ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 6/1 ojú ìwé 14-19
  • “Máa Ja Ìjà Líle Fún Ìgbàgbọ́”!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Máa Ja Ìjà Líle Fún Ìgbàgbọ́”!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dènà Ìṣekúṣe
  • Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Àtọ̀runwá
  • “Ẹ Pa Ara Yín Mọ́ Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
  • A Gbọ́dọ̀ Jà Fitafita Ká Lè Dúró Nínú Òtítọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Ẹ Ṣọra fun Awọn Apẹhinda!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Olùkọ́ Èké!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jòhánù Kìíní, Jòhánù Kejì, Jòhánù Kẹta àti Ìwé Júúdà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 6/1 ojú ìwé 14-19

“Máa Ja Ìjà Líle Fún Ìgbàgbọ́”!

“Máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́ tí a fi lé àwọn ẹni mímọ́ lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.”—JÚÚDÀ 3.

1. Lọ́nà wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí fi ń lọ́wọ́ nínú ogun jíjà?

ÌYÀ tí ń jẹ àwọn sójà lójú ogun kò kéré. Ronú nípa wíwọ tòkètilẹ̀ aṣọ ogun, kí o sì máa yan bí ológun fún àìmọye kìlómítà lábẹ́ onírúurú ipò ojú ọjọ́, kí o máa gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó rorò nípa bí a ṣe ń lo ohun ìjà, tàbí kí ó di dandan fún ọ láti gbèjà ara rẹ lójú onírúurú ipò eléwu tí ó lè fa ikú tàbí ìpalára. Àmọ́ ṣáá o, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í kópa nínú àwọn ogun orílẹ̀ èdè. (Aísáyà 2:2-4; Jòhánù 17:14) Síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé gbogbo wa wà lójú ogun nípa tẹ̀mí. Sátánì kórìíra Jésù Kristi àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gidigidi. (Ìṣípayá 12:17) Nípa báyìí, gbogbo àwọn tí ó bá pinnu láti sin Jèhófà Ọlọ́run ti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun láti ja ogun tẹ̀mí.—2 Kọ́ríńtì 10:4.

2. Báwo ni Júúdà ṣe ṣàpèjúwe ogun Kristẹni, báwo sì ni lẹ́tà yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti lo ìfaradà nínú rẹ̀?

2 Lọ́nà tí ó bá a mu, Júúdà, tí ó jẹ́ iyèkan Jésù, kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí mo tilẹ̀ ti ń ṣe ìsapá gbogbo láti kọ̀wé sí yín nípa ìgbàlà tí gbogbo wa jọ dì mú, mo rí i pé ó pọndandan láti kọ̀wé sí yín láti gbà yín níyànjú láti máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́ tí a fi lé àwọn ẹni mímọ́ lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.” (Júúdà 3) Nígbà tí Júúdà rọ àwọn Kristẹni láti “máa ja ìjà líle,” ó lo ọ̀rọ̀ tí ó tan mọ́ “ìroragógó.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìjà yìí nira gan-an, ó tilẹ̀ máa ń kún fún ìroragógó! O ha máa ń rí i pé ó ṣòro nígbà mìíràn láti lo ìfaradà nínú ìjà yìí? Lẹ́tà Júúdà tí ó kéré, ṣùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ ki sínú rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́. Ó rọ̀ wá láti dènà ìṣekúṣe, láti bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ àtọ̀runwá, àti láti pa ara wa mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kí a wo bí a ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò.

Dènà Ìṣekúṣe

3. Ipò pàjáwìrì wo ni ó dojú kọ ìjọ Kristẹni ní ọjọ́ Júúdà?

3 Júúdà lè rí i pé kì í ṣe gbogbo àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni ó ń borí nínú ogun tí wọ́n ń bá Sátánì jà. Ipò pàjáwìrì dojú kọ agbo. Júúdà kọ̀wé pé àwọn oníwà ìbàjẹ́ ti “yọ́ wọlé.” Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi àrékérekè gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Wọ́n sì ń dọ́gbọ́n fi àwáwí dá iṣẹ́ burúkú wọn láre, “wọ́n ń sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.” (Júúdà 4) Bóyá gẹ́gẹ́ bí àwọn Onímọ̀-awo ìgbàanì, wọ́n ronú pé bí èèyàn bá ṣe túbọ̀ ń dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni èèyàn ṣe lè túbọ̀ rí oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run gbà—nítorí náà, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé ó kúkú sàn láti túbọ̀ máa dẹ́ṣẹ̀! Tàbí kẹ̀, wọ́n rò pé Ọlọ́run aláàánú kò ní fìyà jẹ wọ́n láé. Láìka ohun tí wọ́n rò sí, wọ́n kò tọ̀nà.—1 Kọ́ríńtì 3:19.

4. Àpẹẹrẹ mẹ́ta wo nínú Ìwé mímọ́ ti àwọn ìdájọ́ Jèhófà tí ó ti kọjá ni Júúdà tọ́ka sí?

4 Júúdà já ìrònú burúkú wọn ní koro nípa títọ́ka sí àpẹẹrẹ mẹ́ta ti ìdájọ́ Jèhófà ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá: lòdì sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò “fi ìgbàgbọ́ hàn”; lòdì sí “àwọn áńgẹ́lì tí . . .wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì” kí wọ́n lè dẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin; àti lòdì sí àwọn olùgbé Sódómù àti Gòmórà, àwọn tí ó “ṣe àgbèrè lọ́nà tí ó pọ̀ lápọ̀jù, tí wọ́n sì ti jáde tọ ẹran ara lẹ́yìn fún ìlò tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá.” (Júúdà 5-7; Jẹ́nẹ́sísì 6:2-4; 19:4-25; Númérì 14:35) Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, Jèhófà mú ìdájọ́ mánigbàgbé wá sórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

5. Wòlíì ìgbàanì wo ni Júúdà fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe fi hàn pé ìmúṣẹ rẹ̀ dájú hán-ún?

5 Lẹ́yìn ìgbà náà, Júúdà tọ́ka sí ìdájọ́ tí ó tilẹ̀ tún nasẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó fa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù yọ—àyọkà tí a kò rí níbòmíràn nínú Ìwé Mímọ́ tí a mí sí.a (Júúdà 14, 15) Énọ́kù sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí Jèhófà yóò ṣèdájọ́ gbogbo àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ rẹ̀ mu tí wọ́n ń hù. Lọ́nà tí ó gba àfiyèsí, Énọ́kù sọ̀rọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, nítorí pé ìdájọ́ Ọlọ́run dájú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi lè sọ pé ó ti ṣẹlẹ̀ ná. Àwọn ènìyàn lè ti fi Énọ́kù rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n sì ti lè ṣe bẹ́ẹ̀ sí Nóà pẹ̀lú lẹ́yìn ìgbà náà, ṣùgbọ́n gbogbo irú àwọn olùyọṣùtì bẹ́ẹ̀ bá omi lọ nígbà Ìkún Omi tí ó kárí ayé.

6. (a) Kí ni ó ṣe pàtàkì pé kí a rán àwọn Kristẹni ọjọ́ Júúdà létí? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a fi àwọn ìránnilétí Júúdà sọ́kàn?

6 Èé ṣe tí Júúdà fi kọ̀wé nípa àwọn ìdájọ́ àtọ̀runwá wọ̀nyí? Nítorí ó mọ̀ pé àwọn kan tí ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ Kristẹni ní ọjọ́ tirẹ̀ ń dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jáì tí kò sì bójú mu bí àwọn tí ó ṣokùnfa ìdájọ́ wọnnì tí ó ti kọjá. Nípa báyìí, Júúdà kọ̀wé pé ó ṣe pàtàkì láti rán àwọn ìjọ létí nípa àwọn lájorí òtítọ́ tẹ̀mí. (Júúdà 5) Ó jọ pé wọ́n ti gbàgbé pé Jèhófà Ọlọ́run rí ohun tí wọ́n ń ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá mọ̀ọ́mọ̀ rú àwọn òfin rẹ̀, tí wọ́n sọ ara wọn àti àwọn ẹlòmíràn di ẹlẹ́gbin, ó rí i. (Òwe 15:3) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń dùn ún gan-an. (Jẹ́nẹ́sísì 6:6; Sáàmù 78:40) Ó jẹ́ ìrònú tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ pé àwa ẹ̀dá ènìyàn lásán-làsàn lè nípa lórí ìmọ̀lára Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé. Ó ń wò wá lójoojúmọ́, nígbà tí a bá sì sa gbogbo ipá wa láti tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, nígbà náà ìwà wa ń mú ọkàn-àyà rẹ̀ yọ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí irú àwọn ìránnilétí bẹ́ẹ̀ tí Júúdà pèsè bí wa nínú, ṣùgbọ́n kí a fi wọ́n sọ́kàn.—Òwe 27:11; 1 Pétérù 2:21.

7. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú ìwà àìtọ́ wíwúwo wá ìrànlọ́wọ́ ní kíá? (b) Báwo ni gbogbo wa ṣe lè yàgò fún ìṣekúṣe?

7 Kì í ṣe kìkì pé Jèhófà ń rí gbogbo rẹ̀ nìkan ni ṣùgbọ́n ó máa ń gbé ìgbésẹ̀. Níwọ̀n bí òun ti jẹ́ Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo, ó máa ń mú ìjìyà wá sórí àwọn aṣebi—bó pẹ́ bó yá. (1 Tímótì 5:24) Àwọn tí ń ronú pé ìtàn àtijọ́ lásán ni àwọn ìdájọ́ rẹ̀ àti pé kò bìkítà nípa ìwà ibi tí àwọn ń hù kàn ń tan ara wọn jẹ ni. Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó lónìí pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe lọ bá àwọn Kristẹni alàgbà ní kíá fún ìrànlọ́wọ́! (Jákọ́bù 5:14, 15) Ríronú lórí ewu ńlá tí ìṣekúṣe jẹ́ nínú ogun tẹ̀mí lè mú kí gbogbo wa jí gìrì. Ọdọọdún ni a ń rí àwọn tí ó fara gbọgbẹ́—àwọn tí a lé jáde kúrò láàárín wa, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn nítorí lílọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe láìronúpìwàdà. A gbọ́dọ̀ pinnu tọkàntọkàn láti dènà ìdẹwò èyíkéyìí, àní tí ó lè bẹ̀rẹ̀ sí darí wa lọ sí irúfẹ́ ìhà bẹ́ẹ̀.—Fi wé Mátíù 26:41.

Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Àtọ̀runwá

8. Àwọn wo ni “ẹni ògo” tí a mẹ́nu kàn nínú Júúdà ẹsẹ 8?

8 Ìṣòro mìíràn tí Júúdà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni àìbọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ àtọ̀runwá. Fún àpẹẹrẹ, ní ẹsẹ 8, ó fi ẹ̀sùn kan àwọn olubi kan náà pé wọ́n “ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú.” Àwọn wo ni “ẹni ògo” wọ̀nyí? Wọ́n jẹ́ ènìyàn aláìpé, ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ti gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ kan fún wọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ìjọ ní àwọn alàgbà, tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run. (1 Pétérù 5:2) Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ń bẹ pẹ̀lú, irú bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣàkóso, tí wọ́n ń ṣe àwọn ìpinnu tí ó kan ìjọ Kristẹni lápapọ̀. (Ìṣe 15:6) Ó dun Júúdà gan-an pé àwọn kan nínú àwọn ìjọ ń sọ̀rọ̀ tèébútèébú, tàbí ń sọ̀rọ̀ òdì sí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀.

9. Àwọn àpẹẹrẹ wo ní ti àìbọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ ni Júúdà tọ́ka sí?

9 Láti fi hàn pé irú ọ̀rọ̀ àìlọ́wọ̀ bẹ́ẹ̀ kò dára, ní ẹsẹ 11, Júúdà tọ́ka sí àpẹẹrẹ mẹ́ta sí i gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí: Kéènì, Báláámù, àti Kórà. Kéènì kọ etí dídi sí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fún un, ó sì dìídì tọ ipa ọ̀nà ìpànìyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 4:4-8) Léraléra ni a kìlọ̀ fún Báláámù, ìkìlọ̀ tí ó wá dájúdájú láti orísun tí ó ga ju ti ẹ̀dá lọ—kódà abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ bá a sọ̀rọ̀! Ṣùgbọ́n Báláámù ń fi ìmọtara-ẹni-nìkan bá a nìṣó láti gbèrò búburú sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run. (Númérì 22:28, 32-34; Diutarónómì 23:5) Kórà ní ipò ẹrù iṣẹ́ tirẹ̀, ṣùgbọ́n kò tó o. Ó dìtẹ̀ mọ́ Mósè, tí í ṣe onínú tútù jù lọ lórí ilẹ̀ ayé.—Númérì 12:3; 16:1-3, 32.

10. Báwo ni àwọn kan lónìí ṣe lè kó sínú páńpẹ́ ‘sísọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú,’ èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ láti yẹra fún irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀?

10 Ẹ wo bí àpẹẹrẹ wọ̀nyí ti kọ́ wa lọ́nà tí ó ṣe kedere tó pé kí a máa fetí sí ìmọ̀ràn, kí a sì máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Jèhófà ń lò ní ipò ẹrù iṣẹ́! (Hébérù 13:17) Ó rọrùn gan-an láti rí àléébù lára àwọn alàgbà tí a yàn, nítorí wọ́n jẹ́ aláìpé, gẹ́gẹ́ bí gbogbo wa ti jẹ́ aláìpé. Ṣùgbọ́n bí a bá ń ronú ṣáá lórí àwọn àléébù wọn, tí a sì ń jin ọ̀wọ̀ tí àwọn ènìyàn ní fún wọn lẹ́sẹ̀, ṣé kì í ṣe pé àwa náà “ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú”? Ní ẹsẹ 10, Júúdà mẹ́nu kan àwọn tí “ń sọ̀rọ̀ tèébútèébú nípa gbogbo ohun tí wọn kò mọ̀ ní ti gidi.” Nígbà mìíràn, àwọn kan a bẹnu àtẹ́ lu ìpinnu tí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ṣe tàbí èyí tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ṣe. Síbẹ̀, kì í ṣe pé wọ́n mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ tí àwọn alàgbà gbé yẹ̀ wò kí wọ́n tó dé orí ìpinnu náà. Kí wá ni ìdí tí wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ tèébútèébú nípa àwọn ohun tí wọn kò mọ̀ ní ti gidi? (Òwe 18:13) Àwọn tí kò bá jáwọ́ nínú irúfẹ́ ọ̀rọ̀ burúkú bẹ́ẹ̀ lè fa ìyapa nínú ìjọ, a sì tilẹ̀ lè fi wọ́n wé àwọn àpáta eléwu, “àwọn àpáta tí ó fara sin lábẹ́ omi” níbi àwọn àpéjọ onígbàgbọ́ ẹlẹ́gbẹ́ ẹni. (Júúdà 12, 16, 19) A kò ní fẹ́ jẹ́ ewu fún àwọn ẹlòmíràn láé nípa tẹ̀mí. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí olúkúlùkù wa pinnu láti mọyì àwọn ọkùnrin tí ó ní ẹrù iṣẹ́, nítorí iṣẹ́ àṣekára àti fífara wọn jìn fún agbo Ọlọ́run.—1 Tímótì 5:17.

11. Èé ṣe tí Máíkẹ́lì fi fà sẹ́yìn kúrò nínú lílo àwọn ọ̀rọ̀ èébú láti mú ìdájọ́ wá lòdì sí Sátánì?

11 Júúdà tọ́ka sí àpẹẹrẹ ẹnì kan tí ó bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ yíyẹ. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì ní aáwọ̀ pẹ̀lú Èṣù, tí ó sì ń ṣe awuyewuye nípa òkú Mósè, kò dá a láṣà láti mú ìdájọ́ wá lòdì sí i ní àwọn ọ̀rọ̀ èébú, ṣùgbọ́n ó wí pé: ‘Kí Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná.’” (Júúdà 9) Ìṣẹ̀lẹ̀ fífani lọ́kàn mọ́ra yìí, tí ó jẹ́ pé Júúdà nìkan ṣoṣo ni ó ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ tí a mí sí, kọ́ni ní ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì. Ní ọwọ́ kan, ó kọ́ wa pé kí a fi ìdájọ́ sílẹ̀ fún Jèhófà. Dájúdájú, Sátánì fẹ́ lo òkú Mósè olóòótọ́ lọ́nà àìtọ́, láti lè fi gbé ìjọsìn èké lárugẹ. Sátánì mà burú o! Síbẹ̀, Máíkẹ́lì fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ yẹra fún ìdájọ́ ṣíṣe, nítorí pé Jèhófà nìkan ni ó ní ọlá àṣẹ yẹn. Nítorí náà, ẹ wo bí ó ti túbọ̀ yẹ kí a yẹra fún dídá àwọn olóòótọ́ ọkùnrin lẹ́jọ́ tó, àwọn tí ń gbìyànjú láti sin Jèhófà.

12. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn tí ó ní ipò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni lè kọ́ láti inú àpẹẹrẹ Máíkẹ́lì?

12 Ní ọwọ́ kejì, àwọn tí ó ní ọlá àṣẹ nínú ìjọ pẹ̀lú lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lọ́dọ̀ Máíkẹ́lì. Ó ṣe tán, bí Máíkẹ́lì tilẹ̀ jẹ́ “olú-áńgẹ́lì,” olórí gbogbo àwọn áńgẹ́lì, kò ṣi ipò agbára rẹ̀ lò, àní lábẹ́ ìtánni-ní-sùúrù. Àwọn alàgbà olóòótọ́ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn pẹ́kípẹ́kí, wọ́n mọ̀ pé ṣíṣi ọlá àṣẹ wọn lò jẹ́ àìbọ̀wọ̀ fún ipò ọba aláṣẹ Jèhófà. Lẹ́tà Júúdà ní púpọ̀ láti sọ nípa àwọn ènìyàn tí ó ní ipò ọ̀wọ̀ nínú ìjọ ṣùgbọ́n tí wọ́n wá ṣi agbára wọn lò. Fún àpẹẹrẹ, ní ẹsẹ 12 sí 14, Júúdà kọ̀wé ìfibú gbígbóná janjan nípa “àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń bọ́ ara wọn láìsí ìbẹ̀rù.” (Fi wé Ìsíkíẹ́lì 34:7-10.) Lédè mìíràn, olórí àníyàn wọn ni láti ṣe ara wọn láǹfààní, kì í ṣe agbo Jèhófà. Lónìí, àwọn alàgbà lè kọ́ ohun púpọ̀ láti inú irú àpẹẹrẹ búburú bẹ́ẹ̀. Ní ti tòótọ́, àwọn ọ̀rọ̀ Júúdà níhìn-ín ṣàpèjúwe ní kedere ohun tí a kò fẹ́ láti jẹ́. Nígbà tí a bá juwọ́ sílẹ̀ fún ìmọtara-ẹni-nìkan, a kò lè jẹ́ ọmọ ogun Kristi; àwọn ọ̀ràn ti ara wa yóò ti mú kí ọwọ́ wa dí jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù náà: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

“Ẹ Pa Ara Yín Mọ́ Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”

13. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí gbogbo wa fi tọkàntọkàn fẹ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?

13 Ní apá ìparí lẹ́tà rẹ̀, Júúdà fúnni ní ìmọ̀ràn amọ́kànyọ̀ náà: “Ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Júúdà 21) Ohun náà tí yóò ràn wá lọ́wọ́ jù lọ láti máa ja ìjà Kristẹni ni láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run ní ìfẹ́ sí. Ó ṣe tán, ìfẹ́ ni ànímọ́ títayọ tí Jèhófà ní. (1 Jòhánù 4:8) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní Róòmù pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 8:38, 39) Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè dúró nínú ìfẹ́ yẹn? Ṣàkíyèsí ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí a lè gbé, gẹ́gẹ́ bí Júúdà ti sọ ọ́.

14, 15. (a) Kí ni ó túmọ̀ sí láti gbé ara wa ró lórí “ìgbàgbọ́ mímọ́ jù lọ” wa? (b) Báwo ni a ṣe lè ṣàyẹ̀wò ipò ìhámọ́ra tẹ̀mí wa?

14 Èyí àkọ́kọ́, Júúdà sọ fún wa pé kí a máa bá a lọ ní gbígbé ara wa ró lórí “ìgbàgbọ́” wa “mímọ́ jù lọ.” (Júúdà 20) Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ń bá a nìṣó. A dà bí ilé tí ó nílò títúbọ̀ mú kí ó lágbára sí i nítorí ìgbà tí ìjì bá máa dé. (Fi wé Mátíù 7:24, 25.) Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí a dá ara wa lójú jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a ṣàkíyèsí ibi tí a ti lè gbé ara wa ró lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wa, kí a lè túbọ̀ di alágbára àti olóòótọ́ ọmọ ogun Kristi. Fún àpẹẹrẹ, a lè ronú nípa àwọn apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ìhámọ́ra tẹ̀mí tí a ṣàpèjúwe nínú Éfésù 6:11-18.

15 Ipò wo ni ìhámọ́ra tẹ̀mí tiwa wà? Ṣé “apata ńlá ìgbàgbọ́” wa lágbára tó bí ó ṣe yẹ? Bí a ti bojú wẹ̀yìn wo àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwa ha ń rí àwọn àmì pé a ti ń dẹwọ́, irú bí ṣíṣàìlọ sí ìpàdé déédéé mọ́, pípàdánù ìtara fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, tàbí àìjáramọ́ ìdákẹ́kọ̀ọ́? Irú àwọn àmì bẹ́ẹ̀ léwu! A ní láti gbé ìgbésẹ̀ nísinsìnyí láti gbé ara wa ró, kí a sì fún ara wa lókun nínú òtítọ́.—1 Tímótì 4:15; 2 Tímótì 4:2; Hébérù 10:24, 25.

16. Kí ni ó túmọ̀ sí láti máa gbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, kí sì ni ohun kan tí ó yẹ kí a máa béèrè fún déédéé lọ́wọ́ Jèhófà?

16 Ọ̀nà kejì tí a lè gbà dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run ni láti máa bá a lọ ní “gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́.” (Júúdà 20) Ìyẹn túmọ̀ sí gbígbàdúrà lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí Jèhófà àti ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a fi ẹ̀mí mí sí. Àdúrà jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti gbà sún mọ́ Jèhófà alára, kí a sì fi hàn án pé a ń fọkàn sìn ín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a dágunlá sí àǹfààní àgbàyanu yìí láé! Nígbà tí a bá sì ń gbàdúrà, a lè béèrè—àní a lè máa béèrè ṣáá—fún ẹ̀mí mímọ́. (Lúùkù 11:13) Òun ni agbára tí ó pọ̀ jù lọ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó wa. Pẹ̀lú irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, a lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo, kí a sì lo ìfaradà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun Kristi.

17. (a) Èé ṣe tí àpẹẹrẹ Júúdà nínú ọ̀ràn àánú fi ga lọ́lá tó bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ni olúkúlùkù wa ṣe lè máa bá a lọ ní fífi àánú hàn?

17 Ẹ̀kẹta, Júúdà rọ̀ wá láti máa bá a lọ ní fífi àánú hàn. (Júúdà 22) Àpẹẹrẹ tirẹ̀ nínú èyí ga lọ́lá. Ó ṣe tán, ó dààmú lọ́nà tí ó tọ́ nípa ìwà ìbàjẹ́, ìṣekúṣe, àti ìpẹ̀yìndà tí ń yọ́ wọnú ìjọ Kristẹni. Síbẹ̀síbẹ̀, kò jẹ́ kí ṣìbáṣìbo bá òun, kí ó máa ronú pé lọ́nà kan ṣá àkókò yẹn léwu jù láti fi irú ìwà “jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” bẹ́ẹ̀ bí àánú hàn. Ó tì o, ó rọ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti máa bá a nìṣó ní fífi àánú hàn nígbàkigbà tí ó bá ṣeé ṣe, láti máa fi inú rere fèrò wérò pẹ̀lú àwọn tí ó ní iyèméjì, àní kí wọ́n tilẹ̀ máa já àwọn tí ń rìn gbéregbère nítòsí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo ‘gbà kúrò nínú iná.’ (Júúdà 23; Gálátíà 6:1) Ọ̀rọ̀ ìyànjú yẹn mà dára fún àwọn alàgbà ní àwọn àkókò wàhálà yìí o! Àwọn pẹ̀lú ń sapá láti fi àánú hàn nígbàkigbà tí ìdí bá wà fún un, tí wọ́n sì ń mú ìdúró àìyẹsẹ̀ nígbà tí ó bá pọndandan. Bákan náà, gbogbo wa yóò fẹ́ láti fi àánú hàn sí ara wa lẹ́nì kìíní kejì. Fún àpẹẹrẹ, dípò dídi kùnrùngbùn lórí àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan, kí a kúkú máa dárí jini ní fàlàlà.—Kólósè 3:13.

18. Báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé a óò ṣẹ́gun nínú ogun tẹ̀mí wa?

18 Ogun tí a ń jà kò rọrùn. Gẹ́gẹ́ bí Júúdà ti wí, “ìjà líle” ni. (Júúdà 3) Àwọn ọ̀tá wa lágbára. Kì í ṣe Sátánì nìkan, ṣùgbọ́n ayé burúkú rẹ̀ àti àwọn àìpé ti àwa fúnra wa, gbogbo wọn ní ń gbá kò wá. Síbẹ̀, a lè ní ìdánilójú gbangba pé àwa ni yóò ṣẹ́gun! Èé ṣe? Nítorí ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà ni a wà. Júúdà parí lẹ́tà rẹ̀ pẹ̀lú ìránnilétí pé, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, Jèhófà “ni kí ògo, ọlá ọba, agbára ńlá àti ọlá àṣẹ jẹ́ tirẹ̀ fún gbogbo ayérayé tí ó ti kọjá àti nísinsìnyí àti títí lọ dé gbogbo ayérayé.” (Júúdà 25) Èrò tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ha kọ́ yìí bí? Iyèméjì kankan ha lè wà, nígbà náà, pé Ọlọ́run kan náà yìí “lè ṣọ́ yín kúrò nínú kíkọsẹ̀”? (Júúdà 24) Rárá o! Kí olúkúlùkù wa pinnu láti máa bá a lọ ní dídènà ìṣekúṣe, bíbọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ àtọ̀runwá, kí a sì pa ara wa mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Lọ́nà yẹn, a ó jùmọ̀ gbádùn ìṣẹ́gun ológo.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn olùwádìí kan sọ pé inú ìwé náà, Book of Enoch, tí ìjótìítọ́ rẹ̀ kò dájú ni Júúdà ti fa ọ̀rọ̀ yọ. Ṣùgbọ́n R. C. H. Lenski sọ pé: “Ìbéèrè wa ni pé: ‘Ibo ni ìwé náà, Book of Enoch, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò bára mu yìí ti wá? Àfikún lásán ni ìwé yìí jẹ́, kò sì sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tí a ṣe àwọn apá rẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ dájú. . . ; kò sí ẹni tí ó lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé kì í ṣe inú ìwé Júúdà tìkára rẹ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú rẹ̀ ti wá.”

Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Báwo ni lẹ́tà Júúdà ṣe kọ́ wa láti dènà ìṣekúṣe?

◻ Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ àtọ̀runwá?

◻ Èé ṣe tí ó fi burú gan-an láti ṣi ọlá àṣẹ lò nínú ìjọ?

◻ Báwo ni a ṣe lè sapá láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Láìdàbí àwọn ọmọ ogun Róòmù, ogun tẹ̀mí ni àwọn Kristẹni ń jà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn ń fi ìfẹ́ sìn, kì í ṣe ìmọtara-ẹni-nìkan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́