ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 10/15 ojú ìwé 13-19
  • Jerúsálẹ́mù—Ó Ha ‘Ré Kọjá Olórí Ìdí Tí O Ní fún Ayọ̀ Yíyọ̀ Bí’?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jerúsálẹ́mù—Ó Ha ‘Ré Kọjá Olórí Ìdí Tí O Ní fún Ayọ̀ Yíyọ̀ Bí’?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìbùkún àti Ẹrù Iṣẹ́
  • Àtakò Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Alámùúlégbè Wọn Tí Ń Jowú
  • Ìṣòro Abẹ́lé
  • Kíkọ́ Odi Jerúsálẹ́mù Parí
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Nehemáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Jerúsálẹ́mù Kan Tí Orúkọ Rò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Odi Jerúsálẹ́mù
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 10/15 ojú ìwé 13-19

Jerúsálẹ́mù—Ó Ha ‘Ré Kọjá Olórí Ìdí Tí O Ní fún Ayọ̀ Yíyọ̀ Bí’?

“Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu mi, . . . bí èmi kì yóò bá mú kí Jerúsálẹ́mù gòkè ré kọjá olórí ìdí tí mo ní fún ayọ̀ yíyọ̀.”—SÁÀMÙ 137:6.

1. Irú ẹ̀mí wo ni ọ̀pọ̀ Júù tí ó wà ní ìgbèkùn ní sí ìlú tí Ọlọ́run yàn?

NǸKAN bí àádọ́rin ọdún ti kọjá láti ìgbà tí àwọn Júù tí ó kọ́kọ́ ti ìgbèkùn dé ti padà sí Jerúsálẹ́mù ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Wọ́n ti tún tẹ́ńpìlì Ọlọ́run kọ́, ṣùgbọ́n ìlú náà ṣì wà ní ahoro. Láàárín àkókò náà, ìran tuntun ti dàgbà ní ìgbèkùn. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nínú wọn nímọ̀lára bí ti onísáàmù náà tí ó kọrin pé: “Bí èmi bá gbàgbé rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù, kí ọwọ́ ọ̀tún mi gbàgbé [ìlò rẹ̀].” (Sáàmù 137:5) Ohun tí àwọn kan ṣe kọjá wíwulẹ̀ rántí Jerúsálẹ́mù; ìgbésẹ̀ wọn fi hàn pé ó ti ga “ré kọjá olórí ìdí tí [wọ́n] ní fún ayọ̀ yíyọ̀.”—Sáàmù 137:6.

2. Ta ni Ẹ́sírà, báwo sì ni a ṣe bù kún un?

2 Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn àlùfáà Ẹ́sírà yẹ̀ wò. Àní kí ó tó padà sí Jerúsálẹ́mù pàápàá, ó ti fi ìtara ṣiṣẹ́ fún ire ìjọsìn tòótọ́ ti ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ yìí. (Ẹ́sírà 7:6, 10) Nítorí ìyẹn, a rọ̀jò ìbùkún sórí Ẹ́sírà. Jèhófà Ọlọ́run sún ọkàn-àyà ọba Páṣíà láti fún Ẹ́sírà láǹfààní láti ṣáájú àwùjọ àwọn ìgbèkùn kejì tí ń padà bọ̀ wálé wá sí Jerúsálẹ́mù. Ní àfikún sí i, ọba fún wọn ní ọrẹ wúrà àti fàdákà rẹpẹtẹ “láti ṣe ilé Jèhófà . . . lẹ́wà.”—Ẹ́sírà 7:21-27.

3. Báwo ni Nehemáyà ṣe fi hàn pé Jerúsálẹ́mù ni olórí àníyàn òun?

3 Ní nǹkan bí ọdún 12 lẹ́yìn náà, Júù mìíràn—Nehemáyà—gbé ìgbésẹ̀ akíkanjú. Ààfin Páṣíà ní Ṣúṣánì ni ó ti ń ṣiṣẹ́. Ó sì di ipò pàtàkì mú gẹ́gẹ́ bí agbọ́tí Atasásítà Ọba, ṣùgbọ́n ìyẹn kọ́ ni ‘olórí ìdí tí Nehemáyà ní fún ayọ̀ yíyọ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yán hànhàn fún lílọ sí Jerúsálẹ́mù, kí ó sì tún un kọ́. Ọ̀pọ̀ oṣù ni Nehemáyà fi ń gbàdúrà ṣáá nípa èyí, Jèhófà Ọlọ́run sì bù kún un fun ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Ọba Páṣíà gbọ́ nípa àníyàn Nehemáyà, ó pèsè ẹgbẹ́ ọmọ ogun fún un, ó sì fún un ní lẹ́tà àṣẹ láti tún Jerúsálẹ́mù kọ́.—Nehemáyà 1:1–2:9.

4. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé ìjọsìn Jèhófà ga ré kọjá ìdí èyíkéyìí tí a lè ní fun ayọ̀ yíyọ̀?

4 Láìsí àní-àní, Ẹ́sírà, Nehemáyà, àti ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn fi hàn pé ìjọsìn Jèhófà, tí a gbé kalẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù, jẹ àwọn lógún ju ohunkóhun mìíràn lọ—pé ó ‘ré kọjá olórí ìdí tí wọ́n ní fún yíyọ ayọ̀,’ ìyẹn ni pé, ó ju ohunkóhun mìíràn tí wọ́n lè tìtorí rẹ̀ máa yọ̀. Ẹ wo irú ìṣírí ńláǹlà tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ lónìí fún gbogbo àwọn tí wọ́n ń fojú pàtàkì kan náà wo Jèhófà, ìjọsìn rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ tí ẹ̀mí ń darí! Ṣe bẹ́ẹ̀ ni tìrẹ rí? Ìfaradà rẹ nínú àwọn iṣẹ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí ha fi hàn pé níní àǹfààní jíjọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n ti ṣe ìyàsímímọ́ nìkan ni olórí ìdí tí o ní láti máa yọ̀ bí? (2 Pétérù 3:11) Gẹ́gẹ́ bí ìṣírí síwájú sí i nípa rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò ìyọrísí rere tí ìrìn àjò Ẹ́sírà sí Jerúsálẹ́mù ní.

Àwọn Ìbùkún àti Ẹrù Iṣẹ́

5. Ìbùkún jìngbìnnì wo ni ó wá sórí àwọn olùgbé Júdà ní àwọn ọjọ́ Ẹ́sírà?

5 Àwùjọ tí ó tó nǹkan bí 6,000 òǹdè tí àwọn pẹ̀lú Ẹ́sírà jọ ń padà bọ̀ wálé mú ọrẹ wúrà àti fàdákà wá fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Iye rẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ tó nǹkan bí mílíọ̀nù 35 dọ́là. Èyí tó ìlọ́po méje wúrà àti fàdákà tí àwọn òǹdè tí wọ́n kọ́kọ́ dé rí mú wá. Ẹ wo bí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti Júdà yóò ti kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà tó láti rí gbogbo ìtìlẹ́yìn àwọn ènìyàn àti ìtìlẹ́yìn nípa ti ara wọ̀nyí gbà! Àmọ́ ṣá o, ìbùkún jìngbìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run máa ń mú ẹrù iṣẹ́ lọ́wọ́.—Lúùkù 12:48.

6. Kí ni Ẹ́sírà rí ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, báwo sì ni ó ṣe hùwà padà?

6 Láìpẹ́ Ẹ́sírà rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù, títí kan àwọn àlùfáà kan àti àwọn àgbà ọkùnrin kan, ti ré Òfin Ọlọ́run kọjá nípa fífẹ́ àwọn aya abọ̀rìṣà. (Diutarónómì 7:3, 4) Lọ́nà tí ó tọ́, ríré májẹ̀mú Òfin Ọlọ́run kọjá yìí kó ìdààmú bá a gan-an. “Gbàrà tí mo gbọ́ nípa nǹkan yìí, mo gbọn ẹ̀wù mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá ya, . . . mo sì jókòó tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu.” (Ẹ́sírà 9:3) Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ìdààmú bá tí wọ́n pésẹ̀ síbẹ̀, Ẹ́sírà tú ọkàn-àyà rẹ̀ jáde sí Jèhófà nínú àdúrà. Ní etígbọ̀ọ́ gbogbo wọn, Ẹ́sírà ṣàtúnyẹ̀wò àìgbọràn Ísírẹ́lì látẹ̀yìnwá àti ìkìlọ̀ Ọlọ́run nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ bí wọ́n bá lọ fi àwọn abọ̀rìṣà ilẹ̀ náà ṣe aya. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, olódodo ni ìwọ, nítorí pé a ti ṣẹ́ wa kù gẹ́gẹ́ bí olùsálà bí ó ti rí lónìí yìí. Àwa rèé níwájú rẹ nínú ẹ̀bi wa, nítorí pé kò ṣeé ṣe láti dúró níwájú rẹ ní tìtorí èyí.”—Ẹ́sírà 9:14, 15.

7. (a) Àpẹẹrẹ rere wo ni Ẹ́sírà fi lélẹ̀ ní ti bíbá àwọn oníwà àìtọ́ lò? (b) Báwo ni àwọn tí ó jẹ̀bi ṣe hùwà padà ní ọjọ́ Ẹ́sírà?

7 Ẹ́sírà lo ọ̀rọ̀ náà, “àwa.” Bẹ́ẹ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun alára kò jẹ̀bi, ó ka ara rẹ̀ mọ́ wọn. Ìrora ọkàn ńláǹlà tó dé bá Ẹ́sírà àti àdúrà onírẹ̀lẹ̀ rẹ̀ gún ọkàn àwọn ènìyàn náà ní kẹ́ṣẹ́, ó sì sún wọn láti ṣiṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà. Wọ́n gbà láti ṣàtúnṣe tí ó gba ìsapá gidigidi—gbogbo àwọn tí wọ́n ti ré Òfin Ọlọ́run kọjá yóò rán àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè wọn àti àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún wọn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ẹ́sírà fara mọ́ ìgbésẹ̀ yìí, ó sì rọ àwọn tí ó jẹ̀bi láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Nítorí ọlá àṣẹ tí ọba Páṣíà fún Ẹ́sírà, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti pa gbogbo àwọn arúfin tàbí kí ó lé wọn jáde ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà. (Ẹ́sírà 7:12, 26) Ṣùgbọ́n ó jọ pé kò ní láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. “Gbogbo ìjọ sì dáhùn” pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ó já lé wa léjìká láti ṣe.” Síwájú sí i, wọ́n jẹ́wọ́ pé: “Àwa ti ṣọ̀tẹ̀ gidi gan-an nínú ọ̀ràn yìí.” (Ẹ́sírà 10:11-13) Ẹ́sírà orí 10 to orúkọ àwọn ọkùnrin 111 tí wọ́n tẹ̀ lé ìpinnu náà láti dá àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè wọn àti àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún wọn padà.

8. Èé ṣe tí ìgbésẹ̀ onígírímọ́káì ti dídá àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè padà fi jẹ́ fún ire gbogbo aráyé?

8 Ìgbésẹ̀ yìí kì í ṣe fún ire Ísírẹ́lì nìkan ṣùgbọ́n ó jẹ́ fún ire gbogbo aráyé. Bí kò bá jẹ́ pé a wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà ni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá ti dà bí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀ ni, wọn ì bá ti kó àbààwọ́n bá ìlà ìran ti Irú-Ọmọ náà Tí A Ṣèlérí pé yóò bù kún gbogbo aráyé. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:18) Ì bá ṣòro láti dá Irú-Ọmọ Tí A Ṣèlérí náà mọ̀ pé ó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba, ti ẹ̀yà Júdà. Ní nǹkan bí ọdún 12 lẹ́yìn náà, a fún ọ̀ràn pàtàkì yìí ní àfiyèsí nígbà tí “àwọn irú-ọmọ Ísírẹ́lì . . . bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo ọmọ ilẹ̀ òkèèrè.”—Nehemáyà 9:1, 2; 10:29, 30.

9. Ìmọ̀ràn rere wo ni Bíbélì fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ti fẹ́ aláìgbàgbọ́?

9 Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní lè rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ yìí? Tóò, àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin. (2 Kọ́ríńtì 3:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣègbọràn sí “òfin Kristi.” (Gálátíà 6:2) Nípa báyìí, Kristẹni kan tí ó ti fẹ́ aláìgbàgbọ́ tẹ́lẹ̀ yóò ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi obìnrin náà sílẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:12) Síwájú sí i, Ìwé Mímọ́ sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún àwọn Kristẹni tí ó ti fẹ́ aláìgbàgbọ́ láti rí i pé ìgbéyàwó wọn yọrí sí rere. (1 Pétérù 3:1, 2) Ṣíṣe ìgbọràn sí ìmọ̀ràn àtàtà yìí lọ́pọ̀ ìgbà ti yọrí sí ìbùkún, débi pé àwọn aláìgbàgbọ́ ọkọ tàbí aya ti yí ọkàn wọn padà sí ìjọsìn tòótọ́. Àwọn kan tilẹ̀ ti di Kristẹni olùṣòtítọ́ tí a ti batisí.—1 Kọ́ríńtì 7:16.

10. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn Kristẹni rí kọ́ lára àwọn ọkùnrin 111 tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n dá àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n ti fẹ́ tẹ́lẹ̀ padà?

10 Síbẹ̀, ọ̀ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n dá àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè wọn padà pèsè ẹ̀kọ́ gidi fún àwọn Kristẹni àpọ́n. Kò yẹ kí àwọn wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹ̀yà òdì kejì tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ́nà. Yíyẹra fún irú ìbátan bẹ́ẹ̀ lè nira, ó tilẹ̀ lè béèrè ìsapá gidigidi pàápàá, ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀nà tí ó dára jù lọ kí èèyàn bàa lè máa rí ìbùkún Ọlọ́run gbà. A pàṣẹ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” (2 Kọ́ríńtì 6:14) Ó yẹ kí Kristẹni àpọ́n èyíkéyìí tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó wéwèé láti fẹ́ ojúlówó onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 7:39.

11. Bí ti àwọn ọkùnrin ọmọ Ísírẹ́lì wọnnì, báwo ni a ṣe lè dán wa wò nípa ìdí tí a ní fún ayọ̀ yíyọ̀?

11 Ní àwọn ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú, àwọn Kristẹni ti ṣàtúnṣe nígbà tí a bá mú un wá sí àfiyèsí wọn pé wọ́n ń forí lé ọ̀nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (Gálátíà 6:1) Láti ìgbà dé ìgbà, ìwé ìròyìn yìí ti fi àwọn ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu hàn, tí ó lè sọ ẹnì kan di ẹni tí kò tóótun mọ́ láti wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1973, àwọn ènìyàn Jèhófà wá lóye lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé ìjoògùnyó àti lílo tábà jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Láti tọ ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́, a gbọ́dọ̀ “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ọ̀pọ̀ ni ó fi irú ìmọ̀ràn Bíbélì bẹ́ẹ̀ sílò; wọ́n ṣe tán láti fara da ìnira àkọ́kọ́ tí jíjáwọ́ nínú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń mú wá, kí wọ́n bàa lè wà lára àwọn ènìyàn mímọ́ ti Ọlọ́run. Bákan náà ni a ti fúnni ní ìtọ́sọ́nà ṣíṣe kedere tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀, ìwọṣọ, ìmúra, fífi ọgbọ́n yan iṣẹ́, eré ìnàjú, àti orin. Ìlànà èyíkéyìí láti inú Ìwé Mímọ́ tí a bá mú wá sí àfiyèsí wa, ẹ jẹ́ kí a fi hàn pé a ṣe tán ‘láti gba ìtọ́sọ́nàpadà,’ bí ti àwọn ọkùnrin 111 tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì. (2 Kọ́ríńtì 13:11) Èyí yóò fi hàn pé àǹfààní jíjọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́ ‘ga ré kọjá olórí ìdí tí a ní fún ayọ̀ yíyọ̀.’

12. Kí ní ṣẹlẹ̀ ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa?

12 Lẹ́yìn ríròyìn ọ̀ràn àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè, Bíbélì kò sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 12 tí ó tẹ̀ lé e. Láìsí àní-àní, àwọn alámùúlégbè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá túbọ̀ di ọ̀tá wọn nítorí títú tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tú ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tí wọ́n ti ṣe ká. Ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa, Nehemáyà pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀ṣọ́ dé sí Jerúsálẹ́mù. A ti wá yàn án báyìí gẹ́gẹ́ bí gómìnà Júdà, ó sì gba lẹ́tà wá láti ọ̀dọ̀ ọba Páṣíà tí ó fún un láṣẹ láti tún ìlú náà kọ́.—Nehemáyà 2:9, 10; 5:14.

Àtakò Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Alámùúlégbè Wọn Tí Ń Jowú

13. Ìṣarasíhùwà wo ni àwọn onísìn èké tí wọ́n jẹ́ alámùúlégbè àwọn Júù fi hàn, báwo sì ni Nehemáyà ṣe hùwà padà?

13 Àwọn onísìn èké alámùúlégbè wọn ta ko ète tí Nehemáyà fi wá. Àwọn aṣáájú wọn halẹ̀ mọ́ ọn, ní bíbèèrè pé: “Ṣe ọba ni ẹ̀yin ń ṣọ̀tẹ̀ sí?” Nehemáyà fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Jèhófà, ó fèsì pé: “Ọlọ́run ọ̀run ni Ẹni tí yóò yọ̀ǹda àṣeyọrí sí rere fún wa, àti pé àwa fúnra wa, tí a jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, yóò dìde, a ó sì mọlé; ṣùgbọ́n ẹ̀yin fúnra yín kò ní ìpín kankan, tàbí ẹ̀tọ́ tí ó bá ìdájọ́ òdodo mu, tàbí ìrántí ní Jerúsálẹ́mù.” (Nehemáyà 2:19, 20) Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tún odi náà kọ́, àwọn ọ̀tá kan náà tún fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé: ‘Kí ni àwọn Júù ahẹrẹpẹ ń ṣe? Wọn yóò ha mú àwọn òkúta sọ jí láti inú òkìtì pàǹtí bí? Bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lásán bá kọ lu odi náà, kò ha ní dà á wó bí.’ Kàkà tí Nehemáyà yóò fi fèsì ọ̀rọ̀ yìí, ó gbàdúrà pé: “Gbọ́, ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí a ti di ẹni ìfojú-tín-ín-rín; dá ẹ̀gàn wọn padà sórí wọn.” (Nehemáyà 4:2-4) Láìdẹwọ́, Nehemáyà fi àpẹẹrẹ rere yìí lélẹ̀ ní ti gbígbáralé Jèhófà!—Nehemáyà 6:14; 13:14.

14, 15. (a) Báwo ni Nehemáyà ṣe yanjú ọ̀ràn ìwà ipá tí àwọn ọ̀tá fẹ́ fi mú wọn láyà pámi? (b) Báwo ni ó ti ṣeé ṣe fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa bá iṣẹ́ ìkọ́lé nípa tẹ̀mí wọn lọ láìfi àtakò gbígbóná janjan pè?

14 Láti lè ṣàṣeparí iṣẹ́ pàtàkì ti wíwàásù tí a yàn fún wọn, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí pẹ̀lú gbára lé Ọlọ́run. Àwọn alátakò ń gbìyànjú láti di iṣẹ́ yìí lọ́wọ́ nípa ṣíṣe yẹ̀yẹ́. Nígbà mìíràn, àwọn kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ń juwọ́ sílẹ̀ nítorí pé wọn kò lè fara da ìfiṣẹ̀sín. Bí ìfiṣẹ̀sín bá kùnà, inú lè bí àwọn alátakò, wọ́n sì lè yíjú sí fífi ìwà ipá múni láyà pámi. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ń kọ́ odi Jerúsálẹ́mù nìyẹn. Ṣùgbọ́n Nehemáyà kò jẹ́ kí a mú ohun láyà pámi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mú kí àwọn tí ń kọ́ ilé náà dìhámọ́ra nítorí ogun ọ̀tá, ó sì fún ìgbàgbọ́ wọn lókun ní sísọ pé: “Ẹ má fòyà ní tìtorí wọn. Jèhófà Ẹni ńlá tí ń múni kún fún ẹ̀rù ni kí ẹ fi sọ́kàn yín; kí ẹ sì jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn aya yín àti ilé yín.”—Nehemáyà 4:13, 14.

15 Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Nehemáyà, a ti mú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbára dì dáradára láti máa bá iṣẹ́ ilé kíkọ́ nípa tẹ̀mí nìṣó láìfi àtakò gbígbóná janjan pè. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun, tí ó ran àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ láti méso jáde àní ní àwọn ibi tí a ti fòfin de iṣẹ́ náà pàápàá. (Mátíù 24:45) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, Jèhófà ń bá a nìṣó láti fi ìbísí jákèjádò ilẹ̀ ayé bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀.—Aísáyà 60:22.

Ìṣòro Abẹ́lé

16. Àwọn ìṣòro abẹ́lé wo ni ó fẹ́ bomi paná ẹ̀mí àwọn tí ń kọ́ odi Jerúsálẹ́mù?

16 Bí títún odi Jerúsálẹ́mù kọ́ ti ń tẹ̀ síwájú, tí odi náà sì ń ga sí i, bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ náà túbọ̀ ń nira sí i. Ìgbà yẹn ni ìṣòro kan tí ó fẹ́ bomi paná ẹ̀mí àwọn kọ́lékọ́lé tí ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ náà jẹyọ. Nítorí ọ̀wọ́n oúnjẹ, ó ṣòro fún àwọn Júù kan láti pèsè oúnjẹ fún ìdílé wọn kí wọ́n sì san owó orí fún ìjọba Páṣíà. Àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí yáni ní oúnjẹ àti owó. Ṣùgbọ́n, ní ìlòdì sí Òfin Ọlọ́run, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ tálákà ní láti fi ilẹ̀ àti ọmọ wọn dógò, gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró pé àwọn yóò san owó náà padà pẹ̀lú èlé. (Ẹ́kísódù 22:25; Léfítíkù 25:35-37; Nehemáyà 4:6, 10; 5:1-5) Wàyí o, àwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ wọn láti gba ilẹ̀ wọ́n mọ́ wọn lọ́wọ́, wọ́n sì fẹ́ fipá mú wọn láti ta àwọn ọmọ wọn lẹ́rú. Ìwà ìkà àti ti onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì yìí bí Nehemáyà nínú gan-an. Kíá ni ó gbégbèésẹ̀ láti rí i dájú pé ìbùkún Jèhófà lórí iṣẹ́ títún odi Jerúsálẹ́mù kọ́ kò dáwọ́ dúró.

17. Kí ni Nehemáyà ṣe láti rí i dájú pé Jèhófà kò dáwọ́ ìbùkún rẹ̀ lórí iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?

17 Nehemáyà ṣètò “àpéjọ ńlá,” ó sì fi han àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ pé ohun tí wọ́n ṣe kò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Lẹ́yìn náà, ó rọ àwọn tí wọ́n jẹ̀bi, títíkan àwọn àlùfáà kan, láti dá gbogbo èlé tí wọ́n ti gbà padà, kí wọ́n sì dá ilẹ̀ tí wọ́n ti fi èrú gbà lọ́wọ́ àwọn tí kò rí èlé san padà. Lọ́nà tí ó yẹ fún ìgbóríyìn, àwọn tí wọ́n jẹ̀bi wí pé: “Àwa yóò ṣe ìmúpadàbọ̀sípò, a kò sì ní béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn padà. A ó ṣe gẹ́lẹ́ bí o ti sọ.” Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, nítorí Bíbélì ròyìn pé “àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ [Nehemáyà].” Gbogbo ìjọ náà sì yin Jèhófà.—Nehemáyà 5:7-13.

18. Ẹ̀mí wo ni a ti mọ̀ mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo?

18 Ọjọ́ tiwa lónìí ńkọ́? Kàkà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fi jẹ́ arẹ́nijẹ, a mọ̀ wọ́n níbi gbogbo fún ìwà ọ̀làwọ́ wọn sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti sí àwọn mìíràn tí ìpọ́njú dé bá. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Nehemáyà, èyí ti yọrí sí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìyìn tí ó kún fún ìmoore sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n, lọ́wọ́ kan náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti rí i pé ó pọndandan láti pèsè ìmọ̀ràn tí a gbé ka Ìwé Mímọ́ nípa ọ̀ràn okòwò àti nípa ìjẹ́pàtàkì yíyẹra fún jíjẹ́ kí ìwọra sún wa láti rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ. Ní àwọn ilẹ̀ kan, ó wọ́pọ̀ láti béèrè fún owó orí ìyàwó tí ó pọ̀ gan-an, ṣùgbọ́n Bíbélì kìlọ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere pé, àwọn oníwọra àti alọ́nilọ́wọ́gbà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ọ̀nà rere tí ọ̀pọ̀ jù lọ Kristẹni gbà ń dáhùn padà sí irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ń ránni létí bí àwọn Júù wọnnì ṣe rí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú rírẹ́ àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ́ tálákà jẹ.

Kíkọ́ Odi Jerúsálẹ́mù Parí

19, 20. (a) Ipa wo ni píparí odi Jerúsálẹ́mù ní lórí àwọn onísìn tí wọ́n jẹ́ alátakò? (b) Ìṣẹ́gun wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ní ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀?

19 Láìfi gbogbo àtakò náà pè, a parí kíkọ́ odi Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ 52. Ipa wo ni èyí ní lórí àwọn alátakò? Nehemáyà wí pé: “Gbàrà tí gbogbo ọ̀tá wa gbọ́ nípa rẹ̀, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká sì rí i, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì púpọ̀, wọ́n sì wá mọ̀ pé láti ọwọ́ Ọlọ́run wa ni a ti ṣe iṣẹ́ yìí.”—Nehemáyà 6:16.

20 Lónìí, àtakò àwọn ọ̀tá sí iṣẹ́ Ọlọ́run ń bá a nìṣó ní onírúurú ọ̀nà àti ọ̀pọ̀ ibi. Àmọ́ ṣá o, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti rí òmúlẹ̀mófo tí ó wà nínú títako Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn ìgbìyànjú láti mú iṣẹ́ ìwàásù wá sópin ní Germany ti ìjọba Nazi, ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù, àti ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Áfíríkà. Gbogbo irú ìsapá bẹ́ẹ̀ ti já sí pàbó, ọ̀pọ̀ ènìyàn nísinsìnyí sì ti wá gbà pé ‘láti ọwọ́ Ọlọ́run wa ni a ti ń ṣe iṣẹ́ wa.’ Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ èrè ńláǹlà tó fún àwọn tí wọ́n ti jẹ́ olóòótọ́ fún ìgbà pípẹ́ ní irú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀, tí wọ́n ti mú kí ìjọsìn Jèhófà ‘ga ré kọjá olórí ìdí tí wọn ní fún ayọ̀ yíyọ̀’!

21. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì wo ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?

21 Nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e, a óò ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì tí ó yọrí sí ìdùnnú ayẹyẹ yíya odi Jerúsálẹ́mù tí a tún kọ́ sí mímọ́. A óò sì tún ṣàgbéyẹ̀wò bí píparí ìlú ńlá kan tí ó tóbi gan-an ju ti ìṣáájú lọ ṣe ń sún mọ́lé fún àǹfààní gbogbo aráyé.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Báwo ni Ẹ́sírà àti àwọn mìíràn ṣe yọ̀ nítorí Jerúsálẹ́mù?

◻ Àwọn àṣìṣe wo ni Ẹ́sírà àti Nehemáyà ran ọ̀pọ̀ àwọn Júù lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe?

◻ Ẹ̀kọ́ wo ni o rí kọ́ láti inú àkọsílẹ̀ nípa Ẹ́sírà àti Nehemáyà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jerúsálẹ́mù ni ó jẹ Nehemáyà lógún jù lọ, kì í ṣe ipò pàtàkì tí ó dì mú ní Ṣúṣánì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Gẹ́gẹ́ bí Nehemáyà, ó yẹ kí a máa gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jèhófà àti okun láti máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìwàásù, iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ, tí a yàn fún wa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́