Èé Ṣe Tí Àìní Ìgbọ́kànlé Fi Ń gbilẹ̀?
‘ǸJẸ́ ẹnikẹ́ni ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé lóde òní?’ O lè ti gbọ́ tí àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó ti ní ìjákulẹ̀ ń béèrè ìbéèrè yìí. Ó tilẹ̀ ṣeé ṣe kí ìwọ gan-an ti béèrè ìbéèrè náà nígbà tí o bá ní ìṣòro tàbí tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ.
Kò ṣeé sẹ́ pé àwọn ènìyàn kò ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn àjọ tí a dá sílẹ̀ àti àwọn ènìyàn mìíràn mọ́. Nígbà púpọ̀, àìní ìgbọ́kànlé yìí tọ́. Ǹjẹ́ ẹnì kankan ń retí pé kí àwọn òṣèlú mú àwọn ìlérí tí wọ́n ń ṣe ṣáájú ìdìbò ṣẹ ní gidi? Ìwádìí kan tí a ṣe láàárín 1,000 akẹ́kọ̀ọ́ ní Germany ní 1990 fi hàn pé, nígbà tí ó dá ìpín 16.5 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn lójú pé àwọn òṣèlú lè yanjú àwọn ìṣòro àgbáyé, ìlọ́po méjì iye yẹn ló ṣiyèméjì gidigidi. Àwọn tó pọ̀ gan-an sì sọ pé àwọn kò ní ìgbọ́kànlé pé àwọn òṣèlú lè yanjú àwọn ìṣòro tàbí pé wọ́n fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ìwé ìròyìn Stuttgarter Nachrichten ṣàròyé pé: “Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òṣèlú kọ́kọ́ ń ronú nípa ire ara wọn, bó bá wá ṣeé ṣe, wọ́n lè ronú nípa ire àwọn tó dìbò yàn wọ́n.” Àwọn ènìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn gbà pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí. Ìwé ìròyìn The European sọ nípa orílẹ̀-èdè kan pé: “Àwọn ọ̀dọ́ kò gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òṣèlú nítorí ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ gan-an, àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú sì ṣe bákan náà.” Ó sọ pé ‘léraléra ni àwọn olùdìbò ń rọ àwọn ẹgbẹ́ lóyè.’ Ìwé ìròyìn náà sọ síwájú sí i pé: “Kíákíá ni àìní ìgbọ́kànlé àti àìní ìdarí àwọn ọ̀dọ́ [ibẹ̀] ń hàn sí ẹnikẹ́ni tó bá lo àkókò pẹ̀lú wọn.” Síbẹ̀, kò sí ohun tí ìjọba àfìbòyàn kan lè ṣe yọrí láìní ìgbọ́kànlé ará ìlú. Ààrẹ John F. Kennedy ti United States látijọ́ sọ nígbà kan pé: “Ìgbọ́kànlé àwọn ará ìlú ni ìpìlẹ̀ fún ìjọba tó pójú owó.”
Ní ti ìgbọ́kànlé nínú ọ̀ràn ìṣúnná, àwọn ìjórẹ̀yìn ọrọ̀ ajé àti àwọn ìwéwèé ìtètèdolówó tí ń dojú dé ti ń mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa lọ́ra. Nígbà tí ọjà ìpín ìdókòwò ilé iṣẹ́ ńlá lágbàáyé kò dúró sójú kan lọ́nà lílékenkà ní October 1997, ìwé ìròyìn kan sọ̀rọ̀ nípa “àìní ìgbọ́kànlé kíkàmàmà, tí kò sì ń bọ́gbọ́n mu nígbà mìíràn,” àti nípa “ìrànkálẹ̀ àìní ìgbọ́kànlé.” Ó tún sọ pé “ìgbọ́kànlé ti tán [ní orílẹ̀-èdè Éṣíà kan] débi tí ó fi jọ pé ìjọba náà . . . wà nínú ewu.” Ní àkópọ̀, ó sọ ohun tó ṣe kedere pé: “Ètò ọrọ̀ ajé gbára lé ìgbọ́kànlé.”
Ìsìn pẹ̀lú ń kùnà láti múni ní ìgbọ́kànlé. Ìwé ìròyìn ìsìn ní ilẹ̀ Germany náà, Christ in der Gegenwart, sọ̀rọ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn pé: “Ìgbọ́kànlé tí àwọn ènìyàn ní nínú Ṣọ́ọ̀ṣì túbọ̀ ń dín kù sí i.” Láàárín 1986 sí 1992, iye àwọn ará Germany tó ní ìgbọ́kànlé púpọ̀, tàbí tó ní ìwọ̀n tó jọjú díẹ̀, nínú ṣọ́ọ̀ṣì, dín kù láti ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún sí ìpín 33 nínú ọgọ́rùn-ún. Ní gidi, ní Ìlà Oòrùn Germany àtijọ́, ó dín kù sí iye tí kò tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún. Ní ọ̀nà kejì, àwọn tí ìgbọ́kànlé tí wọ́n ní nínú ṣọ́ọ̀ṣì kéré tàbí tí wọn kò ní ìgbọ́kànlé rárá nínú ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ sí i láti ìpín 56 nínú ọgọ́rùn-ún sí ìpín 66 nínú ọgọ́rùn-ún ní Ìwọ̀ Oòrùn Germany àtijọ́, ó sì pọ̀ dé ìpín 71 nínú ọgọ́rùn-ún ní Ìlà Oòrùn Germany àtijọ́.
Ó ṣe kedere pé ìgbọ́kànlé ń dín kù ní àwọn apá mìíràn yàtọ̀ sí ìṣèlú, ètò ìṣúnná, àti ìsìn—òpó mẹ́ta tó gbé àwùjọ ènìyàn ró. Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti ìgbófinró. Àwọn awúrúju ọ̀nà àbáyọ nínú àwọn òfin ọ̀ràn dídá, àwọn ìṣòro nínú lílo òfin bó ṣe tọ́, àti àwọn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tí ń ṣeni níyèméjì ti mú ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ènìyàn yìnrìn gidigidi. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Time ṣe wí, “ìjákulẹ̀ tí àwọn ará ìlú àti àwọn ọlọ́pàá ń ní ti dé àyè tí wọn kò fi ní ìgbọ́kànlé nínú ètò kan tí ń dá àwọn ọ̀daràn abèṣe sílẹ̀ lómìnira kúrò lẹ́wọ̀n léraléra.” Kódà, ìgbọ́kànlé nínú àwọn ọlọ́pàá ti yìnrìn nítorí àwọn ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìkà tí a fi ń kàn wọ́n.
Ní ti àjọṣe ọ̀ràn ìṣèlú láàárín ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn àdéhùn àlàáfíà tí ń forí ṣánpọ́n àti àwọn àdéhùn ìfòpinsíjà tí ń bà jẹ́ ń fi àìní ìgbọ́kànlé hàn. Bill Richardson, ikọ̀ United States nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tọ́ka ìdènà pàtàkì tí kò jẹ́ kí a lè ṣàṣeyọrí ọ̀ràn àlàáfíà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, nígbà tí ó sọ ní ṣákálá pé: “Kò sí ìgbọ́kànlé.”
Ní báyìí ná, ní ti ẹnì kọ̀ọ̀kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò tilẹ̀ ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn ìbátan tímọ́tímọ́ àti àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá, àwọn tí ó yẹ kí ènìyàn máa wò lọ́nà àdánidá fún òye àti ìtùnú ní àkókò ìṣòro. Ó rí bí ipò tí Míkà, wòlíì Hébérù náà, ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́lẹ́ pé: “Ẹ má ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú alábàákẹ́gbẹ́. Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rẹ́ àfinúhàn. Ṣọ́ líla ẹnu rẹ lọ́dọ̀ obìnrin tí ń dùbúlẹ̀ ní oókan àyà rẹ.”—Míkà 7:5.
Àmì Àkókò
Láìpẹ́ yìí, wọ́n fa ọ̀rọ̀ afìṣemọ̀rònú ará Germany náà, Arthur Fischer, yọ pé: “Níní ìgbọ́kànlé nínú ìtẹ̀síwájú àwùjọ àti ọjọ́ ọ̀la ẹni ti dín kù gan-an níhà gbogbo. Àwọn èwe ń ṣiyèméjì lórí bóyá àwọn ètò tí a gbé kalẹ̀ ní àwùjọ lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọn kò ní ìgbọ́kànlé mọ́, ì bá à jẹ́ nínú ìṣèlú, ìsìn, tàbí àjọ èyíkéyìí mìíràn.” Abájọ tí onímọ̀ ìbágbépọ̀-ẹ̀dá náà, Ulrich Beck, fi sọ̀rọ̀ nípa “àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ iyèméjì” síhà àwọn aláṣẹ tó ti wà tipẹ́, àwọn àjọ, àti àwọn ògbógi.
Nínú irú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn ń fẹ́ máa fà sẹ́yìn, kí wọ́n kọ gbogbo àṣẹ sílẹ̀, kí wọ́n sì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n tiwọn fúnra wọn, kí wọ́n máa dá ṣe ìpinnu láìgba ìmọ̀ràn tàbí ìdarí lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kan wá ń di ẹni tí ń fura jù, bóyá tí wọn kì í tilẹ̀ gba tẹlòmíràn rò nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn tí wọ́n rò pé àwọn kò lè fọkàn tán mọ́ ṣe nǹkan pọ̀. Ìwà yìí ń gbé ipò eléwu lárugẹ, irú èyí tí Bíbélì ṣàpèjúwe pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tímótì 3:1-5; Òwe 18:1) Lóòótọ́, àìní ìgbọ́kànlé tó gbilẹ̀ lóde òní jẹ́ àmì àkókò, àmì “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”
Nínú ayé tí àìní ìgbọ́kànlé ti gbilẹ̀, tí o sì kún fún àwọn ènìyàn tí ó rí bí a ti júwe rẹ̀ lókè yìí, a kò lè gbádùn ìgbésí ayé tó bó ṣe yẹ. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ a lè ronú ní gidi pé nǹkan yóò yí padà bí? Ǹjẹ́ a lè borí àìní ìgbọ́kànlé tó gbilẹ̀ lónìí bí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni, nígbà wo sì ni?