Nígbẹ̀yìngbẹ́yín—Ìdájọ́ Òdodo fún Kóówá
“Ìjọba wa yóò gbìyànjú láti tẹ́tí sílẹ̀ lọ́nà tuntun . . . sí àwọn tí ń pohùn réré, àwọn tí ń dàníyàn, àwọn tí wọ́n ti sọ̀rètínù pé a kò lè tẹ́tí sí àròyé wọn mọ́. . . . Ohun tí ó kù báyìí ni láti tẹ̀ lé àwọn ohun tí ń bẹ nínú òfin: láti rí i dájú pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín bí gbogbo wa ṣe ní iyì ọgbọọgba níwájú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe ní iyì ọgbọọgba níwájú ènìyàn.”—Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ Ààrẹ Richard Milhous Nixon, ti United States, ní January 20, 1969.
NÍGBÀ tí àwọn ọba, ààrẹ, àti àwọn olórí ìjọba bá ń gorí àlééfà, ó ti di àṣà wọn láti sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ òdodo. Ti Richard Nixon, ààrẹ United States nígbà kan rí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀. Ṣùgbọ́n bí a bá fi ìtàn gbé àwọn ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in rẹ̀ yẹ̀ wò, ó ti di òbu pátápátá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣèlérí “láti tẹ̀ lé àwọn ohun tí ń bẹ nínú òfin,” nígbẹ̀yìngbẹ́yín Nixon jẹ̀bi ẹ̀sùn títẹ òfin lójú, a sì fipá mú un láti fi ipò rẹ̀ sílẹ̀. Ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, ‘àwọn tí ń pohùn réré, àwọn tí ń dàníyàn, àti àwọn tí wọ́n ti sọ̀rètínù’ ṣì ń kígbe kí a bàa lè gbọ́ tiwọn.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú tí ó jẹ́ ọlọ́kàn rere ti wá mọ̀, gbígbọ́ irú àwọn igbe bẹ́ẹ̀ àti yíyanjú àwọn ẹ̀dùn ọkàn wọn kò rọrùn. ‘Ìdájọ́ òdodo fún kóówá’ ti di góńgó àléèbá. Síbẹ̀síbẹ̀, ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, a ṣe ìlérí kan tí ó yẹ kí a fiyè sí—ìlérí aláìlẹ́gbẹ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo.
Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà, Ọlọ́run mú un dá àwọn ènìyàn Rẹ̀ lójú pé òun yóò rán “ìránṣẹ́” kan sí wọn, tí òun yóò fọwọ́ ara òun yàn. Jèhófà wí fún wọn pé: “Èmi ti fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀. Ìdájọ́ òdodo fún àwọn orílẹ̀-èdè ni ohun tí yóò mú wá.” (Aísáyà 42:1-3) Kò sí olùṣàkóso kankan tí ó jẹ́ ènìyàn, tí ó tó ṣe irú ìpolongo gbígbòòrò bẹ́ẹ̀, ọ̀kan tí yóò túmọ̀ sí ìdájọ́ òdodo pípẹ́ títí fún gbogbo orílẹ̀-èdè. Ìlérí yìí ha ṣeé gbára lé bí? Ọwọ́ ha lè tẹ irú góńgó àrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀ bí?
Ìlérí Kan Tí A Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé
A lè gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí kan kìkì bí ẹni tí ó ṣe é bá ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Nínú ọ̀ràn yìí, Ọlọ́run Olódùmarè ni ó polongo pé “ìránṣẹ́” òun yóò gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ kárí ayé. Láìdàbí àwọn òṣèlú, Jèhófà kì í ṣe ìlérí lásán. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: ‘Kò ṣeé ṣe fún un láti purọ́.’ (Hébérù 6:18) Ọlọ́run fi ìtẹnumọ́ polongo pé: “Ohun tí mo ti pinnu láti ṣe yóò di ṣíṣe.”—Aísáyà 14:24, Today’s English Version.
Àkọsílẹ̀ “ìránṣẹ́” tí Ọlọ́run yàn, Jésù Kristi, fún ìgbọ́kànlé wa nínú ìlérí yẹn lókun. Ẹni tí ó gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, kí ó sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Jésù fi àkọsílẹ̀ tí kò lábààwọ́n lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ‘nífẹ̀ẹ́ òdodo tí ó sì kórìíra ìwà àìlófin.’ (Hébérù 1:9) Ohun tí ó sọ, ìgbésí ayé tí ó gbé, àti bí ó ṣe kú pàápàá, gbogbo rẹ̀ fi hàn pé ní tòótọ́ ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. Nígbà tí Jésù kú, àánú rẹ̀ ṣe ọmọ ogun Róòmù kan, tí ó hàn gbangba pé ìgbẹ́jọ́ Jésù àti bí a ṣe pa á ṣojú rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ní ti tòótọ́, olódodo ni ọkùnrin yìí.”—Lúùkù 23:47.
Yàtọ̀ sí pé òun fúnra rẹ̀ gbé ìgbé òdodo, Jésù kò fara mọ́ àìṣèdájọ́ òdodo tí ó gbilẹ̀ ní ọjọ́ rẹ̀. Kì í ṣe ìdìtẹ̀gbàjọba tàbí ìyípadà tegbò tigaga ni ó fi ṣe é, bí kò ṣe nípasẹ̀ kíkọ́ gbogbo ẹni tí ó bá létíìgbọ́ ní ìdájọ́ òdodo tòótọ́. Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè jẹ́ àlàyé kan tí ó múná dóko nípa bí a ṣe lè máa ṣe òdodo àti ìdájọ́ òdodo.—Mátíù, orí 5 sí 7.
Jésù ṣe ohun tí ó wàásù. Kò tẹ́ńbẹ́lú àwọn adẹ́tẹ̀ tí kò-rí-bátiṣé, “àwọn má-fọwọ́-kàn” láwùjọ àwọn Júù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó bá wọn sọ̀rọ̀, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó sì mú wọn lára dá. (Máàkù 1:40-42) Gbogbo àwọn tí ó bá pàdé, títí kan àwọn òtòṣì àti àwọn tí a ni lára, ni ó kà sí ẹni pàtàkì. (Mátíù 9:36) Ó wí fún wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.”—Mátíù 11:28.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jésù kọ̀ láti jẹ́ kí àìṣèdájọ́ òdodo tí ó yí i ká ba ìwà òun jẹ́ tàbí kí ó mú kí òun fara ya. Kò fi búburú san búburú rí. (1 Pétérù 2:22, 23) Àní nígbà tí ó wà nínú ìrora gógó pàápàá, ó gbàdúrà sí Baba rẹ̀ ọ̀run nítorí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n kàn án mọ́gi. Ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Baba, dárí jì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” (Lúùkù 23:34) Dájúdájú, Jésù ‘mú ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ṣe kedere fún àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Mátíù 12:18) Ẹ̀rí ńlá mìíràn wo yàtọ̀ sí ti àpẹẹrẹ ṣíṣe kedere ti Ọmọ rẹ̀ ni a tún ní nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní láti gbé ayé onídàájọ́ òdodo kan kalẹ̀?
A Lè Borí Àìṣèdájọ́ Òdodo
Ẹ̀rí ṣíṣe kedere pé ó ṣeé ṣe láti ṣẹ́pá àìṣèdájọ́ òdodo tún wà nínú ayé lónìí. Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, àti gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tiraka láti ṣẹ́gun ẹ̀tanú, ojúsàájú, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àti ìwà ipá. Gbé àpẹẹrẹ tí ó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
Pedroa gbà gbọ́ pé ìwà ìdìtẹ̀gbàjọba ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti gbà mú ìdájọ́ òdodo wá fún Orílẹ̀-Èdè Basque, ẹkùn ilẹ̀ Sípéènì níbi tí òun ń gbé. Nítorí èyí, ó di mẹ́ńbà àjọ apániláyà tí ó kọ́ ọ níṣẹ́ jagunjagun ní ilẹ̀ Faransé. Gbàrà tí ó parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, a pàṣẹ pé kí ó dá ẹgbẹ́ apániláyà kan sílẹ̀, kí ó sì run bárékè ọlọ́pàá kan. Ṣe ni àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣì ń múra ohun tí wọn yóò fi run ibẹ̀ nígbà tí ọwọ́ ṣìnkún àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ ẹ́. Ó fi ẹ̀wọ̀n oṣù 18 jura, kódà nígbà tí ó ń fimú dánrin pàápàá ó ṣì ń bá ìgbòkègbodò òṣèlú rẹ̀ lọ, ó ń febi para rẹ̀, nígbà kan ó ṣá ara rẹ̀ lọ́gbẹ́ ní ọrùn ọwọ́.
Pedro rò pé òun ń jà fún ìdájọ́ òdodo. Lẹ́yìn náà ni ó wá mọ Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀. Nígbà tí Pedro wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, aya rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà tí wọ́n sì tú u sílẹ̀, aya rẹ̀ rọ̀ ọ́ láti wá sí ọ̀kan nínú ìpàdé wọn. Ó gbádùn ìjókòó náà tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ní kí a máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó sún un láti ṣe ìyípadà ńláǹlà nínú ojú ìwòye rẹ̀ àti nínú ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀. Àbálọ-àbábọ̀ rẹ̀, ní ọdún 1989, Pedro àti aya rẹ̀ ṣèrìbọmi.
Pedro sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé n kò pa ẹnikẹ́ni ní àwọn ọdún tí mo fi jẹ́ apániláyà. Wàyí o, mo ń lo ìdá ẹ̀mí Ọlọ́run, Bíbélì, láti fún àwọn ènìyàn ní ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo tòótọ́—ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” Láìpẹ́ yìí Pedro, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nísinsìnyí, ṣèbẹ̀wò sí bárékè náà gan-an tí ó pète láti run níjelòó. Lọ́tẹ̀ yìí, ète wíwàásù ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà fún àwọn ìdílé tí ń gbé níbẹ̀ ni ó bá lọ.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe àwọn ìyípadà wọ̀nyí nítorí pé wọ́n ń yán hànhàn fún ayé òdodo. (2 Pétérù 3:13) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìlérí Ọlọ́run láti mú èyí wá, wọ́n mọ̀ pé ojúṣe wọn ni láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo. Bíbélì ti fi hàn wá ní kedere pé Ọlọ́run ń retí pé kí àwa pẹ̀lú ṣe ipa tiwa.
Fífún Irúgbìn Òdodo
Lóòótọ́, nígbà tí a bá dojú kọ àìṣèdájọ́ òdodo, a lè ní ìtẹ̀sí láti ké jáde pé: “Ibo ni Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo wà?” Igbe tí àwọn Júù ké ní ọjọ́ Málákì nìyẹn. (Málákì 2:17) Ọlọ́run ha ka àròyé wọn sí èyí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bí? Ní òdìkejì pátápátá, ó dá a “lágara” nítorí pé, díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe ni pé, àwọn fúnra wọn ń ṣe àdàkàdekè sí àwọn aya wọn tí wọ́n ti dàgbà, wọ́n ń kọ̀ wọ́n sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí kò tó nǹkan. Jèhófà sọ àníyàn rẹ̀ lórí ‘aya ìgbà èwe wọn, tí wọ́n ti ṣe àdàkàdekè sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ẹnì kejì wọn àti aya májẹ̀mú wọn.’—Málákì 2:14.
A ha lè lẹ́nu àtiṣàròyé nípa àìṣèdájọ́ òdodo bí àwa alára kò bá ṣèdájọ́ òdodo bí? Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí a bá ń gbìyànjú láti fara wé Jésù nípa mímú ẹ̀tanú àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kúrò lọ́kàn wa, nípa jíjẹ́ ẹni tí kì í ṣojúsàájú, tí ó ń fi ìfẹ́ hàn sí kóówá, tí kì í sì í fi búburú san búburú, a ń fi hàn pé ní tòótọ́, a nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.
Bí a óò bá ká ìdájọ́ òdodo, Bíbélì rọ̀ wá láti ‘fún irúgbìn ní òdodo.’ (Hóséà 10:12) Láìka bí ó ṣe lè dà bí ohun kékeré sí, ṣíṣẹ́gun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bá ṣẹ́gun àìṣèdájọ́ òdodo ṣe pàtàkì. Gẹ́gẹ́ bí Martin Luther King, kékeré ti kọ nínú ìwé rẹ̀ Letter From Birmingham Jail, “àìṣèdájọ́ òdodo níbikíbi jẹ́ ewu fún ìdájọ́ òdodo níbi gbogbo.” Àwọn tí ń “wá òdodo” ni àwọn wọnnì tí Ọlọ́run yóò yàn láti jogún ayé tuntun ti òdodo tí yóò dé láìpẹ́.—Sefanáyà 2:3.
A kò lè gbé ìrètí wa fún ìdájọ́ òdodo ka ìpìlẹ̀ tí ń mì, ti ìlérí ènìyàn, síbẹ̀ a lè gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún dídé Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 6:9, 10) Jésù, Ọba Ìjọba náà tí a ti yàn, “yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.”—Sáàmù 72:12, 13.
Ó ṣe kedere pé, àìṣèdájọ́ òdodo kò ní máa bá a lọ títí. Ìṣàkóso Kristi lórí gbogbo ayé yóò ṣẹ́gun àìṣèdájọ́ òdodo títí láé, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti mú un dá wa lójú nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà pé: “Àkókò náà ń bọ̀ nígbà tí èmi yóò mú ìlérí tí mo ṣe ṣẹ . . . Ní àkókò náà èmi yóò yan olódodo àtọmọdọ́mọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba. Ọba náà yóò sì ṣe ohun tí ó tọ́ àti ìdájọ́ òdodo jákèjádò ilẹ̀ náà.”—Jeremáyà 33:14, 15, TEV.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ àfidípò