ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 5/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • A Mú Ọmọdekunrin Tí O Ni Ẹ̀mí Buburu Láradá
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jésù Wo Ọmọkùnrin Tí Ẹ̀mí Èṣù Ń Yọ Lẹ́nu Sàn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu ní Kápánáúmù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 5/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Bí Kristẹni kan bá ń gbọ́ ohùn, ǹjẹ́ ìyẹn wá fi dandan túmọ̀ sí pé ẹ̀mí èṣù ló ń gbógun tì í?

Rárá o. Bá a tiẹ̀ ti gbọ́ ìròyìn pé àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń pa irú itú yẹn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn tó ti gbọ́ ohùn tàbí tí wọ́n ti ní àwọn ìmọ̀lára mìíràn tó ń yọ wọ́n lẹ́nu, tí kò sì ṣeé ṣàlàyé, ni àyẹ̀wò ti fi hàn pé àìsàn kan ló ń fà á.

Kódà ní ọ̀rúndún kìíní pàápàá, ó hàn kedere pé àwọn èèyàn gbà pé ẹ̀mí èṣù àti àìsàn máa ń fa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn. Nínú ìwé Mátíù 17:14-18, a kà nípa ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí Jésù mú lára dá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọkùnrin náà ní àmì àrùn wárápá, síbẹ̀ ẹ̀mí èṣù ló ń fìyà jẹ ẹ́. Àmọ́, ní àkókò kan ṣáájú ìgbà yẹn, nígbà tí wọ́n kó ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ń jẹ̀rora wá sọ́dọ̀ Jésù fún ìwòsàn, “àwọn tí ẹ̀mí èṣù sọ di òǹdè àti alárùn wárápá” wà lára wọn. (Mátíù 4:24) Ó wá hàn kedere pé àwọn alárùn wárápá kan wà tí kì í ṣe ẹ̀mí èṣù ló ń bá wọn jà. Tó jẹ́ pé àìsàn ló kàn ń ṣe wọ́n.

A tún gbọ́ pé àwọn tó ní oríṣi àrùn kan tó jẹ mọ́ ọpọlọ dídàrú, ìyẹn àrùn kan tó ṣeé tọ́jú nípa lílo egbòogi, máa ń gbọ́ ohùn tàbí kí wọ́n ní àwọn àmì àrùn mìíràn tó lè dà bí ohun abàmì kan.a Àwọn ìṣòro mìíràn tún lè da èèyàn lórí rú nígbà mìíràn táwọn kan á sì wá máa fi àṣìṣe ronú pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló fà á. Nítorí náà, bí ẹnì kan tó sọ pé òun ń gbọ́ ohùn tàbí tó ń ní àwọn ìmọ̀lára mìíràn tó ń yọ ọ́ lẹ́nu bá sáà ń tẹnu mọ́ ọn pé ẹ̀mí èṣù ló ń fòòró òun, síbẹ̀ ó yẹ ká gba onítọ̀hún níyànjú pé kó lọ fún àyẹ̀wò ní ọsibítù, bóyá irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ á lè fi ohun tó fà á tó fi ń ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ hàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo “Mímú Ohun-ijinlẹ inu Àmódi Ọpọlọ Kuro,” tó wà nínú Jí! ti March 8, 1987, ìyẹn ìwé ìròyìn tó ṣìkejì Ilé Ìṣọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́