Ìpàdé Ọdọọdún October 3, 1998
ÌPÀDÉ ỌDỌỌDÚN ti àwọn mẹ́ńbà Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania yóò wáyé ní October 3, 1998, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. A óò ṣe ìpàdé àṣeṣáájú ti àwọn mẹ́ńbà nìkan ní agogo 9:15 òwúrọ̀, ìpàdé ọdọọdún ti gbogbogbòò yóò sì tẹ̀ lé e ní agogo 10:00 òwúrọ̀.
Àwọn mẹ́ńbà Àjọ náà ní láti fi ìyípadà èyíkéyìí nínú àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ wọn nínú ọdún tí ó kọjá tó Ọ́fíìsì Akọ̀wé létí nísinsìnyí, kí àwọn lẹ́tà ìfitónilétí tí a ń lò déédéé àti ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni baà lè dé ọ̀dọ̀ wọn ní July.
Kí a dá àwọn ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni, tí a óò fi ránṣẹ́ sí àwọn mẹ́ńbà pẹ̀lú ìfitónilétí nípa ìpàdé ọdọọdún náà, padà, kí ó baà lè dé Ọ́fíìsì Akọ̀wé Society, ó pẹ́ tán, ní August 1. Mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan ní láti kọ ọ̀rọ̀ kún ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tirẹ̀ ní kíá mọ́sá, kí ó sì dá a padà, kí ó sọ bóyá òun fúnra rẹ̀ yóò wà níbi ìpàdé náà tàbí kò ní sí níbẹ̀. Ìsọfúnni tí a kọ sórí ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe pàtó lórí kókó yìí, níwọ̀n bí a óò ti gbára lé e fún pípinnu àwọn tí yóò wà níbẹ̀ fúnra wọn.
A retí pé gbogbo àkókò ìjókòó náà, títí kan ìpàdé àmójútó iṣẹ́ gan-an àti àwọn ìròyìn, yóò parí ní agogo 1:00 ọ̀sán tàbí ní kété lẹ́yìn náà. Kò ní sí àkókò ìjókòó ọ̀sán. Nítorí ìwọ̀nba àyè tí ó wà, àwọn tí ó bá ní tíkẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́ nìkan ni yóò lè wọlé. Kì yóò sí ìṣètò kankan fún fífi ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tẹlifóònù so ìpàdé ọdọọdún náà pọ̀ mọ́ àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ mìíràn.