Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 17:20 ti sọ, àwọn àpọ́sítélì kò lè wo ọmọdékùnrin kan sàn ‘nítorí ìgbàgbọ́ wọn kéré.’ Ṣùgbọ́n nínú Máàkù 9:29, a so àìlágbára wọn mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbígbàdúrà. Èé ṣe tí àwọn ìdí tí a sọ nínú ìwé Ìhìn Rere wọ̀nyí fi yàtọ̀ síra?
Ní gidi, àkọsílẹ̀ méjèèjì wulẹ̀ ń ṣàfikún ara wọn ni, wọn kò ta kora. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wo Mátíù 17:14-20. Ọkùnrin kan ròyìn pé ọmọkùnrin òun jẹ́ alárùn wárápá ṣùgbọ́n pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò lè wò ó sàn. Lẹ́yìn èyí, Jésù wo ọmọdékùnrin náà sàn nípa líle ẹ̀mí èṣù tí ń bá a jà jáde. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn béèrè ìdí tí àwọn kò fi lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Mátíù ti sọ, Jésù fèsì pé: “Nítorí ìgbàgbọ́ yín tí ó kéré ni. Nítorí lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì, ẹ ó sọ fún òkè ńlá yìí pé, ‘Ṣípò kúrò ní ìhín lọ sí ọ̀hún,’ yóò sì ṣípò, kò sì sí ohunkóhun tí kì yóò ṣeé ṣe fún yín.”
Wàyí o, wo Máàkù 9:14-29, níbi tí a ti rí kúlẹ̀kúlẹ̀ púpọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, Máàkù 9:17 fún wa ní kúlẹ̀kúlẹ̀ náà pé nínú ọ̀ràn yìí ẹ̀mí búburú kan ni ó fa àrùn wárápá tí ó gbá a mú náà. Ó yẹ fún àfiyèsí pé Bíbélì sọ níbòmíràn pé Jésù wo àwọn ènìyàn alárùn wárápá àti ẹlẹ́mìí èṣù sàn. (Mátíù 4:24) Nínú irú ipò tí ó yàtọ̀ yìí, “ẹ̀mí tí kò lè sọ̀rọ̀, tí ó sì dití,” ẹ̀mí burúkú, tí Lúùkù oníṣègùn jẹ́rìí sí ni ó fa àrùn náà. (Lúùkù 9:39; Kólósè 4:14) Ṣàkíyèsí àpólà ọ̀rọ̀ náà nínú Máàkù 9:18 tí ó wí pé: “Ibikíbi tí ó [ẹ̀mí èṣù náà] bá ti gbá a mú.” Nítorí náà kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ẹ̀mí èṣù máa ń yọ ọmọ náà lẹ́nu, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni. Síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, kí wọ́n sì wo ọmọ náà sàn. Nígbà tí wọ́n bi í pé, èé ṣe, Jésù fèsì pé: “Irú èyí kò lè jáde nípasẹ̀ ohunkóhun àyàfi nípasẹ̀ àdúrà.”
Ṣùgbọ́n, fífarabalẹ̀ ka àkọsílẹ̀ Máàkù fi hàn pé kò tako àkọsílẹ̀ Mátíù. Nínú Máàkù 9:19, a kà pé Jésù kédàárò nípa ìran aláìnígbàgbọ́ yẹn. Ní ẹsẹ 23, a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ pé ó wí fún baba ọmọ náà pé: “Ohun gbogbo lè rí bẹ́ẹ̀ fún ẹnì kan bí ẹni náà bá ní ìgbàgbọ́.” Nítorí náà, Máàkù tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì níní ìgbàgbọ́. Ẹsẹ 29 nìkan ni Máàkù ti pèsè àfikún kúlẹ̀kúlẹ̀. Máàkù fi ohun tí Jésù sọ nípa àdúrà kún un, èyí tí Mátíù tàbí Lúùkù kò sì fi kún tiwọn.
Nítorí náà, kí ni a lè sọ? Ní àkókò mìíràn àwọn àpọ́sítélì 12 àti àwọn 70 ọmọ ẹ̀yìn lé àwọn ẹ̀mí búburú jáde. (Máàkù 3:15; 6:13; Lúùkù 10:17) Ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn yìí àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò lè lé ẹ̀mí èṣù jáde. Èé ṣe? Bí a bá pa àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí a mẹ́nu kàn nínú àkọsílẹ̀ méjèèjì pọ̀, ó ṣeé ṣe kí a parí èrò sí pé nínú ọ̀ràn yìí wọn kò múra sílẹ̀ tó láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bóyá apá kan ìṣòro náà jẹ́ nítorí irú ẹ̀mí èṣù tí ọ̀rọ̀ kàn, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìṣe, ìfẹ́, àti agbára àwọn ẹ̀mí èṣù lè yàtọ̀ síra. Nínú ọ̀ràn yìí, ó ń béèrè ìgbàgbọ́ tí ó lágbára gan-an àti àdúrà gbígbóná janjan fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Dájúdájú, Jésù ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ó tún ní ìtìlẹ́yìn Olùgbọ́ àdúrà, Baba rẹ̀. (Sáàmù 65:2) Kì i ṣe pé Jésù lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde nìkan ni ṣùgbọ́n ó ṣe bẹ́ẹ̀.