ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/1 ojú ìwé 30-31
  • Jésù Wá Àyè Gbọ́ ti Àwọn Ọmọdé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Wá Àyè Gbọ́ ti Àwọn Ọmọdé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Fayọ̀ Gba Àwọn Ọmọdé
  • Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
  • Ǹjẹ́ O Ní “Èrò Inú Kristi”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ogun Iyebíye Làwọn Ọmọ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ̀kọ́ Wo Lo Lè Rí Kọ́ Lára Àwọn Ọmọdé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ohun Tó Mú Kí Jésù Jẹ́ Olùkọ́ Ńlá
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/1 ojú ìwé 30-31

Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà

Jésù Wá Àyè Gbọ́ ti Àwọn Ọmọdé

IṢẸ́ òjíṣẹ́ ọlọ́dún mẹ́ta ààbọ̀ tí Jésù ṣe ń parí lọ. Láìpẹ́, yóò lọ sí Jerúsálẹ́mù, yóò sì kú ikú oró. Ó mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí òun dáradára, nítorí pé ó ti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọmọ ènìyàn ni a ó fi lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn yóò sì pa á.”—Máàkù 9:31.

Ó dájú pé, Jésù yóò fẹ́ lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, wákàtí kọ̀ọ̀kan, ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan, tó ṣẹ́ kù, lọ́nà tó ṣàǹfààní jù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń fẹ́ àfiyèsí rẹ̀. Jésù rí i pé wọ́n ṣì ń fẹ́ ìṣítí gidigidi nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti nípa ewu ṣíṣi ìwà hù tó wà nígbà gbogbo. (Máàkù 9:35-37, 42-48) Wọ́n tún ń fẹ́ ìtọ́ni nípa ìgbéyàwó, ìkọ̀sílẹ̀, àti wíwà ní àpọ́n. (Mátíù 19:3-12) Ó dájú pé Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní ṣàkó àti láìjáfara, bí ó ti mọ̀ pé òun yóò kú láìpẹ́. Àkókò ló ṣe pàtàkì jù nígbà náà—ìyẹn ló sì mú kí ohun tí Jésù ṣe lẹ́yìn náà túbọ̀ gbàfiyèsí.

Jésù Fayọ̀ Gba Àwọn Ọmọdé

Àkọsílẹ̀ Bíbélì wí pé: “Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè fọwọ́ kàn wọ́n.” Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, lọ́gán ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé kò dùn mọ́ wọn. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ronú pé Jésù ṣe pàtàkì ju ẹni tí í dá sí ọ̀ràn ọmọdé tàbí pé ọwọ́ rẹ̀ dí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ronú bí ó ti ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà lẹ́nu tó nígbà tí Jésù fi ìkannú bá wọn wí! Ó wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun, nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.” Jésù wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnì yòówù tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kì yóò wọ inú rẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Máàkù 10:13-15.

Jésù rí àwọn ànímọ́ wíwọnilọ́kàn lára àwọn ọmọdé. Wọ́n sábà máa ń wádìí nǹkan, wọ́n sì ń gbẹ́kẹ̀ léni. Wọ́n máa ń gba ohun tí àwọn òbí wọn bá wí, wọ́n sì máa ń gbèjà irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọmọ mìíràn. Gbogbo ẹni tó bá ń fẹ́ wọ Ìjọba Ọlọ́run yẹ kí ó fara wé ọ̀nà ìgbésí ayé wọn ní jíjẹ́ ẹni tí ń gba nǹkan gbọ́, tó sì ṣeé kọ́. Bí Jésù ṣe wí, “ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.”—Fi wé Mátíù 18:1-5.

Àmọ́ kì í ṣe pé Jésù wulẹ̀ fi àwọn ọmọdé wọ̀nyí ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ lásán ni. Àkọsílẹ̀ náà mú kí ó ṣe kedere pé Jésù ní ojúlówó ìfẹ́ sí wíwà pẹ̀lú wọn. Máàkù ròyìn pé, Jésù “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.” (Máàkù 10:16) Àkọsílẹ̀ Máàkù nìkan ló fúnni ní kúlẹ̀kúlẹ̀ amọ́kànyọ̀ náà pé, Jésù “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀.”a Jésù tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ju ohun tí àwọn àgbàlagbà tó mú wọn wá sọ́dọ̀ Jésù, kí ó wulẹ̀ lè “fọwọ́ kàn” wọ́n, retí lọ.

Kí ni ohun tó ṣe pàtàkì nínú pé, Jésù “gbé ọwọ́ rẹ̀” lé àwọn ọmọdé náà? Èyí kò túmọ̀ sí ayẹyẹ ìsìn kankan, bí ìbatisí. Nígbà tó jẹ́ pé, nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìgbọ́wọ́léni túmọ̀ sí yíyannisípò, nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, ó wulẹ̀ jẹ́ sísúre fúnni. (Jẹ́nẹ́sísì 48:14; Ìṣe 6:6) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Jésù wulẹ̀ ti máa súre fún àwọn ọmọ náà.

Èyí tó wù kó jẹ́, Máàkù lo ọ̀rọ̀ kan tó túbọ̀ rinlẹ̀ fún “ìre” (ka·teu·lo·geʹo), tó túmọ̀ sí pé ó jinlẹ̀ gan-an. Èyí túmọ̀ sí pé Jésù súre fún àwọn ọmọ náà tìtaratìtara, lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, àti tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Ó ṣe kedere pé, kò ka àwọn ọmọdé sí ẹni tí ń dani láàmú, tí ń fàkókò ẹni ṣòfò.

Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́

Ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà sí tèwetàgbà kì í ṣe ti ìdẹ́rùbani tàbí ti àfojúdi. Ìwé kan ṣàlàyé pé: “Ẹ̀rín músẹ́ ti gbọ́dọ̀ máa hàn lójú rẹ̀, kí ó sì máa rẹ́rìn-ín tayọ̀tayọ̀.” Abájọ tí ara fi ń rọ gbogbo ènìyàn tó bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀, láìka ọjọ́ orí wọn sí. Nígbà tí a bá ń ronú lórí àpẹẹrẹ Jésù, a lè bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn ẹlòmíràn ń kà mí sí ẹni tó ṣeé sún mọ́?’ ‘Ǹjẹ́ ó jọ pé ọwọ́ mi máa ń dí, débi tí n kì í kọbi ara sí ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń ṣe tàbí ohun tó ń ṣe wọn.’ Níní ìfẹ́ tòótọ́ lọ́kàn fún àwọn ènìyàn yóò mú kí a fẹ́ lo ara wa fún wọn, bí Jésù ti ṣe. Àwọn ẹlòmíràn yóò mọ ìfẹ́ tòótọ́ tí a ní, wọn yóò sì sún mọ́ wa.—Òwe 11:25.

Ìròyìn ti Máàkù ṣe fi hàn pé, Jésù gbádùn wíwà pẹ̀lú àwọn ọmọdé. Ó ṣeé ṣe kí ó ti ṣàkíyèsí wọn níbi tí wọ́n ti ń ṣiré, nítorí pé ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn eré tí wọ́n máa ń ṣe nínú ọ̀kan nínú àwọn àkàwé rẹ̀. (Mátíù 11:16-19) Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan nínú àwọn ọmọ tí Jésù súre fún ti kéré ju ẹni tó lè lóye ẹni tí ó jẹ́ tàbí ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ni. Ṣùgbọ́n èyí kò mú un ronú pé òun ń fi àkókò òun ṣòfò. Ó wá àyè gbọ́ ti àwọn ọmọdé nítorí pé ó fẹ́ràn wọn. Ó ṣeé kí ọ̀pọ̀ ọmọdé tí Jésù bá pàdé nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ padà wá dáhùn sí ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn náà nípa dídi ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.

Bí Jésù bá wá àyè gbọ́ ti àwọn ọmọdé ní àárín àwọn ọ̀sẹ̀ pàtàkì tó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, ó dájú pé, àwa náà lè wá àyè fún wọn nínú ìṣètò àkókò wa tó kún fọ́fọ́. Ní pàtàkì, ó yẹ kí a ronú nípa àwọn tí wọ́n ní àìní àrà ọ̀tọ̀, irú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí wọn kò ní baba. Dájúdájú, gbogbo ọmọdé máa ń ní láárí bí a bá fún wọn ní àfiyèsí, ó sì jẹ́ ìfẹ́-ọkàn Jèhófà pé kí a fún wọn ní gbogbo ìfẹ́ àti ìrànlọ́wọ́ tí a bá lè fún wọn.—Sáàmù 10:14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtumọ̀ kan sọ pé, Jésù “gbá wọn mọ́ra.” Òmíràn sọ pé ó “fi ìṣẹ́po apá rẹ̀ kó wọn mọ́ra.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́