ́kọ̀ọ́—ṣùgbọ́n bí ó ti dára tó ni ó yẹ kí a gbé e kà. Gbígbé àwọn góńgó tí ó mọ́gbọ́n dání kalẹ̀, kí a sì nàgà sí wọn lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn fífi ara wa fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ohun tí Jèhófà fẹ́ nìyẹn—kí a “fi ayọ̀ yíyọ̀ sin” òun.—Sáàmù 100:2; fi wé 2 Kọ́ríńtì 9:7.

10. Kí ni àwọn iṣẹ́ Kristẹni mìíràn tí ó yẹ kí a ṣe, báwo sì ni ìwọ̀nyí ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?

10 Àwọn iṣẹ́ tún wà tí a ń ṣe nínú ìjọ tí ń gbé wa ró nínú Kristi. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni ti fífi ìfẹ́ hàn fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì, nítorí èyí ni àmì ìdánimọ̀ àwọn Kristẹni tòótọ́. (Jòhánù 13:34, 35) Nígbà tí a ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ nínú wa fà mọ́ olùkọ́ wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń rí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ a lè wá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù nísinsìnyí láti “gbòòrò síwájú” nípa mímọ àwọn yòókù nínú ìjọ? (2 Kọ́ríńtì 6:13) Àwọn alàgbà fẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́ àwọn, kí a sì mọyì àwọn náà. Nípa fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn, nípa bíbéèrè ìmọ̀ràn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu lọ́wọ́ wọn kí a sì tẹ́wọ́ gbà á, a óò mú kí iṣẹ́ àṣekára wọn di èyí tí ó rọrùn. (Hébérù 13:17) Lọ́wọ́ kan náà, èyí yóò fi kún gbígbé tí a ń gbé wa ró nínú Kristi.

11. Kí ni ojú ìwòye tí ó bójú mu tí ó yẹ kí a ní nípa ìbatisí?

11 Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń múni lórí yá mà ni ìbatisí jẹ́ o! Àmọ́ ṣáá o, kò yẹ kí a retí pé kí gbogbo ìṣẹ́jú ìgbésí ayé lẹ́yìn ìgbà yẹn sáà máa dùn yùngbà bẹ́ẹ̀. Apá tí ó pọ̀ nínú gbígbé wa ró nínú Kristi wé mọ́ “rírìn létòletò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí.” (Fílípì 3:16) Èyí kò túmọ̀ sí ìgbésí ayé pípòkúdu, tí ń súni. Ó kàn túmọ̀ sí rírìn tààrà—lédè mìíràn, mímú àwọn àṣà tẹ̀mí rere dàgbà, kí a sì máa tẹ̀ lé wọn ní ọjọ́ dé ọjọ́, ní ọdún dé ọdún. Rántí o, “ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mátíù 24:13.

O Ha “Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Nínú Ìgbàgbọ́” Bí?

12. Kí ni ó túmọ̀ sí láti “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́”?

12 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé apá kẹta nípa rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ó rọ̀ wá láti “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” Ìtumọ̀ kan kà pé, “ní ìdánilójú nípa ìgbàgbọ́,” nítorí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò lè túmọ̀ sí “láti dáni lójú, láti fọwọ́ sọ̀yà, àti láti sọ di aláìṣeéyípadà lábẹ́ òfin.” Bí a ti ń pọ̀ sí i ní ìmọ̀, a ń rí ìdí púpọ̀ sí i tí ó jẹ́ kí a mọ̀ pé ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà Ọlọ́run ní ẹ̀rí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ àti pé, ní tòótọ́, ó fìdí múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Ìyọrísí rẹ̀ lórí wa ni títúbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Á wá túbọ̀ nira fún ayé Sátánì láti gbò wá. Èyí rán wa létí ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù pé kí a “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Hébérù 6:1) Ìdàgbàdénú àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ jọ ń lọ pa pọ̀ ni.

13, 14. (a) Ewu wo ni ó dojú kọ ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Kólósè? (b) Kí ni ó jọ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe àfiyèsí sí?

13 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Kólósè dojú kọ àwọn ohun tí ó fi ìfẹsẹ̀múlẹ̀ wọn sínú ewu. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” (Kólósè 2:8) Pọ́ọ̀lù kò fẹ́ kí a gbé àwọn ará Kólósè lọ, àwọn tí ó ti di ọmọ abẹ́ “ìjọba Ọmọ ìfẹ́” Ọlọ́run, kí a wá mú wọn lọ kúrò nínú ipò wọn tẹ̀mí tí ó kún fun ìbùkún. (Kólósè 1:13) Kí ni ó fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà? Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí “ìmọ̀ ọgbọ́n orí,” ìgbà kan ṣoṣo tí ọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú Bíbélì. Ṣé àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, bí Plato àti Socrates ni ó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ ewu sí àwọn Kristẹni tòótọ́, ní ọjọ́ wọnnì, ọ̀rọ̀ náà “ìmọ̀ ọgbọ́n orí” ni a ń lò lọ́nà gbígbòòrò. Ó sábà máa ń tọ́ka sí ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ àti onírúurú èrò—títí kan àwọn ti ẹ̀sìn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní bí Josephus àti Philo ń pe ẹ̀sìn tiwọn ní ìmọ̀ ọgbọ́n orí—bóyá láti mú kí ó túbọ̀ fa àwọn ènìyàn mọ́ra.

14 Àwọn ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí Pọ́ọ̀lù pe àfiyèsí sí jẹ́ ti ẹ̀sìn. Ní iwájú, ní orí kan náà nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Kólósè, ó darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn tí ń kọ́ni pé, “Má ṣe fọwọ́ dì mú, tàbí tọ́ wò, tàbí fara kàn,” tí wọ́n ń tipa báyìí tọ́ka sí àwọn apá kan nínú Òfin Mósè tí ikú Kristi ti fòpin sí. (Róòmù 10:4) Ní àfikún sí àwọn ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti kèfèrí, àwọn ohun mìíràn wà tí ń nípa lórí ìjọ, tí ó sì fi ipò tẹ̀mí ìjọ sínú ewu. (Kólósè 2:20-22) Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ lòdì sí ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí í ṣe ara “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé.” Irú ìtọ́ni èké bẹ́ẹ̀ pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.

15. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tí ìrònú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí ń dojú kọ wa nígbà gbogbo mú kí ó yẹsẹ̀?

15 Gbígbé àwọn èrò àti ìrònú ènìyàn tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lárugẹ, lè wu ìfẹsẹ̀múlẹ̀ Kristẹni léwu. Lónìí, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí irúfẹ́ ewu bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù rọ̀ wá pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1) Nítorí náà, bí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ bá ń gbìyànjú láti mú kí o gbà pé gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì kò bóde mu mọ́, tàbí kẹ̀, bí aládùúgbò kan bá fẹ́ sún ọ tẹ́wọ́ gba ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tàbí bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ kan bá rọra ń tì ọ́ lọ sídìí ṣíṣe ìpalára fún ẹ̀rí ọkàn rẹ tí o ti fi Bíbélì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kódà bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ bá ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ òfíntótó, ọ̀rọ̀ òdì, tí ó jẹ́ èrò tirẹ̀, nípa àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ, má kàn tẹ́wọ́ gba ohun tí wọ́n ń sọ. Yàgò fún ohun tí kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. Bí a bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ bí a ti ń rìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.

‘Kíkún fún Ìgbàgbọ́ ní Àkúnwọ́sílẹ̀ Nínú Ìdúpẹ́’

16. Kí ni apá kẹrin nípa rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ìbéèrè wo sì ni a lè béèrè?

16 Apá kẹrin tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn nípa rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni pé kí a “máa kún fún ìgbàgbọ́ ní àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́.” (Kólósè 2:7) Ọ̀rọ̀ náà “àkúnwọ́sílẹ̀” rán wa létí odò tí ń kún bo bèbè rẹ̀. Eléyìí fi hàn pé fún àwa tí a jẹ́ Kristẹni, ìdúpẹ́ wa yóò jẹ́ ohun tí a ń ṣe nígbà gbogbo tàbí ohun tí ó ti mọ́ wa lára. Ó dára kí olúkúlùkù wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Mo ha kún fún ọpẹ́ bí?’

17. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé gbogbo wa ni a ní ohun púpọ̀ tí a lè dúpẹ́ fún, àní ní àwọn àkókò tí ó nira? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá tí o gbà pé ó yẹ ní dídúpẹ́ fún ní pàtàkì?

17 Ní tòótọ́, gbogbo wa ní ìdí púpọ̀ láti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́ sí Jèhófà lójoojúmọ́. Ní àwọn àkókò tí ó burú jù lọ pàápàá, àwọn ohun kékeré kan lè wà tí ó pèsè ìtura fún àkókò ráńpẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀rẹ́ kan lè fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn. Olólùfẹ́ lè fọwọ́ kanni lọ́nà tí ń fini lọ́kàn balẹ̀. Oorun àsùnwọra lálẹ́ lè fún ara lókun. Oúnjẹ àjẹpọ́nnulá lè fòpin sí ebi tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ yọni lójú. Orin ẹyẹ, ẹ̀rín ọmọdé, ojú ọ̀run aláwọ̀ búlúù, atẹ́gùn tí ń tuni lára—a lè ní ìrírí gbogbo ìwọ̀nyí àti jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ọjọ́ kan ṣoṣo. Ó rọrùn púpọ̀ láti fojú yẹpẹrẹ wo irú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. Gbogbo wọn kò ha yẹ fún sísọ pé o ṣeun bí? Gbogbo wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, Orísun “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Ó sì ti fún wa ní àwọn ẹ̀bùn tí ó ta yọ àwọn ẹ̀bùn tí a mẹ́nu kàn lókè yìí—fún àpẹẹrẹ, ó ti fún wa ní ìwàláàyè tìkára rẹ̀. (Sáàmù 36:9) Síwájú sí i, ó ti fún wa ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé. Láti lè pèsè ẹ̀bùn yìí, Jèhófà ṣe ìrúbọ tí ó ga jù lọ nípa rírán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, “ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe.”—Òwe 8:30; Jòhánù 3:16.

18. Báwo ni a ṣe lè fi han Jèhófà pé a kún fún ọpẹ́?

18 Ẹ wá wo bí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà ti jẹ́ òtítọ́ tó pé: “Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà.” (Sáàmù 92:1) Lọ́nà kan náà, Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà létí pé: “Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:18; Éfésù 5:20; Kólósè 3:15) Olúkúlùkù wa lè pinnu láti túbọ̀ máa kún fún ọpẹ́ sí i. Kò yẹ kí àdúrà wa máa jẹ́ kìkì ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run fún àwọn ohun tí a nílò. Kò burú bí a bá ń gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ nígbà mìíràn. Ṣùgbọ́n ronú nípa níní ọ̀rẹ́ tí ó jẹ́ pé kìkì ìgbà tí ó bá nílò nǹkan kan lọ́dọ̀ rẹ ni ó máa ń bá ọ sọ̀rọ̀! Nítorí náà, oò ṣe gbàdúrà sí Jèhófà, kí o kàn fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ kí o sì yìn ín? Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ yóò mà mú inú rẹ̀ dùn o, nígbà tí ó bá bojú wo ayé aláìmoore yìí láti ọ̀run! Àǹfààní kejì ni pé irú àdúrà bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti darí àfiyèsí sí àwọn apá rere inú ìgbésí ayé, èyí yóò sì máa rán wa létí nípa bí a ti jẹ́ alábùkúnfún tó ní tòótọ́.

19. Báwo ni èdè Pọ́ọ̀lù ní Kólósè 2:6, 7 ṣe fi hàn pé a lè máa bá a lọ ní sísunwọ̀n sí i ní rírìn pẹ̀lú Kristi?

19 Kì í ha ṣe ohun títayọ láti rí bí ìtọ́sọ́nà ọlọ́gbọ́n tí a lè fà yọ láti inú ẹsẹ kan ṣoṣo nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti pọ̀ tó? Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé kí a máa bá a lọ ní rírìn pẹ̀lú Kristi jẹ́ ohun tí ó yẹ kí olúkúlùkù wa fẹ́ láti fi sọ́kàn. Nípa báyìí, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti ‘ta gbòǹgbò nínú Kristi,’ ‘kí a máa gbé wa ró nínú rẹ̀,’ ‘kí a fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,’ kí a sì ‘máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́.’ Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ wúlò gan-an fún àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí. Ṣùgbọ́n ó kan gbogbo wa. Ronú lórí bí gbòǹgbò ńlá ti ń wọlẹ̀ lọ dòò, àti bí ilé tí a ń kọ́ lọ́wọ́ ti ń lọ sókè sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìrìn wa pẹ̀lú Kristi kì í dópin. Àyè rẹpẹtẹ wà fún ìdàgbàsókè. Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́, yóò sì bù kún fún wa, nítorí ó fẹ́ kí a máa bá a lọ ní rírìn pẹ̀lú òun àti pẹ̀lú Ọmọ òun olùfẹ́ ọ̀wọ́n, títí ayé.

Báwo ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Kí ni rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi wé mọ́?

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti ‘ta gbòǹgbò nínú Kristi’?

◻ Báwo ni a ṣe lè ‘gbé wa ró nínú Kristi’?

◻ Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ láti “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́”?

◻ Àwọn ìdí wo ni a ní fún ‘kíkún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́’?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Gbòǹgbò igi lè má hàn síta, ṣùgbọ́n òun ni ó ń pèsè oúnjẹ fún igi náà, tí ó sì mú un dúró gbọn-in

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́